ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
6 : 31

وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَشۡتَرِي لَهۡوَ ٱلۡحَدِيثِ لِيُضِلَّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَيَتَّخِذَهَا هُزُوًاۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ

Ó wà nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń ra ọ̀rọ̀ eré[1] láti fi ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú àìnímọ̀ àti nítorí kí ó lè sọ ẹ̀sìn di yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún. info

[1] Ọ̀rọ̀ eré ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ́ orin, odù irọ́, ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ àti ìsọkúsọ. Èyí sì lè jẹ́ odù ifá, orin àlùjó, ọ̀rọ̀ ìròrí (philosophy) àti fíìmù (tíátà).

التفاسير: