કુરઆન મજીદના શબ્દોનું ભાષાંતર - યોરુબ્બા ભાષાતર * - ભાષાંતરોની અનુક્રમણિકા

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

શબ્દોનું ભાષાંતર સૂરહ: મરયમ   આયત:

Suuratu Mar'yam

كٓهيعٓصٓ
Kāf hā yā ‘aēn sọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
2. Àwọn nasọ̄rọ̄ sọ pé: “Fífi sūrah yìí sọrí Mọryam, ìyá ‘Īsā àti fífi sūrah kẹta, ìyẹn sūrah āli ‘Imrọ̄n, sọrí mọ̀lẹ́bí Mọryam ti fi hàn kedere pé, kò sí irú Mọryam nínú àwọn ẹ̀dá nítorí pé, kò tún sí sūrah kan kan mọ́ nínú al-Ƙur’ān tí Allāhu fi sọrí obìnrin mìíràn.” Wọ́n tún fi kún un pé, “Ṣebí kò sí sūrah tí wọ́n fi sọrí ìyá Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tàbí ìyàwó rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀.”
Èsì: Kí ni ìbátan orúkọ Mọryam, ìyá ‘Īsā àti jíjọ́sìn fún Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo? Kò sí. Allāhu tó dá Mọryam, ìyá ‘Īsā, Òun l’Ó ṣà á lẹ́ṣà. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Allāhu kò ṣe Mọryam ní Òjíṣẹ́ Rẹ̀.
Dípò kí òye àwọn nasọ̄rọ̄ lọ síbi pé, tí kò bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé jẹ́ òdodo pọ́nńbélé tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun, ìbá tí sọ àwọn òdodo wọ̀nyẹn nípa Mọryam, ìyá ‘Īsā. Ṣebí wọ́n kúkú fi ẹnu àbùkù kan Mọryam, ìyá ‘Īsā nínú Bíbélì, níbi tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Josẹfu gbẹ́nàgbẹ́nà, ẹni tí wọ́n kà kún ọkọ rẹ̀?
Tí ó bá jẹ́ pé fífi orúkọ sọrí sūrah kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé bá sọ ẹnikẹ́ni di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu, kì í kúkú ṣe Mọryam nìkan ni ẹ̀dá tí wọ́n fi sūrah kan sọrí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Kò sì pọn dandan láti rí orúkọ obìnrin mìíràn yàtọ̀ sí Mọryam nínú al-Ƙur’ān. Ṣebí ẹ̀dá ni Mọryam, ẹ̀dá ni àwọn mìíràn tí Allāhu fi sọrí àwọn sūrah ọ̀rọ̀ Rẹ̀. A kúkú rí sūrah Muhammad, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí sūrah Mọryam. Àmọ́, kò sí sūrah ‘Īsā. Níwọ̀n ìgbà tí kò sì sūrah ‘Īsā, tí kò sì tàbùkù Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -, bẹ́ẹ̀ náà ni kò tàbùkù obìnrin kan kan tí kò bá sí orúkọ rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān. Allāhu - tó ga jùlọ - kúkú fi òdidi sūrah kan sọrí gbogbo àwọn obìnrin, ìyẹn “sūrah an-Nisā’”. Tún wò ó, kò sì sí sūrah àwọn ọkùnrin. Ǹjẹ́ èyí yọ àwọn ọkùnrin kúrò nípò tí Allāhu fi ṣe àjùlọ fún wa lórí àwọn obìnrin bí? Rárá.
Ẹ jẹ́ kí á bi àwọn nasọ̄rọ̄ léèrè ìbéèrè pé, ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam, ìyá ‘Īsā sọ sūrah ló máa sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di olúwa àti olùgbàlà? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam, ìyá ‘Īsā sọ sūrah ló sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di ọlọ́hun ọmọ? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam, ìyá ‘Īsā sọ sūrah ló sọ ẹ̀sìn nasọ̄rọ̄ di ojúlówó ẹ̀sìn Allāhu, nígbà tí àwọn méjèèjì gan-an kò dá nasrọ̄niyyah mọ̀ lójú ayé wọn?
Tí ó bá jẹ́ pé nítorí pé wọ́n fi sūrah kan sọrí Mọryam, ìyá ‘Īsā lágbára tayọ “fífẹ́ bẹ́ẹ̀ Ọlọ́hun”, kí ni àwọn nasọ̄rọ̄ máa sọ nípa àwọn sūrah wọ̀nyí:
Sūrah al-Baƙọrah - sūrah 2, sūrah tí wọ́n fi sọrí màálù tí ìjọ Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - pa láti fi jí òkú dìde?
Sūrah an-Nahl - sūrah 16, sūrah tí wọ́n fi sọrí àwọn kòkòrò oyin?
Sūrah an-Naml - sūrah 27, sūrah tí wọ́n fi sọrí kòkòrò àwúrèbe (èèrà)?
Sūrah al-’Ankabūt - sūrah 29, sūrah tí wọ́n fi sọrí aláǹtakùn?
Sūrah al-Fīl - sūrah 105, sūrah tí wọ́n fi sọrí àwọn erin tí ìjọ Abraha gùn wá ja Kaabah lógun, àmọ́ tí Allāhu pa wọ́n rẹ́?
Ṣé sūrah Màálù sọ màálù di bùrọ̀dá ni tàbí súrah erin sọ erin di bàbá? Ṣé sūrah kòkòrò òyin sọ kòkòrò oyin di òrìṣà ni tàbí sūrah aláǹtakùn sọ aláǹtakùn di ọmọ ọlọ́hun ni? Rárá o!
Kókó ọ̀rọ̀ wa ni pé, Allāhu - tó ga jùlọ - kò pe Mọryam ní orúkọ kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé tayọ olódodo. Bákan náà, ṣíṣe tí Allāhu - tó ga jùlọ - ṣe Mọryam ní ẹ̀ṣà ènìyàn, àmọ́ tí Allāhu kò ṣe ìyá àti bàbá Ànábì wa bẹ́ẹ̀, kò sọ ọmọ Mọryam di olúwà àti olùgbàlà. Ìyá àti bàbá Ànábì ’Ibrọ̄him ńkọ́? Kò sí ẹni tó tàbùkù Ànábì ’Ibrọ̄hīm lórí ẹ̀sùn pé, wọn kò dárúkọ ìyá rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé tàbí pé wọn kò fi sūrah kan sọrí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ànábì Mūsā ńkọ́? Kò sí ẹni tó tàbùkù Ànábì Mūsā lórí ẹ̀sùn pé, wọn kò dárúkọ ìyá àti bàbá rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé tàbí pé wọn kò fi sūrah kan sọrí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé.
Tí wọ́n bá dárúkọ wọn nínú rẹ̀ ńkọ́ tàbí tí wọ́n bá fi orúkọ wọn sọrí àwọn sūrah kan nínú rẹ̀ ńkọ́, kí ni ìwọ̀nyí níí ṣe pẹ̀lú bí a ṣe fẹ́ jọ́sìn fún Allāhu? Bí a ṣe rí sūrah āli ‘Imrọ̄n, tí Allāhu fi sọrí ẹbí Mọryam, a kúkú rí sūrah Ƙuraeṣ, tí Allāhu fi sọrí ẹbí Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Gbogbo ìwọ̀nyí kò sọ ẹnikẹ́ni di ọmọ Ọlọ́hun. Gbogbo ìwọ̀nyí kò sọ ẹnikẹ́ni di olúwa àti olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu. Ṣíṣa ẹ̀dá kan lẹ́ṣà kò sì sí lọ́wọ́ ẹ̀dá. Allāhu l’Ó ń ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà.
