Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (157) Sourate: AN-NISÂ’
وَقَوۡلِهِمۡ إِنَّا قَتَلۡنَا ٱلۡمَسِيحَ عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ رَسُولَ ٱللَّهِ وَمَا قَتَلُوهُ وَمَا صَلَبُوهُ وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمۡۚ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُۚ مَا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٍ إِلَّا ٱتِّبَاعَ ٱلظَّنِّۚ وَمَا قَتَلُوهُ يَقِينَۢا
Àti nítorí ọ̀rọ̀ wọn (yìí): “Dájúdájú àwa pa Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam Òjíṣẹ́ Allāhu.” Wọn kò pa á, wọn kò sì kàn án mọ́ igi àgbélébùú, ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.¹ Dájúdájú àwọn tó yapa-ẹnu lórí rẹ̀, kúkú wà nínú iyèméjì lórí rẹ̀; kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀ àfi títẹ̀lé àbá dídá. Wọn kò pa á ní ti àmọ̀dájú.
1. Kíyè sí ìyàtọ̀ pàtàkì tó wà láààrin awẹ́ gbólóhùn méjì yìí:
Ìkíní “ وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمْۚ” ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “وَلَكِنْ أُلْقِيَ شَبَهُهُ عَلَى غَيْرِهِ لهم” “ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.” Ìyẹn ni pé, àwọn ọ̀tá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, wọ́n kan ẹnì kan mọ́ igi àgbélébùú, wọ́n sì pa onítọ̀ún sórí igi àgbélébùú nítorí pé, Allāhu ti gbé àwòrán àti ìrísí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - wọ ẹni tí ó gba ikú Ànábì ‘Īsā kú. Onítọ̀ún gan-an ni wọ́n kàn mọ́ igi àgbélébùú, kì í ṣe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Èyí sì ni ète ti Allāhu tí Ó fi gba Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ìdí sì nìyí tí àwọn ọ̀tá rẹ̀ fi wà nínú iyèméjì nípa ta gan-an ni wọ́n kàn mọ́ igi àgbélébùú nítorí pé, ìrísí àwọn méjèèjì ló jọra wọn, ohùn àwọn méjèèjì kò jọra wọn rárá.
Síwájú sí i, ẹ̀kọ́ nípa mọfọ́lọ́jì èdè Lárúbáwá (ìyẹn ‘ilmu-ssọrf) fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọ̀rọ̀-orúkọ fún “شُبِّهَ” tó jẹyọ pẹ̀lú háràfí “lām” nínú awẹ́ gbólóhùn “ وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمْۚ” jẹ́ “شَبَهٌ” (ṣabahun / ṣabah) tàbí “شِبْهٌ” (ṣibhun / ṣibh) - ìtúmọ̀ “ìjọra / àfijọ. Àti pé àkòónú “شَبَهٌ”/ “شِبْهٌ” (ṣabahun / ṣibhun) nígbà náà ni pé, wọ́n ń lò ó fún n̄ǹkan méjì tó jẹ́ oríṣìí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àmọ́ tí wọ́n jọra wọn ní àwòrán. Ìtúmọ̀ yìí sì ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó pilẹ̀ lórí àwọn háràfí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí “ش ب ه” ní nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ẹ wo àwọn àyè náà; sūrah al-Baƙọrah; 2:25, sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:7, sūrah al-’Ani‘ām; 6: 99 àti 141, àti sūrah as-Zumọr; 39:23.
Ìkejì, “وَلَكِنْ شُبِّهَ عَلَيْهِمْ” ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “وَلَكِنِ اشْتُبِهَ عَلَيْهِمْ ” “ṣùgbọ́n a fi rú wọn lójú / ṣùgbọ́n a dà á rú mọ́ wọn lójú”. Ìyẹn sì kọ́ ni al-Ƙur’ān sọ. Wòóore, ẹ̀kọ́ nípa mọfọ́lọ́jì èdè Lárúbáwá (‘ilmu-ssọrf) tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọ̀rọ̀-orúkọ fún “شُبِّهَ” tó jẹyọ pẹ̀lú háràfí “ ‘alā” nínú gbólóhùn yìí jẹ́ “شُبْهَةٌ” (ṣubhatun / ṣubhah) – ìtúmọ̀: “ìrújú / rújúrújú”. Àmọ́ sá, “ìjọra” máa ń yọrí sí “ìrújú” nígbà tí kò bá sí “àmọ̀dájú”.
Àkíyèsí kejì: Gbogbo tírà tafsīr tó sọ̀rọ̀ lórí “وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمْ” “ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.” l’ó mú ọ̀rọ̀ wá lórí bí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ṣe gbé àwòrán ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - wọ ẹnì kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Kódà wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà wá ni láti ọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -, gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè rí i kà nínú tafsīr Zādu-l-Mọsīr. Ẹni tí kò bá ní ìmọ̀ nípa ipò Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì - nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ al-Ƙur’ān tàbí ẹni tí kò bá ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ hadīth l’ó lè pe ìtàn náà ní ìtàn ’Isrọ̄’īliyāt
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (157) Sourate: AN-NISÂ’
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture