《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译。 * - 译解目录

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

含义的翻译 段: (28) 章: 阿里欧姆拉尼
لَّا يَتَّخِذِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ فَلَيۡسَ مِنَ ٱللَّهِ فِي شَيۡءٍ إِلَّآ أَن تَتَّقُواْ مِنۡهُمۡ تُقَىٰةٗۗ وَيُحَذِّرُكُمُ ٱللَّهُ نَفۡسَهُۥۗ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلۡمَصِيرُ
Àwọn onígbàgbọ́ òdodo kò gbọ́dọ̀ sọ àwọn aláìgbàgbọ́ di ọ̀rẹ́ àyò (ọ̀rẹ́ finúhannú) lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ wọn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìyẹn, kò sí kiní kan fún un mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.¹ Àfi tí ẹ bá ń (fi ọ̀rẹ́ orí ahọ́n) wá ìṣọ́ra lọ́dọ̀ wọn) dáadáa (lórí ìgbàgbọ́ yín).² Allāhu ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fún yín. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
1. Ẹni tí ó sọ aláìgbàgbọ́ di ọ̀rẹ́ àyò tí yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ Allāhu, Allāhu sì ti yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.
2. Ìyẹn fún àwọn mùsùlùmí tí ń bẹ lábẹ́ àṣẹ àti ìdàrí àwọn aláìgbàgbọ́. Àwọn wọ̀nyẹn lè mú wọn ní ọ̀rẹ́ bí ó bá jẹ́ pé mímú wọn ní ọ̀rẹ́ nìkan ni ọ̀nà tí ó lè gbà rí ẹ̀sìn rẹ̀ ṣe. Àmọ́ kò níí máa dá ọ̀rọ̀ àwọn mùsùlùmí sílẹ̀ lọ́dọ̀ wọn ní ìdásílẹ̀ ẹ̀sín àti ìtúniláṣìírí.
阿拉伯语经注:
 
含义的翻译 段: (28) 章: 阿里欧姆拉尼
章节目录 页码
 
《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译。 - 译解目录

古兰经泰卢固语译解,艾布·拉赫曼·米卡伊里·艾库比尼长老翻译,伊历1432年出版发行。

关闭