Kíyè sí i, tí Allāhu - tó ga jùlọ - bá fi orúkọ ẹ̀dá kan sọrí sūrah kan tàbí Ó dárúkọ ẹ̀dá kan nínú al-Ƙur’ān, n̄ǹkan mẹ́ta kan gbọ́dọ̀ yé wa nípa rẹ̀ dáadáa.
Ìkíní: Kò gbọ́dọ̀ sí ẹ̀sùn fún Allāhu - tó ga jùlọ - lórí dídárúkọ àti àìdárúkọ ẹnì kan nínú al-Ƙur’ān rẹ̀. Bí Allāhu ṣe fẹ́ l’Ó ṣe.
Ìkejì: Òdodo tí kò ṣe é jà níyàn ni Allāhu - tó ga jùlọ - sọ nípa ẹ̀dá tí orúkọ rẹ̀ wà nínú al-Ƙur’ān nítorí pé, òdodo lọ̀rọ̀ Allāhu.
Ìkẹta: Ẹ̀kọ́ tí Allāhu - tó ga jùlọ - bá fẹ́ kọ́ wa lára ẹ̀dá Rẹ̀ náà ni orí ire tiwa nínú rẹ̀, kì í ṣe pé kí ẹnì kan wá lò ó lódì láti fi tako Allāhu - tó ga jùlọ -.
અરબી તફસીરો:
ذِكۡرُ رَحۡمَتِ رَبِّكَ عَبۡدَهُۥ زَكَرِيَّآ
(Èyí ni) ìrántí nípa ìkẹ́ tí Olúwa Rẹ ṣe fún ẹrúsìn Rẹ̀ (Ànábì) Zakariyyā.
અરબી તફસીરો:
إِذۡ نَادَىٰ رَبَّهُۥ نِدَآءً خَفِيّٗا
(Rántí) nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ ní ìpè ìkọ̀kọ̀.
અરબી તફસીરો:
قَالَ رَبِّ إِنِّي وَهَنَ ٱلۡعَظۡمُ مِنِّي وَٱشۡتَعَلَ ٱلرَّأۡسُ شَيۡبٗا وَلَمۡ أَكُنۢ بِدُعَآئِكَ رَبِّ شَقِيّٗا
Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú eegun ara mi ti lẹ, orí (mi) ti kún fún ewú, èmi kò sì níí pasán nípa bí mo ṣe ń pè Ọ́, Olúwa mi.
અરબી તફસીરો:
وَإِنِّي خِفۡتُ ٱلۡمَوَٰلِيَ مِن وَرَآءِي وَكَانَتِ ٱمۡرَأَتِي عَاقِرٗا فَهَبۡ لِي مِن لَّدُنكَ وَلِيّٗا
Àti pé dájúdájú mò ń páyà àwọn ìbátan mi lẹ́yìn (ikú) mi. Ìyàwó mi sì jẹ́ àgàn. Nítorí náà, ta mí lọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Rẹ ọmọ rere kan,
અરબી તફસીરો:
يَرِثُنِي وَيَرِثُ مِنۡ ءَالِ يَعۡقُوبَۖ وَٱجۡعَلۡهُ رَبِّ رَضِيّٗا
(tí) ó máa jogún mi, tí ó sì máa jogún àwọn ẹbí (Ànábì) Ya‘ƙūb. Kí O sì ṣe é ní ẹni tí O yọ́nú sí, Olúwa mi.”
અરબી તફસીરો:
يَٰزَكَرِيَّآ إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَٰمٍ ٱسۡمُهُۥ يَحۡيَىٰ لَمۡ نَجۡعَل لَّهُۥ مِن قَبۡلُ سَمِيّٗا
Zakariyyā, dájúdájú Àwa máa fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ ni Yahyā. A kò fún ẹnì kan ní (irú) orúkọ (yìí) rí ṣíwájú (rẹ̀).
અરબી તફસીરો:
قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَٰمٞ وَكَانَتِ ٱمۡرَأَتِي عَاقِرٗا وَقَدۡ بَلَغۡتُ مِنَ ٱلۡكِبَرِ عِتِيّٗا
Ó sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí ìyàwó mi jẹ́ àgàn, tí mo sì ti di àgbàlagbà gan-an.”
અરબી તફસીરો:
قَالَ كَذَٰلِكَ قَالَ رَبُّكَ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٞ وَقَدۡ خَلَقۡتُكَ مِن قَبۡلُ وَلَمۡ تَكُ شَيۡـٔٗا
(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni (ó máa rí).” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún Mi. Mó kúkú dá ìwọ náà ṣíwájú (rẹ̀), nígbà tí ìwọ kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan.”
અરબી તફસીરો:
قَالَ رَبِّ ٱجۡعَل لِّيٓ ءَايَةٗۖ قَالَ ءَايَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ ٱلنَّاسَ ثَلَٰثَ لَيَالٖ سَوِيّٗا
(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: “Àmì rẹ ni pé, o ò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kì í ṣe ti àmódi.”
અરબી તફસીરો:
فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوۡمِهِۦ مِنَ ٱلۡمِحۡرَابِ فَأَوۡحَىٰٓ إِلَيۡهِمۡ أَن سَبِّحُواْ بُكۡرَةٗ وَعَشِيّٗا
Nígbà náà, ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ láti inú ilé ìjọ́sìn. Ó sì tọ́ka sí wọn pé kí wọ́n máa ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.
અરબી તફસીરો:
يَٰيَحۡيَىٰ خُذِ ٱلۡكِتَٰبَ بِقُوَّةٖۖ وَءَاتَيۡنَٰهُ ٱلۡحُكۡمَ صَبِيّٗا
Yahyā, mú Tírà náà dání dáradára. A sì fún un ní àgbọ́yé ẹ̀sìn láti kékeré.
અરબી તફસીરો:
وَحَنَانٗا مِّن لَّدُنَّا وَزَكَوٰةٗۖ وَكَانَ تَقِيّٗا
(Ànábì Yahyā jẹ́) ìkẹ́ àti ẹni mímọ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó sì jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).
અરબી તફસીરો:
وَبَرَّۢا بِوَٰلِدَيۡهِ وَلَمۡ يَكُن جَبَّارًا عَصِيّٗا
(Ó tún jẹ́) oníwà rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Kò sì jẹ́ ajẹninípá, olùyapa.
અરબી તફસીરો:
وَسَلَٰمٌ عَلَيۡهِ يَوۡمَ وُلِدَ وَيَوۡمَ يَمُوتُ وَيَوۡمَ يُبۡعَثُ حَيّٗا
Àlàáfíà ni fún un ní ọjọ́ tí wọ́n bí i, àti ní ọjọ́ tí ó máa kú àti ní ọjọ́ tí A óò gbé e dìde láàyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde).
અરબી તફસીરો:
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَرۡيَمَ إِذِ ٱنتَبَذَتۡ مِنۡ أَهۡلِهَا مَكَانٗا شَرۡقِيّٗا
Sọ ìtàn Mọryam tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. (Rántí) nígbà tí ó yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí àyè kan ní ìlà òòrùn.
અરબી તફસીરો:
فَٱتَّخَذَتۡ مِن دُونِهِمۡ حِجَابٗا فَأَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهَا رُوحَنَا فَتَمَثَّلَ لَهَا بَشَرٗا سَوِيّٗا
Ó mú gàgá kan (láti fi ara rẹ̀ pamọ́) fún wọn. A sì rán mọlāika Wa sí i. Ó sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:45.
અરબી તફસીરો:
قَالَتۡ إِنِّيٓ أَعُوذُ بِٱلرَّحۡمَٰنِ مِنكَ إِن كُنتَ تَقِيّٗا
(Mọryam) sọ pé: “Èmi sá di Àjọkẹ́-ayé kúrò lọ́dọ̀ rẹ, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).”¹
1. Ìyẹn ni pé, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù Allāhu, ìbẹ̀rù Allāhu kò níí jẹ́ kí o ṣe aburú tí mò ń ṣọ́ra fún lọ́dọ̀ rẹ.
