Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali * - Mealler fihristi

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Anlam tercümesi Sure: Sûretu'n-Necm   Ayet:

Suuratun-Naj'm

وَٱلنَّجۡمِ إِذَا هَوَىٰ
Allāhu fi gbólóhùn kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ búra.¹
1. Ìtúmọ̀ kejì ni pé, Allāhu fi ìràwọ̀ nígbà tí ó bá wálẹ̀ (wọ̀ọ̀kùn ní ìdájí) búra. Àmọ́ ìtúmọ̀ àkọ́kọ́ ló súnmọ́ jùlọ ní ìbámu sí sàkánì rẹ̀ pẹ̀lú àwọn āyah tí ó tẹ̀lé e.
Wòóore! Wọ́n ń pe gbólóhùn ẹyọ kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur’ān ní “an-najm”. Wọ́n sì ń pe ìràwọ̀ ní “an-najm”. Kódà “ìtàkùn” náà ń jẹ́ “an-najm” nínú èdè Lárúbáwá.(Tafsīr ’Adwā’ul-bayān)
Arapça tefsirler:
مَا ضَلَّ صَاحِبُكُمۡ وَمَا غَوَىٰ
Ẹni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù.¹
1. Ènìyàn “dọlla” nígbà tí ó bá fi àìmọ̀kan sẹ̀sìn. Ènìyàn tí kò tẹ̀lé ìmọ̀ tí ó mọ̀, òun ló “gawā”. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò fi àìmọ̀kan sẹ̀sìn. Kò sì yapa ìmọ̀ tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún un.
Arapça tefsirler:
وَمَا يَنطِقُ عَنِ ٱلۡهَوَىٰٓ
Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú.
Arapça tefsirler:
إِنۡ هُوَ إِلَّا وَحۡيٞ يُوحَىٰ
Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i.¹
1. Ìyẹn ni pé, ìmísí mímọ́ ni al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àmọ́ ìgbàkígbà tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá kánjú ṣíwájú ìmísí gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara, Allāhu kì í fi bùn un bí kò ṣe pé, ìmísì máa wá lórí rẹ̀ láti tètè ṣàtúnṣe rẹ̀.
Arapça tefsirler:
عَلَّمَهُۥ شَدِيدُ ٱلۡقُوَىٰ
Alágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l’ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān).
Arapça tefsirler:
ذُو مِرَّةٖ فَٱسۡتَوَىٰ
Ó ní àlàáfíà tó péye, ó sì dúró wámúwámú,
Arapça tefsirler:
وَهُوَ بِٱلۡأُفُقِ ٱلۡأَعۡلَىٰ
nígbà tí ó wà nínú òfurufú lókè pátápátá.
Arapça tefsirler:
ثُمَّ دَنَا فَتَدَلَّىٰ
Lẹ́yìn náà, ó sún mọ́ (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -). Ó sì sọ̀kalẹ̀ (tọ̀ ọ́ wá).
Arapça tefsirler:
فَكَانَ قَابَ قَوۡسَيۡنِ أَوۡ أَدۡنَىٰ
(Àlàfo ààrin àwọn méjèèjì) sì tó ìwọ̀n ọrún ọfà méjì, tàbí kí ó kéré (sí ìyẹn).¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:74.
Arapça tefsirler:
فَأَوۡحَىٰٓ إِلَىٰ عَبۡدِهِۦ مَآ أَوۡحَىٰ
Allāhu sì fún ẹrúsìn Rẹ̀ ní ìmísí tó fún un.
Arapça tefsirler:
مَا كَذَبَ ٱلۡفُؤَادُ مَا رَأَىٰٓ
Ọkàn (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kò parọ́ ohun tó rí.
Arapça tefsirler:
أَفَتُمَٰرُونَهُۥ عَلَىٰ مَا يَرَىٰ
Ṣé ẹ óò jà á níyàn nípa ohun tó rí ni?
