[1] Ànábì Lūt - kí ọlà Allāhu máa bá a - pe “àwọn obìnrin” nínú ìjọ rẹ̀ ní “àwọn ọmọbìnrin rẹ̀” nítorí pé, ipò bàbá ni ànábì kọ̀ọ̀kan wà lórí ìjọ rẹ̀.
[1] Abala kan nínú òru nínú āyah yìí dúró fún abala ìparí òru, tí í ṣe àsìkò sààrì gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:34.