Check out the new design

ಪವಿತ್ರ ಕುರ್‌ಆನ್ ಅರ್ಥಾನುವಾದ - ಯೊರುಬಾ ಅನುವಾದ - ಅಬೂ ರಹೀಮಾ ಮೀಕಾಯಿಲ್ * - ಅನುವಾದಗಳ ವಿಷಯಸೂಚಿ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ಅರ್ಥಗಳ ಅನುವಾದ ಶ್ಲೋಕ: (13) ಅಧ್ಯಾಯ: ಸಬಅ್
يَعۡمَلُونَ لَهُۥ مَا يَشَآءُ مِن مَّحَٰرِيبَ وَتَمَٰثِيلَ وَجِفَانٖ كَٱلۡجَوَابِ وَقُدُورٖ رَّاسِيَٰتٍۚ ٱعۡمَلُوٓاْ ءَالَ دَاوُۥدَ شُكۡرٗاۚ وَقَلِيلٞ مِّنۡ عِبَادِيَ ٱلشَّكُورُ
Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí ó bá fẹ́ fún un nípa mímọ àwọn ilé (ilé ìjọ́sìn àti ilé ìgbé), àwọn ère,[1] àwọn àwo tó jìn kòtò tó fẹ̀ bí àbàtà[2] àti àwọn ìkòkò tó rídìí múlẹ̀.[3] Ẹ̀yin ènìyàn (Ànábì) Dāwūd, ẹ ṣiṣẹ́ ìdúpẹ́ (fún Allāhu). Díẹ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Mi sì ni olùdúpẹ́.
[1] Ní àsìkò Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a -, gbígbẹ́ ère fún fífi ṣe ọ̀ṣọ́ sínú ilé kì í ṣe èèwọ̀. Àmọ́ ní àsìkò Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó ti di èèwọ̀, yálà ó jẹ́ ère tàbí àwòrán n̄ǹkan abẹ̀mí. [2] Àpẹ̀ẹrẹ ìyẹn ni àwọn àwo tí àwọn ènìyàn máa ń ṣe sínú ilé ìwẹ̀ tí ènìyàn máa ń wẹ̀ nínú rẹ̀ “bath tub”. [3] Àpẹ̀ẹrẹ ìyẹn ni àwọn apẹ irin ìdáná ńlá ńlá.
ಅರಬ್ಬಿ ವ್ಯಾಖ್ಯಾನಗಳು:
 
ಅರ್ಥಗಳ ಅನುವಾದ ಶ್ಲೋಕ: (13) ಅಧ್ಯಾಯ: ಸಬಅ್
ಅಧ್ಯಾಯಗಳ ವಿಷಯಸೂಚಿ ಪುಟ ಸಂಖ್ಯೆ
 
ಪವಿತ್ರ ಕುರ್‌ಆನ್ ಅರ್ಥಾನುವಾದ - ಯೊರುಬಾ ಅನುವಾದ - ಅಬೂ ರಹೀಮಾ ಮೀಕಾಯಿಲ್ - ಅನುವಾದಗಳ ವಿಷಯಸೂಚಿ

ಅನುವಾದ - ಶೈಖ್ ಅಬೂ ರಹೀಮಾ ಮೀಕಾಯಿಲ್

ಮುಚ್ಚಿ