Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba * - Indice Traduzioni

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduzione dei significati Versetto: (91) Sura: Al-Anbiyâ’
وَٱلَّتِيٓ أَحۡصَنَتۡ فَرۡجَهَا فَنَفَخۡنَا فِيهَا مِن رُّوحِنَا وَجَعَلۡنَٰهَا وَٱبۡنَهَآ ءَايَةٗ لِّلۡعَٰلَمِينَ
(Ẹ rántí obìnrin) èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn nínú àwọn atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá sí i lára. A sì ṣe òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.¹
1. Kíyè sí i! Ṣíṣe tí Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - ṣe Mọryam àti ọmọ rẹ̀, Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá, kò túmọ̀ sí pé ìkíní kejì wọn jẹ́ olúwa àti olùgbàlà. Àmọ́ kí ẹ̀dá lè wòye sí agbára Allāhu pé, Ó máa ń ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀dá bí Ó bá ṣe fẹ́. Tí ẹnì kan bá wá tìtorí ìyẹn sọ ẹ̀dá kan di olúwa àti olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu, Ọba Oníṣẹ́-ìyanu, onítọ̀ún ti sọnù jìnnà. Bákan náà, ẹ tún wo irú gbólóhùn yìí “àmì fún gbogbo ẹ̀dá” nínú sūrah al-’Ankabūt; 29:15.
Esegesi in lingua araba:
 
Traduzione dei significati Versetto: (91) Sura: Al-Anbiyâ’
Indice delle Sure Numero di pagina
 
Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Indice Traduzioni

Traduzione dei significati del Nobile Corano in yoruba, di Shaikh Abu Rahima Mika'il 'Aikweiny, ed. 1432 H.

Chiudi