Arapça tefsirler:
وَلَقَدۡ رَءَاهُ نَزۡلَةً أُخۡرَىٰ
Àti pé dájúdájú ó tún rí i nígbà kejì¹
1. Gbólóhùn “rọ’āhu” jẹyọ nínú āyah yìí. Ó tún jẹyọ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah at-Takwīr; 81:23. Ìtúmọ̀ rẹ̀ sì ni pé, “Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rí i.” Ta ni ó rí? Ṣé Allāhu ni tàbí mọlāika Jibrīl? Àní sẹ́, ta ni ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ẹnì kẹta yìí “hu” tó jẹyọ nínú gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí? Kí á má gbàgbé pé āyah yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa ìrìn-àjò òru àti ìgun sánmọ̀ tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe ni.
Èsì: Àwọn igun kan nínú àwọn àáfà sọ pé, mọlāika Jibrīl ni Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rí. Igun kejì sì sọ pé, Allāhu - tó ga jùlọ - ni ó rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igun yìí fi kún un pé ọkàn l’ó fi rí Allāhu, kì í ṣe ojú. Ṣebí bí ẹ̀dá ṣe ní ojú ìta, ni ó ní ojú inú. Àmọ́ èyí tí ó gbéwọ̀n jùlọ lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām ni pé, orúkọ mọlāika Jibrīl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni “hu” yẹn ń rọ́pò.
Ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni hadīth tí ìyá wa ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i - gbàwá lórí ọ̀rọ̀ náà pé, “Èmi ni àkọ́kọ́ nínú ìjọ yìí tí ó béèrè nípa ìyẹn lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ó sì sọ pé. “Jibrīl ni mo rí.” (Muslim).
Bákan náà, nínú ẹ̀gbàwá Abū Tharr - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ó sọ pé, mo bi Òjíṣẹ́ Allāhu ní ìbéèrè pé, “Ṣé o fojú rí Olúwa rẹ bí?” Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ pé: “Ìmọ́lẹ̀ kan (dí mi lọ́wọ́), báwo ni mo ṣe máa rí I nígbà náà!” (Muslim)
Irú èyí náà l’ó ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:143.
Tọ́ọ̀, ó ṣeé ṣe kí á rí ọ̀rọ̀ mìíràn kan láti ọ̀dọ̀ àwọn Sọhābah - kí Allāhu yọ́nú sí wọn -, bíi ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí i - wá pé, “Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fi ọkàn rẹ̀ rí Allāhu ni.” Ìyẹn ni pé, ó fojú inú rí I, kì í ṣe ojú ìta.
Kíyè sí i, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó lágbára tó èyí tí ó tọ̀dọ̀ Ànábì fúnra rẹ̀ wá tààrà lórí ọ̀rọ̀ náà. Ẹ̀gbàwá ‘Ā’iṣah àti ẹ̀gbàwá Abū Tharr sì ni ẹ̀gbàwá tó ti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - wá lórí ọ̀rọ̀ náà. Má ṣe fọkàn sí ibò míìràn. Àti pé, sūrah al-’Ani‘ām; 6:103 àti sūrah aṣ-Ṣūrā; 42:51 ti fi rinlẹ̀ pé, ojú kan kò lè fojú rinjú pẹ̀lú Allāhu, yálà fún gbígba iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu tàbí fún n̄ǹkan mìíràn.
Àmọ́ sá, rírí Allāhu sójú máa wáyé fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nìkan lọ́jọ́ Àjíǹde. Èyí sì wà ní ìbámu sí sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:22 - 23.
Arapça tefsirler:
عِندَ سِدۡرَةِ ٱلۡمُنتَهَىٰ
níbi igi sidirah al-Muntahā,
Arapça tefsirler:
عِندَهَا جَنَّةُ ٱلۡمَأۡوَىٰٓ
nítòsí rẹ̀ ni Ọgbà Ibùgbé (gbére) wà.
Arapça tefsirler:
إِذۡ يَغۡشَى ٱلسِّدۡرَةَ مَا يَغۡشَىٰ
(Rántí) nígbà tí ohun tó bo igi Sidirah bò ó mọ́lẹ̀.