અરબી તફસીરો:
قَالَ إِنَّمَآ أَنَا۠ رَسُولُ رَبِّكِ لِأَهَبَ لَكِ غُلَٰمٗا زَكِيّٗا
(Mọlāika) sọ pé: “Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan.”¹
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ ń sọ pé Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - nìkan ṣoṣo ni al-Ƙur’ān pè ní “ẹni mímọ́” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah yìí. Èsì ní ṣókí ni pé, ní òdodo ẹni mímọ́ ni Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, àmọ́ kì í ṣe òun nìkan ni ẹni mímọ́. Āayah 13 nínú sūrah yìí kan náà pe Ànábì Yahyā - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní ẹni mímọ́. Bákan náà, ọmọ tí àsọọ́lẹ̀ wáyé lórí rẹ̀ nínú sūrah al-Kahf; 17:81, ẹni mímọ́ ni al-Ƙur’ān pe òun náà. Báwo ni jíjẹ́ ẹni mímọ́ Ànábì ‘Īsā ṣe máa sọ ọ́ di olúwa àti olùgbàlà nígbà tí jíjẹ́ ẹni mímọ́ àwọn méjèèjì wọ̀nyẹn kò sọ wọ́n di bẹ́ẹ̀.
Sì kíyè sì i, gbogbo àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun nínú al-Ƙur’ān ni ẹni mímọ́. Àti pé ìdà kejì ẹni mímọ́ ni ẹni àìmọ́. Báwo ni Allāhu ṣe máa fi iṣẹ́ mímọ́ rán ẹni àìmọ́? Kò lè ṣẹlẹ̀. Ṣíwájú sí i, nínú èdè Lárúbáwá, ìsọdorúkọ olùṣe fún “ẹni mímọ́” ni “zakiyyun”, ìsọdorúkọ àfòyemọ̀ fún “mímọ́” ni “zakāt”. Ìgbà tí ìròyìn bá bùáyà tán lára ẹni tí a fẹ́ pọ́n ní àpọ́npo, dípò kí Lárúbáwá lo ìsọdorúkọ olùṣe fún irú ẹni náà, ìsọdorúkọ àfòyemọ̀ ni wọ́n máa lò. Ìyẹn ni pé, jíjẹ́ ẹni mímọ́ tó lágbára gan-an ni ìlò èdè tí al-Ƙur’ān lò fún Ànábì Yahyā - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti ọmọ alásọọ́lẹ̀ náà. Ta wá ni ó mọ́ jùlọ láààrin “zakiyyu” tó túmọ̀ sí “ẹni mímọ́” àti “zakāt” tó túmọ̀ sí “mímọ́”? Kò wa tán bí!
અરબી તફસીરો:
قَالَتۡ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَٰمٞ وَلَمۡ يَمۡسَسۡنِي بَشَرٞ وَلَمۡ أَكُ بَغِيّٗا
Ó sọ pé: “Báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí abara kan kò fọwọ́ kàn mí, tí èmi kò sì jẹ́ alágbèrè.”
અરબી તફસીરો:
قَالَ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٞۖ وَلِنَجۡعَلَهُۥٓ ءَايَةٗ لِّلنَّاسِ وَرَحۡمَةٗ مِّنَّاۚ وَكَانَ أَمۡرٗا مَّقۡضِيّٗا
(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ló máa rí.” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún mi. Àti pé nítorí kí Á lè ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn ni. Ó sì jẹ́ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí A ti parí (tí ó gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ.)”
અરબી તફસીરો:
۞ فَحَمَلَتۡهُ فَٱنتَبَذَتۡ بِهِۦ مَكَانٗا قَصِيّٗا
Nítorí náà, ó lóyún rẹ̀. Ó sì yẹra pẹ̀lú rẹ̀ sí àyè kan tó jìnnà.
અરબી તફસીરો:
فَأَجَآءَهَا ٱلۡمَخَاضُ إِلَىٰ جِذۡعِ ٱلنَّخۡلَةِ قَالَتۡ يَٰلَيۡتَنِي مِتُّ قَبۡلَ هَٰذَا وَكُنتُ نَسۡيٗا مَّنسِيّٗا
Ìrọbí ọmọ sì mú un wá sí ìdí igi dàbínù. Ó sọ pé: “Háà! Kí n̄g ti kú ṣíwájú èyí, kí n̄g sì ti di ẹni tí wọ́n ti gbàgbé pátápátá.”
અરબી તફસીરો:
فَنَادَىٰهَا مِن تَحۡتِهَآ أَلَّا تَحۡزَنِي قَدۡ جَعَلَ رَبُّكِ تَحۡتَكِ سَرِيّٗا
Nígbà náà, (mọlāika) pè é láti ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ti ṣe odò kékeré kan sí ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ.
અરબી તફસીરો:
وَهُزِّيٓ إِلَيۡكِ بِجِذۡعِ ٱلنَّخۡلَةِ تُسَٰقِطۡ عَلَيۡكِ رُطَبٗا جَنِيّٗا
Mi igi dàbínù náà sọ́dọ̀ rẹ, kí dàbínú tútù, tó tó ká jẹ sì máa jábọ́ sílẹ̀ fún ọ.
અરબી તફસીરો:
فَكُلِي وَٱشۡرَبِي وَقَرِّي عَيۡنٗاۖ فَإِمَّا تَرَيِنَّ مِنَ ٱلۡبَشَرِ أَحَدٗا فَقُولِيٓ إِنِّي نَذَرۡتُ لِلرَّحۡمَٰنِ صَوۡمٗا فَلَنۡ أُكَلِّمَ ٱلۡيَوۡمَ إِنسِيّٗا
Nítorí náà, jẹ, mu kí ojú rẹ sì tutù. Tí o bá sì rí ẹnì kan nínú abara, sọ fún un pé: “Dájúdájú mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìkẹ́nuró fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, èmi kò níí bá ènìyàn kan sọ̀rọ̀ ní òní.”
અરબી તફસીરો:
فَأَتَتۡ بِهِۦ قَوۡمَهَا تَحۡمِلُهُۥۖ قَالُواْ يَٰمَرۡيَمُ لَقَدۡ جِئۡتِ شَيۡـٔٗا فَرِيّٗا
Ó sì mú ọmọ náà wá bá àwọn ènìyàn rẹ̀ (ní ẹni tí) ó gbé e dání. Wọ́n sọ pé: “Mọryam, dájúdájú o ti gbé n̄ǹkan aburú ńlá wá.
અરબી તફસીરો:
يَٰٓأُخۡتَ هَٰرُونَ مَا كَانَ أَبُوكِ ٱمۡرَأَ سَوۡءٖ وَمَا كَانَتۡ أُمُّكِ بَغِيّٗا
Arábìnrin Hārūn, bàbá rẹ kì í ṣe ènìyàn burúkú. Àti pé ìyá rẹ kì í ṣe alágbèrè.”
અરબી તફસીરો:
فَأَشَارَتۡ إِلَيۡهِۖ قَالُواْ كَيۡفَ نُكَلِّمُ مَن كَانَ فِي ٱلۡمَهۡدِ صَبِيّٗا
Ó sì tọ́ka sí ọmọ náà. Wọ́n sọ pé: “Báwo ni a ó ṣe bá ẹni tó wà lórí ìtẹ́, tó jẹ́ ọmọ òpóǹló sọ̀rọ̀?”
