《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译。 * - 译解目录

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

含义的翻译 章: 艾尔拉   段:

Suuratul-A'laa

سَبِّحِ ٱسۡمَ رَبِّكَ ٱلۡأَعۡلَى
Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ.
阿拉伯语经注:
ٱلَّذِي خَلَقَ فَسَوَّىٰ
Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba.
阿拉伯语经注:
وَٱلَّذِي قَدَّرَ فَهَدَىٰ
Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà.¹
1. Nínú āyah yìí, mẹ́ta gbòòrò ni ìtọ́sọ́nà náà èyí tí Allāhu Afinimọ̀nà ń ṣe fún àwa ènìyàn àti àlùjànnú. Ìkíní: ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām. Nítorí ìtọ́sọ́nà yìí gan-an ni Allāhu ṣe sọ àwọn Tírà Rẹ̀ kalẹ̀, tí Ó sì gbé àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ dìde sí wa.
Ìkejì: ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí-ọkàn. Nípa èyí ni a fi mọ ohun rere àti ohun burúkú ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìfirinlẹ̀ rẹ̀ sì ń jẹyọ nínú àwọn tírà sánmọ̀ àti nínú ọ̀rọ̀ àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -.
Ìkẹta: ìtọ́sọ́nà òye àtinúwá. Nípa èyí ni a ṣe ń ṣàmúlò àwọn ohun àmúṣọrọ̀ fún ìgbáyé-gbádùn. Ìtọ́sọ́nà yìí kò sì sọ ẹnikẹ́ni di Òjíṣẹ́ Allāhu. Tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá rí ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, kò sí ẹ̀san rere kan fún un lórí rẹ̀ ní ọ̀run. Ó kàn wúlò dànù fún ayé ni.
阿拉伯语经注:
وَٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلۡمَرۡعَىٰ
Ẹni tí Ó mú koríko tútù hù jáde,
阿拉伯语经注:
فَجَعَلَهُۥ غُثَآءً أَحۡوَىٰ
Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ tó dúdú.
阿拉伯语经注:
سَنُقۡرِئُكَ فَلَا تَنسَىٰٓ
Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé.
阿拉伯语经注:
إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ يَعۡلَمُ ٱلۡجَهۡرَ وَمَا يَخۡفَىٰ
Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́.¹ Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun tó pamọ́.
1. Ìyẹn nípasẹ̀ fífí ìdájọ́ kan pa ìdájọ́ tó ṣíwájú rẹ̀ rẹ́. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:106.
阿拉伯语经注:
وَنُيَسِّرُكَ لِلۡيُسۡرَىٰ
Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ.
阿拉伯语经注:
فَذَكِّرۡ إِن نَّفَعَتِ ٱلذِّكۡرَىٰ
Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò.¹
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n fẹ́ kí ṣíṣe ìrántí ọ̀rọ̀ Allāhu jìnnà sí àyè ìhunrírà (bí ilé ọtí), ilé eré àti ilé awàdà nítorí pé, àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ kò níí kọbi ara sí olùsọ̀rọ̀. Āyah yìí jọ sūrah an-Nisā’; 4:140 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:68.
阿拉伯语经注:
سَيَذَّكَّرُ مَن يَخۡشَىٰ
Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí.
阿拉伯语经注:
وَيَتَجَنَّبُهَا ٱلۡأَشۡقَى
Olórí-burúkú sì máa takété sí i.
阿拉伯语经注:
ٱلَّذِي يَصۡلَى ٱلنَّارَ ٱلۡكُبۡرَىٰ
(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná tó tóbi.
阿拉伯语经注:
ثُمَّ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحۡيَىٰ
Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà).
阿拉伯语经注:
قَدۡ أَفۡلَحَ مَن تَزَكَّىٰ
Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀sìn rẹ̀) ti jèrè.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:4.
阿拉伯语经注:
وَذَكَرَ ٱسۡمَ رَبِّهِۦ فَصَلَّىٰ
Ó sì rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun.
阿拉伯语经注:
بَلۡ تُؤۡثِرُونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا
Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé.
阿拉伯语经注:
وَٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰٓ
Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé.
阿拉伯语经注:
إِنَّ هَٰذَا لَفِي ٱلصُّحُفِ ٱلۡأُولَىٰ
Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàǹdá àkọ́kọ́,
阿拉伯语经注:
صُحُفِ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ
tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā.
阿拉伯语经注:
 
含义的翻译 章: 艾尔拉
章节目录 页码
 
《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译。 - 译解目录

古兰经泰卢固语译解,艾布·拉赫曼·米卡伊里·艾库比尼长老翻译,伊历1432年出版发行。

关闭