Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (nìyí). Nítorí náà, wàhálà (iyèméjì) kan kò gbọ́dọ̀ sí nínú ọkàn rẹ lórí rẹ̀ láti fi ṣe ìkìlọ̀ àti ìrántí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Nítorí náà, dájúdájú A óò bi àwọn tí A ránṣẹ́ sí léèrè (nípa ìjẹ́pè). Dájúdájú A ó sì bi àwọn Òjíṣẹ́ léèrè (nípa ìjíṣẹ́).
Dájúdájú A óò ròyìn (iṣẹ́ ọwọ́ wọn) fún wọn pẹ̀lú ìmọ̀. Àwa kò ṣàì wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀)[1].
1. Ìyẹn ni pé, A ní ìmọ̀ sí ìgbésí ayé gbogbo wọn ní ìkọ̀ọ̀kan wọn. Kì í ṣe pé Allāhu dìjọ wà pẹ̀lú wọn nílé ayé. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mujādilah 58:7.
Apá kan ni Ó fi mọ̀nà, apa kan sì ni ìṣìnà di ẹ̀tọ́ lórí wọn. (Nítorí pé) dájúdájú wọ́n mú àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n ní aláfẹ̀yìntí lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà.
Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí tó pe àwọn āyah Rẹ̀ ní irọ́? Ìpín àwọn wọ̀nyẹn nínú kádàrá yóò máa tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa yóò wá bá wọn, tí wọn yóò gba ẹ̀mí wọn. Wọn yó sì sọ pé: “Níbo ni àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀yin ń pè lẹ́yìn Allāhu wà?” Wọn yóò wí pé: “Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́.” Wọ́n sì jẹ́rìí léra wọn lórí pé dájúdájú àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́.”
Àwọn tó sì gbàgbọ́ lódodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere - A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀ - àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò pe àwọn èrò inú Iná pé: “A ti rí ohun tí Olúwa wa ṣe àdéhùn rẹ̀ fún wa ní òdodo. Ǹjẹ́ ẹ̀yin náà rí ohun tí Olúwa yín ṣe àdéhùn (rẹ̀ fún yín) ní òdodo?” Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Olùpèpè kan yó sì pèpè láààrin wọn pé: “Kí ibi dandan Allāhu máa bẹ lórí àwọn alábòsí.”
Èrò inú Iná yóò pe èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra pé: “Ẹ fún wa nínú omi tàbí nínú ohun tí Allāhu pa lésè fún yín.” Wọn yóò sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ti ṣe méjèèjì ní èèwọ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́.”
Àwọn tó sọ ẹ̀sìn wọn di ìranù àti eré ṣíṣe, tí ìṣẹ̀mí ayé sì kó ẹ̀tàn bá wọn, ní òní ni A óò gbàgbé wọn[1] gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gbàgbé ìpàdé ọjọ́ wọn ti òní yìí àti (bí) wọ́n ṣe ń tako àwọn āyah Wa.
1. Allāhu kì í gbàgbé n̄ǹkan kan ìbáà kéré bí ọmọ iná igún. Àmọ́ fífi ọmọ Iná gbére sílẹ̀ gbére nínú Iná ti jọ ohun tí ó jọ pé wọ́n ti gbàgbé wọn sínú Iná.
Kí ni wọ́n ń retí bí kò ṣe ẹ̀san Rẹ̀?[1] Lọ́jọ́ tí ẹ̀san Rẹ̀ bá dé, àwọn tó gbàgbé rẹ̀ ṣíwájú yóò wí pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá. Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè rí àwọn olùṣìpẹ̀, kí wọ́n wá ṣìpẹ̀ fún wa tàbí kí wọ́n dá wa padà sílé ayé, kí á lè ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe?” Dájúdájú wọ́n ti ṣe ẹ̀mí wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.²
1. Ìyẹn ni pé, ohun tí ó máa kángun ọ̀rọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ nínú ìyà ní Ọjọ́ Ẹ̀san. 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:24.
Òun ni Ẹni tó ń rán atẹ́gùn wá (tó jẹ́) ìró ìdùnnú ṣíwájú àánú Rẹ̀, títí (atẹ́gùn náà) yóò fi gbé ẹ̀ṣújò tó wúwo, tí A sì máa dari rẹ̀ lọ sí òkú ilẹ̀. Nígbà náà, A máa fi sọ omi kalẹ̀. A sì máa fi mú gbogbo àwọn èso jáde. Báyẹn ni A ó ṣe mú àwọn òkú jáde nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
Wọ́n sì pè é lópùrọ́. Nítorí náà, A gba òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ là nínú ọkọ̀ ojú-omi. A sì tẹ àwọn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́ rì. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ tó fọ́jú (nípa òdodo).
Wọ́n wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí á lè jọ́sìn fún Allāhu nìkan ṣoṣo àti nítorí kí á lè pa ohun tí àwọn bàbá ńlá wa ń jọ́sìn fún tì? Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
Nítorí náà, pẹ̀lú àánú láti ọ̀dọ̀ Wa, A gba òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ là. A sì pa àwọn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́ run pátápátá; wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
Nítorí náà, wọ́n gún abo ràkúnmí náà pa. Wọ́n sì tàpá sí àṣẹ Olúwa wọn. Wọ́n sì wí pé: “Sọ̄lih, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.”
Kí sì ni ó jẹ́ èsì ìjọ rẹ̀ bí kò ṣe pé, wọ́n wí pé: “Ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ìlú yín, dájúdájú wọ́n jẹ́ ènìyàn kan tó ń fọra wọn mọ́ (níbi ẹ̀ṣẹ̀).”
Tí ó bá jẹ́ pé igun kan nínú yín gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n fi rán mi níṣẹ́, tí igun kan kò sì gbàgbọ́, nígbà náà ẹ ṣe sùúrù títí Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́ láààrin wa. Òun sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.
A kò rán Ànábì kan sí ìlú kan láì jẹ́ pé A fi ìpọ́njú àti ìnira kan àwọn ará ìlú náà nítorí kí wọ́n lè rawọ́-rasẹ̀ (sí Allāhu).
Lẹ́yìn náà, A fi (ohun) rere rọ́pò aburú (fún wọn) títí wọ́n fi pọ̀ (lóǹkà àti lọ́rọ̀). Wọ́n sì wí pé: “Ọwọ́ ìnira àti ìdẹ̀ra kúkú ti kan àwọn bàbá wa rí.”[1] Nítorí náà, A gbá wọn mú lójijì, wọn kò sì fura.
1. Àwọn wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ, wọn kò gbàgbọ́ pé àìgbàgbọ́ l’ó kó ìparun bá àwọn bàbá wọn. Èrò-ọkàn wọn ni pé, bí ọ̀rọ̀ ilé ayé ṣe rí ni pé, ènìyàn máa jìyà, ó sì máa jọrọ̀. Èrò-ọkàn wọn yìí mú wọn won̄koko mọ́ ìbọ̀rìṣà. Àwọn náà sì di ẹni ìparun bíi tàwọn bàbá wọn.
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú àwọn ará ìlú náà gbàgbọ́ lódodo ni, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), A ìbá ṣínà àwọn ìbùkún fún wọn láti inú sánmọ̀àti ilẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n pe òdodo nírọ́. Nígbà náà, A mú wọn nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn ìlú wọ̀nyí ni À ń fún ọ ní ìró nínú ìròyìn wọn. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ wọn ti mú àwọn ẹ̀rí tó yánjú wá bá wọn. (Ìkọ̀ọ̀kan ìjọ náà,) wọn kò kúkú níí gbàgbọ́ nínú ohun tí (ijọ́ tó ṣíwájú wọn) pè nírọ́ ṣíwájú (wọn). Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́.[1]
1. Ìyẹn ni pé, bí àwọn aláìgbàgbọ́ tó ṣíwájú ṣe pe ọ̀rọ̀ Allāhu nírọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn aláìgbàgbọ́ tó tẹ̀lé wọn ṣe. Irú kan-ùn ni gbogbo wọn. Ìdí sì nìyí tí ìkọ̀ọ̀kan ìjọ aláìgbàgbọ́ wọ̀nyẹn ṣe parun. Ẹ tún wo sūrah Yūnus; 10:74.
Ẹ̀tọ́ ni fún mi pé èmi kò gbọdọ̀ ṣàfitì ọ̀rọ̀ kan sọ́dọ̀ Allāhu àfi òdodo. Mo sì kúkú ti mú ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá mi lọ.”
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná).” Nígbà tí wọ́n jù ú sílẹ̀, wọ́n lo àlùpàyídà lójú àwọn ènìyàn. Wọ́n sì ṣẹ̀rùbà wọ́n. Àní sẹ́ wọ́n pidán ńlá.
A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” Nígbà náà, ó sì ń gbé ohun tí wọ́n ti pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.
Àti pé o ò kórira kiní kan lára wa (o ò sì rí àlèébù kan lára wa) bí kò ṣe nítorí pé, a gba àwọn àmì Olúwa wa gbọ́ nígbà tí ó dé bá wa. Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu. Kí O sì pa wá sípò mùsùlùmí.”
Nítorí náà, A sì fi ẹ̀kún omi, àwọn eṣú, àwọn kòkòrò iná, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ àti ẹ̀jẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn ní àwọn àmì tí ń tẹ̀léra wọn tó fojú hàn. Ńṣe ni wọ́n tún ṣègbéraga; wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Nígbà tí ìyà sọ̀kalẹ̀ lé wọn lórí, wọ́n wí pé: “Mūsā, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe fún ọ. Dájúdájú tí o bá fi lè gbé ìyà náà kúrò fún wa (pẹ̀lú àdúà rẹ), dájúdájú a máa gbà ọ́ gbọ́, dájúdájú a sì máa jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá ọ lọ.”
Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn, A sì tẹ̀ wọ́n rì sínú agbami odò nítorí pé, wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́. Wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀.
A sì jogún àwọn ibùyọ òòrùn lórí ilẹ̀ ayé àti ibùwọ̀ òòrùn rẹ̀, tí A fi ìbùnkún sí, fún àwọn ènìyàn tí wọ́n kà sí ọ̀lẹ. Ọ̀rọ̀ Olúwa Rẹ tó dára sì ṣẹ lórí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nítorí pé, wọ́n ṣe sùúrù. A sì pa ohun tí Fir‘aon àti ìjọ rẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n ń kọ́ nílé run.
A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄‘īl la agbami òkun kọjá. Nígbà náà, wọ́n kọjá lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n dúró ti àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì wí pé: “Mūsā, ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan.” (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ni ìjọ aláìmọ̀kan.[1]
1. Nínú ẹ̀rí tó ń fi rinlẹ̀ pé iṣẹ́-ìyanu kì í sábà mú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn di onígbàgbọ́ òdodo ni āyah yìí wa.
Èmi yóò ṣẹ́rí àwọn tó ń ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ kúrò níbi àwọn āyah[1] Mi; tí wọ́n bá rí gbogbo āyah, wọn kò níí gbà á gbọ́. Tí wọ́n bá rí ọ̀nà ìmọ̀nà, wọn kò níí mú un ní ọ̀nà. Tí wọ́n bá sì rí ọ̀nà ìṣìnà, wọn yóò mú un ní ọ̀nà. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́; wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀.
Àwọn tó sì pe àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ní irọ́, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Ṣé A óò san wọ́n ní ẹ̀san kan ni bí kò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́?
Àwọn ènìyàn (Ànábì) Mūsā, lẹ́yìn rẹ̀ (nígbà tí ó fi lọ bá Allāhu sọ̀rọ̀), wọ́n mú nínú ọ̀ṣọ́ wọn (láti fi ṣe) ère ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi, ó sì ń dún (bíi màálù). Ṣé wọn kò wòye sí i pé dájúdájú kò lè bá wọn sọ̀rọ̀ ni, kò sì lè fi ọ̀nà mọ̀ wọ́n? Wọ́n sì sọ ọ́ di àkúnlẹ̀bọ. Wọ́n sì jẹ́ alábòsí.
Dájúdájú àwọn tó sọ (ère) ọmọ màálù di àkúnlẹ̀bọ, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àti ìyẹpẹrẹ yóò bá wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn aládapa irọ́ ní ẹ̀san.
Àwọn tó ń tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tí wọ́n yóò bá àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn nínú at-Taorāh àti al-’Injīl, tí ó ń pa wọ́n láṣẹ ohun rere, tí ó ń kọ ohun burúkú fún wọn, tí ó ń ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fún wọn, tí ó sì ń ṣe àwọn n̄ǹkan àìdáa ní èèwọ̀ fún wọn, tí ó tún máa gbé ẹrù (àdéhùn tó wúwo) àti àjàgà tó ń bẹ lọ́rùn wọn[1] kúrò fún wọn; àwọn tó bá gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n bu iyì fún un, tí wọ́n ràn án lọ́wọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìmọ́lẹ̀ náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.
1. “Àjàgà ọrùn wọn ni èyí tí Allāhu - tó ga jùlọ - gbékọ́ ọrùn ọwọ́ wọn nígbà tí wọ́n wí pé “Dídì ni ọwọ́ Allāhu wà” gẹ́gẹ́ bí Allāhu - tó ga jùlọ - ṣe fi rinlẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’dah; 5:64.” (Tọbariy)
A sì pín wọn sí igun méjìlá (igun kọ̀ọ̀kan sì ní) ìran àti ìjọ. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ wá omi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Fi ọ̀pá rẹ na àpáta.” (Ó ṣe bẹ́ẹ̀) orísun omi méjìlá sì ṣẹ́yọ lára rẹ̀. Àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan sì ti dá ibùmu wọn mọ̀. A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fún wọn. A sọ (ohun mímu) mọ́nnù[1] àti (ohun jíjẹ) salwā² kalẹ̀ fun wọ́n. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín. Wọn kò sì ṣe àbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Bi wọ́n léèrè nípa ìlú tó wà ní ẹ̀bádò, nígbà tí wọ́n kọjá ẹnu-ààlà nípa ọjọ́ Sabt, nígbà tí ẹja wọn ń wá bá wọn ní ọjọ́ Sabt wọn, wọ́n sì máa léfòó sí ojú odò, ọjọ́ tí kì í bá sì ṣe ọjọ́ Sabt wọn, wọn kò níí wá bá wọn. Báyẹn ni A ṣe ń dán wọn wò nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.[1]
Nígbà tí wọ́n sì gbàgbé ohun tí wọ́n fi ṣèrántí fún wọn, A gba àwọn tó ń kọ aburú là. A sì fi ìyà tó le jẹ àwọn tó ṣàbòsí nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.
A dá wọn kékekèle sí orí ilẹ̀ ní ìjọ-ìjọ; àwọn ẹni rere wà nínú wọn, àwọn mìíràn tún wà nínú wọn. A sì fi àwọn ohun rere àti ohun burúkú dán wọn wò kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Àwọn bàbá wa ló kúkú bá Allāhu wá akẹgbẹ́ ṣíwájú (wa), àwa sì jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ lẹ́yìn wọn (ni a fi wò wọ́n kọ́ṣe pẹ̀lú àìmọ̀kan). Ṣé Ìwọ yóò pa wá run nítorí ohun tí àwọn tó ń ba iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn jẹ́[1] ṣe ni?”
1. Àwọn tó ń ba iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn jẹ́ ni àwọn ọ̀sẹbọ nítorí pé ẹbọ ṣíṣe máa ń ba iṣẹ́ ẹ̀dá jẹ́.
Dájúdájú A ti dá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àlùjànnú fún iná Jahanamọ (nítorí pé) wọ́n ní ọkàn, wọn kò sì fi gbọ́ àgbọ́yé; wọ́n ní ojú, wọn kò sì fi ríran; wọ́n ní etí, wọn kò sì fi gbọ́ràn. Àwọn wọ̀nyẹn dà bí ẹran-ọ̀sìn. Wọ́n wulẹ̀ sọnù jùlọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni afọ́nú-fọ́ra.
Ti Allāhu ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi pè É. Kí ẹ sì pa àwọn tó ń darí àwọn orúkọ Rẹ̀ kọ ọ̀nà òdì tì.[1] A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
1. Ẹni tí ó ń dárí àwọn orúkọ Allāhu - tó ga jùlọ - kọ ọ̀nà òdì ni ẹni tí ó ń sọ pé, "wọ́n yọ àwọn orúkọ òrìṣà kan jáde láti ara àwọn orúkọ Allāhu tó dára jùlọ àti àwọn ìròyìn Rẹ̀ tó ga jùlọ." Ẹni tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ti bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ó ti ṣẹbọ.
Ṣé wọn kò ronú jinlẹ̀ ni? Kò sí wèrè kan kan lára ẹni wọn (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a -. Ta sì ni bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.
Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?[1]
1. Gbólóhùn yìí "Nígbà náà, “hadīth wo” ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?" àti irú rẹ̀ tó wà nínú sūrah al-Mursalāt; 77:50 àti sūrah al-Jāthiyah; 45:6, kò túmọ̀ sí pé kò sí hadīth Ànábì torí pé, hadīth Ànábì náà ni sunnah Ànábì.
Sọ pé: “Èmi kò ní agbára àǹfààní tàbí ìnira kan tí mo lè fi kan ara mi àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Tí ó bá jẹ́ pé mo ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, èmi ìbá ti kó ohun púpọ̀ jọ nínú oore ayé (sí ọ̀dọ̀ mi) àti pé aburú ayé ìbá tí kàn mí. Ta ni èmi bí kò ṣe olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.”
Ṣùgbọ́n nígbà tí Allāhu fún àwọn méjèèjì ní ọmọ rere, wọ́n sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Un nípasẹ̀ ohun tí Ó fún àwọn méjèèjì. Allāhu sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.[1]
1. Ẹbọ tí wọ́n ṣe nípasẹ̀ ọmọ wọn ni sísọ ọmọ náà ni orúkọ tí ó fi àìmoore hàn sí Allāhu. Bí àpẹ̀ẹrẹ, kí Allāhu fún ènìyàn lọ́mọ, kí ènìyàn wá sọ ọmọ náà ni “ ‘abdu-ṣṣams, ‘abdul-ƙọmọr” dípò “ ‘abdullāh, ‘abdur-Rahmọ̄n” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ṣé wọ́n ní ẹsẹ̀ tí wọ́n lè fi rìn ni? Tàbí ṣé wọ́n ní ọwọ́ tí wọ́n lè fi gbá n̄ǹkan mú? Tàbí ṣé wọ́n ní ojú tí wọ́n lè fi ríran? Tàbí ṣé wọ́n ní etí tí wọ́n lè fi gbọ́rọ̀? Sọ pé: “Ẹ pe àwọn òrìṣà yín, lẹ́yìn náà kí ẹ déte sí mi, kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára.
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
Mga Resulta ng Paghahanap:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".