Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.¹ Wọn kò sì mọ àkókò tí A óò jí wọn dìde (nínú sàréè).
1. Ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ẹ̀rí ìjọ Ahmadiyyah àti àwọn irú wọn gbogbo lórí ìgbàgbọ́ wọn pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti kú, kò sì níí padà wá sílé ayé mọ́ ni gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.”. Àwọn wọ̀nyí ń fi rinlẹ̀ pé níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé āyah 20 tó ṣíwájú gbólóhùn náà ń sọ nípa ipò tí àwọn n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn sọ di olúwa àti ọlọ́hun wọn lẹ́yìn Allāhu wà, ìyẹn ni pé, wọn kò lè dá ẹ̀dá kan àti pé òkú ni wọ́n, wọ́n ní nígbà náà, Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti kú nítorí pé, òun náà wà lára n̄ǹkan tí àwọn kan sọ di ọlọ́hun, olúwa àti olùgbàlà. Wọ́n fi kún un pé, “Ṣebí Ànábì ‘Īsā náà kò lè dá n̄ǹkan kan.”
Ọ̀rọ̀ wọn yìí jìnnà sí òtítọ́. Àti pé wọ́n ti gbé gbólóhùn náà tayọ ẹnu-ààlà. Wọ́n sì ti fi àtamọ́ mọ́ àtamọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Èyí tó jẹ́ òdodo ọ̀rọ̀ ni pé, gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.” kò sọ ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - di ohun tó ti ṣẹlẹ̀. Ṣebí àwọn mọlāika kan wà lára n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣé òkú ni àwọn mọlaika náà ni tàbí alààyè? A ò kúkú tí ì gbọ́ ikú mọlaika kan kan rí. Bákan náà, aṣ-Ṣatọ̄n ar-Rọjīm jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún. Ṣé òkú ni Ṣaetọ̄n náà ni tàbí alààyè? Rárá, kò ì kú.
Síwájú sí i, àwọn ènìyàn kan ń jọ́sìn fún òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀. Ṣé wọ́n ti gbọ́ ikú tiwọn náà ni? Kò sí ọ̀kan nínú wọn tó tí ì di òkú. Kódà a kúkú rí àwọn ọlọ́hun mìíràn tó jẹ́ pé láti ojú-ayé wọn ni àwọn ẹ̀dá kan ti ń jọ́sìn fún wọn lẹ́yìn Allāhu. Àpẹ̀ẹrẹ irú wọn ni “Sati Guru Maraj” tí ó sọ ara di ọlọ́hun nínú ìlú Ìbàdàn. Alààyè ni ọ̀gbẹni náà, kò ì tí ì kú, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kú ni lọ́jọ́ ti àkókò ikú rẹ̀ bá dé.
Lódodo ni pé àwọn nasọ̄rọ̄ ti sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam di ẹni tí wọ́n ń jọ́sìn fún, àmọ́ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - kò ì kù o. Ó sì wà nípò alààyè nínú sánmọ̀, bí Allāhu ṣe fẹ́.” Kò wá sí ẹ̀rí tààrà kan kan tó fi rinlẹ̀ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti kú bí kò ṣe āyah onípọ́nna èyí tí a ti ṣe àlàyé lórí rẹ̀ ṣíwájú nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah āli-’Imrọ̄n 3:55.
Dípò kí á rí āyah kan tàbí hadīth kan tààrà lórí ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, hadīth tó ń fi ìpadàbọ̀ rẹ̀ rinlẹ̀ là ń rí. Ẹni tí kò ì kú ló sì lè padà wá sílé ayé.
Kí wá ni èròǹgbà Allāhu lórí gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n),”? Ìtúmọ̀ àkànlò èdè ló wà fún gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n),” nínú āyah náà, kì í ṣe ìtúmọ̀ àdámọ́. Ìdí ni pé, nígbà tí kò bá sí ìwúlò kan kan tí a lè rí lára ẹ̀dá, irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ti wà nípò ẹni tí a lè ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú “òkú” nítorí pé, òkú ni kò ní àǹfààní kan tí ó lè ṣe fún ara rẹ̀ àti fún àwọn alààyè. Nítorí náà, Allāhu ń fi gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.” pe làákàyè gbogbo ẹnikẹ́ni to ń jọ́sìn fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀ pé kò sí àǹfààní kan kan tí irú olùjọ́sìn náà lè rí lọ́dọ̀ n̄ǹkan tó sọ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu, gẹ́gẹ́ bí alààyè kò ṣe lè rí àǹfààní kan kan láti ara òkú.
