Check out the new design

ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល * - សន្ទស្សន៍នៃការបកប្រែ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ការបកប្រែអត្ថន័យ ជំពូក​: អាល់ហាគកោះ   អាយ៉ាត់:
وَلَا طَعَامٌ إِلَّا مِنۡ غِسۡلِينٖ
Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọnúwẹ̀jẹ̀.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
لَّا يَأۡكُلُهُۥٓ إِلَّا ٱلۡخَٰطِـُٔونَ
Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَا تُبۡصِرُونَ
Nítorí náà, Èmi ń fi ohun tí ẹ̀ ń fojú rí búra
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
وَمَا لَا تُبۡصِرُونَ
àti ohun tí ẹ ò fojú rí.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولٖ كَرِيمٖ
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.[1]
[1] Āyah yìí jọ āyah 19 nínú sūrah at-Takwīr ní ìsọ, àmọ “Òjíṣẹ́” tí wọ́n gbàlérò nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh ni Òjíṣẹ́ abara, ìyẹn Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, Òjíṣẹ́ mọlāika ni wọ́n sì gbàlérò nínú āyah ti sūrah at-Takwīr. Sàkánì ti ìkọ̀ọ̀kan ti jẹyọ l’ó ṣàfi hàn èyí bẹ́ẹ̀.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَاعِرٖۚ قَلِيلٗا مَّا تُؤۡمِنُونَ
Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
وَلَا بِقَوۡلِ كَاهِنٖۚ قَلِيلٗا مَّا تَذَكَّرُونَ
Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
تَنزِيلٞ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
وَلَوۡ تَقَوَّلَ عَلَيۡنَا بَعۡضَ ٱلۡأَقَاوِيلِ
Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni,
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
لَأَخَذۡنَا مِنۡهُ بِٱلۡيَمِينِ
Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
ثُمَّ لَقَطَعۡنَا مِنۡهُ ٱلۡوَتِينَ
Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
فَمَا مِنكُم مِّنۡ أَحَدٍ عَنۡهُ حَٰجِزِينَ
Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa).
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
وَإِنَّهُۥ لَتَذۡكِرَةٞ لِّلۡمُتَّقِينَ
Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
وَإِنَّا لَنَعۡلَمُ أَنَّ مِنكُم مُّكَذِّبِينَ
Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn tó ń pe al-Ƙur’ān ní irọ́ wà nínú yín.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
وَإِنَّهُۥ لَحَسۡرَةٌ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ ńlá fún àwọn aláìgbàgbọ́.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
وَإِنَّهُۥ لَحَقُّ ٱلۡيَقِينِ
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo tó dájú.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ
Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
 
ការបកប្រែអត្ថន័យ ជំពូក​: អាល់ហាគកោះ
សន្ទស្សន៍នៃជំពូក លេខ​ទំព័រ
 
ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល - សន្ទស្សន៍នៃការបកប្រែ

ការបកប្រែដោយលោកអាពូ​ រ៉ហុីម៉ះ​ មុីកាអុីល​ អៃក្វីនី។

បិទ