ಪವಿತ್ರ ಕುರ್‌ಆನ್ ಅರ್ಥಾನುವಾದ - ಯೊರೂಬ ಅನುವಾದ * - ಅನುವಾದಗಳ ವಿಷಯಸೂಚಿ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ಅರ್ಥಗಳ ಅನುವಾದ ಶ್ಲೋಕ: (6) ಅಧ್ಯಾಯ: ಸೂರ ಅಲ್- ಅಹ್ ಝಾಬ್
ٱلنَّبِيُّ أَوۡلَىٰ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ مِنۡ أَنفُسِهِمۡۖ وَأَزۡوَٰجُهُۥٓ أُمَّهَٰتُهُمۡۗ وَأُوْلُواْ ٱلۡأَرۡحَامِ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلَىٰ بِبَعۡضٖ فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُهَٰجِرِينَ إِلَّآ أَن تَفۡعَلُوٓاْ إِلَىٰٓ أَوۡلِيَآئِكُم مَّعۡرُوفٗاۚ كَانَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَسۡطُورٗا
Ànábì ní ẹ̀tọ́ sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo ju ẹ̀mí ara wọn lọ (nípa ìfẹ́ rẹ̀ àti ìdájọ́ rẹ̀).¹ Àwọn aya rẹ̀ sì ni ìyá wọn. Nínú Tírà Allāhu, àwọn ẹbí, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ ju apá kan lọ. (Àwọn ẹbí tún ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ) ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn tó kúrò nínú ìlú Mọkkah fún ààbò ẹ̀sìn, àfi tí ẹ bá máa ṣe dáadáa kan sí àwọn ọ̀rẹ́ yín (wọ̀nyí ni ogún lè fi kàn wọ́n pẹ̀lú àsọọ́lẹ̀).² Ìyẹn wà nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ) ní àkọsílẹ̀.
1. Ìyẹn ni pé, lẹ́yìn Allāhu - tó ga jùlọ -, mùsùlùmí gbọ́dọ̀ fẹ́ràn Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ju ẹ̀mí ara rẹ̀. Bákan náà, nípa ìdájọ́, mùsùlùmí gbọ́dọ̀ tẹ ìfẹ́-inú rẹ̀ ba fún ìdájọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - .
2. Ẹ wo sūrah an-Nisā’; 4:7-8, 11-12 àti 176 fún ogún pípín.
ಅರಬ್ಬಿ ವ್ಯಾಖ್ಯಾನಗಳು:
 
ಅರ್ಥಗಳ ಅನುವಾದ ಶ್ಲೋಕ: (6) ಅಧ್ಯಾಯ: ಸೂರ ಅಲ್- ಅಹ್ ಝಾಬ್
ಅಧ್ಯಾಯಗಳ ವಿಷಯಸೂಚಿ ಪುಟ ಸಂಖ್ಯೆ
 
ಪವಿತ್ರ ಕುರ್‌ಆನ್ ಅರ್ಥಾನುವಾದ - ಯೊರೂಬ ಅನುವಾದ - ಅನುವಾದಗಳ ವಿಷಯಸೂಚಿ

ಪವಿತ್ರ ಕುರ್‌ಆನ್ ಯೊರೂಬ ಅರ್ಥಾನುವಾದ - ಶೈಖ್ ಅಬೂ ರಹೀಮ ಮೀಕಾಯೀಲ್ ಐಕ್ವೀನಿ. ಮುದ್ರಣ: 1432 ಹಿ.

ಮುಚ್ಚಿ