Wàyí níwọ̀n ìgbà tí àwọn nasọ̄rọ̄ ti sọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam di ẹni tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, kò sí àǹfààní kan tàbí oore kan tí ó lè ṣe fún wọn, wọn ìbáà pariwo orúkọ rẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nígbà igba. Àpẹ̀ẹrẹ àyè mìíràn tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - ti lo kalmọh “òkú” àmọ́ tí kò fi ọ̀nà kan kan túmọ̀ sí “ẹni tí ó ti kú” bí kò ṣe ẹni tí kò lè ṣàǹfààní fún ara rẹ̀ àti fún ẹlòmíìràn ni sūrah al-’Ani‘ām; 6:122.
Bákan náà, Allāhu pe àwọn òrìṣà ní òkú nítorí pé, ère tí kò sí ẹ̀mí lára rẹ̀ ni àwọn òrìṣà náà. Ipò òkú, ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, ẹni tí kò lè ríran, ẹni tí kò lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́ áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa ran ẹlòmíìràn lọ́wọ́ ni ipò tí gbogbo ère òrìṣà wà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ère Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam àti igi àgbélébùú rẹ̀ tí wọ́n gbẹ́, tí wọ́n ń jọ́sìn fún, kò lè sọ̀rọ̀, kò lè ríran, kò sì lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́ áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa ran ẹlòmíìràn lọ́wọ́.
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀. Àti pé dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbèéraga.
(Àwọn ni) àwọn tí mọlāika ń pa nígbà tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn lọ́wọ́. Ní àsìkò yìí ni wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (wọ́n sì wí pé): “Àwa kò ṣe iṣẹ́ aburú kan kan.” Bẹ́ẹ̀ ni! Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ṣé wọ́n ń retí ohun kan yàtọ̀ sí pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí àṣẹ Olúwa rẹ dé? Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ti ṣe. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Wọ́n ń fi ìpín kan nínú ohun tí A pèsè fún wọn lélẹ̀ fún ohun tí wọn kò nímọ̀ nípa rẹ̀.¹ Mo fi Allāhu búra, dájúdájú wọn yóò bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń dá ní àdápa irọ́.
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n ń pe àwọn n̄ǹkan kan ní n̄ǹkan òrìṣà bí àpẹ̀ẹrẹ, wọ́n ń pe àwọn ẹran kan ní ẹran òrìṣà, wọ́n sì ń fi àwọn kan rúbọ fún àwọn òrìṣà wọn. Irú āyah yìí ti ṣíwájú nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:103.
Wọ́n tún ń fi (bíbí) àwọn ọmọbìnrin lélẹ̀ fún Allāhu - Mímọ́ ni fún Un (kò bímọ). - Wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń fẹ́ lélẹ̀ fún tiwọn!
Wọ́n ń fi (ọmọbìnrin) - n̄ǹkan tí wọn kórira - lélẹ̀ fún Allāhu. Ahọ́n wọn sì ń ròyìn irọ́ pé dájúdájú rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni tàwọn. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Iná ni tiwọn. Àti pé dájúdájú wọ́n máa pa wọ́n tì sínú rẹ̀ ni.
Allāhu fi ara Rẹ̀ búra,¹ dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. Nígbà náà, Èṣù ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn; òun sì ni ọ̀rẹ́ wọn ní òní. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
1. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi Ara Rẹ̀ búra. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún Un láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Òun l’Ó ni Ara Rẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ẹ̀tọ́ fún ẹ̀dá kan láti fi ara rẹ̀ búra dípò Allāhu, tí Ó ni í.
A kò sọ Tírà náà kalẹ̀ fún ọ bí kò ṣe pé kí o lè ṣàlàyé fún wọn ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí;¹ ó sì jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
Allāhu l’Ó ṣoore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan nínú arísìkí. Àwọn tí A fún ní oore àjùlọ, kí wọ́n fún àwọn ẹrú wọn ní arísìkí wọn, kí wọ́n sì jọ pín in ní dọ́gban̄n̄dọ́gba!¹ Nítorí náà, ṣe ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yóò máa takò?
