ترجمهٔ معانی قرآن کریم - ترجمه ى یوروبایی * - لیست ترجمه ها

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ترجمهٔ معانی سوره: سوره نجم   آیه:

Suuratun-Naj'm

وَٱلنَّجۡمِ إِذَا هَوَىٰ
Allāhu fi gbólóhùn kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ búra.[1]
1. Ìtúmọ̀ kejì ni pé, Allāhu fi ìràwọ̀ nígbà tí ó bá wálẹ̀ (wọ̀ọ̀kùn ní ìdájí) búra. Àmọ́ ìtúmọ̀ àkọ́kọ́ ló súnmọ́ jùlọ ní ìbámu sí sàkánì rẹ̀ pẹ̀lú àwọn āyah tí ó tẹ̀lé e. Wòóore! Wọ́n ń pe gbólóhùn ẹyọ kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur’ān ní “an-najm”. Wọ́n sì ń pe ìràwọ̀ ní “an-najm”. Kódà “ìtàkùn” náà ń jẹ́ “an-najm” nínú èdè Lárúbáwá.(Tafsīr ’Adwā’ul-bayān)
تفسیرهای عربی:
مَا ضَلَّ صَاحِبُكُمۡ وَمَا غَوَىٰ
Ẹni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù.[1]
1. Ènìyàn “dọlla” nígbà tí ó bá fi àìmọ̀kan sẹ̀sìn. Ènìyàn tí kò tẹ̀lé ìmọ̀ tí ó mọ̀, òun ló “gawā”.
تفسیرهای عربی:
وَمَا يَنطِقُ عَنِ ٱلۡهَوَىٰٓ
Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú.
تفسیرهای عربی:
إِنۡ هُوَ إِلَّا وَحۡيٞ يُوحَىٰ
Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i.[1]
1. Ìyẹn ni pé, ìmísí mímọ́ ni al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
تفسیرهای عربی:
عَلَّمَهُۥ شَدِيدُ ٱلۡقُوَىٰ
Alágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l’ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān).
تفسیرهای عربی:
ذُو مِرَّةٖ فَٱسۡتَوَىٰ
Ó ní àlàáfíà tó péye, ó sì dúró wámúwámú,
تفسیرهای عربی:
وَهُوَ بِٱلۡأُفُقِ ٱلۡأَعۡلَىٰ
nígbà tí ó wà nínú òfurufú lókè pátápátá.
تفسیرهای عربی:
ثُمَّ دَنَا فَتَدَلَّىٰ
Lẹ́yìn náà, ó sún mọ́ (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -). Ó sì sọ̀kalẹ̀ (tọ̀ ọ́ wá).
تفسیرهای عربی:
فَكَانَ قَابَ قَوۡسَيۡنِ أَوۡ أَدۡنَىٰ
(Àlàfo ààrin àwọn méjèèjì) sì tó ìwọ̀n ọrún ọfà méjì, tàbí kí ó kéré (sí ìyẹn).[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:74.
تفسیرهای عربی:
فَأَوۡحَىٰٓ إِلَىٰ عَبۡدِهِۦ مَآ أَوۡحَىٰ
Allāhu sì fún ẹrúsìn Rẹ̀ ní ìmísí tó fún un.
تفسیرهای عربی:
مَا كَذَبَ ٱلۡفُؤَادُ مَا رَأَىٰٓ
Ọkàn (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kò parọ́ ohun tó rí.
تفسیرهای عربی:
أَفَتُمَٰرُونَهُۥ عَلَىٰ مَا يَرَىٰ
Ṣé ẹ óò jà á níyàn nípa ohun tó rí ni?
تفسیرهای عربی:
وَلَقَدۡ رَءَاهُ نَزۡلَةً أُخۡرَىٰ
Àti pé dájúdájú ó tún rí i nígbà kejì[1]
1. Igun kan nínú àwọn àáfà sọ pé, mọlāika Jibrīl ni Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rí. Igun kejì sì sọ pé, Allāhu - tó ga jùlọ - ni ó rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igun yìí fi kún un pé ọkàn l’ó fi rí Allāhu, kì í ṣe ojú.
تفسیرهای عربی:
عِندَ سِدۡرَةِ ٱلۡمُنتَهَىٰ
níbi igi sidirah al-Muntahā,
تفسیرهای عربی:
عِندَهَا جَنَّةُ ٱلۡمَأۡوَىٰٓ
nítòsí rẹ̀ ni Ọgbà Ibùgbé (gbére) wà.
