Check out the new design

ශුද්ධවූ අල් කුර්ආන් අර්ථ කථනය - යුරෝපීය පරිවර්තනය - අබූ රහීමා මයිකල් * - පරිවර්තන පටුන

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

අර්ථ කථනය පරිච්ඡේදය: අල් මාඉදා   වාක්‍යය:
أُحِلَّ لَكُمۡ صَيۡدُ ٱلۡبَحۡرِ وَطَعَامُهُۥ مَتَٰعٗا لَّكُمۡ وَلِلسَّيَّارَةِۖ وَحُرِّمَ عَلَيۡكُمۡ صَيۡدُ ٱلۡبَرِّ مَا دُمۡتُمۡ حُرُمٗاۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِيٓ إِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ
Wọ́n ṣe odò dídẹ àti jíjẹ oúnjẹ (òkúǹbete) inú rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fún yín. Ó jẹ́ n̄ǹkan ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn onírìn-àjò. Wọ́n sì ṣe ìgbẹ́ dídẹ ní èèwọ̀ fún yín nígbà tí ẹ bá wà ní nínú aṣọ hurumi (hajj tàbí ‘umrah). Ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí wọ́n máa ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
අල්කුර්ආන් අරාබි අර්ථ විවරණ:
۞ جَعَلَ ٱللَّهُ ٱلۡكَعۡبَةَ ٱلۡبَيۡتَ ٱلۡحَرَامَ قِيَٰمٗا لِّلنَّاسِ وَٱلشَّهۡرَ ٱلۡحَرَامَ وَٱلۡهَدۡيَ وَٱلۡقَلَٰٓئِدَۚ ذَٰلِكَ لِتَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَأَنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٌ
Allāhu ṣe Kaabah Ilé Ọ̀wọ̀ ní ibùdúró ṣẹ̀sìn fún àwọn ènìyàn. (N̄ǹkan ààbò náà ni) àwọn oṣù ọ̀wọ̀, àwọn ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
අල්කුර්ආන් අරාබි අර්ථ විවරණ:
ٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ وَأَنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le níbi ìyà. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
අල්කුර්ආන් අරාබි අර්ථ විවරණ:
مَّا عَلَى ٱلرَّسُولِ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُۗ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تُبۡدُونَ وَمَا تَكۡتُمُونَ
Kò sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ náà bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn). Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
අල්කුර්ආන් අරාබි අර්ථ විවරණ:
قُل لَّا يَسۡتَوِي ٱلۡخَبِيثُ وَٱلطَّيِّبُ وَلَوۡ أَعۡجَبَكَ كَثۡرَةُ ٱلۡخَبِيثِۚ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ
Sọ pé: “Ohun burúkú àti ohun dáadáa kò dọ́gba, púpọ̀ ohun burúkú ìbáà jọ ọ́ lójú”. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, ẹ̀yin onílàákàyè, nítorí kí ẹ lè jèrè.”
අල්කුර්ආන් අරාබි අර්ථ විවරණ:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَسۡـَٔلُواْ عَنۡ أَشۡيَآءَ إِن تُبۡدَ لَكُمۡ تَسُؤۡكُمۡ وَإِن تَسۡـَٔلُواْ عَنۡهَا حِينَ يُنَزَّلُ ٱلۡقُرۡءَانُ تُبۡدَ لَكُمۡ عَفَا ٱللَّهُ عَنۡهَاۗ وَٱللَّهُ غَفُورٌ حَلِيمٞ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe máa bèèrè nípa àwọn n̄ǹkan sá. Tí A bá fi hàn yín, ó máa kó ìpalára ba yín. Tí ẹ bá sì bèèrè nípa (àwọn n̄ǹkan tó yẹ láti bèèrè nípa ẹ̀sìn) nígbà tí À ń sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ lọ́wọ́, A máa fi hàn yín. Allāhu ti ṣe àmójúkúrò nípa rẹ̀. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.[1]
1. Ìyẹn ni pé, ìbéèrè àpọ̀jù lè bí wàhálà.
අල්කුර්ආන් අරාබි අර්ථ විවරණ:
قَدۡ سَأَلَهَا قَوۡمٞ مِّن قَبۡلِكُمۡ ثُمَّ أَصۡبَحُواْ بِهَا كَٰفِرِينَ
Ìjọ kan kúkú ti bèèrè rẹ̀ ṣíwájú yín. Lẹ́yìn náà, wọ́n sì di aláìgbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.
අල්කුර්ආන් අරාබි අර්ථ විවරණ:
مَا جَعَلَ ٱللَّهُ مِنۢ بَحِيرَةٖ وَلَا سَآئِبَةٖ وَلَا وَصِيلَةٖ وَلَا حَامٖ وَلَٰكِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَۖ وَأَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ
Allāhu kò fi ẹran bahīrah, ẹran sā’ibah, ẹran wasīlah àti ẹran hām lọ́lẹ̀.[1] Ṣùgbọ́n àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.
1. Ìwọ̀nyí ni orúkọ tí àwọn Lárúbáwá fún àwọn ẹran-ọ̀sìn tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì ka àwọn ẹran náà kún ẹran òrìṣà.
අල්කුර්ආන් අරාබි අර්ථ විවරණ:
 
අර්ථ කථනය පරිච්ඡේදය: අල් මාඉදා
සූරා පටුන පිටු අංක
 
ශුද්ධවූ අල් කුර්ආන් අර්ථ කථනය - යුරෝපීය පරිවර්තනය - අබූ රහීමා මයිකල් - පරිවර්තන පටුන

අෂ්-ෂෙයික් අබූ රහීමා මයිකල් එක්වයිනී විසින් පරිවර්තනය කරන ලදී.

වසන්න