Check out the new design

ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល * - សន្ទស្សន៍នៃការបកប្រែ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ការបកប្រែអត្ថន័យ អាយ៉ាត់: (60) ជំពូក​: អាល់ម៉ាអ៊ីដះ
قُلۡ هَلۡ أُنَبِّئُكُم بِشَرّٖ مِّن ذَٰلِكَ مَثُوبَةً عِندَ ٱللَّهِۚ مَن لَّعَنَهُ ٱللَّهُ وَغَضِبَ عَلَيۡهِ وَجَعَلَ مِنۡهُمُ ٱلۡقِرَدَةَ وَٱلۡخَنَازِيرَ وَعَبَدَ ٱلطَّٰغُوتَۚ أُوْلَٰٓئِكَ شَرّٞ مَّكَانٗا وَأَضَلُّ عَن سَوَآءِ ٱلسَّبِيلِ
Sọ pé: “Ṣé kí n̄g fún yín ní ìró nípa èyí tí ó burú ju ìyẹn lọ ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ Allāhu?”[1](Òhun ni ẹ̀san) ẹni tí Allāhu ṣẹ́bilé, tí Ó sì bínú sí, tí Ó sì sọ àwọn kan nínú wọn di ọ̀bọ àti ẹlẹ́dẹ̀ àti (ẹ̀san) ẹni tí ó ń bọ àwọn n̄ǹkan kan, tí wọn kò pe ara wọn ní ọlọ́hun, tí wọn kò sì yọ̀nù sí bí ẹ ṣe sọ wọ́n di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Àwọn wọ̀nyẹn ni ipò wọn burú jùlọ, àwọn sì ni wọ́n ṣìnà jùlọ kúrò lójú-ọ̀nà tààrà.
[1] Ìyẹn ni pé, bí ẹ̀yin onítírà bá ń bú àwa onígbàgbọ́ òdodo, tí ẹ bá ń kórira wa nítorí ìgbàgbọ́ òdodo wa nínú Allāhu àti àwọn Tírà Rẹ̀, èébú wa àti ìkórira wa kò burú tó ẹ̀san tí Allāhu san yín láyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ẹ fi di ẹni ìsẹ́bilé, ẹni ìbínú, ọbọ, ẹlẹ́dẹ̀ àti ẹni tí ń bọ àwọn Ànábì kan tí wọn kò pe ara wọn ní ọlọ́hun, tí wọn kò sì yọ̀nù sí bí ẹ ṣe sọ wọ́n di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Ọ̀rọ̀ ayé yín àti ọ̀rọ̀ ọ̀run yín sì ti dàrú pátápátá.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
 
ការបកប្រែអត្ថន័យ អាយ៉ាត់: (60) ជំពូក​: អាល់ម៉ាអ៊ីដះ
សន្ទស្សន៍នៃជំពូក លេខ​ទំព័រ
 
ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល - សន្ទស្សន៍នៃការបកប្រែ

ការបកប្រែដោយលោកអាពូ​ រ៉ហុីម៉ះ​ មុីកាអុីល​ អៃក្វីនី។

បិទ