Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Sourate: AN-NISÂ’   Verset:

Suuratun-Nisaa'

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمُ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ وَخَلَقَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا وَبَثَّ مِنۡهُمَا رِجَالٗا كَثِيرٗا وَنِسَآءٗۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِي تَسَآءَلُونَ بِهِۦ وَٱلۡأَرۡحَامَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَيۡكُمۡ رَقِيبٗا
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan (ìyẹn, Ànábì Ādam). Ó sì ṣẹ̀dá aya rẹ̀ (Hawā’) láti ara rẹ̀. Ó fọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin jáde láti ara àwọn méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀ ń fi bẹ ara yín. (Ẹ ṣọ́) okùn-ìbí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí yín.
Les exégèses en arabe:
وَءَاتُواْ ٱلۡيَتَٰمَىٰٓ أَمۡوَٰلَهُمۡۖ وَلَا تَتَبَدَّلُواْ ٱلۡخَبِيثَ بِٱلطَّيِّبِۖ وَلَا تَأۡكُلُوٓاْ أَمۡوَٰلَهُمۡ إِلَىٰٓ أَمۡوَٰلِكُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ حُوبٗا كَبِيرٗا
Ẹ fún àwọn ọmọ òrukàn ní dúkìá wọn.¹ Ẹ má ṣe fi n̄ǹkan dáadáa pààrọ̀ n̄ǹkan burúkú.² Ẹ sì má ṣe jẹ dúkìá wọn mọ́ dúkìá yín; dájúdájú ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi.
1. Ìyẹn nígbà tí ọmọ òrukàn bá bàlágà, tí ó sì ní òye àmójútó dúkìá náà fúnra rẹ̀.
2. Bí àpẹ̀ẹrẹ, èyí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí alágbàtọ́ ọmọ-òrukàn bá fi dúkìá kan tó dára nínú àwọn dúkìá ọmọ òrukàn pààrọ̀ dúkìá tirẹ̀ tí kò dára mọ́ ọn lọ́wọ́. Allāhu sì ṣe ìṣesí yìí ní èèwọ̀.
Les exégèses en arabe:
وَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا تُقۡسِطُواْ فِي ٱلۡيَتَٰمَىٰ فَٱنكِحُواْ مَا طَابَ لَكُم مِّنَ ٱلنِّسَآءِ مَثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَۖ فَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا تَعۡدِلُواْ فَوَٰحِدَةً أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۚ ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَلَّا تَعُولُواْ
Tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé nípa (fífẹ́) ọmọ òrukàn,¹ ẹ fẹ́ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ si yín nínú àwọn obìnrin; méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin.² Ṣùgbọ́n tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé, (ẹ fẹ́) ẹyọ kan tàbí ẹrúbìnrin yín. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ pé ẹ ò níí ṣàbòsí.
1. Bí àpẹ̀ẹrẹ, kí ẹni tí ó ń mójútó ọmọ òrukàn obìnrin nífẹ̀ẹ́ láti fẹ́ ọmọbìnrin náà lẹ́yìn tí ó bàlágà tán, àmọ́ ọkùnrin náà kọ̀ láti fún un ní sọ̀daàkí rẹ̀ nítorí pé, ó mọ bí ogún ọmọbìnrin náà ṣe tó ní iye.
2. Kíyè sí i, àgbọ́yé “méjì” ni pé “fẹ́ méjì”, àgbọ́yé “mẹ́ta” ni pé “fẹ́ mẹ́ta”, àgbọ́yé “mẹ́rin” sì ni pé, “fẹ́ mẹ́rin”. Àgbọ́yé ọ̀rọ̀ àsọpọ̀ “wa” tó sì jẹyọ láààrin “mọthnā wa thulātha wa rubā‘” ni “tàbí”. Ìyẹn ni pé, “fẹ́ méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin”. Níwọ̀n ìgbà tí o ò bá gbọ́ “méjì” yé sí “fẹ́ méjì papọ̀ ní ọjọ́ kan náà”, tí o ò gbọ́ “mẹ́ta” yé sí “fẹ́ mẹ́ta papọ̀ ní ọjọ́ kan náà”, tí o ò sí gbọ́ “mẹ́rin” yé sí “fẹ́ mẹ́rin papọ̀ ní ọjọ́ kan náà”, o ò gbọ́dọ̀ gbọ́ “mọthnā wa thulātha wa rubā‘” yé sí “fẹ́ mẹ́sàn-án” ìyẹn, nípasẹ̀ lílo ọ̀rọ̀-àsopọ̀ “àti” fún ṣíṣírò méjì, mẹ́ta àti mẹ́rin papọ̀ mọ́ra wọn. Má sì ṣe sọ̀rọ̀ ní ìsọ̀rọ̀ àwọn aláìmọ̀kan nípa sísọ pé, “mẹ́ ni Ọlọ́hun wí”. Wọ́n ń parọ́ mọ́ Allāhu ni. Allāhu kò sọ “mẹ́”. Àwọn ni ìyà “mẹ́” ń wù ú jẹ.
Bákan náà, má ṣe korò ojú sí fífẹ́ ìyàwó dé orí méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin fún ẹni tí ó fẹ́ máa gbé bùkátà púpọ̀.
Ọkọ lè jẹ̀bi ẹ̀sùn àìṣe déédé, kódà kó jẹ́ oníyàwó kan péré, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ ahun, aláìbìkátà tàbí alápámáṣiṣẹ́ ọkùnrin.
Wòóore! Pẹ̀lú āyah yìí, mẹ́rin lòpin òǹkà àpapọ̀ ìyàwó tó lè wà nípò ìyàwó fún mùsùlùmí ẹyọ kan. Òfin t’ó rọ̀ mọ́ òǹkà àpapọ̀ ìyàwó Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni sūrah al-’Ahazāb; 33: 50 - 52. Òfin náà ló fún Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ẹ̀tọ́ láti fẹ́ kọjá mẹ́rin. Kò dojú rú rárá. Al-hamdu lillāh. Láti ọ̀dọ̀ ọmọ Ṣihāb, dájúdájú ó gbọ́ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ fún ọkùnrin kan láti ìdìlé Thaƙīf tí ó gba ’Islām, tí ìyàwó rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́wàá ní àsìkò tí ó gba ’Islām pé, “Mú mẹ́rin nínú wọn, kí o sì kọ àwọn yòókù sílẹ̀.” (Muwattọ’u Imām Mọ̄lik, Musnad Ṣāfi‘iy, Sunan Baehaƙiy àti Sọhīhu bn Hibbān)
Les exégèses en arabe:
وَءَاتُواْ ٱلنِّسَآءَ صَدُقَٰتِهِنَّ نِحۡلَةٗۚ فَإِن طِبۡنَ لَكُمۡ عَن شَيۡءٖ مِّنۡهُ نَفۡسٗا فَكُلُوهُ هَنِيٓـٔٗا مَّرِيٓـٔٗا
Ẹ fún àwọn obìnrin ní sọ̀daàkí wọn tó jẹ́ ọ̀ran-anyàn ní tọkàn-tọkàn. Tí wọ́n bá sì fi inú dídùn yọ̀ǹda kiní kan fún yín nínú rẹ̀, ẹ jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn àti ìgbádùn.
Les exégèses en arabe:
وَلَا تُؤۡتُواْ ٱلسُّفَهَآءَ أَمۡوَٰلَكُمُ ٱلَّتِي جَعَلَ ٱللَّهُ لَكُمۡ قِيَٰمٗا وَٱرۡزُقُوهُمۡ فِيهَا وَٱكۡسُوهُمۡ وَقُولُواْ لَهُمۡ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗا
Ẹ má ṣe kó dúkìá yín tí Allāhu fí ṣe gbẹ́mìíró fún yín lé àwọn aláìlóye lọ́wọ́. Ẹ pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn nínú rẹ̀, kí ẹ sì raṣọ fún wọn. Kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn.
Les exégèses en arabe:
وَٱبۡتَلُواْ ٱلۡيَتَٰمَىٰ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغُواْ ٱلنِّكَاحَ فَإِنۡ ءَانَسۡتُم مِّنۡهُمۡ رُشۡدٗا فَٱدۡفَعُوٓاْ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡۖ وَلَا تَأۡكُلُوهَآ إِسۡرَافٗا وَبِدَارًا أَن يَكۡبَرُواْۚ وَمَن كَانَ غَنِيّٗا فَلۡيَسۡتَعۡفِفۡۖ وَمَن كَانَ فَقِيرٗا فَلۡيَأۡكُلۡ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ فَإِذَا دَفَعۡتُمۡ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡ فَأَشۡهِدُواْ عَلَيۡهِمۡۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ حَسِيبٗا
Ẹ dán àwọn ọmọ òrukàn wò¹ títí wọn yóò fi dàgbà wọ ẹni tí ò lè ṣe ìgbéyàwó.² Tí ẹ bá sì ti rí òye lára wọn, kí ẹ dá dúkìá wọn padà fún wọn. Ẹ ò gbọdọ̀ jẹ dúkìá wọn ní ìjẹ àpà àti ìjẹkújẹ kí wọ́n tó dàgbà. Ẹni tí ó bá jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí ó mójú kúrò (níbẹ̀). Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìní, kí ó jẹ nínú rẹ̀ ní ọ̀nà tó dára. Nítorí náà, tí ẹ bá fẹ́ dá dúkìá wọn padà fún wọn, ẹ pe àwọn ẹlẹ́rìí sí wọn. Allāhu sì tó ní Olùṣírò.
1. Ìyẹn ni pé, ẹ kọ́kọ́ fi díẹ̀ tó kéré gan-an lé e lọ́wọ́ nínú ogún rẹ̀ tó jẹ́ ohun àmúṣọrọ̀, kí ẹ wo bí ó ṣe máa ṣe àmójútó rẹ̀.
2. “eni tí ó lè ṣe ìgbéyàwó” ni ẹni tí ó ti di ọmọkùnrin tàbí ẹni tí ó ti di ọmọbìnrin. Irú ọmọ náà ni a óò sọ nípa rẹ̀ pé, “ó ti bàlágà”. Ẹni tí ó = = ti bàlágà ni ẹni tí ó lè ṣe ìgbéyàwó. Ẹni tí ó ti bàlágà sì ni ẹni tí ó ti kúrò nípò ọmọdé. Ẹni tí ó ti bàlágà sì ni ẹni tí wọ́n ti la àwọn iṣẹ́ ẹ̀sìn bọ̀ lọ́rùn “mukallaf”. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ó máa gba ẹ̀san rẹ̀. Bí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú, ó máa gba ẹ̀san rẹ̀. Kí wá ni àwọn àmì tí ẹ̀sìn ’Islām gbékalẹ̀ fún bíbàlágà ọmọdé? Òhun ni ìwọ̀nyí: (1) Dída àtọ̀ mọniyyu sára yálà láti ojú-oorun tàbí láti ojú-ayé nípasẹ̀ oorun ìfẹ́ tàbí ní ọ̀nà mìíràn, (2) tàbí híhu irun abẹ́, (3) tàbí kí ọjọ́ orí ẹni wọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún pẹ̀lú òǹkà oṣù ’Islām, (4) tàbí kí obìnrin bẹ̀rẹ̀ n̄ǹkan oṣù rẹ̀ (héélà), (5) tàbí kí obìnrin ní oyún. Èyíkéyìí tí ó bá kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nínú àwọn n̄ǹkan márààrún wọ̀nyí ti sọ ọmọdé di àgbà (ẹni tí ó bàlágà).
Les exégèses en arabe:
لِّلرِّجَالِ نَصِيبٞ مِّمَّا تَرَكَ ٱلۡوَٰلِدَانِ وَٱلۡأَقۡرَبُونَ وَلِلنِّسَآءِ نَصِيبٞ مِّمَّا تَرَكَ ٱلۡوَٰلِدَانِ وَٱلۡأَقۡرَبُونَ مِمَّا قَلَّ مِنۡهُ أَوۡ كَثُرَۚ نَصِيبٗا مَّفۡرُوضٗا
Àwọn ọkùnrin ní ìpín nínú ohun tí òbí méjèèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Àti pé àwọn obìnrin náà ní ìpín nínú ohun tí òbí méjéèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Nínú ohun tó kéré nínú rẹ̀ tàbí tó pọ̀; (ó jẹ́) ìpín tí wọ́n ti pín (tí wọ́n ti ṣàdáyanrí rẹ̀ fún wọn).
Les exégèses en arabe:
وَإِذَا حَضَرَ ٱلۡقِسۡمَةَ أُوْلُواْ ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينُ فَٱرۡزُقُوهُم مِّنۡهُ وَقُولُواْ لَهُمۡ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗا
Nígbà tí àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù bá wà ní (ìjókòó) ogún pípín, ẹ fún wọn nínú rẹ̀ (ṣíwájú kí ẹ tó pín ogún), kí ẹ sì sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn.
Les exégèses en arabe:
وَلۡيَخۡشَ ٱلَّذِينَ لَوۡ تَرَكُواْ مِنۡ خَلۡفِهِمۡ ذُرِّيَّةٗ ضِعَٰفًا خَافُواْ عَلَيۡهِمۡ فَلۡيَتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلۡيَقُولُواْ قَوۡلٗا سَدِيدًا
Àwọn (olùpíngún àti alágbàwò-ọmọ-òrukàn) tí ó bá jẹ́ pé àwọn náà máa fi ọmọ wẹ́wẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì ń páyà lórí wọn, kí wọ́n yáa bẹ̀rù Allāhu. Kí wọ́n sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa (fún ọmọ òrukàn).
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَأۡكُلُونَ أَمۡوَٰلَ ٱلۡيَتَٰمَىٰ ظُلۡمًا إِنَّمَا يَأۡكُلُونَ فِي بُطُونِهِمۡ نَارٗاۖ وَسَيَصۡلَوۡنَ سَعِيرٗا
Dájúdájú àwọn tó ń jẹ dúkìá ọmọ òrukàn pẹ̀lú àbòsí, Iná kúkú ni wọ́n ń jẹ sínú ikùn wọn. Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó ń jó.
Les exégèses en arabe:
يُوصِيكُمُ ٱللَّهُ فِيٓ أَوۡلَٰدِكُمۡۖ لِلذَّكَرِ مِثۡلُ حَظِّ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۚ فَإِن كُنَّ نِسَآءٗ فَوۡقَ ٱثۡنَتَيۡنِ فَلَهُنَّ ثُلُثَا مَا تَرَكَۖ وَإِن كَانَتۡ وَٰحِدَةٗ فَلَهَا ٱلنِّصۡفُۚ وَلِأَبَوَيۡهِ لِكُلِّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا ٱلسُّدُسُ مِمَّا تَرَكَ إِن كَانَ لَهُۥ وَلَدٞۚ فَإِن لَّمۡ يَكُن لَّهُۥ وَلَدٞ وَوَرِثَهُۥٓ أَبَوَاهُ فَلِأُمِّهِ ٱلثُّلُثُۚ فَإِن كَانَ لَهُۥٓ إِخۡوَةٞ فَلِأُمِّهِ ٱلسُّدُسُۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصِي بِهَآ أَوۡ دَيۡنٍۗ ءَابَآؤُكُمۡ وَأَبۡنَآؤُكُمۡ لَا تَدۡرُونَ أَيُّهُمۡ أَقۡرَبُ لَكُمۡ نَفۡعٗاۚ فَرِيضَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Allāhu ń sọ àsọọ́lẹ̀ (òfin) fún yín nípa (ogún tí ẹ máa pín fún) àwọn ọmọ yín; ti ọkùnrin ni irú ìpín ti obìnrin méjì. Tí wọ́n bá sì jẹ́ obìnrin (nìkan), méjì sókè, tiwọn ni ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ohun tí (òkú) fi sílẹ̀. Tí ó bá jẹ́ obìnrin kan ṣoṣo, ìdajì ni tirẹ̀. Ti òbí rẹ̀ méjèèjì, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì nínú ohun tí òkú fi sílẹ̀, tí ó bá ní ọmọ láyé. Tí kò bá sì ní ọmọ láyé, tí ó sì jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì l’ó máa jogún rẹ̀, ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ni ti ìyá rẹ̀. Tí ó bá ní arákùnrin (tàbí arábìnrin), ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìyá rẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ó sọ tàbí gbèsè. Àwọn bàbá yín àti àwọn ọmọkùnrin yín; ẹ̀yin kò mọ èwo nínú wọn ló máa mú àǹfààní ba yín jùlọ. (Ìpín) ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Les exégèses en arabe:
۞ وَلَكُمۡ نِصۡفُ مَا تَرَكَ أَزۡوَٰجُكُمۡ إِن لَّمۡ يَكُن لَّهُنَّ وَلَدٞۚ فَإِن كَانَ لَهُنَّ وَلَدٞ فَلَكُمُ ٱلرُّبُعُ مِمَّا تَرَكۡنَۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصِينَ بِهَآ أَوۡ دَيۡنٖۚ وَلَهُنَّ ٱلرُّبُعُ مِمَّا تَرَكۡتُمۡ إِن لَّمۡ يَكُن لَّكُمۡ وَلَدٞۚ فَإِن كَانَ لَكُمۡ وَلَدٞ فَلَهُنَّ ٱلثُّمُنُ مِمَّا تَرَكۡتُمۚ مِّنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ تُوصُونَ بِهَآ أَوۡ دَيۡنٖۗ وَإِن كَانَ رَجُلٞ يُورَثُ كَلَٰلَةً أَوِ ٱمۡرَأَةٞ وَلَهُۥٓ أَخٌ أَوۡ أُخۡتٞ فَلِكُلِّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا ٱلسُّدُسُۚ فَإِن كَانُوٓاْ أَكۡثَرَ مِن ذَٰلِكَ فَهُمۡ شُرَكَآءُ فِي ٱلثُّلُثِۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصَىٰ بِهَآ أَوۡ دَيۡنٍ غَيۡرَ مُضَآرّٖۚ وَصِيَّةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَلِيمٞ
Tiyín ni ìlàjì ohun tí àwọn ìyàwó yín fi sílẹ̀, tí wọn kò bá ní ọmọ. Tí wọ́n bá sì ní ọmọ, tiyín ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí wọ́n fi sílẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè. Tiwọn sì ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí ẹ fi sílẹ̀, tí ẹ̀yin kò bá ní ọmọ láyé. Tí ẹ bá ní ọmọ láyé, ìdá kan nínú ìdá mẹ́jọ ni tiwọn nínú ohun tí ẹ fi sílẹ̀ lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ẹ sọ tàbí gbèsè. Tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan tí wọ́n fẹ́ jogún rẹ̀ kò bá ní òbí àti ọmọ, tí ó sì ní arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì. Tí wọ́n bá sì pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ, wọn yóò dìjọ pín ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè, tí kò níí jẹ́ ìpalára. Àsọọ́lẹ̀ (òfin) kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Aláfaradà.
Les exégèses en arabe:
تِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِۚ وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ يُدۡخِلۡهُ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ
Ìyẹn ni àwọn ẹnu-ààlà (tí) Allāhu (gbékalẹ̀ fún ogún pípín). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
Les exégèses en arabe:
وَمَن يَعۡصِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَيَتَعَدَّ حُدُودَهُۥ يُدۡخِلۡهُ نَارًا خَٰلِدٗا فِيهَا وَلَهُۥ عَذَابٞ مُّهِينٞ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ó sì ń tayọ àwọn ẹnu-ààlà tí Allāhu gbékalẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú Iná kan. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì ń bẹ fún un.¹
1. Kíyè sí i, kò bá òfin ’Islām mu láti pín ogún ara ẹni sílẹ̀. Àti pé bí ènìyàn kò bá tí ì kú, dúkìá rẹ̀ kò ì di ogún fún ẹnì kan kan. Bákan náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe lérò pé tí òun bá ti ka àwọn āyah ogún pípín, òun ti nímọ̀ nípa ogún pípín nìyẹn. Rárá o. Ènìyàn gbọ́dọ̀ ka àwọn tírà tí àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām fi ṣàlàyé nípa ogún pípín. Fómúlà nìkan ni àwọn āyah ogún pípín jẹ́, bí a ṣe máa lo àwọn fọ́múlà náà wà nínú àwọn tírà ogún pípín.
Les exégèses en arabe:
وَٱلَّٰتِي يَأۡتِينَ ٱلۡفَٰحِشَةَ مِن نِّسَآئِكُمۡ فَٱسۡتَشۡهِدُواْ عَلَيۡهِنَّ أَرۡبَعَةٗ مِّنكُمۡۖ فَإِن شَهِدُواْ فَأَمۡسِكُوهُنَّ فِي ٱلۡبُيُوتِ حَتَّىٰ يَتَوَفَّىٰهُنَّ ٱلۡمَوۡتُ أَوۡ يَجۡعَلَ ٱللَّهُ لَهُنَّ سَبِيلٗا
Àwọn tó ń ṣe sìná nínú àwọn obìnrin yín, ẹ wá ẹlẹ́rìí mẹ́rin nínú yín tí ó máa jẹ́rìí lé wọn lórí. Tí wọ́n bá jẹ́rìí lé wọn lórí, kí ẹ dè wọ́n mọ́ inú ilé títí ikú yóò fi pa wọ́n tàbí (títí) Allāhu yóò fi gbé ọ̀nà (ìjìyà) kan kalẹ̀ fún wọn.¹
1. Èyí ni òfin àkọ́kọ́ lórí ìdíyàjẹ onísìná obìnrin tó ti ní yìgì lórí rí. Lẹ́yìn náà, òfin lílẹ onísìná lókò pa dé lórí ẹni tí ó bá ṣe sìná lẹ́yìn tí ó ti ṣe nikāh rí, yálà obìnrin tàbí ọkùnrin. Èyí sì ni ọ̀nà mìíràn tí Allāhu mú wá lórí ahọ́n Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Òfin àkọ́kọ́ yẹn “títi onísìná adélébọ̀ àti abilékọ obìnrin mọ́nú ilé d’ọjọ́ ikú” ni àwọn kògbédè-ó-gbékèé ń lò fún ẹ̀há (hijāb) àwọn obìnrin mùsùlùmí. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀tọ̀ ni āyah ìdíyàjẹ onísìná bíi tinú sūrah an-Nūr; 24:2, ọ̀tọ̀ sì ni āyah ẹ̀há (hijāb) bíi tinú sūrah an-Nūr; 24:31 àti sūrah al-’Ahzāb; 33:59.
Les exégèses en arabe:
وَٱلَّذَانِ يَأۡتِيَٰنِهَا مِنكُمۡ فَـَٔاذُوهُمَاۖ فَإِن تَابَا وَأَصۡلَحَا فَأَعۡرِضُواْ عَنۡهُمَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ تَوَّابٗا رَّحِيمًا
Àwọn méjì tí wọ́n ṣe sìná nínú yín, kí ẹ (fi ẹnu tàbí ọwọ́) bá wọn wí.¹ Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣàtúnṣe, kí ẹ mójú kúrò lára wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́- ọ̀run.
1. Wọ́n ti fi sūrah an-Nūr; 24:2 pa ìdájọ́ āyah yìí rẹ̀ nítorí pé, āyah méjèèjì dálé ìjìyà fún onísìná tí kò ì ṣe ìgbéyàwó rí.
Les exégèses en arabe:
إِنَّمَا ٱلتَّوۡبَةُ عَلَى ٱللَّهِ لِلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسُّوٓءَ بِجَهَٰلَةٖ ثُمَّ يَتُوبُونَ مِن قَرِيبٖ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَتُوبُ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Ìronúpìwàdà tí Allāhu yóò gbà ni ti àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan.¹ Lẹ́yìn náà, wọ́n ronú pìwàdà láìpẹ́ (ìyẹn ṣíwájú ọjọ́ ikú wọn). Àwọn wọ̀nyí ni Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ṣíṣe aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan ni ṣíṣe aburú nígbà tí ènìyàn kò nímọ̀ nípa ìdàjọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kódà kí ènìyàn ní ìmọ̀, bí ó bá ṣiṣẹ́ aburú, kì í ṣe ìmọ̀ ló pàṣẹ aburú fún un bí kò ṣe pé ní àsìkò tí onímọ̀ náà bá ń ṣiṣẹ́ aburú lọ́wọ́, ó ti wọ aṣọ àìmọ̀kan, ó sì ṣe aburú náà pẹ̀lú àìmọ̀kan tàbí ó ṣe aburú náà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ̀kan.
Les exégèses en arabe:
وَلَيۡسَتِ ٱلتَّوۡبَةُ لِلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ حَتَّىٰٓ إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ ٱلۡمَوۡتُ قَالَ إِنِّي تُبۡتُ ٱلۡـَٰٔنَ وَلَا ٱلَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمۡ كُفَّارٌۚ أُوْلَٰٓئِكَ أَعۡتَدۡنَا لَهُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا
Kò sí ìronúpìwàdà fún àwọn tó ń ṣe aburú títí ikú fi dé bá ọ̀kan nínú wọn, kí ó wá wí pé: “Dájúdájú èmi ronú pìwàdà nísisìnyìí.” (Kò tún sí ìronúpìwàdà) fún àwọn tó kú sípò aláìgbàgbọ́. Àwọn wọ̀nyẹn, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta eléro sílẹ̀ dè wọ́n.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا يَحِلُّ لَكُمۡ أَن تَرِثُواْ ٱلنِّسَآءَ كَرۡهٗاۖ وَلَا تَعۡضُلُوهُنَّ لِتَذۡهَبُواْ بِبَعۡضِ مَآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ إِلَّآ أَن يَأۡتِينَ بِفَٰحِشَةٖ مُّبَيِّنَةٖۚ وَعَاشِرُوهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ فَإِن كَرِهۡتُمُوهُنَّ فَعَسَىٰٓ أَن تَكۡرَهُواْ شَيۡـٔٗا وَيَجۡعَلَ ٱللَّهُ فِيهِ خَيۡرٗا كَثِيرٗا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti jẹ àwọn obìnrin mógún pẹ̀lú ipá (bíi ṣíṣú obìnrin lópó.) Ẹ má ṣe fúnlẹ̀ mọ́ wọn nítorí kí ẹ le gba apá kan n̄ǹkan tí ẹ fún wọn àyàfi tí wọ́n bá hùwà ìbàjẹ́ tó fojú hàn. Ẹ bá wọn lòpọ̀ pẹ̀lú dáadáa. Tí ẹ bá kórira wọn, ó lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí Allāhu sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oore sínú rẹ̀.
Les exégèses en arabe:
وَإِنۡ أَرَدتُّمُ ٱسۡتِبۡدَالَ زَوۡجٖ مَّكَانَ زَوۡجٖ وَءَاتَيۡتُمۡ إِحۡدَىٰهُنَّ قِنطَارٗا فَلَا تَأۡخُذُواْ مِنۡهُ شَيۡـًٔاۚ أَتَأۡخُذُونَهُۥ بُهۡتَٰنٗا وَإِثۡمٗا مُّبِينٗا
Tí ẹ bá sì fẹ́ fi ìyàwó kan pààrọ̀ àyè ìyàwó kan, tí ẹ sì ti fún ọ̀kan nínú wọn ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá, ẹ ò gbọdọ̀ gba n̄ǹkan kan nínú rẹ̀ mọ́. Ṣé ẹ̀yin yóò gbà á ní ti àdápa irọ́ (tí ẹ̀ ń pa mọ́ wọn) àti ẹ̀ṣẹ̀ tó fojú hàn(tí ẹ̀ ń dá nípa wọn)?¹
1. Pípa irọ́ mọ́ ìyàwó ẹni àti fífi ìnira kàn án nítorí kí ó lè sọ pé òun kò ṣe mọ́, - ṣebí ọkọ kúkú ti mọ̀ pé bí ìkọ̀sílẹ̀ bá wáyé láti ọ̀dọ̀ obìnrin, èyí tí a mọ̀ sí kul‘u, ó máa dá sọ̀daàkí rẹ̀ padà fún ọkọ - ó jẹ́ ìṣesí burúkú tí āyah yìí ń ṣe ní harām.
Les exégèses en arabe:
وَكَيۡفَ تَأۡخُذُونَهُۥ وَقَدۡ أَفۡضَىٰ بَعۡضُكُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٖ وَأَخَذۡنَ مِنكُم مِّيثَٰقًا غَلِيظٗا
Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè gbà á padà nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ ti wọlé tọ’ra yín, tí wọ́n sì ti gba àdéhùn tó nípọn lọ́wọ́ yín!¹
1. Àdéhùn tó nípọn tí ọkọ ṣe fún ìyàwó rẹ̀ ni pé, “Èmi yóò máa ṣe dáadáa pẹ̀lú rẹ̀ tàbí kí n̄g tú ọ sílẹ̀ pẹ̀lú dáadáa, ìyẹn tí ìkọ̀sílẹ̀ bá ṣẹlẹ̀.”
Les exégèses en arabe:
وَلَا تَنكِحُواْ مَا نَكَحَ ءَابَآؤُكُم مِّنَ ٱلنِّسَآءِ إِلَّا مَا قَدۡ سَلَفَۚ إِنَّهُۥ كَانَ فَٰحِشَةٗ وَمَقۡتٗا وَسَآءَ سَبِيلًا
Ẹ má ṣe fẹ́ ẹni tí àwọn bàbá yín ti fẹ́ nínú àwọn obìnrin àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ àti ohun ìkórira. Ó sì burú ní ọ̀nà.
Les exégèses en arabe:
حُرِّمَتۡ عَلَيۡكُمۡ أُمَّهَٰتُكُمۡ وَبَنَاتُكُمۡ وَأَخَوَٰتُكُمۡ وَعَمَّٰتُكُمۡ وَخَٰلَٰتُكُمۡ وَبَنَاتُ ٱلۡأَخِ وَبَنَاتُ ٱلۡأُخۡتِ وَأُمَّهَٰتُكُمُ ٱلَّٰتِيٓ أَرۡضَعۡنَكُمۡ وَأَخَوَٰتُكُم مِّنَ ٱلرَّضَٰعَةِ وَأُمَّهَٰتُ نِسَآئِكُمۡ وَرَبَٰٓئِبُكُمُ ٱلَّٰتِي فِي حُجُورِكُم مِّن نِّسَآئِكُمُ ٱلَّٰتِي دَخَلۡتُم بِهِنَّ فَإِن لَّمۡ تَكُونُواْ دَخَلۡتُم بِهِنَّ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ وَحَلَٰٓئِلُ أَبۡنَآئِكُمُ ٱلَّذِينَ مِنۡ أَصۡلَٰبِكُمۡ وَأَن تَجۡمَعُواْ بَيۡنَ ٱلۡأُخۡتَيۡنِ إِلَّا مَا قَدۡ سَلَفَۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا
A ṣe é ní èèwọ̀ fún yín (láti fẹ́) àwọn ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin yín àti àwọn arábìnrin yín àti àwọn arábìnrin bàbá yín àti àwọn arábìnrin ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin yín àti àwọn ìyá yín tí ó fún yín ní ọyàn mu àti àwọn arábìnrin yín nípasẹ̀ ọyàn àti àwọn ìyá ìyàwó yín àti àwọn ọmọbìnrin ìyàwó yín tí ẹ gbà tọ́, èyí tó wà nínú ilé yín,¹ tí ẹ sì ti wọlé tọ àwọn ìyá wọn, - tí ẹ̀yin kò bá sì tí ì wọlé tọ̀ wọ́n, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín (láti fẹ́ ọmọbìnrin wọn), - àti àwọn ìyàwó ọmọ yín, èyí tí ó ti ìbàdí yín jáde. (Ó tún jẹ́ èèwọ̀) láti fẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò papọ̀ àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
1. Awẹ́ gbólóhùn “èyí t’ó wà nínú ilé yín” kì í ṣe májẹ̀mu. Àmọ́ ó ń fún wa ní ìtọ́ka sí pé, kì í ṣe èèwọ̀ fún ọmọ tí obìnrin ti bí fún ọkùnrin kan láti gbé lọ́dọ̀ ọkọ ìyá rẹ̀.
Les exégèses en arabe:
۞ وَٱلۡمُحۡصَنَٰتُ مِنَ ٱلنِّسَآءِ إِلَّا مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۖ كِتَٰبَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡۚ وَأُحِلَّ لَكُم مَّا وَرَآءَ ذَٰلِكُمۡ أَن تَبۡتَغُواْ بِأَمۡوَٰلِكُم مُّحۡصِنِينَ غَيۡرَ مُسَٰفِحِينَۚ فَمَا ٱسۡتَمۡتَعۡتُم بِهِۦ مِنۡهُنَّ فَـَٔاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ فَرِيضَةٗۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ فِيمَا تَرَٰضَيۡتُم بِهِۦ مِنۢ بَعۡدِ ٱلۡفَرِيضَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا
(Ó tún jẹ́ èèwọ̀ láti fẹ́) àwọn abilékọ nínú àwọn obìnrin àyàfi àwọn ẹrúbìnrin yín. Òfin Allāhu nìyí lórí yín. Wọ́n sì ṣe ẹni tó ń bẹ lẹ́yìn àwọn wọ̀nyẹn (àwọn obìnrin yòókù) ní ẹ̀tọ́ fún yín pé kí ẹ wá wọn fẹ́ pẹ̀lú dúkìá yín; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ ìyàwó, láì nìí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì síso). Ẹni tí ẹ bá sì fẹ́ ní fífẹ́ ìyàwó nínú wọn, tí ẹ sì ti jẹ ìgbádùn oorun ìfẹ́ lára wọn¹ (àmọ́ tí ẹ fẹ́ kọ̀ wọ́n sílẹ̀), ẹ fún wọn ní sọ̀daàkí wọn tí ó jẹ́ ìpín ọ̀ran-anyàn.² Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín nípa ohun tí ẹ dìjọ yọ́nú sí (láti fojúfò láààrin ara yín) lẹ́yìn sọ̀daàkí (tó jẹ́ ìpín ọ̀ran-anyàn)³. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì - “Kódà kí ó jẹ́ ìbálòpọ̀ ẹ̀ẹ̀ kan péré.”
2. Gbólóhùn yìí jẹmọ́ sūrah al-Baƙọrah; 2:236 - 237 nítorí pé, ọ̀rọ̀ obìnrin tí ọkọ fẹ́ tán tí ìkọ̀sílẹ̀ wáyé láààrin wọn ṣíwájú ìbálòpọ̀, èyí ló jẹyọ nínú āyah méjèèjì yẹn. Àmọ́ nínú āyah yìí ìkọ̀sílẹ̀ wáyé lẹ́yìn ìbálòpọ̀ díẹ̀, ó kéré parí ẹ̀ẹ̀ kan péré. Ó gbọ́dọ̀ san sọ̀daàkí rẹ̀ fún un.
3. Ìyẹn ni pé, kò sí aburú tí obìnrin náà bá gba àdínkù, kò sì sí aburú tí ọkọ bá fún un ní àlékún sí òdíwọ̀n sọ̀daàkí tí wọ́n dìjọ fẹnukò sí.
Les exégèses en arabe:
وَمَن لَّمۡ يَسۡتَطِعۡ مِنكُمۡ طَوۡلًا أَن يَنكِحَ ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ فَمِن مَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُم مِّن فَتَيَٰتِكُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِۚ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِإِيمَٰنِكُمۚ بَعۡضُكُم مِّنۢ بَعۡضٖۚ فَٱنكِحُوهُنَّ بِإِذۡنِ أَهۡلِهِنَّ وَءَاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِ مُحۡصَنَٰتٍ غَيۡرَ مُسَٰفِحَٰتٖ وَلَا مُتَّخِذَٰتِ أَخۡدَانٖۚ فَإِذَآ أُحۡصِنَّ فَإِنۡ أَتَيۡنَ بِفَٰحِشَةٖ فَعَلَيۡهِنَّ نِصۡفُ مَا عَلَى ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ مِنَ ٱلۡعَذَابِۚ ذَٰلِكَ لِمَنۡ خَشِيَ ٱلۡعَنَتَ مِنكُمۡۚ وَأَن تَصۡبِرُواْ خَيۡرٞ لَّكُمۡۗ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Ẹni tí kò bá lágbára ọrọ̀ nínú yín láti fẹ́ àwọn olómìnira onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, kí ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúbìnrin yín onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ yín, ara kan náà sì ni yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda àwọn olówó wọn (àwọn ọ̀gá wọn). Kí ẹ sì fún wọn ní sọ̀daàkí wọn ní ọ̀nà tó dára, (ìyẹn) àwọn ọmọlúàbí (ẹrúbìnrin), yàtọ̀ sí àwọn onísìná obìnrin àti àwọn obìnrin tí ń yan àlè¹. Nígbà tí wọ́n bá sì di abilékọ, tí wọ́n bá (tún) lọ ṣe sìná, ìlàjì ìyà tí ń bẹ fún àwọn olómìnira obìnrin ni ìyà tí ń bẹ fún wọn.² (Fífẹ́ ẹrúbìnrin), ìyẹn wà fún ẹni tó ń páyà ìnira (sìná) nínú yín. Àti pé kí ẹ ṣe sùúrù lóore jùlọ fún yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
1. Musāfihah ni onísìná obìnrin tí kò sí lábẹ́ ọkọ. Muttẹkithatu- ’akdān ni onísìná obìnrin tí ó wà lábẹ́ ọkọ.
2. Ìyẹn ni pé, ẹrúbìnrin, tí ó bá ṣe sìná, kòbókò àádọ́ta ni ìjìyà rẹ̀, kì í ṣe lílẹ̀-lókò-pa nítorí pé, lílẹ̀-lókò-pa kò ṣe é pín sí méjì.
Les exégèses en arabe:
يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُبَيِّنَ لَكُمۡ وَيَهۡدِيَكُمۡ سُنَنَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ وَيَتُوبَ عَلَيۡكُمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ
Allāhu fẹ́ ṣàlàyé (òfin) fún yín, Ó fẹ́ tọ yín sí ọ̀nà àwọn tó ṣíwájú yín, Ó sì fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Les exégèses en arabe:
وَٱللَّهُ يُرِيدُ أَن يَتُوبَ عَلَيۡكُمۡ وَيُرِيدُ ٱلَّذِينَ يَتَّبِعُونَ ٱلشَّهَوَٰتِ أَن تَمِيلُواْ مَيۡلًا عَظِيمٗا
Àti pé Allāhu fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Àwọn tó sì ń tẹ̀lé ìfẹ́-adùn ara sì ń fẹ́ kí ẹ yẹ̀ kúrò (nínú ẹ̀sìn) ní yíyẹ̀ tó tóbi pátápátá.
Les exégèses en arabe:
يُرِيدُ ٱللَّهُ أَن يُخَفِّفَ عَنكُمۡۚ وَخُلِقَ ٱلۡإِنسَٰنُ ضَعِيفٗا
Allāhu fẹ́ gbé e fúyẹ́ fún yín; A sì ṣẹ̀dá ènìyàn ní ọ̀lẹ.¹
1. Ìyẹn ni pé, àdámọ́ lílẹ wà nínú ìṣẹ̀dá ènìyàn.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَأۡكُلُوٓاْ أَمۡوَٰلَكُم بَيۡنَكُم بِٱلۡبَٰطِلِ إِلَّآ أَن تَكُونَ تِجَٰرَةً عَن تَرَاضٖ مِّنكُمۡۚ وَلَا تَقۡتُلُوٓاْ أَنفُسَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُمۡ رَحِيمٗا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín àyàfi kí ó jẹ́ òwò ṣíṣe pẹ̀lú ìyọ́nú láààrin ara yín. Ẹ má ṣe para yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú si yín.
Les exégèses en arabe:
وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ عُدۡوَٰنٗا وَظُلۡمٗا فَسَوۡفَ نُصۡلِيهِ نَارٗاۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرًا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe ìyẹn láti fi tayọ ẹnu-ààlà àti láti fi ṣe àbòsí, láìpẹ́ A máa mú un wọ inú Iná. Ìrọ̀rùn sì ni ìyẹn jẹ́ fún Allāhu.
Les exégèses en arabe:
إِن تَجۡتَنِبُواْ كَبَآئِرَ مَا تُنۡهَوۡنَ عَنۡهُ نُكَفِّرۡ عَنكُمۡ سَيِّـَٔاتِكُمۡ وَنُدۡخِلۡكُم مُّدۡخَلٗا كَرِيمٗا
Tí ẹ bá jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá tí A kọ̀ fún yín, A máa pa àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fún yín, A sì máa mu yín wọ àyè alápọ̀n-ọ́nlé.
Les exégèses en arabe:
وَلَا تَتَمَنَّوۡاْ مَا فَضَّلَ ٱللَّهُ بِهِۦ بَعۡضَكُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۚ لِّلرِّجَالِ نَصِيبٞ مِّمَّا ٱكۡتَسَبُواْۖ وَلِلنِّسَآءِ نَصِيبٞ مِّمَّا ٱكۡتَسَبۡنَۚ وَسۡـَٔلُواْ ٱللَّهَ مِن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا
Ẹ má ṣe jẹ̀rankàn ohun tí Allāhu fi ṣ’oore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan.¹ Ìpín (ẹ̀san) ń bẹ fún àwọn ọkùnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, ìpín (ẹ̀san) sì ń bẹ fún àwọn obìnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Kí ẹ sì tọrọ lọ́dọ̀ Allāhu nínú àlékún oore Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
1. Āyah yìí sọ̀kalẹ̀ nítorí bí àwọn obìnrin kan ṣe ń jẹ̀rankàn pé kí àwọn obìnrin àti àwọn ọkùnrin dìjọ wà ní ipò orí-ò-jorí nínú ètò ilé ayé yìí, bí ogún pípín, lílọ-bíbọ̀ ní ìgboro àti lórí ìrìn-àjò, iṣẹ́ ṣíṣe láààrin àwọn ọkùnrin, dídi ipò àṣẹ mú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sì jẹ́ kí ó yé wa pé kò rí bẹ́ẹ̀ rárá àfi níbi iṣẹ́ ìjọ́sìn àti ẹ̀san rẹ̀.
Les exégèses en arabe:
وَلِكُلّٖ جَعَلۡنَا مَوَٰلِيَ مِمَّا تَرَكَ ٱلۡوَٰلِدَانِ وَٱلۡأَقۡرَبُونَۚ وَٱلَّذِينَ عَقَدَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡ فَـَٔاتُوهُمۡ نَصِيبَهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدًا
Ìkọ̀ọ̀kan (àwọn dúkìá) ni A ti ṣe àdáyanrí rẹ̀ fún àwọn tí ó máa jogún rẹ̀ nínú ohun tí àwọn òbí àti ẹbí fi sílẹ̀. Àwọn tí ẹ sì búra fún (pé ẹ máa fún ní n̄ǹkan), ẹ fún wọn ní ìpín wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
Les exégèses en arabe:
ٱلرِّجَالُ قَوَّٰمُونَ عَلَى ٱلنِّسَآءِ بِمَا فَضَّلَ ٱللَّهُ بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ وَبِمَآ أَنفَقُواْ مِنۡ أَمۡوَٰلِهِمۡۚ فَٱلصَّٰلِحَٰتُ قَٰنِتَٰتٌ حَٰفِظَٰتٞ لِّلۡغَيۡبِ بِمَا حَفِظَ ٱللَّهُۚ وَٱلَّٰتِي تَخَافُونَ نُشُوزَهُنَّ فَعِظُوهُنَّ وَٱهۡجُرُوهُنَّ فِي ٱلۡمَضَاجِعِ وَٱضۡرِبُوهُنَّۖ فَإِنۡ أَطَعۡنَكُمۡ فَلَا تَبۡغُواْ عَلَيۡهِنَّ سَبِيلًاۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيّٗا كَبِيرٗا
Àwọn ọkùnrin ni òpómúléró¹ fún àwọn obìnrin nítorí pé, Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan² àti nítorí ohun tí wọ́n ń ná nínú dúkìá wọn.³ Àwọn obìnrin rere ni àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ (Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà àṣẹ ọkọ), àwọn olùṣọ́-ẹ̀tọ́ ọkọ ní kọ̀rọ̀ fún wí pé Allāhu ṣọ́ (ẹ̀tọ́ tiwọn náà fún wọn lọ́dọ̀ ọkọ wọn). Àwọn tí ẹ sì ń páyà oríkunkun wọn4, ẹ ṣe wáàsí fún wọn, ẹ takété sí ibùsùn wọn, ẹ lù wọ́n. Tí wọ́n bá sì tẹ̀lé àṣẹ yín, ẹ má ṣe fí ọ̀nà kan kan wá wọn níjà5. Dájúdájú Allāhu ga, Ó tóbi.6
1. aláṣẹ, olùdarí, alámòójútó àti onímọ̀ràn rere.
2. Ìyẹn ni pé, Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún àwọn ọkùnrin lórí àwọn obìnrin wọn.
3. Ìyẹn ni pé, àwọn ọkùnrin ni wọn yóò máa gbé bùkátà àwọn obìnrin wọn. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọkùnrin ti yẹrí kúrò níbẹ̀. Ìdí nìyí tí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ obìnrin fi kún ìgboro fọ́fọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣì tí ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dẹ sí àwọn ará ìlú jẹ́ okùnfà kan pàtàkì, àwọn ọlọ́mọge fúnra wọn ń fi títako ṣíṣe ìyàwó kejì tàbí ìkẹta tàbí ìkẹrin bọ́ sí ọwọ́ alápámáṣiṣẹ́ ọ̀dọ́ ọkùnrin.
