Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Sourate: AL-MÂ’OUN   Verset:

Suuratul-Maahuun

أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يُكَذِّبُ بِٱلدِّينِ
Sọ fún mi nípa ẹni tó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san ní irọ́!
Les exégèses en arabe:
فَذَٰلِكَ ٱلَّذِي يَدُعُّ ٱلۡيَتِيمَ
Ìyẹn ni ẹni tó ń lé ọmọ-òrukàn dànù.
Les exégèses en arabe:
وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ
Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù.
Les exégèses en arabe:
فَوَيۡلٞ لِّلۡمُصَلِّينَ
Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) tó ń kírun;¹
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ kan ń sọ pé, “Ìrun túmọ̀ sí ohun tí ó máa run ènìyàn.” Wọ́n ní, “Ìdí nìyí tí Allāhu fi sọ pé “ègbé ni fún àwọn olùkírun.”
Èsì: Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ìkẹ́ àti ìbùkún ni ìrun kíkí jẹ́ fún olùkírun. Ní àkọ́kọ́ ná, ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ọ̀tá Allāhu máa ń fún àwọn ọ̀rọ̀ kan ní ìtúmọ̀ tó ń tàbùkù ẹ̀sìn ’Islām. Ọ̀kan ni bí wọ́n ṣe túmọ̀ “ìrun” sí “ohun tó ń run ènìyàn”. Òmíràn ni bí wọ́n ṣe ń sọ pé “ẹlẹ́hàá” túmọ̀ sí “ẹni tó bọ́ há” tàbí kí wọ́n sọ pé “ẹ̀há híhá wà fún àwọn obìnrin onísìná” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Mo ti ṣàlàyé nípa ọ̀rọ̀ “ẹ̀há híhá” nínú sūrah an-Nisā’; 4:15 àti sūrah an-Nūr; 24:31.
Ní ti “ìrun”, kò túmọ̀ sí “ohun tó ń run ènìyàn”. Àmọ́ ìtúmọ̀ “ìrun” ni “ohun tó ń run ẹ̀ṣẹ̀ olùkírun” nítorí pé, tí olùkírun bá ti ṣe àlùwàlá, ó ti ṣan gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ tí ó ti fi àwọn oríkèé ara rẹ̀ dá ṣíwájú nù. Bákan náà, ìrun kan sí ìrun kejì máa run gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ tí olùkírun dá láààrin ìrun àkọ́kọ́ sí ìrun kejì. Pẹ̀lú ìrun wákàtí márààrún lójoojúmọ́, ó ti run gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ rẹ̀ dànù. Ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ-àforíjìn l’ó máa run àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá dànù.
Kíyè sí i! Nínú èdè Yorùbá, “ẹ̀run” ni “ohun tí ó ń run ènìyàn”, àmọ́ “ìrun” ni “ohun tí ó ń run ẹ̀ṣẹ̀”.
Ní ti āyah tí wọ́n ń tìràn mọ́, kò rújú rárá pé, Allāhu ń sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ ìrun tí àwọn munāfiki ń kí lẹ́yìn tí àsìkò ìrun náà ti kọjá àti ìrun oníṣekárími. Āyah (5) sí āyah (7) tó tẹ̀lé āyah (4) ti fi èyí hàn kedere nítorí pé, “àwọn tí” tí í ṣe atọ́ka awẹ́-gbólóhùn aṣàpèjúwe l’ó bẹ̀rẹ̀ āyah (5) àti āyah (6).
Les exégèses en arabe:
ٱلَّذِينَ هُمۡ عَن صَلَاتِهِمۡ سَاهُونَ
àwọn tó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀;
Les exégèses en arabe:
ٱلَّذِينَ هُمۡ يُرَآءُونَ
àwọn tó ń ṣe ṣekárími;
Les exégèses en arabe:
وَيَمۡنَعُونَ ٱلۡمَاعُونَ
àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn).
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Sourate: AL-MÂ’OUN
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture