Check out the new design

કુરઆન મજીદના શબ્દોનું ભાષાંતર - યોરૂબા ભાષામાં અનુવાદ - અબૂ રહીમા મિકાઈલ * - ભાષાંતરોની અનુક્રમણિકા

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

શબ્દોનું ભાષાંતર સૂરહ: હૂદ   આયત:
قَالَتۡ يَٰوَيۡلَتَىٰٓ ءَأَلِدُ وَأَنَا۠ عَجُوزٞ وَهَٰذَا بَعۡلِي شَيۡخًاۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيۡءٌ عَجِيبٞ
Ó sọ pé: “Hẹ̀n-ẹ́n! Ṣé pé mo máa bímọ, arúgbóbìnrin ni mí, baálé mi yìí sì ti dàgbàlágbà! Dájúdájú èyí ni n̄ǹkan ìyanu.”
અરબી તફસીરો:
قَالُوٓاْ أَتَعۡجَبِينَ مِنۡ أَمۡرِ ٱللَّهِۖ رَحۡمَتُ ٱللَّهِ وَبَرَكَٰتُهُۥ عَلَيۡكُمۡ أَهۡلَ ٱلۡبَيۡتِۚ إِنَّهُۥ حَمِيدٞ مَّجِيدٞ
Wọ́n sọ pé: “Ṣé o máa ṣèèmọ̀ nípa àṣẹ Allāhu ni? Ìkẹ́ Allāhu àti ìbùkún Rẹ̀ kí ó máa bẹ fún yín, ẹ̀yin ará ilé (yìí). Dájúdájú Allāhu ni Ẹlẹ́yìn, Ológo.”
અરબી તફસીરો:
فَلَمَّا ذَهَبَ عَنۡ إِبۡرَٰهِيمَ ٱلرَّوۡعُ وَجَآءَتۡهُ ٱلۡبُشۡرَىٰ يُجَٰدِلُنَا فِي قَوۡمِ لُوطٍ
Nígbà tí ìbẹ̀rù kúrò lára (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, tí ìró ìdùnnú sì ti dé bá a ló bá ń pàrọwà fún (àwọn Òjíṣẹ́) Wa nípa ìjọ (Ànábì) Lūt.
અરબી તફસીરો:
إِنَّ إِبۡرَٰهِيمَ لَحَلِيمٌ أَوَّٰهٞ مُّنِيبٞ
Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni aláfaradà, olùrawọ́rasẹ̀, olùronúpìwàdà.
અરબી તફસીરો:
يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُ أَعۡرِضۡ عَنۡ هَٰذَآۖ إِنَّهُۥ قَدۡ جَآءَ أَمۡرُ رَبِّكَۖ وَإِنَّهُمۡ ءَاتِيهِمۡ عَذَابٌ غَيۡرُ مَرۡدُودٖ
(Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Dájúdájú àṣẹ Olúwa rẹ ti dé. Àti pé dájúdájú àwọn (wọ̀nyẹn) ni ìyà tí kò ṣe é dá padà yóò dé bá.
અરબી તફસીરો:
وَلَمَّا جَآءَتۡ رُسُلُنَا لُوطٗا سِيٓءَ بِهِمۡ وَضَاقَ بِهِمۡ ذَرۡعٗا وَقَالَ هَٰذَا يَوۡمٌ عَصِيبٞ
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé bá (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Ó sì sọ pé: “Ọjọ́ tó le gan-an ní èyí.”
અરબી તફસીરો:
وَجَآءَهُۥ قَوۡمُهُۥ يُهۡرَعُونَ إِلَيۡهِ وَمِن قَبۡلُ كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ هَٰٓؤُلَآءِ بَنَاتِي هُنَّ أَطۡهَرُ لَكُمۡۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُخۡزُونِ فِي ضَيۡفِيٓۖ أَلَيۡسَ مِنكُمۡ رَجُلٞ رَّشِيدٞ
Àwọn ènìyàn rẹ̀ wá bá a, tí wọ́n ń sáré gbọ̀n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ti ń ṣe iṣẹ́ aburú (bí ìbálòpọ̀ ọkùnrin sí ọkùnrin). Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn wọ̀nyí ni ọmọbìnrin mi[1], wọ́n mọ́ jùlọ fún yín (láti fi ṣaya dípò ìbálòpọ̀ ọkùnrin sí ọkùnrin). Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe dójú tì mí lọ́dọ̀ àlejò mi. Ṣé kò sí ọkùnrin kan tí ó lóye lórí nínú yín ni?”
1. Ànábì Lūt - kí ọlà Allāhu máa bá a - pe “àwọn obìnrin” nínú ìjọ rẹ̀ ní “àwọn ọmọbìnrin rẹ̀” nítorí pé, ipò bàbá ni ànábì kọ̀ọ̀kan wà lórí ìjọ rẹ̀.
અરબી તફસીરો:
قَالُواْ لَقَدۡ عَلِمۡتَ مَا لَنَا فِي بَنَاتِكَ مِنۡ حَقّٖ وَإِنَّكَ لَتَعۡلَمُ مَا نُرِيدُ
Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú ti mọ̀ pé àwa kò ní bùkátà kan sí àwọn ọmọbìnrin rẹ. O sì ti mọ n̄ǹkan tí à ń fẹ́.”
અરબી તફસીરો:
قَالَ لَوۡ أَنَّ لِي بِكُمۡ قُوَّةً أَوۡ ءَاوِيٓ إِلَىٰ رُكۡنٖ شَدِيدٖ
Ó sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú agbára kan wà fún mi lórí yín ni, tàbí (pé) mo lè darapọ̀ mọ́ ẹbí kan (tàbí ikọ̀ ọmọ-ogun kan) tó lágbára ni, (èmi ìbá di yín lọ́wọ́ níbi aburú yín).”
અરબી તફસીરો:
قَالُواْ يَٰلُوطُ إِنَّا رُسُلُ رَبِّكَ لَن يَصِلُوٓاْ إِلَيۡكَۖ فَأَسۡرِ بِأَهۡلِكَ بِقِطۡعٖ مِّنَ ٱلَّيۡلِ وَلَا يَلۡتَفِتۡ مِنكُمۡ أَحَدٌ إِلَّا ٱمۡرَأَتَكَۖ إِنَّهُۥ مُصِيبُهَا مَآ أَصَابَهُمۡۚ إِنَّ مَوۡعِدَهُمُ ٱلصُّبۡحُۚ أَلَيۡسَ ٱلصُّبۡحُ بِقَرِيبٖ
(Àwọn mọlāika) sọ pé: “(Ànábì) Lūt, dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa. Wọn kò lè (fọwọ́ aburú) kàn ọ́. Nítorí náà, mú àwọn ará ilé rẹ jáde ní abala kan nínú òru.[1] Kí ẹnì kan nínú yín má sì ṣe ṣíjú wẹ̀yìn wò, àfi ìyàwó rẹ, dájúdájú ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn ló máa ṣẹlẹ̀ sí i. Dájúdájú àkókò (àdánwò) wọn ni òwúrọ̀. Ṣé òwúrọ̀ kò súnmọ́ ni?
1. Abala kan nínú òru nínú āyah yìí dúró fún abala ìparí òru, tí í ṣe àsìkò sààrì gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:34.
અરબી તફસીરો:
 
શબ્દોનું ભાષાંતર સૂરહ: હૂદ
સૂરહ માટે અનુક્રમણિકા પેજ નંબર
 
કુરઆન મજીદના શબ્દોનું ભાષાંતર - યોરૂબા ભાષામાં અનુવાદ - અબૂ રહીમા મિકાઈલ - ભાષાંતરોની અનુક્રમણિકા

તેનું અનુવાદ શૈખ અબૂ રહીમા મિકાઈલ એકવેની દ્વારા કરવામાં આવ્યું છે.

બંધ કરો