4. Èyí ni ti olóríkunkun obìnrin. Ní ti olóríkunkun ọkùnrin, ẹ wo āyah 128.
5. Ẹ má ṣe fi ọ̀nà kan kan ṣàbòsí sí wọn, Ẹ má ṣe fi ọ̀nà kan kan tayọ ẹnu-ààlà sí wọn.
6. Kíyè sí i, ọkọ kò gbọ́dọ̀ lu ìyàwó rẹ̀ àfi pẹ̀lú àwọn májẹ̀mu mẹ́fà kan. Ìkíní: lílù náà gbọ́dọ̀ jẹ́ lẹ́yìn tí wáàsí àti títakété sí ibùsùn rẹ̀ kò bá so èso rere lára ìyàwó. Ìkejì: lílù náà kò gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lásìkò ìbínú. Ìkẹta: ohun tí ọkọ yóò fi lu ìyàwó rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ nípọn ju etí aṣọ lọ. Ìkẹrin: kò gbọ́dọ̀ tayọ òǹkà mẹ́wàá. Ìkarùn-ún: kò gbọ́dọ̀ fi àpá sí ìyàwó rẹ̀ lára. Ìkẹfà: kò gbọ́dọ̀ lu ìyàwó rẹ̀ ní àyè ọ̀wọ̀ tàbí àyè ẹlẹgẹ́ bí ojú, orí àti ikùn. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Sọ̄d; 38:44.
Bákan náà, tí lílù bá ń wáyé lemọ́lemọ́, ìfisùn fún àtúnṣe tàbí ìkọ̀sílẹ̀ lọpọ́n súnkàn ní ìbámu sí āyah 35.
Les exégèses en arabe:
وَإِنۡ خِفۡتُمۡ شِقَاقَ بَيۡنِهِمَا فَٱبۡعَثُواْ حَكَمٗا مِّنۡ أَهۡلِهِۦ وَحَكَمٗا مِّنۡ أَهۡلِهَآ إِن يُرِيدَآ إِصۡلَٰحٗا يُوَفِّقِ ٱللَّهُ بَيۡنَهُمَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا خَبِيرٗا
Tí ẹ bà sì mọ̀ pé ìyapa wà láààrin àwọn méjèèjì, ẹ gbé olóye kan dìde láti inú ẹbí ọkọ àti olóye kan láti inú ẹbí ìyàwó. Tí àwọn (tọkọ tìyàwó) méjèèjì bá ń fẹ́ àtúnṣe, Allāhu yóò fi àwọn (olóye méjèèjì) ṣe kòǹgẹ́ àtúnṣe lórí ọ̀rọ̀ ààrin wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alámọ̀tán.
Les exégèses en arabe:
۞ وَٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُشۡرِكُواْ بِهِۦ شَيۡـٔٗاۖ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنٗا وَبِذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱلۡجَارِ ذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡجَارِ ٱلۡجُنُبِ وَٱلصَّاحِبِ بِٱلۡجَنۢبِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ مَن كَانَ مُخۡتَالٗا فَخُورًا
Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I. Ẹ ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì àti ẹbí àti àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù àti aládùúgbò tó súnmọ́ àti aládùúgbò tó jìnnà àti ọ̀rẹ́ alábàárìn àti onírìn-àjò (tí agara dá) àti àwọn ẹrú yín. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ onígbèéraga onífáàrí.
Les exégèses en arabe:
ٱلَّذِينَ يَبۡخَلُونَ وَيَأۡمُرُونَ ٱلنَّاسَ بِٱلۡبُخۡلِ وَيَكۡتُمُونَ مَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦۗ وَأَعۡتَدۡنَا لِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٗا مُّهِينٗا
Àwọn tó ń ṣahun, (àwọn) tó ń pa ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe àti (àwọn) tó ń fi ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ pamọ́; A ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Les exégèses en arabe:
وَٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُمۡ رِئَآءَ ٱلنَّاسِ وَلَا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَلَا بِٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۗ وَمَن يَكُنِ ٱلشَّيۡطَٰنُ لَهُۥ قَرِينٗا فَسَآءَ قَرِينٗا
Àwọn tó ń ná dúkìá wọn pẹ̀lú ṣekárími, tí wọn kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ẹnikẹ́ni tí Èṣù bá jẹ́ ọ̀rẹ́ fún, ó burú ní ọ̀rẹ́.
Les exégèses en arabe:
وَمَاذَا عَلَيۡهِمۡ لَوۡ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَأَنفَقُواْ مِمَّا رَزَقَهُمُ ٱللَّهُۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِهِمۡ عَلِيمًا
Kí ni ìpalára tí ó máa ṣe fún wọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí wọ́n sì ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún wọn? Allāhu sì jẹ́ Onímọ̀ nípa wọ́n.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَظۡلِمُ مِثۡقَالَ ذَرَّةٖۖ وَإِن تَكُ حَسَنَةٗ يُضَٰعِفۡهَا وَيُؤۡتِ مِن لَّدُنۡهُ أَجۡرًا عَظِيمٗا
Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí òdíwọ̀n ọmọ iná-igún. Tí ó bá jẹ iṣẹ́ rere, Ó máa ṣàdìpèlé (ẹ̀san) rẹ̀. Ó sì máa fún (olùṣe rere) ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Les exégèses en arabe:
فَكَيۡفَ إِذَا جِئۡنَا مِن كُلِّ أُمَّةِۭ بِشَهِيدٖ وَجِئۡنَا بِكَ عَلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِ شَهِيدٗا
Báwo ni ọ̀rọ̀ wọn yóò ti rí nígbà tí A bá mú ẹlẹ́rìí jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, tí A sì mú ìwọ jáde ní ẹlẹ́rìí lórí àwọn wọ̀nyí?
Les exégèses en arabe:
يَوۡمَئِذٖ يَوَدُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَعَصَوُاْ ٱلرَّسُولَ لَوۡ تُسَوَّىٰ بِهِمُ ٱلۡأَرۡضُ وَلَا يَكۡتُمُونَ ٱللَّهَ حَدِيثٗا
Ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì yapa Òjíṣẹ́ náà, wọ́n á fẹ́ kí àwọn bá ilẹ̀ dọ́gba (kí wọ́n di erùpẹ̀). Wọn kò sì lè fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́ fún Allāhu.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقۡرَبُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنتُمۡ سُكَٰرَىٰ حَتَّىٰ تَعۡلَمُواْ مَا تَقُولُونَ وَلَا جُنُبًا إِلَّا عَابِرِي سَبِيلٍ حَتَّىٰ تَغۡتَسِلُواْۚ وَإِن كُنتُم مَّرۡضَىٰٓ أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوۡ جَآءَ أَحَدٞ مِّنكُم مِّنَ ٱلۡغَآئِطِ أَوۡ لَٰمَسۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَلَمۡ تَجِدُواْ مَآءٗ فَتَيَمَّمُواْ صَعِيدٗا طَيِّبٗا فَٱمۡسَحُواْ بِوُجُوهِكُمۡ وَأَيۡدِيكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَفُوًّا غَفُورًا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe súnmọ́ ìrun kíkí nígbà tí ọtí bá ń pa yín títí ẹ máa fi mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ¹ àti àwọn oníjánnábà, àfi àwọn olùkọjá nínú mọ́sálásí, títí ẹ máa fi wẹ̀ (ìwẹ̀ jánnábà). Tí ẹ bá sì jẹ́ aláìsàn tàbí ẹ wà lórí ìrìn-àjò tàbí ẹnì kan nínú yín dé láti ibi ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ẹ súnmọ́ obínrin (yín), tí ẹ kò rí omi, ẹ fi erùpẹ̀ tó dára ṣe táyàmọ́mù; ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòójúkúrò, Aláforíjìn.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:219.
Les exégèses en arabe:
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ أُوتُواْ نَصِيبٗا مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ يَشۡتَرُونَ ٱلضَّلَٰلَةَ وَيُرِيدُونَ أَن تَضِلُّواْ ٱلسَّبِيلَ
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń ra ìṣìnà, tí wọ́n sì fẹ́ kí ẹ ṣìnà lójú-ọ̀nà?
Les exégèses en arabe:
وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِأَعۡدَآئِكُمۡۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَلِيّٗا وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ نَصِيرٗا
Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn ọ̀tá yín. Allāhu tó ní Aláàbò. Allāhu sì tó ní Alárànṣe.
Les exégèses en arabe:
مِّنَ ٱلَّذِينَ هَادُواْ يُحَرِّفُونَ ٱلۡكَلِمَ عَن مَّوَاضِعِهِۦ وَيَقُولُونَ سَمِعۡنَا وَعَصَيۡنَا وَٱسۡمَعۡ غَيۡرَ مُسۡمَعٖ وَرَٰعِنَا لَيَّۢا بِأَلۡسِنَتِهِمۡ وَطَعۡنٗا فِي ٱلدِّينِۚ وَلَوۡ أَنَّهُمۡ قَالُواْ سَمِعۡنَا وَأَطَعۡنَا وَٱسۡمَعۡ وَٱنظُرۡنَا لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۡ وَأَقۡوَمَ وَلَٰكِن لَّعَنَهُمُ ٱللَّهُ بِكُفۡرِهِمۡ فَلَا يُؤۡمِنُونَ إِلَّا قَلِيلٗا
Ó ń bẹ nínú àwọn yẹhudi, àwọn tó ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “A gbọ́, a sì yapa. Gbọ́ tiwa, àwa kò níí gbọ́ tìrẹ, òmùgọ̀ wa.”¹ Wọ́n ń fi ahọ́n wọn yí ọ̀rọ̀ sódì àti pé wọ́n ń bu ẹnu-àtẹ́ lu ẹ̀sìn. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e. Gbọ́, kí o sì kíyè sí wa”, ìbá dára fún wọn, ìbá sì tọ̀nà jùlọ. Ṣùgbọ́n Allāhu fi wọ́n gégùn-ún nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn).
1. Ẹ wọ ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah 2:104.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ ءَامِنُواْ بِمَا نَزَّلۡنَا مُصَدِّقٗا لِّمَا مَعَكُم مِّن قَبۡلِ أَن نَّطۡمِسَ وُجُوهٗا فَنَرُدَّهَا عَلَىٰٓ أَدۡبَارِهَآ أَوۡ نَلۡعَنَهُمۡ كَمَا لَعَنَّآ أَصۡحَٰبَ ٱلسَّبۡتِۚ وَكَانَ أَمۡرُ ٱللَّهِ مَفۡعُولًا
Ẹ̀yin tí A fún ní tírà, ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín, ṣíwájú kí Á tó fọ́ àwọn ojú kan, A sì máa dá a padà sí (ìpàkọ́) lẹ́yìn wọn, tàbí kí Á ṣẹ́bi lé wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ́bi lé ìjọ Sabt. Àti pé àṣẹ Allāhu máa ṣẹ.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَغۡفِرُ أَن يُشۡرَكَ بِهِۦ وَيَغۡفِرُ مَا دُونَ ذَٰلِكَ لِمَن يَشَآءُۚ وَمَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَقَدِ ٱفۡتَرَىٰٓ إِثۡمًا عَظِيمًا
Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I.1 Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́.¹ Ẹni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti dá àdápa irọ́ (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
Ìyẹn ni ìdájọ́ ẹni tí ó kú sórí “aṣ-ṣirk” ẹbọ. Àmọ́ ẹni tí ó bá túúbá kúrò níbi ẹbọ ṣíṣe ṣíwájú ìpọ́kàkà ikú, tí ó sì ṣe ’Islām rẹ̀ dáradára, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - yóò ṣe àforíjìn fún un.
“Aṣ-ṣirk” ẹbọ ṣíṣe pín sí oríṣi méjì. Ìkíní: “aṣ-ṣirk al-’akbar” ẹbọ ńlá. Ẹbọ ńlá ni jíjọ́sìn fún ẹ̀dá kan tàbí pípe ẹ̀dá kan nínú àdúà lẹ́yìn Allāhu. Nítorí náà, ẹlẹ́bọ ńlá ni ẹni tí ó ń jọ́sìn fún ẹ̀dá. Ẹlẹ́bọ ńlá sì ni ẹni tí ó ń pe ẹ̀dá kan nínú àdúà rẹ̀ lẹ́yìn Allāhu. Bí àpẹ̀ẹrẹ, ẹbọ ńlá ni sísọ pé, “ní orúkọ Jésù”. Ìdájọ́ tó wà fún ẹni tí ó sọ bẹ́ẹ̀ ló wà fún ẹni tí ó ṣe “ààmín” sí irúfẹ́ àdúà ẹbọ náà. Ẹbọ ńlá ni ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà àti ẹ̀sìn nasrọ̄niyyah dúró lé (báyìí) nítorí pé, ẹni tí kì í ṣe Allāhu ni gbogbo wọn ń jọ́sìn fún, tí wọ́n tún ń képè nínú àdúà wọn. Irú ẹbọ ńlá yìí náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ nínú sūfī Tijāniyyah àti Ƙọ̄diriyyah àti ìjọ Ṣī‘ah. Àwọn ṣeeu ìjọ kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ń sọ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu.
Ìkejì: “aṣ-ṣirk al-’asgar” ẹbọ kékeré. Ẹbọ kékeré ni ṣekárími àti ohunkóhun tí ẹ̀dá bá fi ń sọ ẹ̀dá kan di akẹgbẹ́ Allāhu níbi àwọn iṣẹ́ àti ìròyìn Allāhu. Àpẹ̀ẹrẹ ẹbọ kékeré pọ̀ gan-an nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe ọmọnìyàn. Bí àpẹ̀ẹrẹ, fífi n̄ǹkan búra lẹ́yìn Allāhu bíi sí sọ pé, “Mo fi al-Ƙur’ān búra.” dípò sí sọ pé, “Mo fi Allāhu búra.” Tàbí “Mo fi Allāhu Ẹni tí Ó sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ búra.” Àpẹ̀ẹrẹ ẹbọ kékeré ni gbólóhùn “Bí Allāhu bá fẹ́, bí ìwọ náà bá fẹ́.” Dípò, “bí Allāhu bá fẹ́”. Àpẹ̀ẹrẹ mìíràn, “ọpẹ́lọpẹ́ lágbájá” dípò “Ọpẹ́lọpẹ́ Allāhu”. Àpẹ̀ẹrẹ mìíràn ni gbólóhùn “Ajé á tà á” tàbí “Ajé á wá.” Dípò “Allāhu á tà á.” Ìyàtọ̀ tó wà láààrin ẹbọ ńlá àti ẹbọ kékeré ni ìwọ̀nyí:
(1) Ẹbọ ńlá máa ba odidi ẹ̀sìn jẹ́ mọ́ mùsùlùmí lọ́wọ́, àmọ́ abala ibi tí ẹbọ kékeré bá ti ṣẹlẹ̀ nìkan ni ìbàjẹ́ máa kàn.
(2) Ẹbọ ńlá kò ní àforíjìn tí ènìyàn kò bá ronú pìwàdà títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, àmọ́ ẹlẹ́bọ kékeré lè rí àforíjìn bí kò bá ronú pìwàdà, ó sì lè jẹ̀yà rẹ̀ nínú Iná ní ọ̀run bí kò bá ronú pìwàdà lórí rẹ̀ ṣíwájú ikú rẹ̀.
(3) Iná gbére ni ẹ̀san ẹbọ ńlá fún ẹni tí ó bá kú sórí rẹ̀, àmọ́ ẹlẹ́bọ kékeré máa padà jáde kúrò nínú Iná bí ó bá jẹ́ pé, ó ti ipasẹ̀ ẹbọ kékeré wọnú Iná. Ẹ jẹ́ kí á ronú pìwàdà lórí gbogbo ẹbọ pátápátá.
Les exégèses en arabe:
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ يُزَكُّونَ أَنفُسَهُمۚ بَلِ ٱللَّهُ يُزَكِّي مَن يَشَآءُ وَلَا يُظۡلَمُونَ فَتِيلًا
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tó ń ṣàfọ̀mọ́ ara wọn ni? Kò sì rí bẹ́ẹ̀, Allāhu l’Ó ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Wọn kò sì níí fi (ohun tó tó) ìbójú kóró èso dàbínù ṣàbòsí sí wọn.¹
1. Ìyẹn ni pé, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní ẹ̀san ọ̀run, kò níí dín rárá.
Les exégèses en arabe:
ٱنظُرۡ كَيۡفَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَۖ وَكَفَىٰ بِهِۦٓ إِثۡمٗا مُّبِينًا
Wo bí wọ́n ṣe ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Ó sì tó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé.
Les exégèses en arabe:
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ أُوتُواْ نَصِيبٗا مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡجِبۡتِ وَٱلطَّٰغُوتِ وَيَقُولُونَ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ هَٰٓؤُلَآءِ أَهۡدَىٰ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ سَبِيلًا
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń gbàgbọ́ nínú idán àti òrìṣà, wọ́n sì ń wí fún àwọn aláìgbàgbọ́ pé: “Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) wọ̀nyí mọ̀nà ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
Les exégèses en arabe:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَعَنَهُمُ ٱللَّهُۖ وَمَن يَلۡعَنِ ٱللَّهُ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ نَصِيرًا
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣẹ́bi lé. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá sì ṣẹ́bi lé, o ò níí rí alárànṣe kan fún un.
Les exégèses en arabe:
أَمۡ لَهُمۡ نَصِيبٞ مِّنَ ٱلۡمُلۡكِ فَإِذٗا لَّا يُؤۡتُونَ ٱلنَّاسَ نَقِيرًا
Tàbí ìpín kan ń bẹ fún wọn nínú ìjọba (Wa) ni? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀ wọn kò níí fún àwọn ẹ̀nìyàn ní àmì ẹ̀yìn kóró èso dàbínú.
Les exégèses en arabe:
أَمۡ يَحۡسُدُونَ ٱلنَّاسَ عَلَىٰ مَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦۖ فَقَدۡ ءَاتَيۡنَآ ءَالَ إِبۡرَٰهِيمَ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَءَاتَيۡنَٰهُم مُّلۡكًا عَظِيمٗا
Tàbí wọ́n ń ṣe ìlara àwọn ènìyàn lórí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ ni? Dájúdájú A fún àwọn ẹbí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (sunnah). A sì fún wọn ní ìjọba ńlá.
Les exégèses en arabe:
فَمِنۡهُم مَّنۡ ءَامَنَ بِهِۦ وَمِنۡهُم مَّن صَدَّ عَنۡهُۚ وَكَفَىٰ بِجَهَنَّمَ سَعِيرًا
Nítorí náà, ó ń bẹ nínú wọn ẹni tó gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tó ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀. Jahanamọ sì tó ní iná tó ń jo.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِنَا سَوۡفَ نُصۡلِيهِمۡ نَارٗا كُلَّمَا نَضِجَتۡ جُلُودُهُم بَدَّلۡنَٰهُمۡ جُلُودًا غَيۡرَهَا لِيَذُوقُواْ ٱلۡعَذَابَۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَزِيزًا حَكِيمٗا
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, láìpẹ́ A máa mú wọn wọ inú Iná. Ìgbàkígbà tí awọ ara wọn bá jóná, A óò máa pààrọ̀ awọ ara mìíràn fún wọn kí wọ́n lè máa tọ́ ìyà wò lọ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Les exégèses en arabe:
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ سَنُدۡخِلُهُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۖ لَّهُمۡ فِيهَآ أَزۡوَٰجٞ مُّطَهَّرَةٞۖ وَنُدۡخِلُهُمۡ ظِلّٗا ظَلِيلًا
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, A óò mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Àwọn ìyàwó mímọ́ ń bẹ fún wọn nínú rẹ̀. A sì máa fi wọ́n sí abẹ́ ibòji tó máa ṣíji bò wọ́n dáradára.
Les exégèses en arabe:
۞ إِنَّ ٱللَّهَ يَأۡمُرُكُمۡ أَن تُؤَدُّواْ ٱلۡأَمَٰنَٰتِ إِلَىٰٓ أَهۡلِهَا وَإِذَا حَكَمۡتُم بَيۡنَ ٱلنَّاسِ أَن تَحۡكُمُواْ بِٱلۡعَدۡلِۚ إِنَّ ٱللَّهَ نِعِمَّا يَعِظُكُم بِهِۦٓۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ سَمِيعَۢا بَصِيرٗا
Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ dá àgbàfipamọ́ padà fún àwọn olówó wọn. Àti pé nígbà tí ẹ bá ń dájọ́ láààrin àwọn ènìyàn, ẹ dájọ́ pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu ń fi n̄ǹkan tó dára ṣe wáàsí fún yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُواْ ٱلرَّسُولَ وَأُوْلِي ٱلۡأَمۡرِ مِنكُمۡۖ فَإِن تَنَٰزَعۡتُمۡ فِي شَيۡءٖ فَرُدُّوهُ إِلَى ٱللَّهِ وَٱلرَّسُولِ إِن كُنتُمۡ تُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٞ وَأَحۡسَنُ تَأۡوِيلًا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà àti àwọn aláṣẹ nínú yín. Nítorí náà, tí ẹ bá yapa-ẹnu lórí kiní kan, ẹ ṣẹ́rí rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -,¹ tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ fún ìkángun ọ̀rọ̀ (ìyọrísí).
1. Kíyè sí i, ṣíṣẹ́rí ìyapa-ẹnu padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - àti ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò túmọ̀ sí gbígbé ìyapa-ẹnu lọ pàdé Allāhu l’ọ́jọ́ Àjíǹde tàbí gbígbé ìyapa-ẹnu lọ síbi sàréè Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bí kò ṣe pé fífi al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ yanjú àwọn ìyapa-ẹnu pátápátá. Gbólóhùn yìí jọ sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:10.
Les exégèses en arabe:
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ يَزۡعُمُونَ أَنَّهُمۡ ءَامَنُواْ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ وَمَآ أُنزِلَ مِن قَبۡلِكَ يُرِيدُونَ أَن يَتَحَاكَمُوٓاْ إِلَى ٱلطَّٰغُوتِ وَقَدۡ أُمِرُوٓاْ أَن يَكۡفُرُواْ بِهِۦۖ وَيُرِيدُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَن يُضِلَّهُمۡ ضَلَٰلَۢا بَعِيدٗا
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ (tí kò sì rí bẹ́ẹ̀) pé dájúdájú àwọn gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, tí wọ́n sì ń gbèrò láti gbé ẹjọ́ lọ bá òrìṣà, A sì ti pa wọ́n láṣẹ pé kí wọ́n lòdì sí i. Èṣù sì fẹ́ ṣì wọ́n lọ́nà ní ìṣìnà tó jìnnà.
Les exégèses en arabe:
وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ تَعَالَوۡاْ إِلَىٰ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ وَإِلَى ٱلرَّسُولِ رَأَيۡتَ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ يَصُدُّونَ عَنكَ صُدُودٗا
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, ẹ wá bá Òjíṣẹ́.”, o máa rí àwọn mùnááfìkí tí wọn yóò máa ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ rẹ tààrà.
Les exégèses en arabe:
فَكَيۡفَ إِذَآ أَصَٰبَتۡهُم مُّصِيبَةُۢ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡ ثُمَّ جَآءُوكَ يَحۡلِفُونَ بِٱللَّهِ إِنۡ أَرَدۡنَآ إِلَّآ إِحۡسَٰنٗا وَتَوۡفِيقًا
Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọ́n tì síwájú, lẹ́yìn náà wọ́n máa wá bá ọ, wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé kò sí ohun tí a gbàlérò bí kò ṣe dáadáa àti ìrẹ́pọ̀.
Les exégèses en arabe:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ يَعۡلَمُ ٱللَّهُ مَا فِي قُلُوبِهِمۡ فَأَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ وَعِظۡهُمۡ وَقُل لَّهُمۡ فِيٓ أَنفُسِهِمۡ قَوۡلَۢا بَلِيغٗا
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ṣe wáàsí fún wọn, kí o sì bá wọn sọ ọ̀rọ̀ tó máa mì wọ́n lọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ ara wọn.
Les exégèses en arabe:
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن رَّسُولٍ إِلَّا لِيُطَاعَ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَلَوۡ أَنَّهُمۡ إِذ ظَّلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ جَآءُوكَ فَٱسۡتَغۡفَرُواْ ٱللَّهَ وَٱسۡتَغۡفَرَ لَهُمُ ٱلرَّسُولُ لَوَجَدُواْ ٱللَّهَ تَوَّابٗا رَّحِيمٗا
A kò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi nítorí kí wọ́n lè tẹ̀lé e pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n wá bá ọ,¹ wọ́n sì tọrọ àforíjìn Allāhu, tí Òjíṣẹ́ sì tún bá wọn tọrọ àforíjìn, wọn ìbá kúkú rí Allāhu ní Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
1. Ìyẹn nígbà tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -wà nílé ayé ṣíwájú kí ó tó kú. Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò sí àǹfààní fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti lọ bá a nídìí sàréè rẹ̀. Tí ènìyàn kan bá dán an wò pẹ́rẹ́, ó máa kó sínú ẹbọ ńlá. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-’Imrọ̄n; 3:101.
Les exégèses en arabe:
فَلَا وَرَبِّكَ لَا يُؤۡمِنُونَ حَتَّىٰ يُحَكِّمُوكَ فِيمَا شَجَرَ بَيۡنَهُمۡ ثُمَّ لَا يَجِدُواْ فِيٓ أَنفُسِهِمۡ حَرَجٗا مِّمَّا قَضَيۡتَ وَيُسَلِّمُواْ تَسۡلِيمٗا
Rárá, Èmi fi Olúwa rẹ búra pé wọn kò tí ì gbàgbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi gbà ọ́ ní olùdájọ́ lórí ohun tí ó bá dá yánpọnyánrin sílẹ̀ láààrin wọn. Lẹ́yìn náà, wọn kò níí ní ẹ̀hónú kan sí ìdájọ́ tí o bá dá. Wọ́n sì máa gbà pátápátá.
Les exégèses en arabe:
وَلَوۡ أَنَّا كَتَبۡنَا عَلَيۡهِمۡ أَنِ ٱقۡتُلُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ أَوِ ٱخۡرُجُواْ مِن دِيَٰرِكُم مَّا فَعَلُوهُ إِلَّا قَلِيلٞ مِّنۡهُمۡۖ وَلَوۡ أَنَّهُمۡ فَعَلُواْ مَا يُوعَظُونَ بِهِۦ لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۡ وَأَشَدَّ تَثۡبِيتٗا
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní ọ̀ran- anyàn fún wọn pé: "Ẹ pa ara yín tàbí ẹ jáde kúrò nínú ìlú yín," wọn kò níí ṣe é àfi díẹ̀ nínú wọn. Tí ó bá tún jẹ́ pé wọ́n ṣe ohun tí A fi ń ṣe wáàsí fún wọn ni, ìbá jẹ́ oore àti ìdúróṣinṣin tó lágbára jùlọ fún wọn.
Les exégèses en arabe:
وَإِذٗا لَّأٓتَيۡنَٰهُم مِّن لَّدُنَّآ أَجۡرًا عَظِيمٗا
Nígbà náà, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Wa.
Les exégèses en arabe:
وَلَهَدَيۡنَٰهُمۡ صِرَٰطٗا مُّسۡتَقِيمٗا
Àti pé dájúdájú Àwa ìbá tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà.
Les exégèses en arabe:
وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَ فَأُوْلَٰٓئِكَ مَعَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ وَٱلصِّدِّيقِينَ وَٱلشُّهَدَآءِ وَٱلصَّٰلِحِينَۚ وَحَسُنَ أُوْلَٰٓئِكَ رَفِيقٗا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, àwọn olódodo, àwọn tó kú ikú ṣẹhīdi¹ àti àwọn ẹni rere. Àwọn wọ̀nyẹn sì dára ní alábàárìn.
1. Àpẹ̀ẹrẹ ikú ṣẹhīdi ni ikú ojú ogun ẹ̀sìn, ikú ìjàǹbá àjálù, ikú odò, ikú àìsàn inú àti ikú olóyún tàbí ẹni tí ó kú sínú ẹ̀jẹ̀ ìbímọ.
Les exégèses en arabe:
ذَٰلِكَ ٱلۡفَضۡلُ مِنَ ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ عَلِيمٗا
Oore àjùlọ yẹn máa wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu; Allāhu sì tó ní Onímọ̀.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ خُذُواْ حِذۡرَكُمۡ فَٱنفِرُواْ ثُبَاتٍ أَوِ ٱنفِرُواْ جَمِيعٗا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú ohun ìṣọ́ra yín lọ́wọ́, kí ẹ sì tú jáde s’ójú ogun ẹ̀sìn níkọ̀níkọ̀ tàbí kí ẹ tú jáde ní àpapọ̀.¹
1. Àkànlò èdè ni mímú ìṣọ́ra lọ́wọ́. N̄ǹkan ìjagun bí ọfà àti idà ló ṣe é mú lọ́wọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àtẹ ìgbọfà wà nínú ìṣọ́ra tí ó ṣe é mú lọ́wọ́, wíwà tífura-tìfura lójú ogun ẹ̀sìn ní wíwà-ojú-lalákàn-fi-í- ṣọ́rí ni àgbọ́yé āyah náà. Má ṣe gba ìtànjẹ nípa títúmọ̀ ìṣọ́ra sí lílo òògùn bíi àgbéró, òkígbẹ́, ìṣíjú, ayẹta, àfẹ́ẹ̀rí, asákì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èèwọ̀ ni gbogbo ìwọ̀nyẹn nítorí pé, wọn kò là níbi idán pípa àti bíbẹ àwọn ẹ̀mí àìrí èṣù àlùjànnú kan níṣẹ́. Nítorí náà, ẹnì kan kò níí fi òògùn abẹnugọ̀ǹgọ̀ ja’gun ẹ̀sìn àfi kí ó jẹ́ ẹlẹ́bọ.
