Check out the new design

《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖。 * - 译解目录

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

含义的翻译 章: 玛仪戴   段:
وَقَفَّيۡنَا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم بِعِيسَى ٱبۡنِ مَرۡيَمَ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ مِنَ ٱلتَّوۡرَىٰةِۖ وَءَاتَيۡنَٰهُ ٱلۡإِنجِيلَ فِيهِ هُدٗى وَنُورٞ وَمُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ مِنَ ٱلتَّوۡرَىٰةِ وَهُدٗى وَمَوۡعِظَةٗ لِّلۡمُتَّقِينَ
A fi ‘Īsā ọmọ Mọryam tẹ̀lé orípa wọn (ìyẹn, àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí); tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú at-Taorāh. A sì fún un ní al-’Injīl. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ wà nínú rẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú at-Taorāh. (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti wáàsí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu ní àsìkò tirẹ̀).
阿拉伯语经注:
وَلۡيَحۡكُمۡ أَهۡلُ ٱلۡإِنجِيلِ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فِيهِۚ وَمَن لَّمۡ يَحۡكُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ
Kí àwọn tí A fún ní al-’Injīl ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́.[1]
1. Kíyè sí i, tí àwọn onítírà ’Injīl bá lò ó gẹ́gẹ́ bí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀, dandan ni fún wọn láti tẹ̀lé Ànábì àsìkò yìí, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
阿拉伯语经注:
وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَمُهَيۡمِنًا عَلَيۡهِۖ فَٱحۡكُم بَيۡنَهُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُۖ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَهُمۡ عَمَّا جَآءَكَ مِنَ ٱلۡحَقِّۚ لِكُلّٖ جَعَلۡنَا مِنكُمۡ شِرۡعَةٗ وَمِنۡهَاجٗاۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَكُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَلَٰكِن لِّيَبۡلُوَكُمۡ فِي مَآ ءَاتَىٰكُمۡۖ فَٱسۡتَبِقُواْ ٱلۡخَيۡرَٰتِۚ إِلَى ٱللَّهِ مَرۡجِعُكُمۡ جَمِيعٗا فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ
A sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú Tírà. Ó ń wá ààbò fún àwọn òfin inú rẹ̀. Nítorí náà, fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ dájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn tó yapa sí ohun tí ó dé bá ọ nínú òdodo. Olúkùlùkù nínú yín ni A ti ṣe òfin àti ìlànà fún. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fún yín ni. Nítorí náà, ẹ gbawájú níbi iṣẹ́ rere. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Ó sì máa fún yín ní ìró nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
阿拉伯语经注:
وَأَنِ ٱحۡكُم بَيۡنَهُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَهُمۡ وَٱحۡذَرۡهُمۡ أَن يَفۡتِنُوكَ عَنۢ بَعۡضِ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ إِلَيۡكَۖ فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَٱعۡلَمۡ أَنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ أَن يُصِيبَهُم بِبَعۡضِ ذُنُوبِهِمۡۗ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلنَّاسِ لَفَٰسِقُونَ
Àti pé kí o fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Ṣọ́ra fún wọn kí wọ́n má baà fòòró rẹ kúrò níbi apá kan ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, mọ̀ pé Allāhu kàn fẹ́ fi àdánwò kàn wọ́n ni nítorí apá kan ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Àti pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ènìyàn ni òbìlẹ̀jẹ́.
阿拉伯语经注:
أَفَحُكۡمَ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِ يَبۡغُونَۚ وَمَنۡ أَحۡسَنُ مِنَ ٱللَّهِ حُكۡمٗا لِّقَوۡمٖ يُوقِنُونَ
Ṣé ìdájọ́ ìgbà àìmọ̀kan ni wọ́n ń wá ni? Ta ni ẹni tí ó dára ju Allāhu lọ níbi ìdájọ́ fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú (nípa Rẹ̀)?
阿拉伯语经注:
 
含义的翻译 章: 玛仪戴
章节目录 页码
 
《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖。 - 译解目录

谢赫艾布·拉西麦·米卡依赖·艾奎尼翻译。

关闭