અરબી તફસીરો:
قَالَ إِنِّي عَبۡدُ ٱللَّهِ ءَاتَىٰنِيَ ٱلۡكِتَٰبَ وَجَعَلَنِي نَبِيّٗا
(Ọmọ náà) sọ̀rọ̀ pé: “Dájúdájú ẹrú Allāhu ni èmi. (Allāhu) fún mi ní Tírà. Ó sì ṣe mí ní Ànábì. ¹
1. Ẹrú Allāhu ni Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, àmọ́ àwọn nasọ̄rọ̄ kò gbàgbọ́ pé ẹrú Allāhu ni. Wọ́n ní, “ọmọ Ọlọ́hun ni.” Kódà àwọn náà sọra wọn di ọmọ Ọlọ́hun! Kí ni ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun”. Nínú èdè Yorùbá, kò sí ọ̀rọ̀ mìíràn fún ìdàkejì ẹrú bí kò ṣe “ọmọ”. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, “Bí ẹrú bá pẹ́ títí ẹrú á dọmọ”. Dọmọ ta ni? Ẹrú á dọmọ bàbá rẹ̀ nítorí pé, “ọ̀nà ló jìn, ẹrú ní baba”. Kí wá ni ọ̀rọ̀ mìíràn fún “ọmọ”? Ọmọ ni ẹni tí kò sí lóko-ẹrú. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ mìíràn fún ọmọ àti òbí tí kò sí lóko ẹrú ni “olómìnira”.
Ní ọ̀dọ̀ àwa mùsùlùmí, ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun” nìyí: “Ẹ̀dá tí ó ń tẹ̀lé ìlànà àti òfin Ọlọ́hun, ẹ̀dá tí ó ń bọ̀wọ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun, ẹ̀dá tí ó juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun àti ẹ̀dá tí ó ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun lábẹ́ ìlànà àti òfin Ọlọ́hun. Ẹ̀dá náà kò sì níí yọ́nú sí ìlànà àti òfin mìíràn tó yàtọ̀ sí ti Ọlọ́hun.” Ẹni tí ó bá ń ṣe ìwọ̀nyẹn fún ohun mìíràn tàbí ẹlòmíìràn, ó ti sọra rẹ̀ di ẹrú rẹ̀, láì la wíwà ní oko-ẹrú lọ bíi ti ẹrú àfowórà tàbí ẹrú ogun. Èyí fi hàn pé, ẹrú ẹ̀dá yàtọ̀ sí ẹrú Ọlọ́hun.
Àwọn òǹkọ-bíbèlí mọ̀ọ́mọ̀ yọ “ẹrú Ọlọ́hun” kúrò nínú bíbélì òde-òní ni. Wọ́n sì fi “ọmọ Ọlọ́hun” rọ́pò rẹ̀. Àmọ́ kò sí bí wọ́n ṣe lè sin òkú àbòsí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò níí yọ sílẹ̀. Ìdí nìyí tí a fi rí ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun” kà nínú ìwé Róòmù 7:25 báyìí pé: “So then, with my mind I am a slave to the law of God, but with my flesh I am a slave to the law of sin.” Ìtúmọ̀: “Nítorí náà nígbà náà, pẹ̀lú ẹ̀mí mi, ẹrú ni mi sí òfin Ọlọ́hun, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹran ara mi, ẹrú ni mi sí òfin ẹ̀ṣẹ̀. (New Revised Standard Version àti New International Version) Ìyẹn ni pé, tí ìwọ bá tẹ̀lé òfin Ọlọ́hun, ẹrú ni ìwọ lábẹ́ òfin Ọlọ́hun. Tí ìwọ bá sì tẹ̀lé òfin ẹ̀ṣẹ̀, ẹrú ni ìwọ lábẹ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti tẹ̀lé òfin Ọlọ́hun, ẹrú Ọlọ́hun ni. Tàbí ẹnu àwọn nasọ̄rọ̄ gbà á láti sọ pé Ànábì ‘Īsā kò lo òfin àti ìlànà Ọlọ́hun pẹ̀lú ẹ̀mí àti ara rẹ̀? Rárá. Tàbí ẹnu àwọn nasọ̄rọ̄ gbà á láti sọ pé òfin ẹ̀ṣẹ̀ ni Ànábì ‘Īsā tẹ̀lé? Rárá. Kò kúkú sí ìkẹta, lẹ́yìn òfin Ọlọ́hun, òfin èṣù ló tún kù. Ànábì ‘Īsā kò sì lo òfin Èṣù rí nínú ayé rẹ̀.
Àwa mùsùlùmí kú orí ire. Ọpẹ́ sì ni fún Ọlọ́hun tó jẹ́ kí á dá bàbá wa mọ̀ lọ́tọ̀ pé kì í ṣe Ọlọ́hun. Bákan náà, ẹ̀rù kò bà wá láti pe ara wa ní ẹrú Ọlọ́hun níbikíbi nítorí pé, pẹ̀lú ọkàn àti ara wa ni a fi gbà láti wà lábẹ́ òfin Rẹ̀. Ìwọ̀nba àṣìṣe tí a bá sì fi ara ṣe gẹ́gẹ́ bí àdámọ́ ènìyàn, ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni ọ̀nà àbáyọ lórí rẹ̀. Aláforíjìn, Olùgba-ìrònúpìwàdà sì ni Allāhu.
અરબી તફસીરો:
وَجَعَلَنِي مُبَارَكًا أَيۡنَ مَا كُنتُ وَأَوۡصَٰنِي بِٱلصَّلَوٰةِ وَٱلزَّكَوٰةِ مَا دُمۡتُ حَيّٗا
Ó ṣe mí ní ẹni ìbùkún ní ibikíbi tí mo bá wà. Ó pa mí láṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ lódiwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nípò alààyè (lórí ilẹ̀ ayé).
અરબી તફસીરો:
وَبَرَّۢا بِوَٰلِدَتِي وَلَمۡ يَجۡعَلۡنِي جَبَّارٗا شَقِيّٗا
(Ó ṣe mí ní) oníwà rere sí ìyá mi. Kò sì ṣe mí ní ajẹninípá, olórí burúkú.
અરબી તફસીરો:
وَٱلسَّلَٰمُ عَلَيَّ يَوۡمَ وُلِدتُّ وَيَوۡمَ أَمُوتُ وَيَوۡمَ أُبۡعَثُ حَيّٗا
Àlàáfíà ni fún mi ní ọjọ́ tí wọ́n bí mi, àti ní ọjọ́ tí mo máa kú àti ní ọjọ́ tí Wọ́n á gbé mi dìde ní alààyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde).”
અરબી તફસીરો:
ذَٰلِكَ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَۖ قَوۡلَ ٱلۡحَقِّ ٱلَّذِي فِيهِ يَمۡتَرُونَ
Ìyẹn ni (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam. (Èyí jẹ́) ọ̀rọ̀ òdodo tí àwọn (yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.
અરબી તફસીરો:
مَا كَانَ لِلَّهِ أَن يَتَّخِذَ مِن وَلَدٖۖ سُبۡحَٰنَهُۥٓۚ إِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرٗا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ
Kò yẹ fún Allāhu láti sọ ẹnì kan kan di ọmọ. Mímọ́ ni fún Un. Nígbà tí Ó bá pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
અરબી તફસીરો:
وَإِنَّ ٱللَّهَ رَبِّي وَرَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ
Àti pé dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.
અરબી તફસીરો:
فَٱخۡتَلَفَ ٱلۡأَحۡزَابُ مِنۢ بَيۡنِهِمۡۖ فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن مَّشۡهَدِ يَوۡمٍ عَظِيمٍ
Àwọn ìjọ (yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) sì yapa-ẹnu (lórí èyí) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (ní àsìkò) ìjẹ́rìí gban̄gba l’ọ́jọ́ ńlá (Ọjọ́ Àjíǹde).
અરબી તફસીરો:
أَسۡمِعۡ بِهِمۡ وَأَبۡصِرۡ يَوۡمَ يَأۡتُونَنَا لَٰكِنِ ٱلظَّٰلِمُونَ ٱلۡيَوۡمَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ
Kí ni wọn kò níí gbọ́, kí sì ni wọn kò níí rí ní ọjọ́ tí wọn yóò wá bá Wa!¹ Ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ní ọjọ́ náà ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
1. Ìyẹn ni pé, bí àwọn aláìgbàgbọ́ kò bá lo ìgbọ́rọ̀ wọn fún gbígbọ́ òdodo, tí wọn kò sì lo ìríran wọn fún rírí òdodo ní ilé ayé yìí, wọn yóò fi ìgbọ́rọ̀ wọn gbọ́ òdodo ketekete, wọn yó sì fi ìríran wọn rí òdodo kedere pẹ̀lú àbámọ̀ ní ọ̀run nítorí pé, Ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ náà.
અરબી તફસીરો:
وَأَنذِرۡهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡحَسۡرَةِ إِذۡ قُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ وَهُمۡ فِي غَفۡلَةٖ وَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́.
અરબી તફસીરો:
إِنَّا نَحۡنُ نَرِثُ ٱلۡأَرۡضَ وَمَنۡ عَلَيۡهَا وَإِلَيۡنَا يُرۡجَعُونَ
Dájúdájú Àwa l’A máa jogún ilẹ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí.
અરબી તફસીરો:
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ إِبۡرَٰهِيمَۚ إِنَّهُۥ كَانَ صِدِّيقٗا نَّبِيًّا
Mú (ìtàn) ’Ibrọ̄hīm wá sí ìrántí (bí ó ṣe) wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.
અરબી તફસીરો:
إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ يَٰٓأَبَتِ لِمَ تَعۡبُدُ مَا لَا يَسۡمَعُ وَلَا يُبۡصِرُ وَلَا يُغۡنِي عَنكَ شَيۡـٔٗا
Rántí nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, nítorí kí ni o fi ń jọ́sìn fún ohun tí kò gbọ́rọ̀, tí kò ríran, tí kò sì lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kan kan.
અરબી તફસીરો:
يَٰٓأَبَتِ إِنِّي قَدۡ جَآءَنِي مِنَ ٱلۡعِلۡمِ مَا لَمۡ يَأۡتِكَ فَٱتَّبِعۡنِيٓ أَهۡدِكَ صِرَٰطٗا سَوِيّٗا
Bàbá mi, dájúdájú ìmọ̀ tí ìwọ kò ní ti dé bá mi. Nítorí náà, tẹ̀lé mi, kí n̄g fi ọ̀nà tààrà mọ̀ ọ́.
અરબી તફસીરો:
يَٰٓأَبَتِ لَا تَعۡبُدِ ٱلشَّيۡطَٰنَۖ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ كَانَ لِلرَّحۡمَٰنِ عَصِيّٗا
Bàbá mi, má ṣe bọ Èṣù. Dájúdájú Èṣù jẹ́ olùyapa àṣẹ Àjọkẹ́-ayé.
અરબી તફસીરો:
يَٰٓأَبَتِ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يَمَسَّكَ عَذَابٞ مِّنَ ٱلرَّحۡمَٰنِ فَتَكُونَ لِلشَّيۡطَٰنِ وَلِيّٗا
Bàbá mi, dájúdájú èmi ń páyà pé kí ìyà kan láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé má fọwọ́ bà ọ́ nítorí kí ìwọ má baà di ọ̀rẹ́ Èṣù (nínú Iná).”
અરબી તફસીરો:
قَالَ أَرَاغِبٌ أَنتَ عَنۡ ءَالِهَتِي يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُۖ لَئِن لَّمۡ تَنتَهِ لَأَرۡجُمَنَّكَۖ وَٱهۡجُرۡنِي مَلِيّٗا
(Bàbá rẹ̀) wí pé: “Ṣé ìwọ yóò kọ àwọn ọlọ́hun mi sílẹ̀ ni, ’Ibrọ̄hīm? Dájúdájú tí o ò bá jáwọ́ (nínú ohun tí ò ń sọ), dájúdájú mo máa lẹ̀ ọ́ lókò pa. Tíẹ̀ yẹra fún mi wọ́ọ́rọ́wọ́ ná.”
અરબી તફસીરો:
قَالَ سَلَٰمٌ عَلَيۡكَۖ سَأَسۡتَغۡفِرُ لَكَ رَبِّيٓۖ إِنَّهُۥ كَانَ بِي حَفِيّٗا
(’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Àlàáfíà kí ó máa bá ọ. Mo máa bá ọ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Ó jẹ́ Olóore mi.
અરબી તફસીરો:
وَأَعۡتَزِلُكُمۡ وَمَا تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَأَدۡعُواْ رَبِّي عَسَىٰٓ أَلَّآ أَكُونَ بِدُعَآءِ رَبِّي شَقِيّٗا
Àti pé mo máa yẹra fún ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Èmi yó sì máa pe Olúwa mi. Ó sì súnmọ́ pé èmi kò níí pasán pẹ̀lú àdúà mi sí Olúwa mi.”
અરબી તફસીરો:
فَلَمَّا ٱعۡتَزَلَهُمۡ وَمَا يَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَهَبۡنَا لَهُۥٓ إِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَۖ وَكُلّٗا جَعَلۡنَا نَبِيّٗا
Nígbà tí ó yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, A sì ta á lọ́rẹ (ọmọ), ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ rẹ̀). A sì ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Ànábì.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Hūd; 11:71.
અરબી તફસીરો:
وَوَهَبۡنَا لَهُم مِّن رَّحۡمَتِنَا وَجَعَلۡنَا لَهُمۡ لِسَانَ صِدۡقٍ عَلِيّٗا
Àti pé A ta wọ́n lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa. A sì fi òdodo sórí ahọ́n gbogbo àwọn ènìyàn nìpa wọn (ìyẹn ni pé, gbogbo ìjọ ẹlẹ́sìn ló ń sọ̀rọ̀ wọn ní dáadáa).
અરબી તફસીરો:
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مُوسَىٰٓۚ إِنَّهُۥ كَانَ مُخۡلَصٗا وَكَانَ رَسُولٗا نَّبِيّٗا
Sọ ìtàn (Ànábì) Mūsā tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ ẹni-ẹ̀ṣà, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.
અરબી તફસીરો:
وَنَٰدَيۡنَٰهُ مِن جَانِبِ ٱلطُّورِ ٱلۡأَيۡمَنِ وَقَرَّبۡنَٰهُ نَجِيّٗا
A pè é ní ẹ̀bá àpáta ní apá ọwọ́ ọ̀tún (Mūsā). A sì mú un súnmọ́ tòsí láti bá a sọ̀rọ̀.
અરબી તફસીરો:
وَوَهَبۡنَا لَهُۥ مِن رَّحۡمَتِنَآ أَخَاهُ هَٰرُونَ نَبِيّٗا
A sì fi arákùnrin rẹ̀, Hārūn, (tí ó jẹ́) Ànábì, ta á lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa.
અરબી તફસીરો:
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ إِسۡمَٰعِيلَۚ إِنَّهُۥ كَانَ صَادِقَ ٱلۡوَعۡدِ وَكَانَ رَسُولٗا نَّبِيّٗا
Sọ ìtàn (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olùmú-àdéhùn-ṣẹ, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.
અરબી તફસીરો:
وَكَانَ يَأۡمُرُ أَهۡلَهُۥ بِٱلصَّلَوٰةِ وَٱلزَّكَوٰةِ وَكَانَ عِندَ رَبِّهِۦ مَرۡضِيّٗا
Ó máa ń pa ará ilé rẹ̀ ní àṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Ó sì jẹ́ ẹni ìyọ́nú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀.
