Check out the new design

Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail * - Indise ng mga Salin

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Salin ng mga Kahulugan Surah: Saba’   Ayah:
قُلۡ جَآءَ ٱلۡحَقُّ وَمَا يُبۡدِئُ ٱلۡبَٰطِلُ وَمَا يُعِيدُ
Sọ pé: “Òdodo ti dé. Irọ́ (aṣ-ṣaetọ̄n) kò lè mú n̄ǹkan bẹ, kò sì lè dá n̄ǹkan padà (lẹ́yìn tó ti kú).”
Ang mga Tafsir na Arabe:
قُلۡ إِن ضَلَلۡتُ فَإِنَّمَآ أَضِلُّ عَلَىٰ نَفۡسِيۖ وَإِنِ ٱهۡتَدَيۡتُ فَبِمَا يُوحِيٓ إِلَيَّ رَبِّيٓۚ إِنَّهُۥ سَمِيعٞ قَرِيبٞ
Sọ pé: “Tí mo bá ṣìnà, mo ṣìnà fún ẹ̀mí ara mi ni. Tí mo bá sì mọ̀nà, nípa ohun tí Olúwa mi fi ránṣẹ́ sì mi ní ìmísí ni. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Alásùn-únmọ́ ẹ̀dá.”[1]
1. Okùnfà āyah yìí ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah ń sọ fún Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé, “Tí o bá fi lè pa ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà àwọn bàbá rẹ tì, o ti ṣìnà nìyẹn.” Allāhu sì sọ āyah kalẹ̀.
Ang mga Tafsir na Arabe:
وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذۡ فَزِعُواْ فَلَا فَوۡتَ وَأُخِذُواْ مِن مَّكَانٖ قَرِيبٖ
Tí ó bá jẹ́ pé o lè rí (ẹ̀sín wọn ni) nígbà tí ẹ̀rù bá dé bá wọn (ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí i pé), kò níí sí ìmóríbọ́ kan (fún wọn). A sì máa gbá wọn mú láti àyè tó súnmọ́.
Ang mga Tafsir na Arabe:
وَقَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِهِۦ وَأَنَّىٰ لَهُمُ ٱلتَّنَاوُشُ مِن مَّكَانِۭ بَعِيدٖ
Wọn yóò wí pé: “A gbàgbọ́ nínú (al-Ƙur’ān báyìí).” Báwo ni ọwọ́ wọn ṣe lè tẹ ìgbàgbọ́ òdodo láti àyè tó jìnnà (ìyẹn, ọ̀run).”
Ang mga Tafsir na Arabe:
وَقَدۡ كَفَرُواْ بِهِۦ مِن قَبۡلُۖ وَيَقۡذِفُونَ بِٱلۡغَيۡبِ مِن مَّكَانِۭ بَعِيدٖ
Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ ṣíwájú (nílé ayé). Wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀kọ̀ láti àyè tó jìnnà (ìyẹn, ilé ayé).
Ang mga Tafsir na Arabe:
وَحِيلَ بَيۡنَهُمۡ وَبَيۡنَ مَا يَشۡتَهُونَ كَمَا فُعِلَ بِأَشۡيَاعِهِم مِّن قَبۡلُۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ فِي شَكّٖ مُّرِيبِۭ
A sì fi gàgá sí ààrin àwọn àti ohun tí wọ́n ń ṣojú kòkòrò rẹ̀[1] gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe fún àwọn ẹgbẹ́ wọn ní ìṣáájú. Dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì tó gbópọn (nípa Ọjọ́ Àjíǹde).
1. Àwọn aláìgbàgbọ́ yóò máa ṣojú kòkòrò sí ìronúpìwàdà àti ìpadà sí ilé ayé ní Ọjọ́ Àjíǹde nígbà tí àìgbàgbọ́ wọn bá di ìyà ńlá fún wọn. Àmọ́ Allāhu kò níí fún wọn ní àyè láti lọ ronú pìwàdà tàbí láti padà sí ilé ayé.
Ang mga Tafsir na Arabe:
 
Salin ng mga Kahulugan Surah: Saba’
Indise ng mga Surah Numero ng Pahina
 
Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail - Indise ng mga Salin

Salin ni Abu Rahima Mikhail Aikweiny.

Isara