Arapça tefsirler:
مَا زَاغَ ٱلۡبَصَرُ وَمَا طَغَىٰ
Ojú (Ànábì) kò yẹ̀, kò sì tayọ ẹnu-ààlà.
Arapça tefsirler:
لَقَدۡ رَأَىٰ مِنۡ ءَايَٰتِ رَبِّهِ ٱلۡكُبۡرَىٰٓ
Dájúdájú ó rí nínú àwọn àmì Olúwa rẹ̀, tó tóbi.
Arapça tefsirler:
أَفَرَءَيۡتُمُ ٱللَّٰتَ وَٱلۡعُزَّىٰ
Ẹ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā,
Arapça tefsirler:
وَمَنَوٰةَ ٱلثَّالِثَةَ ٱلۡأُخۡرَىٰٓ
àti Mọnāh, òrìṣà kẹta mìíràn.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hajj; 22:52.
Arapça tefsirler:
أَلَكُمُ ٱلذَّكَرُ وَلَهُ ٱلۡأُنثَىٰ
Ṣé ọmọkùnrin ni tiyín, ọmọbìnrin sì ni tiRẹ̀?
Arapça tefsirler:
تِلۡكَ إِذٗا قِسۡمَةٞ ضِيزَىٰٓ
Ìpín àbòsí nìyẹn nígbà náà.
Arapça tefsirler:
إِنۡ هِيَ إِلَّآ أَسۡمَآءٞ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٍۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَمَا تَهۡوَى ٱلۡأَنفُسُۖ وَلَقَدۡ جَآءَهُم مِّن رَّبِّهِمُ ٱلۡهُدَىٰٓ
(Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá àti ohun tí ẹ̀mí (wọn) ń fẹ́ (ìfẹ́-inú). Ìmọ̀nà kúkú ti dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.
Arapça tefsirler:
أَمۡ لِلۡإِنسَٰنِ مَا تَمَنَّىٰ
Tàbí ti ènìyàn ni n̄ǹkan tó bá ń fẹ́!
Arapça tefsirler:
فَلِلَّهِ ٱلۡأٓخِرَةُ وَٱلۡأُولَىٰ
Ti Allāhu sì ni ọ̀run àti ayé.
Arapça tefsirler:
۞ وَكَم مِّن مَّلَكٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ لَا تُغۡنِي شَفَٰعَتُهُمۡ شَيۡـًٔا إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ أَن يَأۡذَنَ ٱللَّهُ لِمَن يَشَآءُ وَيَرۡضَىٰٓ
Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn mọlāika tó wà nínú àwọn sánmọ̀, tí ìṣìpẹ̀ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan àyàfi lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu bá yọ̀ǹda fún ẹni tí Ó bá fẹ́, tí Ó sì yọ́nú sí.
Arapça tefsirler:
إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ لَيُسَمُّونَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ تَسۡمِيَةَ ٱلۡأُنثَىٰ
Dájúdájú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn mọlāika ní orúkọ obìnrin.
Arapça tefsirler:
وَمَا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّۖ وَإِنَّ ٱلظَّنَّ لَا يُغۡنِي مِنَ ٱلۡحَقِّ شَيۡـٔٗا
Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá. Dájúdájú àbá dídá kò sì níí rọrọ̀ kiní kan lára òdodo.
Arapça tefsirler:
فَأَعۡرِضۡ عَن مَّن تَوَلَّىٰ عَن ذِكۡرِنَا وَلَمۡ يُرِدۡ إِلَّا ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا
Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni tó kẹ̀yìn sí ìrántí Wa, tí kò sì gbèrò kiní kan àfi ìṣẹ̀mí ayé.
Arapça tefsirler:
ذَٰلِكَ مَبۡلَغُهُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِمَنِ ٱهۡتَدَىٰ
Ìyẹn ni ohun tí wọ́n wọ̀n nínú ìmọ̀. Dájúdájú Olúwa rẹ lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó mọ̀nà.
