[1] Àwọn onímọ̀ pín sí mẹ́ta lórí ìtúmọ̀ āyah yìí nítorí pé, ìtúmọ̀ mẹ́ta tí ó ń padà síbi n̄ǹkan ẹyọ kan ni kalmọh “nikāh” ń túmọ̀ sí nínú al-Ƙur’ān, hadīth àti èdè Lárúbáwá. Àwọn ìtúmọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni fífẹ́ (ṣíṣe ìgbéyàwó), títi kálámù bọ inú ìgò tàdáà yálà ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tàbí ní ọ̀nà àìtọ́ àti ṣíṣe sìná (àgbèrè). [2] Nítorí náà, “ìyẹn” nínú gbólóhùn yìí “A sì ṣe ìyẹn ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” ń tọ́ka sí “zinā”. Ìyẹn ni pé, “A sì ṣe zinā ṣíṣe ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” Èyí sì ni ìtúmọ̀ rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ tí ó túmọ̀ “lā yankihu” sí “kò níí ṣe sìná”.