《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译。 * - 译解目录

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

含义的翻译 段: (74) 章: 拜格勒
ثُمَّ قَسَتۡ قُلُوبُكُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ فَهِيَ كَٱلۡحِجَارَةِ أَوۡ أَشَدُّ قَسۡوَةٗۚ وَإِنَّ مِنَ ٱلۡحِجَارَةِ لَمَا يَتَفَجَّرُ مِنۡهُ ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ وَإِنَّ مِنۡهَا لَمَا يَشَّقَّقُ فَيَخۡرُجُ مِنۡهُ ٱلۡمَآءُۚ وَإِنَّ مِنۡهَا لَمَا يَهۡبِطُ مِنۡ خَشۡيَةِ ٱللَّهِۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ
Lẹ́yìn náà, ọkàn yín le lẹ́yìn ìyẹn. Ó sì dà bí òkúta tàbí líle tó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ.¹ Dájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn òkúta tí àwọn odò ń ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó máa sán kànkàn. Omi sì máa jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó ń wó lulẹ̀ gbì fún ìpáyà Allāhu. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
1. Nínú èdè Lárúbáwá, ìtúmọ̀ “ ’ao” ni “tàbí”. Nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, kò sì sí ọ̀rọ̀ tàbí-ṣùgbọ́n tó ń bí iyèméjì nínú rẹ̀. Nítorí náà, ẹ wo àwọn ìtúmọ̀ ìjìnlẹ̀ fún“ ’ao”.
(Ìkíní) Lárúbáwá ń lo “ ’ao” láti ṣe àfihàn ìwọ̀fún àti ìṣẹ̀ṣà láààrin n̄ǹkan méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
(Ìkejì) Wọ́n ń lo “ ’ao” nígbà tí òǹsọ̀rọ̀ bá ń ṣiyèméjì nípa ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ. Ìlò yìí kò sì lè ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - àti ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
(Ìkẹta) Wọ́n ń lo “ ’ao” nígbà tí òǹsọ̀rọ̀ kò ṣiyèméjì nípa ohun tí ó ń sọ, àmọ́ tí kò fẹ́ kí olùbásọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ pàtó nípa ọ̀rọ̀ náà. Àpẹ̀ẹrẹ ìlò yìí ni ìtúmọ̀ “ ’ao” tó jẹyọ nínú sūrah as-Sọffāt; 37:147.
(Ìkẹrin) Wọ́n ń lo “’ao” nígbà tí òǹsọ̀rọ̀ kò ṣiyèméjì nípa ohun tí ó ń sọ, tí ó sì ti fún olùbásọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àǹfààní láti mọ pàtó àti òkodoro ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ tí olùbásọ̀rọ̀ ń ṣe ìṣe aláìníkan-ánṣe tàbí aláìgbàgbọ́. Àpẹ̀ẹrẹ ìlò yìí ni ìtúmọ̀ “ ’ao” tó jẹyọ nínú sūrah Saba’; 34:24.
(Ìkarùn-ún) Wọ́n ń lo “ ’ao” láààrin ọ̀rọ̀ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó dúró fún ọ̀kan-ùn. Àpẹ̀ẹrẹ ìlò yìí ni ìtúmọ̀ “ ’ao” tó jẹyọ nínú sūrah al-’Isrọ̄’; 17:110.
(Ìkẹfà) Wọ́n ń lo “wāwu-l-‘atf” fún “ ’ao” tó ń túmọ̀ sí “tàbí”. Àpẹ̀ẹrẹ ìlò yìí ni ìtúmọ̀ “wāwu-l-‘atf” tó jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:3 àti Fātir; 35:1.
(Ìkejè) Wọ́n ń lo “ ’ao” fún “bal” - “rárá” - nígbà tí òǹsọ̀rọ̀ bá fẹ́ bàbàrà ọ̀rọ̀. Àpẹ̀ẹrẹ ìlò yìí ni ìtúmọ̀ “ ’ao” tó jẹyọ nínú sūrah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́. Ìyẹn ni pé, ọkàn àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ìbá le bí òkúta ṣe le, ìrètí gbígba òdodo gbọ́ ìbá wà fún wọn nítorí pé, bí òkúta ṣe le tó, ó ń sán, ó ń fọ́, tí omi àti n̄ǹkan rere mìíràn ń tibẹ̀ jáde. Àmọ́ ọkàn wọn kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ńṣe ni ọkàn wọn le ju òkúta. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
阿拉伯语经注:
 
含义的翻译 段: (74) 章: 拜格勒
章节目录 页码
 
《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译。 - 译解目录

古兰经泰卢固语译解,艾布·拉赫曼·米卡伊里·艾库比尼长老翻译,伊历1432年出版发行。

关闭