Check out the new design

ಪವಿತ್ರ ಕುರ್‌ಆನ್ ಅರ್ಥಾನುವಾದ - ಯೊರುಬಾ ಅನುವಾದ - ಅಬೂ ರಹೀಮಾ ಮೀಕಾಯಿಲ್ * - ಅನುವಾದಗಳ ವಿಷಯಸೂಚಿ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ಅರ್ಥಗಳ ಅನುವಾದ ಅಧ್ಯಾಯ: ಅಲ್ -ಮಾಇದ   ಶ್ಲೋಕ:
وَلَوۡ أَنَّ أَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ ءَامَنُواْ وَٱتَّقَوۡاْ لَكَفَّرۡنَا عَنۡهُمۡ سَيِّـَٔاتِهِمۡ وَلَأَدۡخَلۡنَٰهُمۡ جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú àwọn onítírà gbàgbọ́ ní òdodo, kí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), Àwa ìbá pa àwọn àìda wọn rẹ́ fún wọn, Àwa ìbá sì mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
ಅರಬ್ಬಿ ವ್ಯಾಖ್ಯಾನಗಳು:
وَلَوۡ أَنَّهُمۡ أَقَامُواْ ٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِم مِّن رَّبِّهِمۡ لَأَكَلُواْ مِن فَوۡقِهِمۡ وَمِن تَحۡتِ أَرۡجُلِهِمۚ مِّنۡهُمۡ أُمَّةٞ مُّقۡتَصِدَةٞۖ وَكَثِيرٞ مِّنۡهُمۡ سَآءَ مَا يَعۡمَلُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn (ìyẹn, al-Ƙur’ān), wọn ìbá máa jẹ láti òkè wọn àti láti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn. Ìjọ kan ń bẹ nínú wọn tó dúró déédé, (àmọ́) ohun tí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn ń ṣe níṣẹ́ burú.[1]
1. Ọ̀wọ́ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ìpèpè Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dé bá láyé, tí wọ́n sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Wọ́n sì gba ’Islām.
ಅರಬ್ಬಿ ವ್ಯಾಖ್ಯಾನಗಳು:
۞ يَٰٓأَيُّهَا ٱلرَّسُولُ بَلِّغۡ مَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَۖ وَإِن لَّمۡ تَفۡعَلۡ فَمَا بَلَّغۡتَ رِسَالَتَهُۥۚ وَٱللَّهُ يَعۡصِمُكَ مِنَ ٱلنَّاسِۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Ìwọ Òjíṣẹ́, kéde gbogbo ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Tí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò jẹ́ iṣẹ́ Rẹ̀ pé. Allāhu yó sì dáàbò bò ọ́ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́ (àwọn tí wọn kò fẹ́ mọ̀nà).
ಅರಬ್ಬಿ ವ್ಯಾಖ್ಯಾನಗಳು:
قُلۡ يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَسۡتُمۡ عَلَىٰ شَيۡءٍ حَتَّىٰ تُقِيمُواْ ٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكُم مِّن رَّبِّكُمۡۗ وَلَيَزِيدَنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُم مَّآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَ طُغۡيَٰنٗا وَكُفۡرٗاۖ فَلَا تَأۡسَ عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Sọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, ẹ ò rí kiní kan ṣe (nínú ẹ̀sìn) títí ẹ máa fi lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín (ìyẹn, al-Ƙur’ān).” Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ aláìgbàgbọ́.
ಅರಬ್ಬಿ ವ್ಯಾಖ್ಯಾನಗಳು:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلصَّٰبِـُٔونَ وَٱلنَّصَٰرَىٰ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tó di yẹhudi, - àwọn sọ̄bi’ūn àti àwọn nasọ̄rọ̄, - ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì ṣiṣẹ́ rere, kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:62 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:90.
ಅರಬ್ಬಿ ವ್ಯಾಖ್ಯಾನಗಳು:
لَقَدۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ وَأَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهِمۡ رُسُلٗاۖ كُلَّمَا جَآءَهُمۡ رَسُولُۢ بِمَا لَا تَهۡوَىٰٓ أَنفُسُهُمۡ فَرِيقٗا كَذَّبُواْ وَفَرِيقٗا يَقۡتُلُونَ
A kúkú gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. A sì rán àwọn Òjíṣẹ́ kan sí wọn. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ kan bá dé bá wọn pẹ̀lú ohun tí ẹ̀mí wọn kò fẹ́, wọ́n pe igun kan ní òpùrọ́, wọ́n sì ń pa igun kan.
ಅರಬ್ಬಿ ವ್ಯಾಖ್ಯಾನಗಳು:
 
ಅರ್ಥಗಳ ಅನುವಾದ ಅಧ್ಯಾಯ: ಅಲ್ -ಮಾಇದ
ಅಧ್ಯಾಯಗಳ ವಿಷಯಸೂಚಿ ಪುಟ ಸಂಖ್ಯೆ
 
ಪವಿತ್ರ ಕುರ್‌ಆನ್ ಅರ್ಥಾನುವಾದ - ಯೊರುಬಾ ಅನುವಾದ - ಅಬೂ ರಹೀಮಾ ಮೀಕಾಯಿಲ್ - ಅನುವಾದಗಳ ವಿಷಯಸೂಚಿ

ಅನುವಾದ - ಶೈಖ್ ಅಬೂ ರಹೀಮಾ ಮೀಕಾಯಿಲ್

ಮುಚ್ಚಿ