Les exégèses en arabe:
وَإِنَّ مِنكُمۡ لَمَن لَّيُبَطِّئَنَّ فَإِنۡ أَصَٰبَتۡكُم مُّصِيبَةٞ قَالَ قَدۡ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيَّ إِذۡ لَمۡ أَكُن مَّعَهُمۡ شَهِيدٗا
Dájúdájú ó ń bẹ nínú yín ẹni tó ń fà sẹ́yìn. Tí àdánwó kan bá kàn yín, ó máa wí pé: “Allāhu kúkú ti ṣe ìdẹ̀ra fún mi nítorí pé èmi kò sí níbẹ̀ pẹ̀lú wọn (wọn kò sì rí mi pa pẹ̀lú àwọn tó kú ikú ṣẹhīdi).”
Les exégèses en arabe:
وَلَئِنۡ أَصَٰبَكُمۡ فَضۡلٞ مِّنَ ٱللَّهِ لَيَقُولَنَّ كَأَن لَّمۡ تَكُنۢ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُۥ مَوَدَّةٞ يَٰلَيۡتَنِي كُنتُ مَعَهُمۡ فَأَفُوزَ فَوۡزًا عَظِيمٗا
Dájúdájú tí oore àjùlọ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu bá sì tẹ̀ yín lọ́wọ́, dájúdájú ó máa sọ̀rọ̀ - bí ẹni pé kò sí ìfẹ́ láààrin ẹ̀yin àti òun (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) - pé: “Yéè! Èmi ìbá wà pẹ̀lú wọn, èmi ìbá jẹ èrè ńlá.”
Les exégèses en arabe:
۞ فَلۡيُقَٰتِلۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ٱلَّذِينَ يَشۡرُونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا بِٱلۡأٓخِرَةِۚ وَمَن يُقَٰتِلۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَيُقۡتَلۡ أَوۡ يَغۡلِبۡ فَسَوۡفَ نُؤۡتِيهِ أَجۡرًا عَظِيمٗا
Nítorí náà, kí àwọn tó ń fi ayé ra ọ̀run máa jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu, yálà wọ́n pa á tàbí ó ṣẹ́gun, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san ńlá.
Les exégèses en arabe:
وَمَا لَكُمۡ لَا تُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلۡمُسۡتَضۡعَفِينَ مِنَ ٱلرِّجَالِ وَٱلنِّسَآءِ وَٱلۡوِلۡدَٰنِ ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَآ أَخۡرِجۡنَا مِنۡ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلظَّالِمِ أَهۡلُهَا وَٱجۡعَل لَّنَا مِن لَّدُنكَ وَلِيّٗا وَٱجۡعَل لَّنَا مِن لَّدُنكَ نَصِيرًا
Kí l’ó ṣe yín tí ẹ kò níí jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn Rẹ̀) àti (fún ààbò) àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú ìlú yìí, ìlú àwọn alábòsí. Fún wa ní aláàbò kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ́. Kí Ó sì fún wa ní alárànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ.”
Les exégèses en arabe:
ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱلطَّٰغُوتِ فَقَٰتِلُوٓاْ أَوۡلِيَآءَ ٱلشَّيۡطَٰنِۖ إِنَّ كَيۡدَ ٱلشَّيۡطَٰنِ كَانَ ضَعِيفًا
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń jagun sí ojú-ọ̀nà òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ja àwọn ọ̀rẹ́ Èṣù lógun. Dájúdájú ète Èṣù, ó jẹ́ ohun tí ó lẹ.
Les exégèses en arabe:
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ قِيلَ لَهُمۡ كُفُّوٓاْ أَيۡدِيَكُمۡ وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقِتَالُ إِذَا فَرِيقٞ مِّنۡهُمۡ يَخۡشَوۡنَ ٱلنَّاسَ كَخَشۡيَةِ ٱللَّهِ أَوۡ أَشَدَّ خَشۡيَةٗۚ وَقَالُواْ رَبَّنَا لِمَ كَتَبۡتَ عَلَيۡنَا ٱلۡقِتَالَ لَوۡلَآ أَخَّرۡتَنَآ إِلَىٰٓ أَجَلٖ قَرِيبٖۗ قُلۡ مَتَٰعُ ٱلدُّنۡيَا قَلِيلٞ وَٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لِّمَنِ ٱتَّقَىٰ وَلَا تُظۡلَمُونَ فَتِيلًا
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A sọ fún pé: “Ẹ káwọ́ ró (ẹ má ì jagun ẹ̀sìn, àmọ́) ẹ máa kírun, kí ẹ sì máa yọ Zakāh.” Ṣùgbọ́n nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí, ìgbà náà ni apá kan nínú wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn bí ẹni tí ń bẹ̀rù Allāhu tàbí tí ìbẹ̀rù rẹ̀ le koko jùlọ. Wọ́n sì wí pé: “Olúwa wa, nítorí kí ni O fi ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wa lórí? Kúkú lọ́ wa lára di ìgbà díẹ̀ sí i.¹” Sọ pé: “Bín-íntín ní ìgbádùn ayé, ọ̀run lóore jùlọ fún ẹni tó bá bẹ̀rù Allāhu. Wọn kò sì níí fi (ohun tó tó) ìbójú kóró èso dàbínù ṣàbòsí sí yín.”²
1. Ìyẹn ni pé, Ìwọ ìbá má ì sọ ogun ẹ̀sìn di ọ̀ran-anyàn fún wa, bóyá ẹ̀mí wa ìbá gùn sí i, àwa ìbá sí jáyé pẹ́.
2. Ìyẹn ni pé, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní ẹ̀san ọ̀run, kò níí dín rárá.
Les exégèses en arabe:
أَيۡنَمَا تَكُونُواْ يُدۡرِككُّمُ ٱلۡمَوۡتُ وَلَوۡ كُنتُمۡ فِي بُرُوجٖ مُّشَيَّدَةٖۗ وَإِن تُصِبۡهُمۡ حَسَنَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِكَۚ قُلۡ كُلّٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ فَمَالِ هَٰٓؤُلَآءِ ٱلۡقَوۡمِ لَا يَكَادُونَ يَفۡقَهُونَ حَدِيثٗا
Ibikíbi tí ẹ bá wà, ikú yóò pàdé yín, ẹ̀yin ìbáà wà nínú odi ilé orí òkè ilé gíga fíofío. Tí oore (ìkógun) kan bá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Tí aburú (ìfọ́gun) kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Sọ pé: “Gbogbo rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kí ló ń ṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí ná, tí wọn kò fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan.
Les exégèses en arabe:
مَّآ أَصَابَكَ مِنۡ حَسَنَةٖ فَمِنَ ٱللَّهِۖ وَمَآ أَصَابَكَ مِن سَيِّئَةٖ فَمِن نَّفۡسِكَۚ وَأَرۡسَلۡنَٰكَ لِلنَّاسِ رَسُولٗاۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدٗا
Ohunkóhun tó bá tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ nínú oore, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Ohunkóhun tí ó bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ nínú aburú, láti ọ̀dọ̀ ara rẹ ni. A rán ọ níṣẹ́ pé kí o jẹ́ Òjíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.¹
1. Èbùbù, àyànmọ́ àti kádàrá ń túmọ̀ ara wọn. Ohun rere tí ó máa tẹ ẹ̀dá lọ́wọ́ àti aburú tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá láyé àti lọ́run pẹ̀lú ọ̀nà tí ó máa gbà ṣẹlẹ̀ ni kìkìdá kádàrá ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - l’Ó pébùbù fún ẹnì kọ̀ọ̀kan. Òun l’Ó yan àyànmọ́ fún wa. Láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni orísun gbogbo rẹ̀ ti ṣẹ̀ wá pẹ̀lú déédé Rẹ̀ àti ọlá Rẹ̀ lórí wa nítorí pé, kì í ṣe Ọba alábòsí. Kò sì ṣe é pè lẹ́jọ́. Èyí ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ń tọ́ka sí nínú āyah 78. Àmọ́ nígbà tí ẹ̀dá tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fún ní ẹ̀ṣà bá ṣẹ̀ṣà iṣẹ́ rere, ó máa dúpẹ́ fún Allāhu ni. Nígbà tí ẹ̀dá tí Allāhu fún ní ẹ̀ṣà bá sì ṣẹ̀ṣà iṣẹ́ aburú, òun fúnra rẹ̀ ló fọwọ́ ara rẹ̀ fa aburú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ dídá tó ṣà lẹ́ṣà. Èyí ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ń tọ́ka sí nínú āyah 79 àti nínú sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:30.
Bákan náà, Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lè ṣẹ̀ṣà láti nawọ́ aburú sí ènìyàn, ìyẹn sì ni ogun Èṣù. Èyí ni Allāhu ń tọ́ka sí nínú sūrah Sọ̄d; 38:41. Àmọ́ sá, kì í ṣe Èṣù ni a máa bẹ̀, kì í ṣe ìyọ́nú ayé tàbí ẹ̀bẹ̀ àwọn àgbà la máa ṣe bí kò ṣe wíwá ìyọ́nú Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - nípa ìṣẹ̀ṣà ìtẹ̀lé àṣẹ Rẹ̀, ìdojú àdúà kọ Ọ́ àti wíwá ààbò ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nìkan ṣoṣo. Ní ṣókí, gbogbo ohun tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ti wà nínú kádàrá rẹ̀, àmọ́ ó lè ṣẹlẹ̀ tààrà láti ọ̀dọ̀ Allāhu sí ọ̀dọ̀ ẹ̀dá, tàbí kí Allāhu gbé e gba ọ̀nà sábàbí bíi àfọwọ́fà tàbí àkóbá láti ọ̀dọ̀ ẹ̀dá mìíràn. W-Allāhu-l-musta‘ān.
Les exégèses en arabe:
مَّن يُطِعِ ٱلرَّسُولَ فَقَدۡ أَطَاعَ ٱللَّهَۖ وَمَن تَوَلَّىٰ فَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ عَلَيۡهِمۡ حَفِيظٗا
Ẹnikẹ́ni tó bá tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, ó ti tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu. Ẹnikẹ́ni tó bá sì pẹ̀yìndà, A kò rán ọ níṣẹ́ olùṣọ́ lórí wọn.
Les exégèses en arabe:
وَيَقُولُونَ طَاعَةٞ فَإِذَا بَرَزُواْ مِنۡ عِندِكَ بَيَّتَ طَآئِفَةٞ مِّنۡهُمۡ غَيۡرَ ٱلَّذِي تَقُولُۖ وَٱللَّهُ يَكۡتُبُ مَا يُبَيِّتُونَۖ فَأَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلًا
Wọ́n ń wí pé: “A tẹ̀lé àṣẹ rẹ.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ, igun kan nínú wọn máa pètepèrò ní òru n̄ǹkan mìíràn tí ó yàtọ̀ sí èyí tí ó ń sọ (ní ọ̀sán). Allāhu sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n ń pètepèrò rẹ̀ ní òru. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó ní Aláàbò.
Les exégèses en arabe:
أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ ٱلۡقُرۡءَانَۚ وَلَوۡ كَانَ مِنۡ عِندِ غَيۡرِ ٱللَّهِ لَوَجَدُواْ فِيهِ ٱخۡتِلَٰفٗا كَثِيرٗا
Ṣé wọn kò ronú nípa al-Ƙur’ān ni? Tí ó bá jẹ́ pé ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn yàtọ̀ sí Allāhu, wọn ìbá rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìtakora nínú rẹ̀.¹
1. Kò sí āyah kan tó tako āyah mìíràn nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Àmọ́ tí ẹnì kan bá rí āyah kan tí ó fẹ́ tako āyah mìíràn lójú tirẹ̀, kó lọ tẹ́tí gbọ́ àgbọ́yé rẹ̀ lọ́dọ̀ onímọ̀ ẹ̀sìn tó nímọ̀ nípa àwọn ìsọ̀rí àti àtúnpín ìsọ̀rí tí àwọn āyah pín sí nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé pẹ̀lú ohun tó rọ̀ mọ́ wọn.
Les exégèses en arabe:
وَإِذَا جَآءَهُمۡ أَمۡرٞ مِّنَ ٱلۡأَمۡنِ أَوِ ٱلۡخَوۡفِ أَذَاعُواْ بِهِۦۖ وَلَوۡ رَدُّوهُ إِلَى ٱلرَّسُولِ وَإِلَىٰٓ أُوْلِي ٱلۡأَمۡرِ مِنۡهُمۡ لَعَلِمَهُ ٱلَّذِينَ يَسۡتَنۢبِطُونَهُۥ مِنۡهُمۡۗ وَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَرَحۡمَتُهُۥ لَٱتَّبَعۡتُمُ ٱلشَّيۡطَٰنَ إِلَّا قَلِيلٗا
Nígbà tí ọ̀rọ̀ ìfàyàbalẹ̀ tàbí ìpáyà kan bá dé bá wọn, wọ́n sì máa tàn án kálẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́rí rẹ̀ sí (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ àti àwọn aláṣẹ (ìyẹn, àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn) nínú wọn, àwọn tó ń yọ òdodo jáde nínú ọ̀rọ̀ nínú wọn ìbá mọ̀ ọ́n. Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ lórí yín ni, ẹ̀yin ìbá tẹ̀lé Èṣù àfi ìba díẹ̀ (nínú yín).¹
1. Ẹ tún wo āyah 59. Àmọ́ āyah yìí ń kìlọ̀ fún wa níbi fífọ́n ìròyìn irọ́ ká.
Les exégèses en arabe:
فَقَٰتِلۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ لَا تُكَلَّفُ إِلَّا نَفۡسَكَۚ وَحَرِّضِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ عَسَى ٱللَّهُ أَن يَكُفَّ بَأۡسَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۚ وَٱللَّهُ أَشَدُّ بَأۡسٗا وَأَشَدُّ تَنكِيلٗا
Nítorí náà, jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Wọn kò là á bọ ẹnì kan lọ́rùn àfi ìwọ. Kí o sì gbẹ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóǹgbẹ ogun ẹ̀sìn. Ó ṣeé ṣe kí Allāhu ká ọwọ́ ìjà àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ró. Àti pé Allāhu le jùlọ ní ogun. Ó sì le jùlọ níbi ìjẹni-níyà.
Les exégèses en arabe:
مَّن يَشۡفَعۡ شَفَٰعَةً حَسَنَةٗ يَكُن لَّهُۥ نَصِيبٞ مِّنۡهَاۖ وَمَن يَشۡفَعۡ شَفَٰعَةٗ سَيِّئَةٗ يَكُن لَّهُۥ كِفۡلٞ مِّنۡهَاۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ مُّقِيتٗا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣìpẹ̀ ìṣìpẹ̀ rere, ó máa ní kan nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìpẹ̀ ìṣìpẹ̀ aburú, ó máa ní ìpín kan nínú rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan¹.
1. “Muƙīt” túmọ̀ sí alágbára, olùṣọ́, olùṣírò, arínú-róde àti alámòójútó.
Les exégèses en arabe:
وَإِذَا حُيِّيتُم بِتَحِيَّةٖ فَحَيُّواْ بِأَحۡسَنَ مِنۡهَآ أَوۡ رُدُّوهَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ حَسِيبًا
86. Nígbà tí wọ́n bá ki yín ní kíkí kan, ẹ kí wọn (padà) pẹ̀lú èyí tó dára jù ú lọ tàbí kí ẹ dá a padà (pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ki yín). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣírò lórí gbogbo n̄ǹkan.
