《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译。 * - 译解目录

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

含义的翻译 段: (48) 章: 拜格勒
وَٱتَّقُواْ يَوۡمٗا لَّا تَجۡزِي نَفۡسٌ عَن نَّفۡسٖ شَيۡـٔٗا وَلَا يُقۡبَلُ مِنۡهَا شَفَٰعَةٞ وَلَا يُؤۡخَذُ مِنۡهَا عَدۡلٞ وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. Wọn kò níí gba ìṣìpẹ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. Wọn kò níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀.¹ Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.²
1. Ìyẹn ni pé, l’ọ́jọ́ Àjíǹde dúkìá kan kan kò níí wúlò fún ìràpadà ẹ̀mí níbi Iná àfi iṣẹ́ rere tí í ṣe ìjọ́sìn fún Allāhu àti ìwà rere tó tọ sunnah.
2. Àwọn kan sọ pé, “Àwọn āyah kan sọ pé kò sí ìṣìpẹ̀ l’ọ́jọ́ Àjíǹde, àwọn āyah mìíràn sọ pé ìṣìpẹ̀ wà.” Wọ́n ní, “Ìtakora nìyẹn.”
Èsì: Èyí jẹ́ “ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀”, kì í ṣe “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀”. Àlàyé rẹ̀ nìyí. Àwọn āyah tó ń sọ pé kò sí ìṣìpẹ̀ l’ọ́jọ́ Àjíǹde ń jẹ́ ọ̀rọ̀ ajáni-ní-tànmọ́ọ̀n fún àwọn yẹhudi àti àwọn nasọ̄rọ̄ tí wọ́n ń fọkàn sí ìṣìpẹ̀ láì ṣe iṣẹ́ tí ó máa mú wọn lẹ́tọ̀ọ́ sí ìṣìpẹ̀ àti àwọn ọ̀ṣẹbọ tí ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà tiwọn wulẹ̀ dúró sórí bíbọ ẹ̀dá kan nítorí kí ó lè ṣìpẹ̀ wọn l’ọ́jọ́ Àjíǹde. Irúfẹ́ àwọn āyah náà ni sūrah al-Baƙọrah; 2:48, 123 àti 254 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:51. Àmọ́ àwọn āyah tó ń sọ pé ìṣìpẹ̀ máa wà l’ọ́jọ́ Àjíǹde ń sọ nípa àwọn májẹ̀mú tí ó wà fún ìṣìpẹ̀, olùṣìpẹ̀ àti olùṣìpẹ̀-fún. Irúfẹ́ àwọn āyah náà ni sūrah al-Baƙọrah; 2:255, sūrah Tọ̄hā; 20:109, sūrah Saba’; 34:23, sūrah az-Zukruf; 43:86 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:70. Kíyè sí i, gbígbà tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - máa gba ìṣìpẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kan fún àwọn kan kò kéré ipò fún agbára Allāhu, àmọ́ ipò tí ìbániṣàdúà wà ni ìṣìpẹ̀ wà. Nítorí náà, bí ó ṣe lẹ́tọ̀ọ́ láti bá ẹlòmíìràn ṣàdúà, bẹ́ẹ̀ náà ló máa ní ẹ̀tọ́ láti bá ẹlòmíìràn ṣìpẹ̀ l’ọ́jọ́ Àjíǹde. Olùṣìpẹ̀ àkọ́kọ́ fún gbogbo ẹ̀dá sì ni Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àmọ́ má ṣe fọkàn sí pé mùsùlùmí kan máa ṣìpẹ̀ rẹ tàbí pé o máa ṣìpẹ̀ mùsùlùmí kan nítorí pé, nínú ohun tó pamọ́ fún ẹ̀dá ni ìmọ̀ nípa ta gan-an ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - máa fi ìṣìpẹ̀ pọ́nlé nínú àwa ẹrúsìn Rẹ̀. Àdúà wa ni pé, kí Allāhu fi ìṣìpẹ̀ ṣe àpọ́nlé fún èmi àti ẹ̀yin.
阿拉伯语经注:
 
含义的翻译 段: (48) 章: 拜格勒
章节目录 页码
 
《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译。 - 译解目录

古兰经泰卢固语译解,艾布·拉赫曼·米卡伊里·艾库比尼长老翻译,伊历1432年出版发行。

关闭