Check out the new design

Bản dịch ý nghĩa nội dung Qur'an - Bản dịch tiếng Yoruba - Abu Rahimah Mikail * - Mục lục các bản dịch

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Ý nghĩa nội dung Chương: Al-Nur   Câu:

An-Nuur

سُورَةٌ أَنزَلۡنَٰهَا وَفَرَضۡنَٰهَا وَأَنزَلۡنَا فِيهَآ ءَايَٰتِۭ بَيِّنَٰتٖ لَّعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ
(Èyí ni) Sūrah kan tí A sọ̀kalẹ̀. A ṣe ìdájọ́ inú rẹ̀ ní òfin (dandan). A sì sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ sínú rẹ̀ nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
Các Tafsir tiếng Ả-rập:
ٱلزَّانِيَةُ وَٱلزَّانِي فَٱجۡلِدُواْ كُلَّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا مِاْئَةَ جَلۡدَةٖۖ وَلَا تَأۡخُذۡكُم بِهِمَا رَأۡفَةٞ فِي دِينِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ تُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۖ وَلۡيَشۡهَدۡ عَذَابَهُمَا طَآئِفَةٞ مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Onísìná lóbìnrin àti onísìná lọ́kùnrin, ẹ na ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì ní ọgọ́rùn-ún kòbókò. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àánú wọn ṣe yín nípa ìdájọ́ Allāhu tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kí igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo sì jẹ́rìí sí ìyà àwọn méjèèjì.[1]
[1] Ọgọ́rùn-ún kòbókò àti ẹ̀wọ̀n ọdún kan tàbí ọgọ́rùn-ún kòbókò àti lílé kúrò nínú ìlú fún ọdún kan ni ìjìyà fún onísìná tí kò ì ṣe ‘akdu-nnikāh pẹ̀lú ẹnikẹ́ni rí. Àmọ́ lílẹ̀ lókòpa ni ìjìyà fún onísìná tí ó ti ṣe ‘akdu-nnikāh rí.
Các Tafsir tiếng Ả-rập:
ٱلزَّانِي لَا يَنكِحُ إِلَّا زَانِيَةً أَوۡ مُشۡرِكَةٗ وَٱلزَّانِيَةُ لَا يَنكِحُهَآ إِلَّا زَانٍ أَوۡ مُشۡرِكٞۚ وَحُرِّمَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Onísìná lọ́kùnrin kò níí ṣe sìná pẹ̀lú ẹnì kan bí kò ṣe onísìná lóbìnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin. Onísìná lóbìnrin, ẹnì kan kò níí bá a ṣe sìná bí kò ṣe onísìná lọ́kùnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin.[1] A sì ṣe ìyẹn (sìná ṣíṣe) ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.[2]
[1] Àwọn onímọ̀ pín sí mẹ́ta lórí ìtúmọ̀ āyah yìí nítorí pé, ìtúmọ̀ mẹ́ta tí ó ń padà síbi n̄ǹkan ẹyọ kan ni kalmọh “nikāh” ń túmọ̀ sí nínú al-Ƙur’ān, hadīth àti èdè Lárúbáwá. Àwọn ìtúmọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni fífẹ́ (ṣíṣe ìgbéyàwó), títi kálámù bọ inú ìgò tàdáà yálà ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tàbí ní ọ̀nà àìtọ́ àti ṣíṣe sìná (àgbèrè). [2] Nítorí náà, “ìyẹn” nínú gbólóhùn yìí “A sì ṣe ìyẹn ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” ń tọ́ka sí “zinā”. Ìyẹn ni pé, “A sì ṣe zinā ṣíṣe ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” Èyí sì ni ìtúmọ̀ rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ tí ó túmọ̀ “lā yankihu” sí “kò níí ṣe sìná”.
Các Tafsir tiếng Ả-rập:
وَٱلَّذِينَ يَرۡمُونَ ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ ثُمَّ لَمۡ يَأۡتُواْ بِأَرۡبَعَةِ شُهَدَآءَ فَٱجۡلِدُوهُمۡ ثَمَٰنِينَ جَلۡدَةٗ وَلَا تَقۡبَلُواْ لَهُمۡ شَهَٰدَةً أَبَدٗاۚ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ
Àwọn tó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ọmọlúàbí lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò mú àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá, ẹ nà wọ́n ní ọgọ́rin kòbókò. Ẹ má ṣe gba ẹ̀rí wọn mọ́ láéláé; àwọn wọ̀nyẹn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
Các Tafsir tiếng Ả-rập:
إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُواْ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ وَأَصۡلَحُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.[1]
[1] Ẹ̀sùn zinā lágbára púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó jẹ́ pé kòbókò ọgọrin ni ìjìyà tí Allāhu gbékalẹ̀ lórí ẹni tí ó bá parọ́ zina mọ́ ẹlòmíìràn.
Các Tafsir tiếng Ả-rập:
وَٱلَّذِينَ يَرۡمُونَ أَزۡوَٰجَهُمۡ وَلَمۡ يَكُن لَّهُمۡ شُهَدَآءُ إِلَّآ أَنفُسُهُمۡ فَشَهَٰدَةُ أَحَدِهِمۡ أَرۡبَعُ شَهَٰدَٰتِۭ بِٱللَّهِ إِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ
Àwọn tó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ìyàwó wọn, tí kò sì sí ẹlẹ́rìí fún wọn àfi àwọn fúnra wọn, ẹ̀rí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni kí ó fi Allāhu jẹ́rìí ní ẹ̀ẹ̀ mẹrin pé dájúdájú òun wà nínú àwọn olódodo.
Các Tafsir tiếng Ả-rập:
وَٱلۡخَٰمِسَةُ أَنَّ لَعۡنَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡهِ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ
Ẹ̀ẹ̀ karùn-ún sì ni pé kí ibi dandan Allāhu máa bá òun, tí òun bá wà nínú àwọn òpùrọ́.
Các Tafsir tiếng Ả-rập:
وَيَدۡرَؤُاْ عَنۡهَا ٱلۡعَذَابَ أَن تَشۡهَدَ أَرۡبَعَ شَهَٰدَٰتِۭ بِٱللَّهِ إِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ
Ohun tí ó máa yẹ ìyà fún ìyàwó ni pé, kí ó fi Allāhu jẹ́rìí ní ẹ̀ẹ̀ mẹrin pé dájúdájú ọkọ òun wà nínú àwọn òpùrọ́.
Các Tafsir tiếng Ả-rập:
وَٱلۡخَٰمِسَةَ أَنَّ غَضَبَ ٱللَّهِ عَلَيۡهَآ إِن كَانَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ
Ẹ̀ẹ̀ karùn-ún sì ni pé kí ìbínú Allāhu máa bá òun, tí ọkọ òun bá wà nínú àwọn olódodo.[1]
[1] Tí abilékọ bá ní oyún tàbí bí ọmọ, àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ sọ pé kì í ṣe tòun ni oyún náà tàbí ọmọ náà, tí ìyàwó sì takú pé ọkọ òun ló ni í, ìgbéyàwó náà máa túká pẹ̀lú ìṣẹ́bi láààrin tọkọ tìyàwo náà lórí ìlànà tó wà nínú āyah 6 sí āyah 9. Lẹ́yìn ìṣẹ́bi náà, ọmọ náà yóò máa bá ìyá rẹ̀ lọ. Ìkíní kejì kò sì lè di tọkọ tìyàwó mọ́.
Các Tafsir tiếng Ả-rập:
وَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَرَحۡمَتُهُۥ وَأَنَّ ٱللَّهَ تَوَّابٌ حَكِيمٌ
Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni (Allāhu ìbá máa tú àṣírí yín ni). Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Ọlọ́gbọ́n.
Các Tafsir tiếng Ả-rập:
 
Ý nghĩa nội dung Chương: Al-Nur
Mục lục các chương Kinh Số trang
 
Bản dịch ý nghĩa nội dung Qur'an - Bản dịch tiếng Yoruba - Abu Rahimah Mikail - Mục lục các bản dịch

Người dịch Sheikh Abu Rahimah Mikail Aikoyini.

Đóng lại