تفسیرهای عربی:
إِذۡ يَغۡشَى ٱلسِّدۡرَةَ مَا يَغۡشَىٰ
(Rántí) nígbà tí ohun tó bo igi Sidirah bò ó mọ́lẹ̀.
تفسیرهای عربی:
مَا زَاغَ ٱلۡبَصَرُ وَمَا طَغَىٰ
Ojú (Ànábì) kò yẹ̀, kò sì tayọ ẹnu-ààlà.
تفسیرهای عربی:
لَقَدۡ رَأَىٰ مِنۡ ءَايَٰتِ رَبِّهِ ٱلۡكُبۡرَىٰٓ
Dájúdájú ó rí nínú àwọn àmì Olúwa rẹ̀, tó tóbi.
تفسیرهای عربی:
أَفَرَءَيۡتُمُ ٱللَّٰتَ وَٱلۡعُزَّىٰ
Ẹ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā,
تفسیرهای عربی:
وَمَنَوٰةَ ٱلثَّالِثَةَ ٱلۡأُخۡرَىٰٓ
àti Mọnāh, òrìṣà kẹta mìíràn.[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hajj; 22:52.
تفسیرهای عربی:
أَلَكُمُ ٱلذَّكَرُ وَلَهُ ٱلۡأُنثَىٰ
Ṣé ọmọkùnrin ni tiyín, ọmọbìnrin sì ni tiRẹ̀?
تفسیرهای عربی:
تِلۡكَ إِذٗا قِسۡمَةٞ ضِيزَىٰٓ
Ìpín àbòsí nìyẹn nígbà náà.
تفسیرهای عربی:
إِنۡ هِيَ إِلَّآ أَسۡمَآءٞ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٍۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَمَا تَهۡوَى ٱلۡأَنفُسُۖ وَلَقَدۡ جَآءَهُم مِّن رَّبِّهِمُ ٱلۡهُدَىٰٓ
(Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá àti ohun tí ẹ̀mí (wọn) ń fẹ́ (ìfẹ́-inú). Ìmọ̀nà kúkú ti dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.
تفسیرهای عربی:
أَمۡ لِلۡإِنسَٰنِ مَا تَمَنَّىٰ
Tàbí ti ènìyàn ni n̄ǹkan tó bá ń fẹ́!
تفسیرهای عربی:
فَلِلَّهِ ٱلۡأٓخِرَةُ وَٱلۡأُولَىٰ
Ti Allāhu sì ni ọ̀run àti ayé.
تفسیرهای عربی:
۞ وَكَم مِّن مَّلَكٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ لَا تُغۡنِي شَفَٰعَتُهُمۡ شَيۡـًٔا إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ أَن يَأۡذَنَ ٱللَّهُ لِمَن يَشَآءُ وَيَرۡضَىٰٓ
Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn mọlāika tó wà nínú àwọn sánmọ̀, tí ìṣìpẹ̀ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan àyàfi lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu bá yọ̀ǹda fún ẹni tí Ó bá fẹ́, tí Ó sì yọ́nú sí.
تفسیرهای عربی:
إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ لَيُسَمُّونَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ تَسۡمِيَةَ ٱلۡأُنثَىٰ
Dájúdájú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn mọlāika ní orúkọ obìnrin.
تفسیرهای عربی:
وَمَا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّۖ وَإِنَّ ٱلظَّنَّ لَا يُغۡنِي مِنَ ٱلۡحَقِّ شَيۡـٔٗا
Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá. Dájúdájú àbá dídá kò sì níí rọrọ̀ kiní kan lára òdodo.
تفسیرهای عربی:
فَأَعۡرِضۡ عَن مَّن تَوَلَّىٰ عَن ذِكۡرِنَا وَلَمۡ يُرِدۡ إِلَّا ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا
Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni tó kẹ̀yìn sí ìrántí Wa, tí kò sì gbèrò kiní kan àfi ìṣẹ̀mí ayé.
تفسیرهای عربی:
ذَٰلِكَ مَبۡلَغُهُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِمَنِ ٱهۡتَدَىٰ
