[1] Ìyẹn ni pé, kí Allāhu má ṣe fi ọ̀tá ẹ̀sìn wa borí wa. Tàbí àdánwò tó máa kàn wá tí àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn wa yóò fi lérò pé a kì í ṣe ẹni Allāhu, kí Allāhu má ṣe fi kàn wá.
[1] Ìyẹn nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n láti máa lọ kírun nínú mọ́sálásí nítorí iṣẹ́ aburú ọwọ́ Fir'aon àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
[1] “torí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ” ìyẹn ni pé, Allāhu fi oore ayé ṣe ẹ̀dẹ fún wọn.