અરબી તફસીરો:
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ إِدۡرِيسَۚ إِنَّهُۥ كَانَ صِدِّيقٗا نَّبِيّٗا
Sọ ìtàn (Ànábì) ’Idrīs tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.
અરબી તફસીરો:
وَرَفَعۡنَٰهُ مَكَانًا عَلِيًّا
A sì gbé e sí àyè gíga (nínú sánmọ̀).
અરબી તફસીરો:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ مِن ذُرِّيَّةِ ءَادَمَ وَمِمَّنۡ حَمَلۡنَا مَعَ نُوحٖ وَمِن ذُرِّيَّةِ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡرَٰٓءِيلَ وَمِمَّنۡ هَدَيۡنَا وَٱجۡتَبَيۡنَآۚ إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُ ٱلرَّحۡمَٰنِ خَرُّواْۤ سُجَّدٗاۤ وَبُكِيّٗا۩
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) Ādam àti nínú àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh àti nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Isrọ̄’īl àti nínú àwọn tí A ti fi mọ̀nà, tí A sì ṣà lẹ́ṣà. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Àjọkẹ́-ayé fún wọn, wọ́n máa dojú bolẹ̀; tí wọ́n á foríkanlẹ̀, tí wọ́n á sì máa sunkún.
અરબી તફસીરો:
۞ فَخَلَفَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ خَلۡفٌ أَضَاعُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَٱتَّبَعُواْ ٱلشَّهَوَٰتِۖ فَسَوۡفَ يَلۡقَوۡنَ غَيًّا
Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn, tí wọ́n rá ìrun kíkí láre, tí wọ́n tẹ̀lé àwọn adùn. Láìpẹ́ wọn máa pàdé òfò (nínú Iná).
અરબી તફસીરો:
إِلَّا مَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَأُوْلَٰٓئِكَ يَدۡخُلُونَ ٱلۡجَنَّةَ وَلَا يُظۡلَمُونَ شَيۡـٔٗا
Àyàfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí kan kan sí wọn.
અરબી તફસીરો:
جَنَّٰتِ عَدۡنٍ ٱلَّتِي وَعَدَ ٱلرَّحۡمَٰنُ عِبَادَهُۥ بِٱلۡغَيۡبِۚ إِنَّهُۥ كَانَ وَعۡدُهُۥ مَأۡتِيّٗا
(Wọn yóò wọ inú) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn ní ìkọ̀kọ̀¹ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Dájúdájú (Allāhu), àdéhùn Rẹ̀ ń bọ̀ wá ṣẹ.
1. Ìyẹn ni pé, wọn kò lè fojú rí àdéhùn náà nílé ayé, àmọ́ òdodo ni, wọ́n sì máa rí i ṣójú ní Ọjọ́ Àjíǹde.
અરબી તફસીરો:
لَّا يَسۡمَعُونَ فِيهَا لَغۡوًا إِلَّا سَلَٰمٗاۖ وَلَهُمۡ رِزۡقُهُمۡ فِيهَا بُكۡرَةٗ وَعَشِيّٗا
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀ àfi àlàáfíà. Ìjẹ-ìmu wọn wà nínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.
અરબી તફસીરો:
تِلۡكَ ٱلۡجَنَّةُ ٱلَّتِي نُورِثُ مِنۡ عِبَادِنَا مَن كَانَ تَقِيّٗا
Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A óò jogún rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù (Mi) nínú àwọn ẹrúsìn Wa.
અરબી તફસીરો:
وَمَا نَتَنَزَّلُ إِلَّا بِأَمۡرِ رَبِّكَۖ لَهُۥ مَا بَيۡنَ أَيۡدِينَا وَمَا خَلۡفَنَا وَمَا بَيۡنَ ذَٰلِكَۚ وَمَا كَانَ رَبُّكَ نَسِيّٗا
Àwa (mọlāika) kì í sọ̀kalẹ̀ àyàfi pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ. TiRẹ̀ ni ohun tí ń bẹ níwájú wa, ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wa àti ohun tí ń bẹ láààrin (méjèèjì) yẹn. Àti pé Olúwa rẹ kì í ṣe onígbàgbé.
અરબી તફસીરો:
رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا فَٱعۡبُدۡهُ وَٱصۡطَبِرۡ لِعِبَٰدَتِهِۦۚ هَلۡ تَعۡلَمُ لَهُۥ سَمِيّٗا
Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀?
અરબી તફસીરો:
وَيَقُولُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَءِذَا مَا مِتُّ لَسَوۡفَ أُخۡرَجُ حَيًّا
Ènìyàn ń wí pé: “Ṣé nígbà tí mo bá kú, wọn yóò tún mú mi jáde láìpẹ́ ní alààyè?”
અરબી તફસીરો:
أَوَلَا يَذۡكُرُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَنَّا خَلَقۡنَٰهُ مِن قَبۡلُ وَلَمۡ يَكُ شَيۡـٔٗا
Ṣé ènìyàn kò rántí pé dájúdájú Àwa ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan?
અરબી તફસીરો:
فَوَرَبِّكَ لَنَحۡشُرَنَّهُمۡ وَٱلشَّيَٰطِينَ ثُمَّ لَنُحۡضِرَنَّهُمۡ حَوۡلَ جَهَنَّمَ جِثِيّٗا
Nítorí náà, mo fi Olúwa rẹ búra; dájúdájú A máa kó àwọn àti àwọn èṣù jọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú wọn wá sí ayíká iná Jahanamọ lórí ìkúnlẹ̀.
અરબી તફસીરો:
ثُمَّ لَنَنزِعَنَّ مِن كُلِّ شِيعَةٍ أَيُّهُمۡ أَشَدُّ عَلَى ٱلرَّحۡمَٰنِ عِتِيّٗا
Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan ẹni tí ó le jùlọ nínú wọn níbi ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí Àjọkẹ́-ayé.
અરબી તફસીરો:
ثُمَّ لَنَحۡنُ أَعۡلَمُ بِٱلَّذِينَ هُمۡ أَوۡلَىٰ بِهَا صِلِيّٗا
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí wíwọ inú Iná.
અરબી તફસીરો:
وَإِن مِّنكُمۡ إِلَّا وَارِدُهَاۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ حَتۡمٗا مَّقۡضِيّٗا
Kò sí ẹnì kan nínú yín àfi kí ó débẹ̀ (àfi kí ó gba ibẹ̀ kọjá). Ó di dandan kí ó ṣẹlẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
અરબી તફસીરો:
ثُمَّ نُنَجِّي ٱلَّذِينَ ٱتَّقَواْ وَّنَذَرُ ٱلظَّٰلِمِينَ فِيهَا جِثِيّٗا
Lẹ́yìn náà, A máa gba àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu) là. A sì máa fi àwọn alábósì sílẹ̀ sínú Iná lórí ìkúnlẹ̀.¹
1. Ìgbàkígbà tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” bíi “A” tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ bíi “Àwa” fún Ara Rẹ̀, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ àpọ́nlé fún Un, kì í ṣe pé Ẹni tó ń jẹ́ “Allāhu” pé méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ “ọ̀pọ̀” náà ń dúró fún iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa ń dá ṣe pẹ̀lú gbólóhùn “Jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀” tàbí iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa yan àwọn mọlāika Rẹ̀ láti ṣe. Ní ti āyah 68 àti 69, àwọn mọlāika ni Allāhu máa pàṣẹ iṣẹ́ wọ̀nyẹn fún lọ́jọ́ Àjíǹde. Àwọn mọlāika náà sì ni ẹ̀ṣọ́ Iná. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah at-Tahrim; 66:6 àti sūrah al-Mudaththir; 74:30-31.