1. Àkàwé kan nìyí tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi lélẹ̀ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti pe làákàyè wọn sí ohun tí wọn kò lè gbà, àmọ́ tí wọ́n ń fi lọ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -. Kókó àkàwé náà sì ni pé, ǹjẹ́ ẹnì kan lè gbà fún ẹrú rẹ̀, yálà ẹrú ogun tàbí ẹrú àfowórà, pé kí òun àti ẹrú rẹ̀ jọ pín dúkìá rẹ̀ sí méjì ní dọ́gban̄n̄dọ́gba. Àwọn dúkìá bíi àwọn ìyàwó, àwọn ọmọ àti gbogbo dúkìá mìíràn, ǹjẹ́ olówó ẹrú lè kó ìlàjì rẹ̀ fún ẹrú rẹ̀ bí? Kò níí ṣe bẹ́ẹ̀, kò sì lè ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, pípe ẹ̀dá kan nínú ẹ̀dá Allāhu ní olúwa àti olùgbàlà tí wọn yóò máa jọ́sìn fún, ó ti jọ pé ẹ̀dá náà tí ó jẹ́ ẹrú fún Allāhu ti sọra rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Allāhu níbi dúkìá Rẹ̀, tí í ṣe àwa ẹ̀dá Rẹ̀. Nítorí náà, āyah yìí kò ní ìtúmọ̀ pípín dúkìá ẹni sí méjì fún ẹrú wa, bí kò ṣe àkàwé. Bákan náà, āyah yìí kò sì ní kí á sọ olówó di ẹgbẹ́ olòṣì, gẹ́gẹ́ bí ètò ìjọba “communism”. Ohun tí ẹ̀dá kò lè gbà, àmọ́ tí ó ń fi lọ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ni àkàwé tí ó jẹyọ nínú āyah náà.
Dípò (kí wọ́n jọ́sìn fún) Allāhu, wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò ní ìkápá arísìkí kan kan fún wọn nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; wọn kò sì lágbára (láti ṣe n̄ǹkan kan).
Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ẹrú kan tí ó wà lábẹ́ ọ̀gá, tí kò sì lè dá n̄ǹkan kan ṣe àti ẹni tí A fún ní arísìkí tó dára láti ọ̀dọ̀ wa, tí ó sì ń ná nínú rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Ṣé wọ́n dọ́gba bí?¹ Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
(Rántí) ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí kan dìde nínú gbogbo ìjọ (àwọn Ànábì), lẹ́yìn náà, A ò níí yọ̀ǹda (àròyé ṣíṣe) fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti padà ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A ó ṣe àlékún ìyà lórí ìyà fún wọn ni nítorí pé wọ́n ń ṣèbàjẹ́.
Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ yín máa tán. Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì máa wà títí láéláé. Dájúdájú A sì máa san àwọn tó ṣe sùúrù ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé tó dára. Dájúdájú A sì máa san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Àti pé A ṣe ohun tí A sọ fún ọ ṣíwájú ní èèwọ̀ fún àwọn tó di yẹhudi.¹ A kò sì ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.
Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jẹ́ aṣíwájú-àwòkọ́ṣe-rere, olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì jẹ́ ara àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Àwọn tí wọ́n ṣe (àgbéga) ọjọ́ Sabt fún ni àwọn tó yapa-ẹnu nípa lórí rẹ̀.¹ Dájúdájú Olúwa rẹ yóò kúkú ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
1. Yíyapa-ẹnu tí àwọn yẹhudi yapa-ẹnu lórí ṣíṣe àgbéga fún ọjọ́ Jímọ̀, tí wọ́n sì fi ọjọ́ Sabt dípò rẹ̀, l’ó ṣokùnfà bí ọjọ́ náà ṣe di dandan fún ọ̀wọ́ wọn nìkan láti ṣe àgbéga rẹ̀. Nítorí náà, ọpẹ́ ni fún Allāhu tí kò ṣe ìjọ́ mùsùlùmí ní olùyapa lórí ṣíṣe àgbéga ọjọ́ Jímọ̀, ọjọ́ t’ó lóore jùlọ nínú ọ̀ṣẹ̀.
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
ผลการค้นหา:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".