Ìyẹn ni ohun tí wọ́n wọ̀n nínú ìmọ̀. Dájúdájú Olúwa rẹ lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó mọ̀nà.
تفسیرهای عربی:
وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَسَٰٓـُٔواْ بِمَا عَمِلُواْ وَيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ بِٱلۡحُسۡنَى
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere.
تفسیرهای عربی:
ٱلَّذِينَ يَجۡتَنِبُونَ كَبَٰٓئِرَ ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡفَوَٰحِشَ إِلَّا ٱللَّمَمَۚ إِنَّ رَبَّكَ وَٰسِعُ ٱلۡمَغۡفِرَةِۚ هُوَ أَعۡلَمُ بِكُمۡ إِذۡ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ وَإِذۡ أَنتُمۡ أَجِنَّةٞ فِي بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡۖ فَلَا تُزَكُّوٓاْ أَنفُسَكُمۡۖ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَنِ ٱتَّقَىٰٓ
Àwọn tó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́.[1] Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó bẹ̀rù (Rẹ̀).
1. Ìyẹn ni pé, ẹ má ṣe yin ara yín.
تفسیرهای عربی:
أَفَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي تَوَلَّىٰ
Sọ fún mi nípa ẹni tó gbúnrí (kúrò níbi òdodo),
تفسیرهای عربی:
وَأَعۡطَىٰ قَلِيلٗا وَأَكۡدَىٰٓ
tí ó fi díẹ̀ tọrẹ, tí ó sì di ìyókù mọ́wọ́!
تفسیرهای عربی:
أَعِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلۡغَيۡبِ فَهُوَ يَرَىٰٓ
Ṣé ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí ó sì ń rí i (pé ẹlòmíìràn l’ó ma bá òun jìyà lọ́run)?
تفسیرهای عربی:
أَمۡ لَمۡ يُنَبَّأۡ بِمَا فِي صُحُفِ مُوسَىٰ
Tàbí wọn kò fún un ní ìró ohun tó wà nínú tírà (Ànábì) Mūsā ni,
تفسیرهای عربی:
وَإِبۡرَٰهِيمَ ٱلَّذِي وَفَّىٰٓ
àti (tírà Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ẹni tó mú (òfin Allāhu) ṣẹ,
تفسیرهای عربی:
أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰ
pé dájúdájú ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn.[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nahl; 16:25.
تفسیرهای عربی:
وَأَن لَّيۡسَ لِلۡإِنسَٰنِ إِلَّا مَا سَعَىٰ
Àti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun tó ṣe níṣẹ́.
تفسیرهای عربی:
وَأَنَّ سَعۡيَهُۥ سَوۡفَ يُرَىٰ
Àti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án.
تفسیرهای عربی:
ثُمَّ يُجۡزَىٰهُ ٱلۡجَزَآءَ ٱلۡأَوۡفَىٰ
Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san tó kún jùlọ.
تفسیرهای عربی:
وَأَنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلۡمُنتَهَىٰ
Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá).
تفسیرهای عربی:
وَأَنَّهُۥ هُوَ أَضۡحَكَ وَأَبۡكَىٰ
Dájúdájú Òun l’Ó ń pa (ẹ̀dá) ní ẹ̀rín. Ó sì ń pa (ẹ̀dá) ní ẹkún.
تفسیرهای عربی:
وَأَنَّهُۥ هُوَ أَمَاتَ وَأَحۡيَا
Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ (ẹ̀dá) di òkú. Ó sì ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè.
تفسیرهای عربی:
وَأَنَّهُۥ خَلَقَ ٱلزَّوۡجَيۡنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰ
Dájúdájú Òun l’Ó dá ẹ̀dá ní oríṣi méjì, ọkùnrin àti obìnrin,[1]
1. Ẹ̀dá ènìyàn ni èròǹgbà nínú āyah yìí, kì í ṣe ẹ̀dá mìíràn. Āyah 46 l’ó fi èyí rinlẹ̀.
تفسیرهای عربی:
مِن نُّطۡفَةٍ إِذَا تُمۡنَىٰ
láti ara àtọ̀ nígbà tí wọ́n bá dà á sínú àpòlùkẹ́.
تفسیرهای عربی:
وَأَنَّ عَلَيۡهِ ٱلنَّشۡأَةَ ٱلۡأُخۡرَىٰ
Dájúdájú Òun l’Ó máa ṣe ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn fún àjíǹde,
تفسیرهای عربی:
وَأَنَّهُۥ هُوَ أَغۡنَىٰ وَأَقۡنَىٰ
Dájúdájú Òun l’Ó ń fún ẹ̀dá ní ọrọ̀ dúkìá, Ó sì ń ta ẹ̀dá ní òṣì.
تفسیرهای عربی:
وَأَنَّهُۥ هُوَ رَبُّ ٱلشِّعۡرَىٰ
Dájúdájú Òun sì ni Olúwa ìràwọ̀ Ṣi‘rọ̄ (tí wọ́n sọ di òrìṣà).
تفسیرهای عربی:
وَأَنَّهُۥٓ أَهۡلَكَ عَادًا ٱلۡأُولَىٰ
Dájúdájú Òun l’Ó pa ìran ‘Ād rẹ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́;
تفسیرهای عربی:
وَثَمُودَاْ فَمَآ أَبۡقَىٰ
àti ìran Thamūd, kò sì ṣẹ́ wọn kù;
تفسیرهای عربی:
وَقَوۡمَ نُوحٖ مِّن قَبۡلُۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ هُمۡ أَظۡلَمَ وَأَطۡغَىٰ
àti ìjọ Nūh tó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ alábòsí jùlọ, wọ́n sì tayọ ẹnu-ààlà jùlọ;
تفسیرهای عربی:
وَٱلۡمُؤۡتَفِكَةَ أَهۡوَىٰ
àti ìlú tó dojú bolẹ̀ (ìlú Ànábì Lūt), Allāhu ló yẹ̀ ẹ́ lulẹ̀ (láti òkè).
تفسیرهای عربی:
فَغَشَّىٰهَا مَا غَشَّىٰ
Ohun tó bò wọ́n mọ́lẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀.
تفسیرهای عربی:
فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكَ تَتَمَارَىٰ
Nítorí náà, èwo nínú ìdẹ̀ra Olúwa rẹ ni ìwọ (ènìyàn) ń jà níyàn?
تفسیرهای عربی:
هَٰذَا نَذِيرٞ مِّنَ ٱلنُّذُرِ ٱلۡأُولَىٰٓ
Èyí ni ìkìlọ̀ kan nínú àwọn ìkìlọ̀ àkọ́kọ́.
تفسیرهای عربی:
أَزِفَتِ ٱلۡأٓزِفَةُ
Ohun tó súnmọ́[1] súnmọ́.
1. “Ohun tó súnmọ́” jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ àjíǹde.
تفسیرهای عربی:
لَيۡسَ لَهَا مِن دُونِ ٱللَّهِ كَاشِفَةٌ
Lẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni tó lè tú gbèdéke Àkókò náà jáde.[1]
1. Ó tún túmọ̀ sí pé, “Lẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni tó lè gbé ìdààmú ọjọ́ Àkókò náà kúrò fún ẹ̀dá.”
تفسیرهای عربی:
أَفَمِنۡ هَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ تَعۡجَبُونَ
Ṣé ọ̀rọ̀ yìí l’ó ń ṣe yín ní kàyéfì?
تفسیرهای عربی:
وَتَضۡحَكُونَ وَلَا تَبۡكُونَ
Ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín, ẹ kò sì sunkún!
تفسیرهای عربی:
وَأَنتُمۡ سَٰمِدُونَ
Afọ́nú-fọ́ra ni yín.
تفسیرهای عربی:
فَٱسۡجُدُواْۤ لِلَّهِۤ وَٱعۡبُدُواْ۩
Nítorí náà, ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, kí ẹ jọ́sìn (fún Un).
تفسیرهای عربی:
 
ترجمهٔ معانی سوره: سوره نجم
فهرست سوره ها شماره صفحه
 
ترجمهٔ معانی قرآن کریم - ترجمه ى یوروبایی - لیست ترجمه ها

ترجمه ى معانی قرآن کریم به زبان یوروبایی. مترجم: شیخ ابو رحیمه میکائیل ایکوینی. سال چاپ: 1432هجرى قمرى.

بستن