Check out the new design

Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail * - Indise ng mga Salin

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Salin ng mga Kahulugan Surah: Fātir   Ayah:

Faatir

ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ جَاعِلِ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ رُسُلًا أُوْلِيٓ أَجۡنِحَةٖ مَّثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَۚ يَزِيدُ فِي ٱلۡخَلۡقِ مَا يَشَآءُۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin ní Òjíṣẹ́. Ó ń ṣe àlékún ohun tí Ó bá fẹ́ lára ẹ̀dá. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.[1]
1. Àgbọ́yé òǹkà tí ó jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:3 ni àgbọ́yé òǹkà tó tún jẹyọ nínú āyah yìí. Èyí túmọ̀ sí pé, alápá méjì wà nínú àwọn mọlāika, alápá mẹ́ta wà nínú wọn, alápá mẹ́rin sì wà nínú wọn. Alápá púpọ̀, tí apá rẹ̀ lé ní mẹ́rin, tún wà nínú wọn.
Ang mga Tafsir na Arabe:
مَّا يَفۡتَحِ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ مِن رَّحۡمَةٖ فَلَا مُمۡسِكَ لَهَاۖ وَمَا يُمۡسِكۡ فَلَا مُرۡسِلَ لَهُۥ مِنۢ بَعۡدِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Ohunkóhun tí Allāhu bá ṣí ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìkẹ́ fún àwọn ènìyàn, kò sí ẹni tí ó lè dì í mọ́wọ́ (láti dá a dúró). Ohunkóhun tí Ó bá sì mú dání, kò sí ẹni tí ó lè mú un wá lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ang mga Tafsir na Arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡۚ هَلۡ مِنۡ خَٰلِقٍ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fún yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?
Ang mga Tafsir na Arabe:
 
Salin ng mga Kahulugan Surah: Fātir
Indise ng mga Surah Numero ng Pahina
 
Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail - Indise ng mga Salin

Salin ni Abu Rahima Mikhail Aikweiny.

Isara