Bákan náà, kalmọh “wārid” tó jẹyọ nínú āyah 71 jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tí wọ́n ṣẹ̀dá láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe “warada”. Nínú al-Ƙur’ān, a lè rí ìtúmọ̀ méjì tó súnmọ́ ara wọn, àmọ́ tó tún ń dúró fún ọ̀rọ̀ àti ìdàkejì rẹ̀ fún “warada”. “Warada” túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, ó sì wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah Hūd; 11:98 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:98-100. “Warada” tún túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, àmọ́ kò wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:23.
Ìtúmọ̀ méjèèjì wọ̀nyí ti fi hàn kedere pé kò sí ẹ̀dá tí kò níí dé ibi tí Iná wà lọ́jọ́ Àjíǹde. Àmọ́ àwọn kan máa “débẹ̀ wọbẹ̀”, àwọn kan sì máa “débẹ̀ láì wọbẹ̀”. Ìdí tí gbogbo ẹ̀dá máa fi dé ibi tí Iná wà ni pé, ojú ọ̀nà tí a máa tọ̀ dé ibi tí Ọgbà Ìdẹ̀ra wà ni Iná wà. Ìsàlẹ̀ lọ́wọ́ iwájú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni Allāhu fi àyè Iná sí. Kódà, ọ̀nà tí a máa tọ̀ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra sì jẹ́ afárá tín-ínrín yíyọ̀ lórí Iná. Igun mẹ́ta sì ni àwọn ènìyàn àti àlùjọ̀nnú máa pín sí lórí ìrìn wọn lórí afárá Iná.
Igun kìíní ni àwọn Ànábì, àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ìkẹ́ Allāhu máa bá wọn - àti àwọn kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, tó máa rìn lórí afárá Iná láì níí jábọ́ sínú Iná títí wọ́n fi máa gúnlẹ̀ sínú ilé ìgbàlà wọn, Ọgbà Ìdẹ̀ra. - Kí Allāhu fi àánú Rẹ̀ ta wá lọ́rẹ àrìnyè náà. - Igun yìí ni Allāhu ti ṣe àforíjìn fún pátápátá lórí àṣìṣe wọn. Ṣebí kò sí bí a ó ṣe rìn tí orí wa kò níí mì lọ̀rọ̀ ẹ̀dá nílé ayé. Allāhu sì ni Aláforíjìn ẹ̀dá. Igun kìíní yìí ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ń sọ nípa wọn nínú sūrah al-’Anbiyā’; 21:101-102 àti sūrah az-Zumọr; 39:61.
Igun kejì ni àwọn kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, tó máa rìn lórí afárá Iná ní àrìnjábọ́ sínú Iná. Igun yìí ni wọ́n ní àwọn àṣìṣe kan lọ́rùn, àmọ́ tí Allāhu kò forí rẹ̀ jìn wọ́n. Sebí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kúkú ti sọ pé kí ẹni tí ó bá ń dá ẹ̀ṣẹ̀, tí kò tọrọ àforíjìn tàbí ronú pìwàdà lórí rẹ̀ títí ó fi kú má ṣe fọkàn balẹ̀ pé Òun kúkú máa forí rẹ̀ jìn ín. Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa forí rẹ̀ jìn ín. Tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa fìyà ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:116. Igun kejì yìí ló máa padà jáde kúrò nínú Iná lásìkò tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá fẹ́, yálà nípasẹ̀ ìṣìpẹ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tàbí nípasẹ̀ àánú àti ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta’ālā -.
Igun kẹta ni igun gbogbo ẹni tí ó kú sórí àìgbàgbọ́ tàbí ìṣẹbọ tàbí ìṣojúméjì pẹ̀lú Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -. Igun kẹta yìí náà máa rìn lórí afárá Iná ní àrìnjábọ́, àmọ́ wọn kò níí jáde kúrò nínú rẹ̀ títí láéláé nítorí pé, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kò níí ṣíjú àánú wò wọ́n rárá.
Nítorí náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò níí sí igun kan kan tí Iná kò níí jó nítorí gbólóhùn “wa ’in minkum ’illā wāriduhā”, ẹni náà ti sọ̀rọ̀ àìmọ̀kan tó gbópọn lẹnu nítorí pé, ó ti fi ìtúmọ̀ “warada” mọ sórí “ó débẹ̀ wọbẹ̀” nìkan, ó sì kọ̀yìn sí ìtúmọ̀ “warada” tó túmọ̀ sí “ó débẹ̀ kò wọbẹ̀”.
Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó bá sọ pé kò sí igun kan kan tí ó máa padà jáde kúrò nínú Iná. Kò sí ẹni tí ó máa sọ bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe aláìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Bákan náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò níí sí igun kan kan tí ó máa wà nínú Iná gbére, irú ẹni náà ti sọ ọ̀rọ̀ tí ó lòdì sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ āyah tó ń fi Iná gbere rinlẹ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́. Irú ẹni náà súnmọ́ kó jẹ́ ẹlẹ́sìn Ahmadiyyah.
Lẹ́yìn náà, yálà igun tí ó máa rin àrìnyè lórí afárá Iná tàbí igun tí ó máa rin àrìnjábọ́ sínú Inȧ, igun kìíní kejì máa wá lábẹ́ àkórìn àwọn mọlāika kan ni. Ìyẹn ni pé, àwọn mọlāika kan ló máa kó gbogbo ẹ̀dá lọ sórí afárá Iná nítorí pé, kò sí ẹ̀dá kan tó máa fẹ́ fínnú fíndọ̀ gba orí afárá Iná kọjá. Dándan sì ni fún gbogbo wọn láti gba orí rẹ̀ kọjá bọ́ sí àyè wọn. Àwọn mọlāika wọ̀nyẹn ni àwọn mọlāika agbèrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti àwọn mọlāika agbèrò Iná. Èyí ni Allāhu - subhānahu wa ta’ālā - tún fi rinlẹ̀ nínú sūrah az-Zumọr; 39:71-73.
અરબી તફસીરો:
وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَيُّ ٱلۡفَرِيقَيۡنِ خَيۡرٞ مَّقَامٗا وَأَحۡسَنُ نَدِيّٗا
Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò sọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Èwo nínú ìjọ méjèèjì (àwa tàbí ẹ̀yin) ló lóore jùlọ ní ibùgbé, ló sì dára jùlọ ní ìjókòó (afẹ́)?”
અરબી તફસીરો:
وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّن قَرۡنٍ هُمۡ أَحۡسَنُ أَثَٰثٗا وَرِءۡيٗا
Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn, tí wọ́n dára jùlọ ní ọrọ̀ (ayé) àti ní ìrísí!
અરબી તફસીરો:
قُلۡ مَن كَانَ فِي ٱلضَّلَٰلَةِ فَلۡيَمۡدُدۡ لَهُ ٱلرَّحۡمَٰنُ مَدًّاۚ حَتَّىٰٓ إِذَا رَأَوۡاْ مَا يُوعَدُونَ إِمَّا ٱلۡعَذَابَ وَإِمَّا ٱلسَّاعَةَ فَسَيَعۡلَمُونَ مَنۡ هُوَ شَرّٞ مَّكَانٗا وَأَضۡعَفُ جُندٗا
Sọ pé: “Ẹni tí ó bá wà nínú ìṣìnà, Àjọkẹ́-ayé yó sì fẹ (ìṣìnà) lójú fún un tààrà, títí di ìgbà tí wọn máa rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, yálà ìyà tàbí Àkókò náà. Nígbà náà, wọn yóò mọ ẹni tí ó burú jùlọ ní ipò, tí ó sì lẹ jùlọ ní ọmọ ogun.