Les exégèses en arabe:
ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۚ لَيَجۡمَعَنَّكُمۡ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ لَا رَيۡبَ فِيهِۗ وَمَنۡ أَصۡدَقُ مِنَ ٱللَّهِ حَدِيثٗا
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ta ló sọ̀dodo ọ̀rọ̀ ju Allāhu?
Les exégèses en arabe:
۞ فَمَا لَكُمۡ فِي ٱلۡمُنَٰفِقِينَ فِئَتَيۡنِ وَٱللَّهُ أَرۡكَسَهُم بِمَا كَسَبُوٓاْۚ أَتُرِيدُونَ أَن تَهۡدُواْ مَنۡ أَضَلَّ ٱللَّهُۖ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ سَبِيلٗا
Kí ni ó máa mu yín pín sí ìjọ méjì nípa àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí! Ṣebí Allāhu l’Ó dá wọn padà sẹ́yìn¹ nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ṣé ẹ fẹ́ fi ẹni tí Allāhu ṣì lọ́nà mọ̀nà ni? Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, o ò níí rí ọ̀nà kan fún un.
1. Allāhu dá wọn padà sẹ́yìn; wọ́n di kèfèrí lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tí di mùsùlùmí.
Les exégèses en arabe:
وَدُّواْ لَوۡ تَكۡفُرُونَ كَمَا كَفَرُواْ فَتَكُونُونَ سَوَآءٗۖ فَلَا تَتَّخِذُواْ مِنۡهُمۡ أَوۡلِيَآءَ حَتَّىٰ يُهَاجِرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۚ فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَخُذُوهُمۡ وَٱقۡتُلُوهُمۡ حَيۡثُ وَجَدتُّمُوهُمۡۖ وَلَا تَتَّخِذُواْ مِنۡهُمۡ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرًا
Wọ́n fẹ́ kí ẹ ṣàì gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́, kí ẹ lè jọ di ẹgbẹ́ kan náà. Nítorí náà, ẹ má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò nínú wọn títí wọ́n fi máa kúrò nínú ìlú ẹbọ wá sí ìlú ’Islām nítorí ẹ̀sìn Allāhu. Tí wọ́n bá kẹ̀yìn (sí ìgbàgbọ́ òdodo), ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ẹ bá ti bá wọn. Kí ẹ sì má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò àti olùrànlọ́wọ́ kan nínú wọn.
Les exégèses en arabe:
إِلَّا ٱلَّذِينَ يَصِلُونَ إِلَىٰ قَوۡمِۭ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٌ أَوۡ جَآءُوكُمۡ حَصِرَتۡ صُدُورُهُمۡ أَن يُقَٰتِلُوكُمۡ أَوۡ يُقَٰتِلُواْ قَوۡمَهُمۡۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَسَلَّطَهُمۡ عَلَيۡكُمۡ فَلَقَٰتَلُوكُمۡۚ فَإِنِ ٱعۡتَزَلُوكُمۡ فَلَمۡ يُقَٰتِلُوكُمۡ وَأَلۡقَوۡاْ إِلَيۡكُمُ ٱلسَّلَمَ فَمَا جَعَلَ ٱللَّهُ لَكُمۡ عَلَيۡهِمۡ سَبِيلٗا
Àyàfi àwọn tó bá darapọ̀ mọ́ ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Tàbí wọ́n wá ba yín, tí ọkàn wọn ti pami láti ba yín jà tàbí láti bá àwọn ènìyàn wọn jà. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá fún wọn lágbára (ọkàn-akin) lórí yín, wọn ìbá sì jà yín lógun. Nítorí náà, tí wọ́n bá yẹra fún yín, tí wọn kò sì jà yín lógun, tí wọ́n sì juwọ́ sílẹ̀ fún yín, nígbà náà Allāhu kò fún yín ní ọ̀nà lórí wọn (láti jà wọ́n lógun).
Les exégèses en arabe:
سَتَجِدُونَ ءَاخَرِينَ يُرِيدُونَ أَن يَأۡمَنُوكُمۡ وَيَأۡمَنُواْ قَوۡمَهُمۡ كُلَّ مَا رُدُّوٓاْ إِلَى ٱلۡفِتۡنَةِ أُرۡكِسُواْ فِيهَاۚ فَإِن لَّمۡ يَعۡتَزِلُوكُمۡ وَيُلۡقُوٓاْ إِلَيۡكُمُ ٱلسَّلَمَ وَيَكُفُّوٓاْ أَيۡدِيَهُمۡ فَخُذُوهُمۡ وَٱقۡتُلُوهُمۡ حَيۡثُ ثَقِفۡتُمُوهُمۡۚ وَأُوْلَٰٓئِكُمۡ جَعَلۡنَا لَكُمۡ عَلَيۡهِمۡ سُلۡطَٰنٗا مُّبِينٗا
Ẹ máa rí àwọn ẹlòmíìràn tí wọ́n ń fẹ́ ààbò lọ́dọ̀ yín (wọ́n bá ní àwọn gba ’Islām), wọ́n tún ń fẹ́ ààbò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọn (wọ́n tún ń bá wọn ṣẹbọ), ìgbàkígbà tí wọ́n bá dá wọn padà sínú ìfòòró (ìbọ̀rìṣà), wọ́n sì ń padà sínú rẹ̀. Tí wọn kò bá yẹra fún yín, tí wọn kò juwọ́ sílẹ̀ fún yín, tí wọn kò sì dáwọ́ jíjà yín lógun dúró, nígbà náà ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu sì fún yín ní agbára tó yanjú lórí wọn (láti jà wọ́n lógun).
Les exégèses en arabe:
وَمَا كَانَ لِمُؤۡمِنٍ أَن يَقۡتُلَ مُؤۡمِنًا إِلَّا خَطَـٔٗاۚ وَمَن قَتَلَ مُؤۡمِنًا خَطَـٔٗا فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖ وَدِيَةٞ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦٓ إِلَّآ أَن يَصَّدَّقُواْۚ فَإِن كَانَ مِن قَوۡمٍ عَدُوّٖ لَّكُمۡ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖۖ وَإِن كَانَ مِن قَوۡمِۭ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٞ فَدِيَةٞ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ وَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖۖ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ شَهۡرَيۡنِ مُتَتَابِعَيۡنِ تَوۡبَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo kan láti pa onígbàgbọ́ òdodo kan àyàfi tí ó bá ṣèèsì. Ẹni tí ó bá sì ṣèèsì pa onígbàgbọ́ òdodo kan, ó máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ó tún máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn òkú àfi tí wọ́n bá fi tọrẹ (fún un, tí wọ́n bá yọ̀ǹda rẹ̀ fún un). Tí ó bá sì wà nínú àwọn ènìyàn kan tí ó jẹ́ ọ̀tá fún yín, onígbàgbọ́ sì ni (ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Tí ó bá jẹ́ ìjọ tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn (ni ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó tún máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹni tí kò bá rí (ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo), ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. (Ọ̀nà) ìronúpìwàdà kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (nìyí). Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Les exégèses en arabe:
وَمَن يَقۡتُلۡ مُؤۡمِنٗا مُّتَعَمِّدٗا فَجَزَآؤُهُۥ جَهَنَّمُ خَٰلِدٗا فِيهَا وَغَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ وَلَعَنَهُۥ وَأَعَدَّ لَهُۥ عَذَابًا عَظِيمٗا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa onígbàgbọ́ òdodo kan, iná Jahanamọ ni ẹ̀san rẹ̀. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Allāhu yóò bínú sí i. Ó máa ṣẹ́bilé e. Ó sì ti pèsè ìyà ńlá sílẹ̀ dè é.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا ضَرَبۡتُمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَتَبَيَّنُواْ وَلَا تَقُولُواْ لِمَنۡ أَلۡقَىٰٓ إِلَيۡكُمُ ٱلسَّلَٰمَ لَسۡتَ مُؤۡمِنٗا تَبۡتَغُونَ عَرَضَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا فَعِندَ ٱللَّهِ مَغَانِمُ كَثِيرَةٞۚ كَذَٰلِكَ كُنتُم مِّن قَبۡلُ فَمَنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمۡ فَتَبَيَّنُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò ní ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ogun ẹ̀sìn), ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn). Ẹ sì má ṣe sọ fún ẹni tí ó bá sálámọ̀ si yín pé kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo látara pé ẹ̀yin ń wá dúkìá ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu kúkú ni ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọrọ̀ ogun wà. Báyẹn ni ẹ̀yin náà ṣe wà tẹ́lẹ̀, Allāhu sì ṣe ìdẹ̀ra (ẹ̀sìn) fún yín. Nítorí náà, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn náà). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Les exégèses en arabe:
لَّا يَسۡتَوِي ٱلۡقَٰعِدُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ غَيۡرُ أُوْلِي ٱلضَّرَرِ وَٱلۡمُجَٰهِدُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡۚ فَضَّلَ ٱللَّهُ ٱلۡمُجَٰهِدِينَ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡ عَلَى ٱلۡقَٰعِدِينَ دَرَجَةٗۚ وَكُلّٗا وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ وَفَضَّلَ ٱللَّهُ ٱلۡمُجَٰهِدِينَ عَلَى ٱلۡقَٰعِدِينَ أَجۡرًا عَظِيمٗا
Àwọn olùjókòó sínú ilé nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, yàtọ̀ sí àwọn aláìlera, àti àwọn olùjagun ní ojú-ọ̀nà Allāhu pẹ̀lú dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn, wọn kò dọ́gba. Allāhu fi ipò kan ṣoore àjùlọ fún àwọn olùjagun ní ojú-ọ̀nà Allāhu pẹ̀lú dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn lórí àwọn olùjókòó sínú ilé. Olúkùlùkù (wọn) ni Allāhu ṣe àdéhùn ohun rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) fún. Allāhu gbọ́lá fún àwọn olùjagun ẹ̀sìn lórí àwọn olùjókòó sínú ilé pẹ̀lú ẹ̀san ńlá;
Les exégèses en arabe:
دَرَجَٰتٖ مِّنۡهُ وَمَغۡفِرَةٗ وَرَحۡمَةٗۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمًا
àwọn ipò kan àti àforíjìn àti àánú láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ تَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ ظَالِمِيٓ أَنفُسِهِمۡ قَالُواْ فِيمَ كُنتُمۡۖ قَالُواْ كُنَّا مُسۡتَضۡعَفِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ قَالُوٓاْ أَلَمۡ تَكُنۡ أَرۡضُ ٱللَّهِ وَٰسِعَةٗ فَتُهَاجِرُواْ فِيهَاۚ فَأُوْلَٰٓئِكَ مَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ وَسَآءَتۡ مَصِيرًا
Dájúdájú àwọn tí mọlāika gba ẹ̀mí wọn, (lásìkò) tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, (àwọn mọlāika) sọ pé: “Kí ni ẹ̀ ń ṣe (nínú ẹ̀sìn)?¹” Wọ́n wí pé: “Wọ́n dá wa lágara lórí ilẹ̀ ni.” (Àwọn mọlāika) sọ pé: “Ṣé ilẹ̀ Allāhu kò fẹ̀ tó (fún yín) láti gbé ẹ̀sìn yín sá lórí ilẹ̀?” Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ó sì burú ní ìkángun.
1. Tàbí “nínú igun wo ni ẹ wà, igun àwọn mùsùlùmí ni tàbí igun àwọn ọ̀ṣẹbọ? Tàbí nínú ìlú wo ni ẹ wà, ìlú 'Islām ni tàbí ìlú ọ̀ṣẹbọ? ”
Les exégèses en arabe:
إِلَّا ٱلۡمُسۡتَضۡعَفِينَ مِنَ ٱلرِّجَالِ وَٱلنِّسَآءِ وَٱلۡوِلۡدَٰنِ لَا يَسۡتَطِيعُونَ حِيلَةٗ وَلَا يَهۡتَدُونَ سَبِيلٗا
Àyàfi àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí kò ní ìkápá ọgbọ́n kan, wọn kò sì dá ọ̀nà mọ̀ (dé ìlú Mọdīnah).
Les exégèses en arabe:
فَأُوْلَٰٓئِكَ عَسَى ٱللَّهُ أَن يَعۡفُوَ عَنۡهُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَفُوًّا غَفُورٗا
Nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn, ó súnmọ́ kí Allāhu ṣàmójúkúrò fún wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn.
Les exégèses en arabe:
۞ وَمَن يُهَاجِرۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ يَجِدۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُرَٰغَمٗا كَثِيرٗا وَسَعَةٗۚ وَمَن يَخۡرُجۡ مِنۢ بَيۡتِهِۦ مُهَاجِرًا إِلَى ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ ثُمَّ يُدۡرِكۡهُ ٱلۡمَوۡتُ فَقَدۡ وَقَعَ أَجۡرُهُۥ عَلَى ٱللَّهِۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمٗا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ìlú rẹ̀ jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, ó máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ibùsásí àti ìgbàláyè lórí ilẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde kúrò nínú ilé rẹ̀ (tí ó jẹ́) olùfìlú-sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí ikú bá a (lójú ọ̀nà), ẹ̀san rẹ̀ kúkú ti dúró lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.¹
1. Gbígbé ìlú ẹni jù sílẹ̀ láti tẹ̀dó sínú ìlú mìíràn yóò di dandan fún mùsùlùmí nígbà tí wíwà nínú ìlú rẹ̀ kò bá rọgbọ fún ẹ̀sìn ṣíṣe, bákan náà tí mùsùlùmí kò sì ní ìkápá láti ja àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn lógun. Èyí ni a mọ̀ sí Hijrah nínú èdè Lárúbáwá.
Les exégèses en arabe:
وَإِذَا ضَرَبۡتُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَلَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٌ أَن تَقۡصُرُواْ مِنَ ٱلصَّلَوٰةِ إِنۡ خِفۡتُمۡ أَن يَفۡتِنَكُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْۚ إِنَّ ٱلۡكَٰفِرِينَ كَانُواْ لَكُمۡ عَدُوّٗا مُّبِينٗا
Nígbà tí ẹ bá ṣe ìrìn-àjò lórí ilẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín láti dín ìrun kù,¹ tí ẹ̀yin bá ń bẹ̀rù pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò fòòró yín. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, wọ́n jẹ́ ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.
1. Ìyẹn ni dídín àwọn ìrun onírákáà mẹ́rin kù sí rákáà méjì.