Arapça tefsirler:
وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَسَٰٓـُٔواْ بِمَا عَمِلُواْ وَيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ بِٱلۡحُسۡنَى
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere.
Arapça tefsirler:
ٱلَّذِينَ يَجۡتَنِبُونَ كَبَٰٓئِرَ ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡفَوَٰحِشَ إِلَّا ٱللَّمَمَۚ إِنَّ رَبَّكَ وَٰسِعُ ٱلۡمَغۡفِرَةِۚ هُوَ أَعۡلَمُ بِكُمۡ إِذۡ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ وَإِذۡ أَنتُمۡ أَجِنَّةٞ فِي بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡۖ فَلَا تُزَكُّوٓاْ أَنفُسَكُمۡۖ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَنِ ٱتَّقَىٰٓ
Àwọn tó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́.¹ Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó bẹ̀rù (Rẹ̀).
1. Ìyẹn ni pé, ẹ má ṣe yin ara yín.
Arapça tefsirler:
أَفَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي تَوَلَّىٰ
Sọ fún mi nípa ẹni tó gbúnrí (kúrò níbi òdodo),
Arapça tefsirler:
وَأَعۡطَىٰ قَلِيلٗا وَأَكۡدَىٰٓ
tí ó fi díẹ̀ tọrẹ, tí ó sì di ìyókù mọ́wọ́!
Arapça tefsirler:
أَعِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلۡغَيۡبِ فَهُوَ يَرَىٰٓ
Ṣé ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí ó sì ń rí i (pé ẹlòmíìràn l’ó ma bá òun jìyà lọ́run)?
Arapça tefsirler:
أَمۡ لَمۡ يُنَبَّأۡ بِمَا فِي صُحُفِ مُوسَىٰ
Tàbí wọn kò fún un ní ìró ohun tó wà nínú tírà (Ànábì) Mūsā ni,
Arapça tefsirler:
وَإِبۡرَٰهِيمَ ٱلَّذِي وَفَّىٰٓ
àti (tírà Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ẹni tó mú (òfin Allāhu) ṣẹ,
Arapça tefsirler:
أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰ
pé dájúdájú ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nahl; 16:25.
Arapça tefsirler:
وَأَن لَّيۡسَ لِلۡإِنسَٰنِ إِلَّا مَا سَعَىٰ
Àti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun tó ṣe níṣẹ́.
Arapça tefsirler:
وَأَنَّ سَعۡيَهُۥ سَوۡفَ يُرَىٰ
Àti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án.
Arapça tefsirler:
ثُمَّ يُجۡزَىٰهُ ٱلۡجَزَآءَ ٱلۡأَوۡفَىٰ
Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san tó kún jùlọ.
Arapça tefsirler:
وَأَنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلۡمُنتَهَىٰ
Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá).
Arapça tefsirler:
وَأَنَّهُۥ هُوَ أَضۡحَكَ وَأَبۡكَىٰ
Dájúdájú Òun l’Ó ń pa (ẹ̀dá) ní ẹ̀rín. Ó sì ń pa (ẹ̀dá) ní ẹkún.
Arapça tefsirler:
وَأَنَّهُۥ هُوَ أَمَاتَ وَأَحۡيَا
Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ (ẹ̀dá) di òkú. Ó sì ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè.
Arapça tefsirler:
وَأَنَّهُۥ خَلَقَ ٱلزَّوۡجَيۡنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰ
Dájúdájú Òun l’Ó dá ẹ̀dá ní oríṣi méjì, ọkùnrin àti obìnrin,¹
1. Ẹ̀dá ènìyàn ni èròǹgbà nínú āyah yìí, kì í ṣe ẹ̀dá mìíràn. Āyah 46 l’ó fi èyí rinlẹ̀.
Arapça tefsirler:
مِن نُّطۡفَةٍ إِذَا تُمۡنَىٰ
láti ara àtọ̀ nígbà tí wọ́n bá dà á sínú àpòlùkẹ́.
Arapça tefsirler:
وَأَنَّ عَلَيۡهِ ٱلنَّشۡأَةَ ٱلۡأُخۡرَىٰ
Dájúdájú Òun l’Ó máa ṣe ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn fún àjíǹde,
Arapça tefsirler:
وَأَنَّهُۥ هُوَ أَغۡنَىٰ وَأَقۡنَىٰ
Dájúdájú Òun l’Ó ń fún ẹ̀dá ní ọrọ̀ dúkìá, Ó sì ń ta ẹ̀dá ní òṣì.
Arapça tefsirler:
وَأَنَّهُۥ هُوَ رَبُّ ٱلشِّعۡرَىٰ
Dájúdájú Òun sì ni Olúwa ìràwọ̀ Ṣi‘rọ̄ (tí wọ́n sọ di òrìṣà).
Arapça tefsirler:
وَأَنَّهُۥٓ أَهۡلَكَ عَادًا ٱلۡأُولَىٰ
Dájúdájú Òun l’Ó pa ìran ‘Ād rẹ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́;
Arapça tefsirler:
وَثَمُودَاْ فَمَآ أَبۡقَىٰ
àti ìran Thamūd, kò sì ṣẹ́ wọn kù;
Arapça tefsirler:
وَقَوۡمَ نُوحٖ مِّن قَبۡلُۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ هُمۡ أَظۡلَمَ وَأَطۡغَىٰ
àti ìjọ Nūh tó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ alábòsí jùlọ, wọ́n sì tayọ ẹnu-ààlà jùlọ;
Arapça tefsirler:
وَٱلۡمُؤۡتَفِكَةَ أَهۡوَىٰ
àti ìlú tó dojú bolẹ̀ (ìlú Ànábì Lūt), Allāhu ló yẹ̀ ẹ́ lulẹ̀ (láti òkè).
Arapça tefsirler:
فَغَشَّىٰهَا مَا غَشَّىٰ
Ohun tó bò wọ́n mọ́lẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Arapça tefsirler:
فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكَ تَتَمَارَىٰ
Nítorí náà, èwo nínú ìdẹ̀ra Olúwa rẹ ni ìwọ (ènìyàn) ń jà níyàn?
Arapça tefsirler:
هَٰذَا نَذِيرٞ مِّنَ ٱلنُّذُرِ ٱلۡأُولَىٰٓ
Èyí ni ìkìlọ̀ kan nínú àwọn ìkìlọ̀ àkọ́kọ́.
Arapça tefsirler:
أَزِفَتِ ٱلۡأٓزِفَةُ
Ohun tó súnmọ́¹ súnmọ́.
1. “Ohun tó súnmọ́” jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ àjíǹde.
Arapça tefsirler:
لَيۡسَ لَهَا مِن دُونِ ٱللَّهِ كَاشِفَةٌ
Lẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni tó lè tú gbèdéke Àkókò náà jáde.¹
1. Ó tún túmọ̀ sí pé, “Lẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni tó lè gbé ìdààmú ọjọ́ Àkókò náà kúrò fún ẹ̀dá.”
Arapça tefsirler:
أَفَمِنۡ هَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ تَعۡجَبُونَ
Ṣé ọ̀rọ̀ yìí l’ó ń ṣe yín ní kàyéfì?
Arapça tefsirler:
وَتَضۡحَكُونَ وَلَا تَبۡكُونَ
Ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín, ẹ kò sì sunkún!
Arapça tefsirler:
وَأَنتُمۡ سَٰمِدُونَ
Afọ́nú-fọ́ra ni yín.
Arapça tefsirler:
فَٱسۡجُدُواْۤ لِلَّهِۤ وَٱعۡبُدُواْ۩
Nítorí náà, ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, kí ẹ jọ́sìn (fún Un).
Arapça tefsirler:
 
Anlam tercümesi Sure: Sûretu'n-Necm
Surelerin fihristi Sayfa numarası
 
Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali - Mealler fihristi

Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali- Tercüme Şeyh Ebu Rahime Mikail İykuviyni, Basım Yılı hicri 1432.

Kapat