[1] Pípe al-Ƙur’ān ní “hakīm” túmọ̀ sí tírà tí ó kún fún ọgbọ́n, tírà tí ó ń ṣe ìdájọ́ àti tírà tí wọ́n to àwọn āyah rẹ̀ àti sūrah rẹ̀ tó gún régé láì sí ìdàrúdàpọ̀ àti ìtakora kan nínú rẹ̀.
[1] Ọ̀rọ̀ eré ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ́ orin, odù irọ́, ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ àti ìsọkúsọ. Èyí sì lè jẹ́ odù ifá, orin àlùjó, ọ̀rọ̀ ìròrí (philosophy) àti fíìmù (tíátà).