Check out the new design

《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖。 * - 译解目录

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

含义的翻译 章: 金尼   段:
وَأَنَّا مِنَّا ٱلۡمُسۡلِمُونَ وَمِنَّا ٱلۡقَٰسِطُونَۖ فَمَنۡ أَسۡلَمَ فَأُوْلَٰٓئِكَ تَحَرَّوۡاْ رَشَدٗا
Dájúdájú àwọn mùsùlùmí wà nínú wa. Àwọn arúfin náà wà nínú wa. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ’Islām, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ṣe àwárí ìmọ̀nà.”
阿拉伯语经注:
وَأَمَّا ٱلۡقَٰسِطُونَ فَكَانُواْ لِجَهَنَّمَ حَطَبٗا
Ní ti àwọn arúfin, àwọn ni wọ́n máa jẹ́ igi ìkoná fún iná Jahanamọ.”
阿拉伯语经注:
وَأَلَّوِ ٱسۡتَقَٰمُواْ عَلَى ٱلطَّرِيقَةِ لَأَسۡقَيۡنَٰهُم مَّآءً غَدَقٗا
Àti pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n dúró ṣinṣin lójú ọ̀nà (’Islām) ni, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní omi púpọ̀ mu.
阿拉伯语经注:
لِّنَفۡتِنَهُمۡ فِيهِۚ وَمَن يُعۡرِضۡ عَن ذِكۡرِ رَبِّهِۦ يَسۡلُكۡهُ عَذَابٗا صَعَدٗا
Nítorí kí Á lè fi dán wọn wò ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Olúwa rẹ̀, Allāhu máa mú un wọ inú ìyà ìnira.
阿拉伯语经注:
وَأَنَّ ٱلۡمَسَٰجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدۡعُواْ مَعَ ٱللَّهِ أَحَدٗا
Dájúdájú àwọn mọ́sálásí ń jẹ́ ti Allāhu.[1] Nítorí náà, ẹ kò gbọ́dọ̀ pe ẹnì kan pẹ̀lú Allāhu.
[1] Nínú ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí kalmọh “mọsājid” dúró fún àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀. Àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ ni iwájú orí àti góńgórí imú, àtẹ́lẹwọ́ méjéèjì, orúnkún méjéèjì àti orí ọmọníkasẹ̀ méjéèjì. Èèwọ̀ ni fún ẹ̀dá lati fi ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ wọ̀nyí jọ́sìn tàbí kí ẹnikẹ́ni.
阿拉伯语经注:
وَأَنَّهُۥ لَمَّا قَامَ عَبۡدُ ٱللَّهِ يَدۡعُوهُ كَادُواْ يَكُونُونَ عَلَيۡهِ لِبَدٗا
Dájúdájú nígbà tí ẹrúsìn Allāhu dìde dúró tó ń pe Allāhu, àwọn àlùjànnú fẹ́ẹ̀ máa dìfún-ùn-ùnfún lọ́dọ̀ rẹ̀ (láti tẹ́tí sí al-Ƙur’ān).
阿拉伯语经注:
قُلۡ إِنَّمَآ أَدۡعُواْ رَبِّي وَلَآ أُشۡرِكُ بِهِۦٓ أَحَدٗا
Sọ pé: “Olúwa mi ni mò ń pè. Àti pé èmi kò níí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Un.”
阿拉伯语经注:
قُلۡ إِنِّي لَآ أَمۡلِكُ لَكُمۡ ضَرّٗا وَلَا رَشَدٗا
Sọ pé: “Dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ìnira àti ìmọ̀nà fún yín.”
阿拉伯语经注:
قُلۡ إِنِّي لَن يُجِيرَنِي مِنَ ٱللَّهِ أَحَدٞ وَلَنۡ أَجِدَ مِن دُونِهِۦ مُلۡتَحَدًا
Sọ pé: “Dájúdájú èmi, kò sí ẹnì kan tó lè gbà mí là lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì rí ibùsásí kan lẹ́yìn Rẹ̀.
阿拉伯语经注:
إِلَّا بَلَٰغٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِسَٰلَٰتِهِۦۚ وَمَن يَعۡصِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَإِنَّ لَهُۥ نَارَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا
Àfi (kí n̄g ṣe) ìkédé ẹ̀sìn (tó wá) láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti pé (kí n̄g sì jẹ́) àwọn iṣẹ́ Rẹ̀ (t’Ó fi rán mi). Ẹnikẹ́ni tó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ń bẹ fún un. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé.
阿拉伯语经注:
حَتَّىٰٓ إِذَا رَأَوۡاْ مَا يُوعَدُونَ فَسَيَعۡلَمُونَ مَنۡ أَضۡعَفُ نَاصِرٗا وَأَقَلُّ عَدَدٗا
(Aláìgbàgbọ́ kò níí yé ṣàì gbàgbọ́) títí di ìgbà tí wọ́n yóò fi rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn. Nígbà náà, wọn yóò mọ ta ni ó lẹ jùlọ ní alárànṣe, tí ó sì kéré jùlọ ní òǹkà.
阿拉伯语经注:
قُلۡ إِنۡ أَدۡرِيٓ أَقَرِيبٞ مَّا تُوعَدُونَ أَمۡ يَجۡعَلُ لَهُۥ رَبِّيٓ أَمَدًا
Sọ pé: “Èmi kò mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín ti súnmọ́ tàbí Olúwa mi yóò fún un ní àkókò tó jìnnà.
阿拉伯语经注:
عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ فَلَا يُظۡهِرُ عَلَىٰ غَيۡبِهِۦٓ أَحَدًا
Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, kò sì fi (ìmọ̀) ìkọ̀kọ̀ Rẹ̀ han ẹnì kan
阿拉伯语经注:
إِلَّا مَنِ ٱرۡتَضَىٰ مِن رَّسُولٖ فَإِنَّهُۥ يَسۡلُكُ مِنۢ بَيۡنِ يَدَيۡهِ وَمِنۡ خَلۡفِهِۦ رَصَدٗا
àyàfi ẹni tí Ó ṣàlẹ́ṣà tí ó jẹ́ Òjísẹ́.[1] Dájúdájú Ó ń mú ẹ̀ṣọ́ kan rìn níwájú Òjíṣẹ́ náà àti lẹ́yìn rẹ̀
[1] Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni òpin àwọn Ànábì àti òpin àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sí àáfà kan kan tí Allāhu ń fi iṣẹ́ ìmísí rán mọ́. aṣ-Ṣaetọ̄n àlùjànnú ni àwọn àáfà tó ń woṣẹ́ bá dòwò pọ̀. Òjíṣẹ́ àlùjànnú ni irú wọn, wọn kì í ṣe “òjíṣẹ́ Ọlọ́hun”.
阿拉伯语经注:
لِّيَعۡلَمَ أَن قَدۡ أَبۡلَغُواْ رِسَٰلَٰتِ رَبِّهِمۡ وَأَحَاطَ بِمَا لَدَيۡهِمۡ وَأَحۡصَىٰ كُلَّ شَيۡءٍ عَدَدَۢا
nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn pé wọ́n ti jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa wọn dé ògòńgó. Àti pé Allāhu fi ìmọ̀ rọkiri ká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì ṣọ́ òǹkà gbogbo n̄ǹkan.
阿拉伯语经注:
 
含义的翻译 章: 金尼
章节目录 页码
 
《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖。 - 译解目录

谢赫艾布·拉西麦·米卡依赖·艾奎尼翻译。

关闭