قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ * - ترجمے کی لسٹ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

معانی کا ترجمہ آیت: (101) سورت: سورۂ آل عمران
وَكَيۡفَ تَكۡفُرُونَ وَأَنتُمۡ تُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتُ ٱللَّهِ وَفِيكُمۡ رَسُولُهُۥۗ وَمَن يَعۡتَصِم بِٱللَّهِ فَقَدۡ هُدِيَ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣàì gbàgbọ́, ẹ̀yin mà ni wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu fún, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín! Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró ṣinṣin ti Allāhu, A ti tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà.¹
1. Kíyè sí i, gbólóhùn yìí, “Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín!” Ìyẹn ṣíwájú kí ó tó kú - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, kò sí láààrin wa mọ́. Irú āyah yìí wà nínú sūrah at-Taobah; 9:94 àti 105 àti sūrah an-Nisā’; 4:64.
Àwọn onibidia nìkan ni wọ́n tún gbà pé títí dí àsìkò yìí ni Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ń bẹ láààrin wa, tí ó ń rí iṣẹ́ ọwọ́ wa. Bí àpẹ̀ẹrẹ, ìjọ Ahmadiyyah gbà pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a- padà wá sáyé, ó sì ń bá mirza Ghulam Ahmad, olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah ṣe ìpàdé ojú ayé. Bákan náà, ìjọ Tijāniyyah náà gbà pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a- padà wá sáyé láti fún ṣeeu Ahmada Tijāni lọ́wọ́ wírìdí. Kódà wọ́n gbà pé lójoojúmọ́ àti níbi gbogbo ni Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a- àti àwọn àrólé rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin - kí Allāhu yọ́nú sí wọn - máa wá jókòó sórí aṣọ funfun, èyí tí wọ́n máa ń tẹ́ sáààrin lásìkò tí wọ́n bá ń ka Jaoharatul-kamāl lọ́wọ́. Irọ́ ńlá ni gbogbo àdìsọ́kàn burúkú wọ̀nyí. Àwọn āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ kò sì jẹmọ́ “lẹ́yìn ikú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a-” bí kò ṣe “ṣíwájú ikú rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a-”. Kí á lè mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àmọ̀dájú, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a- sọ pé: “Kíyè sí i, dájúdájú wọn máa mú àwọn ọkùnrin kan wá nínú ìjọ mi (ìyẹn l’ọ́jọ́ Ìdájọ́), wọ́n sì máa mú wọn lọ sí apá òṣì, n̄g ó sì sọ pé; “Olúwa mi, àwọn ènìyàn mi (nìyí).” Wọ́n sì máa sọ pé: “Dájúdájú ìwọ kò mọ ohun tí wọ́n dáálẹ̀ lẹ́yìn (ikú) rẹ.” (Bukọ̄riy àti Muslim)
عربی تفاسیر:
 
معانی کا ترجمہ آیت: (101) سورت: سورۂ آل عمران
سورتوں کی لسٹ صفحہ نمبر
 
قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ - ترجمے کی لسٹ

قرآن کریم کے معانی کا یوروبا ترجمہ۔ ترجمہ شیخ ابو رحیمہ میکائیل ایکویینی نے کیا ہے۔ طباعت سنہ 1432ھ۔

بند کریں