અરબી તફસીરો:
وَيَزِيدُ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ٱهۡتَدَوۡاْ هُدٗىۗ وَٱلۡبَٰقِيَٰتُ ٱلصَّٰلِحَٰتُ خَيۡرٌ عِندَ رَبِّكَ ثَوَابٗا وَخَيۡرٞ مَّرَدًّا
Allāhu yó sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún àwọn tó mọ̀nà. Àwọn iṣẹ́ rere ẹlẹ́san gbére lóore jùlọ ní ẹ̀san, ó sì lóore jùlọ ní ibùdésí lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
અરબી તફસીરો:
أَفَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي كَفَرَ بِـَٔايَٰتِنَا وَقَالَ لَأُوتَيَنَّ مَالٗا وَوَلَدًا
Sọ fún mi nípa ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí ó sì wí pé: “Dájúdájú wọn yóò fún mi ní dúkìá àti ọmọ!”
અરબી તફસીરો:
أَطَّلَعَ ٱلۡغَيۡبَ أَمِ ٱتَّخَذَ عِندَ ٱلرَّحۡمَٰنِ عَهۡدٗا
Ṣé ó rí ìkọ̀kọ̀ ni tàbí ó rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé?
અરબી તફસીરો:
كَلَّاۚ سَنَكۡتُبُ مَا يَقُولُ وَنَمُدُّ لَهُۥ مِنَ ٱلۡعَذَابِ مَدّٗا
Rárá. A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ń wí. A sì máa fẹ ìyà lójú fún un tààrà.
અરબી તફસીરો:
وَنَرِثُهُۥ مَا يَقُولُ وَيَأۡتِينَا فَرۡدٗا
A ó sì jogún ohun tó ń wí fún un. Ó sì máa wá bá Wa ní òun nìkan.
અરબી તફસીરો:
وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ ءَالِهَةٗ لِّيَكُونُواْ لَهُمۡ عِزّٗا
Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè fún wọn ní agbára.
અરબી તફસીરો:
كَلَّاۚ سَيَكۡفُرُونَ بِعِبَادَتِهِمۡ وَيَكُونُونَ عَلَيۡهِمۡ ضِدًّا
Rárá. Wọ́n máa tako ìjọ́sìn wọn, wọ́n si máa di ọ̀tá wọn.
અરબી તફસીરો:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّآ أَرۡسَلۡنَا ٱلشَّيَٰطِينَ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ تَؤُزُّهُمۡ أَزّٗا
Ṣé ìwọ kò wòye pé dájúdájú Àwa ń dẹ àwọn èṣù sí àwọn aláìgbàgbọ́ ni, tí wọ́n sì ń gùn wọ́n gan-an (síbi ẹ̀ṣẹ̀)?
અરબી તફસીરો:
فَلَا تَعۡجَلۡ عَلَيۡهِمۡۖ إِنَّمَا نَعُدُّ لَهُمۡ عَدّٗا
Nítorí náà, má ṣe kánjú nípa (ìyà) wọn. A kúkú ń ka (ọjọ́) fún wọn ní kíkà tààrà.
અરબી તફસીરો:
يَوۡمَ نَحۡشُرُ ٱلۡمُتَّقِينَ إِلَى ٱلرَّحۡمَٰنِ وَفۡدٗا
(Rántí) ọjọ́ tí A óò kó àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) jọ sọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé lórí n̄ǹkan ìgùn.
અરબી તફસીરો:
وَنَسُوقُ ٱلۡمُجۡرِمِينَ إِلَىٰ جَهَنَّمَ وِرۡدٗا
A sì máa da àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ sínú iná Jahanamọ wìtìwìtì.
અરબી તફસીરો:
لَّا يَمۡلِكُونَ ٱلشَّفَٰعَةَ إِلَّا مَنِ ٱتَّخَذَ عِندَ ٱلرَّحۡمَٰنِ عَهۡدٗا
Wọn kò níí ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àdéhùn láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé.
અરબી તફસીરો:
وَقَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَلَدٗا
Wọ́n wí pé: “Àjọkẹ́-ayé fi ẹnì kan ṣe ọmọ.”
અરબી તફસીરો:
لَّقَدۡ جِئۡتُمۡ شَيۡـًٔا إِدّٗا
Dájúdájú ẹ ti mú n̄ǹkan aburú wá.
અરબી તફસીરો:
تَكَادُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ يَتَفَطَّرۡنَ مِنۡهُ وَتَنشَقُّ ٱلۡأَرۡضُ وَتَخِرُّ ٱلۡجِبَالُ هَدًّا
Àwọn sánmọ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí rẹ̀, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn àpáta sì fẹ́rẹ̀ dàwó lulẹ̀ gbì
અરબી તફસીરો:
أَن دَعَوۡاْ لِلرَّحۡمَٰنِ وَلَدٗا
fún wí pé wọ́n pe ẹnì kan ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé.
અરબી તફસીરો:
وَمَا يَنۢبَغِي لِلرَّحۡمَٰنِ أَن يَتَّخِذَ وَلَدًا
Kò sì yẹ fún Àjọkẹ́-ayé láti fi ẹnì kan ṣe ọmọ.
અરબી તફસીરો:
إِن كُلُّ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ إِلَّآ ءَاتِي ٱلرَّحۡمَٰنِ عَبۡدٗا
Kò sí ẹnì kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àyàfi kí ó wá bá Àjọkẹ́-ayé ní ipò ẹrúsìn.
અરબી તફસીરો:
لَّقَدۡ أَحۡصَىٰهُمۡ وَعَدَّهُمۡ عَدّٗا
Dájúdájú (Allāhu) mọ̀ wọ́n. Ó sì ka òǹkà wọn tààrà.
અરબી તફસીરો:
وَكُلُّهُمۡ ءَاتِيهِ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فَرۡدًا
Gbogbo wọn yó sì wá bá A ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìkọ̀ọ̀kan.
અરબી તફસીરો:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ سَيَجۡعَلُ لَهُمُ ٱلرَّحۡمَٰنُ وُدّٗا
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, Àjọkẹ́-ayé yóò fi ìfẹ́ sáààrin wọn.
અરબી તફસીરો:
فَإِنَّمَا يَسَّرۡنَٰهُ بِلِسَانِكَ لِتُبَشِّرَ بِهِ ٱلۡمُتَّقِينَ وَتُنذِرَ بِهِۦ قَوۡمٗا لُّدّٗا
Nítorí náà, dájúdájú A fi èdè abínibí rẹ (èdè Lárúbáwá) ṣe (kíké al-Ƙur’ān àti àgbọ́yé rẹ̀) ní ìrọ̀rùn nítorí kí o lè fi ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọ tó ń ja òdodo níyàn
અરબી તફસીરો:
وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّن قَرۡنٍ هَلۡ تُحِسُّ مِنۡهُم مِّنۡ أَحَدٍ أَوۡ تَسۡمَعُ لَهُمۡ رِكۡزَۢا
Mélòó mélòó nínú ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn! Ǹjẹ́ o gbọ́ ìró ẹnì kan kan nínú wọn mọ́ tàbí (ǹjẹ́) o gbọ́ ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ wọn bí?
અરબી તફસીરો:
 
શબ્દોનું ભાષાંતર સૂરહ: મરયમ
સૂરહ માટે અનુક્રમણિકા પેજ નંબર
 
કુરઆન મજીદના શબ્દોનું ભાષાંતર - યોરુબ્બા ભાષાતર - ભાષાંતરોની અનુક્રમણિકા

યોરુબ્બા ભાષામાં કુરઆન મજીદનું ભાષાતર, જેનું ભાષાતર અશ શેખ અબૂ રહીમહ મિકાઈલ એકવીનીએ ૧૪૩૨ હિજરીસનમાં કર્યું છે,

બંધ કરો