Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail Aikweiny * - Indise ng mga Salin

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Salin ng mga Kahulugan Ayah: (14) Surah: Al-Mulk
أَلَا يَعۡلَمُ مَنۡ خَلَقَ وَهُوَ ٱللَّطِيفُ ٱلۡخَبِيرُ
Ṣé kò mọ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ni?¹ Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán.
1. Ìtúmọ̀ méjì ló wà fún āyah yìí nínú àwọn tírà Tafsīr. Ìtúmọ̀ kìíní: “Ṣé kò mọ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ni?” Ìyẹn ni pé, “Ṣé ẹ̀dá kò mọ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni?” Ìyẹn ni pé, tí ẹ̀dá bá lérò pé, bí òun bá sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀, ó yẹ kí ẹ̀dá náà mọ̀ dájú pé, nínú ìròyìn Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni pé, Ẹlẹ́dàá nímọ̀ èrò-ọkàn àwọn ẹ̀dá Rẹ̀, áḿbọ̀sìbọ́sí ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ sọ ní ìkọ̀kọ̀.
Ìtúmọ̀ kejí: “Ṣé Allāhu kò mọ ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ni?” Ìyẹn ni pé, ṣé Allāhu kò mọ àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ tòhun tí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn, ọ̀rọ̀ gban̄gba wọn àti èrò-ọkàn wọn? Allāhu mọ gbogbo rẹ̀. Nítorí náà, kí ẹ̀dá bẹ̀rù Ẹlẹ́dàá ṣíwájú kí Ẹlẹ́dàá tó tú àwọn àṣírí ẹ̀dá Rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìṣírò-iṣẹ́ ẹ̀dá.
Ang mga Tafsir na Arabe:
 
Salin ng mga Kahulugan Ayah: (14) Surah: Al-Mulk
Indise ng mga Surah Numero ng Pahina
 
Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail Aikweiny - Indise ng mga Salin

Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an sa wikang Yoruba. Salin ni Abu Rahima Mikhail Aikweiny. Imprenta ng taong 1432 H.

Isara