Les exégèses en arabe:
وَإِذَا كُنتَ فِيهِمۡ فَأَقَمۡتَ لَهُمُ ٱلصَّلَوٰةَ فَلۡتَقُمۡ طَآئِفَةٞ مِّنۡهُم مَّعَكَ وَلۡيَأۡخُذُوٓاْ أَسۡلِحَتَهُمۡۖ فَإِذَا سَجَدُواْ فَلۡيَكُونُواْ مِن وَرَآئِكُمۡ وَلۡتَأۡتِ طَآئِفَةٌ أُخۡرَىٰ لَمۡ يُصَلُّواْ فَلۡيُصَلُّواْ مَعَكَ وَلۡيَأۡخُذُواْ حِذۡرَهُمۡ وَأَسۡلِحَتَهُمۡۗ وَدَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡ تَغۡفُلُونَ عَنۡ أَسۡلِحَتِكُمۡ وَأَمۡتِعَتِكُمۡ فَيَمِيلُونَ عَلَيۡكُم مَّيۡلَةٗ وَٰحِدَةٗۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ إِن كَانَ بِكُمۡ أَذٗى مِّن مَّطَرٍ أَوۡ كُنتُم مَّرۡضَىٰٓ أَن تَضَعُوٓاْ أَسۡلِحَتَكُمۡۖ وَخُذُواْ حِذۡرَكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ أَعَدَّ لِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٗا مُّهِينٗا
Nígbà tí o bá wà láààrin wọn, gbé ìrun dúró fún wọn. Kí igun kan nínú wọn kírun pẹ̀lú rẹ, kí wọ́n mú n̄ǹkan ìjagun wọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n bá sì forí kanlẹ̀ (tí wọ́n parí ìrun), kí wọn bọ́ sẹ́yìn yín, kí igun mìíràn tí kò tí ì kírun wá kírun pẹ̀lú rẹ. Kí wọ́n mú ìṣọ́ra wọn¹ àti n̄ǹkan ìjagun wọn lọ́wọ́.² Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ kí ẹ gbàgbé àwọn n̄ǹkan ìjagun yín àti n̄ǹkan ìgbádùn yín (ẹrù oúnjẹ yín), kí wọ́n lè kọlù yín ní ẹ̀ẹ̀ kan náà. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín tí ó bá jẹ́ pé ìpalára kan ń bẹ fún yín látara òjò tàbí (pé) ẹ jẹ́ aláìsàn, pé kí ẹ fi n̄ǹkan ìjagun yín sílẹ̀ (lórí ìrun). Ẹ mú n̄ǹkan ìṣọ́ra yín lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 71.
2. Àpèjúwe ìrun ojú ogun nínú āyah yìí nìyí: Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - máa kí rákáà ẹyọ kan parí fún igun àkọ́kọ́. Ó máa wà lórí ìjókòó rẹ̀ bẹ́ẹ̀ títí igun náà yóò fi kí rákáà ẹyọ kan tí ó ṣẹ́kù kún un. Olúkùlùkù wọn sì máa sálámọ̀ fúnra rẹ̀ ní ìparí rákáà kejì. Igun kejì tí wọ́n dúró sẹ́yìn wọn máa bọ́ síwájú lẹ́yìn Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, igun àkọ́kọ́ tí rákáà méjì tirẹ̀ ti pé máa bọ́ sẹ́yìn wọn. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - máa kí rákáà ẹyọ kan tirẹ̀ tó ṣẹ́kù fún igun kejì. Lẹ́yìn náà, igun kejì yìí náà yóò kí rákáà ẹyọ kan tí ó ṣẹ́kù kún un. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lè sálámọ̀ tirẹ̀ tàbí kí ó dúró dè wọ́n láti sálámọ̀ fún wọn. Báyẹn ni àpèjúwe ìrun Subh, Ṭḥuhr, ‘Asr àti ‘Iṣā’ lójú ogun.
Les exégèses en arabe:
فَإِذَا قَضَيۡتُمُ ٱلصَّلَوٰةَ فَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ قِيَٰمٗا وَقُعُودٗا وَعَلَىٰ جُنُوبِكُمۡۚ فَإِذَا ٱطۡمَأۡنَنتُمۡ فَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَۚ إِنَّ ٱلصَّلَوٰةَ كَانَتۡ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ كِتَٰبٗا مَّوۡقُوتٗا
Nígbà tí ẹ bá parí ìrun, kí ẹ ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní ìdúró, ìjókòó àti ìdùbúlẹ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá sì fọkàn balẹ̀, kí ẹ kírun (ní pípé). Dájúdájú ìrun kíkí jẹ́ ọ̀ran-anyàn tí A fi àkókò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Les exégèses en arabe:
وَلَا تَهِنُواْ فِي ٱبۡتِغَآءِ ٱلۡقَوۡمِۖ إِن تَكُونُواْ تَأۡلَمُونَ فَإِنَّهُمۡ يَأۡلَمُونَ كَمَا تَأۡلَمُونَۖ وَتَرۡجُونَ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا يَرۡجُونَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
Ẹ má ṣe káàárẹ̀ nípa wíwá àwọn ènìyàn náà (láti jà wọ́n lógun). Tí ẹ̀yin bá ń jẹ ìrora (ọgbẹ́), dájúdájú àwọn náà ń jẹ ìrora (ọgbẹ́) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe ń jẹ ìrora rẹ̀. Ẹ̀yin sì ń retí ohun tí àwọn kò retí lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Les exégèses en arabe:
إِنَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ لِتَحۡكُمَ بَيۡنَ ٱلنَّاسِ بِمَآ أَرَىٰكَ ٱللَّهُۚ وَلَا تَكُن لِّلۡخَآئِنِينَ خَصِيمٗا
Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí kí o lè máa ṣèdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn pẹ̀lú ohun tí Allāhu fi hàn ọ́. Má ṣe jẹ́ olùgbèjà fún àwọn oníjàǹbá.¹
1. Kí ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ agbẹjọ́rò má ṣe jẹ́ ẹni tí yóò máa kọ́ ọ̀daràn ní irọ́ nítorí kí ó lè móríbọ́ nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kí ẹ̀yin adájọ́ náà má ṣe dá ọ̀daràn láre.
Les exégèses en arabe:
وَٱسۡتَغۡفِرِ ٱللَّهَۖ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا
Tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu,¹ dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Gọ̄fir; 40:55.
Les exégèses en arabe:
وَلَا تُجَٰدِلۡ عَنِ ٱلَّذِينَ يَخۡتَانُونَ أَنفُسَهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ مَن كَانَ خَوَّانًا أَثِيمٗا
Má ṣe bá àwọn tó ń jàǹbá ẹ̀mí ara wọn wá àwíjàre. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ oníjàǹbá, ẹlẹ́ṣẹ̀.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 105.
Les exégèses en arabe:
يَسۡتَخۡفُونَ مِنَ ٱلنَّاسِ وَلَا يَسۡتَخۡفُونَ مِنَ ٱللَّهِ وَهُوَ مَعَهُمۡ إِذۡ يُبَيِّتُونَ مَا لَا يَرۡضَىٰ مِنَ ٱلۡقَوۡلِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِمَا يَعۡمَلُونَ مُحِيطًا
Wọ́n ń fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn, wọn kò sì lè fara pamọ́ fún Allāhu (nítorí pé) Ó wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀) nígbà tí wọ́n ń pètepèrò lórí ohun tí (Allāhu) kò yọ́nú sí nínú ọ̀rọ̀ sísọ.¹ Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mujādilah; 58:7.
Les exégèses en arabe:
هَٰٓأَنتُمۡ هَٰٓؤُلَآءِ جَٰدَلۡتُمۡ عَنۡهُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا فَمَن يُجَٰدِلُ ٱللَّهَ عَنۡهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ أَم مَّن يَكُونُ عَلَيۡهِمۡ وَكِيلٗا
Kíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí ni ẹ̀ ń bá wọn mú àwíjàre wá nílé ayé. Ta ni ó máa bá wọn mú àwíjàre wá ní ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde? Tàbí ta ni ó máa jẹ́ aláàbò fún wọn?
Les exégèses en arabe:
وَمَن يَعۡمَلۡ سُوٓءًا أَوۡ يَظۡلِمۡ نَفۡسَهُۥ ثُمَّ يَسۡتَغۡفِرِ ٱللَّهَ يَجِدِ ٱللَّهَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan tàbí tí ó ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀, lẹ́yìn náà tí ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, ó máa bá Allāhu ní Aláforíjìn, Aláàánú.
Les exégèses en arabe:
وَمَن يَكۡسِبۡ إِثۡمٗا فَإِنَّمَا يَكۡسِبُهُۥ عَلَىٰ نَفۡسِهِۦۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, ó dá a fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Les exégèses en arabe:
وَمَن يَكۡسِبۡ خَطِيٓـَٔةً أَوۡ إِثۡمٗا ثُمَّ يَرۡمِ بِهِۦ بَرِيٓـٔٗا فَقَدِ ٱحۡتَمَلَ بُهۡتَٰنٗا وَإِثۡمٗا مُّبِينٗا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣìṣe kan tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kan, lẹ́yìn náà, ó dì í ru aláìmọwọ́-mẹsẹ̀, ó ti dá ọ̀ràn ìparọ́mọ́ni àti ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé.
Les exégèses en arabe:
وَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكَ وَرَحۡمَتُهُۥ لَهَمَّت طَّآئِفَةٞ مِّنۡهُمۡ أَن يُضِلُّوكَ وَمَا يُضِلُّونَ إِلَّآ أَنفُسَهُمۡۖ وَمَا يَضُرُّونَكَ مِن شَيۡءٖۚ وَأَنزَلَ ٱللَّهُ عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَعَلَّمَكَ مَا لَمۡ تَكُن تَعۡلَمُۚ وَكَانَ فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكَ عَظِيمٗا
Tí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ tí ń bẹ lórí rẹ ni, igun kan nínú wọn ìbá ti gbèrò láti ṣì ọ́ lọ́nà. Wọn kò sì níí ṣi ẹnì kan lọ́nà àfi ẹ̀mí ara wọn. Wọn kò sì lè fi n̄ǹkan kan kó ìnira bá ọ. Allāhu sì sọ Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah) kalẹ̀ fún ọ. Ó tún fi ohun tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ mọ̀ ọ́;¹ oore àjùlọ Allāhu lórí rẹ jẹ́ ohun tó tóbi.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:52.
Les exégèses en arabe:
۞ لَّا خَيۡرَ فِي كَثِيرٖ مِّن نَّجۡوَىٰهُمۡ إِلَّا مَنۡ أَمَرَ بِصَدَقَةٍ أَوۡ مَعۡرُوفٍ أَوۡ إِصۡلَٰحِۭ بَيۡنَ ٱلنَّاسِۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ ٱبۡتِغَآءَ مَرۡضَاتِ ٱللَّهِ فَسَوۡفَ نُؤۡتِيهِ أَجۡرًا عَظِيمٗا
Kò sí oore kan nínú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn àfi ẹni tí ó bá pàṣẹ ọrẹ títa tàbí iṣẹ́ rere tàbí àtúnṣe láààrin àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn láti fi wá ìyọ́nú Allāhu, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san ńlá.
Les exégèses en arabe:
وَمَن يُشَاقِقِ ٱلرَّسُولَ مِنۢ بَعۡدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُ ٱلۡهُدَىٰ وَيَتَّبِعۡ غَيۡرَ سَبِيلِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ نُوَلِّهِۦ مَا تَوَلَّىٰ وَنُصۡلِهِۦ جَهَنَّمَۖ وَسَآءَتۡ مَصِيرًا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa Òjíṣẹ́ náà lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú han sí i kedere, tí ó tún tẹ̀lé ọ̀nà tó yàtọ̀ sí ti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, A óò dojú rẹ̀ kọ ohun tí ó dojú ara rẹ̀ kọ (nínú ìṣìnà),A sì máa mú un wọ inú iná Jahanamọ. Ó sì burú ní ìkángun.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَغۡفِرُ أَن يُشۡرَكَ بِهِۦ وَيَغۡفِرُ مَا دُونَ ذَٰلِكَ لِمَن يَشَآءُۚ وَمَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَقَدۡ ضَلَّ ضَلَٰلَۢا بَعِيدًا
Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́.¹ Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà tó jìnnà.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 48.
Les exégèses en arabe:
إِن يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦٓ إِلَّآ إِنَٰثٗا وَإِن يَدۡعُونَ إِلَّا شَيۡطَٰنٗا مَّرِيدٗا
Wọn kò pe kiní kan lẹ́yìn Allāhu bí kò ṣe àwọn abo òrìṣà.¹ Wọn kò sì pe kiní kan bí kò ṣe Èṣù olùyapa.
1. Nínú āyah yìí, “abo òrìṣà” túmọ̀ sí àwọn n̄ǹkan ọ̀bọrọgidi tí orúkọ wọn wá pẹ̀lú jẹ́ńdà abo tàbí àwọn orúkọ òrìṣà kan tí wọ́n wá pẹ̀lú jẹ́ńdà abo gẹ́gẹ́ bí òrìṣà Lāt, òrìṣà ‘Uzzā àti òrìṣà Mọnāt, tàbí àwọn mọlāika tí wọ́n kàkún abo, tí wọ́n sì sọ wọ́n di òrìṣà. Nítorí náà, abo òrìṣà kò túmọ̀ sí pé abo ni gbogbo àwọn òrìṣà ayé.
Les exégèses en arabe:
لَّعَنَهُ ٱللَّهُۘ وَقَالَ لَأَتَّخِذَنَّ مِنۡ عِبَادِكَ نَصِيبٗا مَّفۡرُوضٗا
Allāhu ṣẹ́bilé Èṣù. Ó sì wí pé: “Dájúdájú mo máa mú ìpín tí wọ́n pín fún mi nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ.
Les exégèses en arabe:
وَلَأُضِلَّنَّهُمۡ وَلَأُمَنِّيَنَّهُمۡ وَلَأٓمُرَنَّهُمۡ فَلَيُبَتِّكُنَّ ءَاذَانَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ وَلَأٓمُرَنَّهُمۡ فَلَيُغَيِّرُنَّ خَلۡقَ ٱللَّهِۚ وَمَن يَتَّخِذِ ٱلشَّيۡطَٰنَ وَلِيّٗا مِّن دُونِ ٱللَّهِ فَقَدۡ خَسِرَ خُسۡرَانٗا مُّبِينٗا
Dájúdájú mo máa ṣì wọ́n lọ́nà. Dájúdájú mo máa tàn wọ́n jẹ. Dájúdájú mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa gé etí ẹran-ọ̀sìn (láti yà á sọ́tọ̀ fún òrìṣà). Dájúdájú mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa yí ẹ̀sìn Allāhu padà.”¹ Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú Èṣù ní ọ̀rẹ́ lẹ́yìn Allāhu, dájúdájú ó ti ṣòfò ní òfò pọ́nńbélé.
1. Ìyẹn ni pé, Èṣù yóò máa pa wọ́n ní àṣẹ pé kí wọ́n di kèfèrí àti ọ̀ṣẹbọ. Allāhu sì ń pàṣẹ pé wọn kò gbọ́dọ̀ yí ẹ̀sìn wọn tí ó jẹ́ ẹ̀sìn àdámọ́ wọn padà. Ẹ wo sūrah ar-Rūm; 30:30.
Les exégèses en arabe:
يَعِدُهُمۡ وَيُمَنِّيهِمۡۖ وَمَا يَعِدُهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ إِلَّا غُرُورًا
Ó ń ṣàdéhùn fún wọn, ó sì ń tàn wọ́n jẹ. Èṣù kò sì ṣàdéhùn kan fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn.
Les exégèses en arabe:
أُوْلَٰٓئِكَ مَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُ وَلَا يَجِدُونَ عَنۡهَا مَحِيصٗا
Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; wọn kò níí rí ibùsásí kan (wọn kò níí rí ọ̀nà láti sá jàde kúrò nínú rẹ̀).
Les exégèses en arabe:
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ سَنُدۡخِلُهُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۖ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٗاۚ وَمَنۡ أَصۡدَقُ مِنَ ٱللَّهِ قِيلٗا
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere, A máa mú wọn wọ inu àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọn nínú rẹ̀ títí láéláé. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní ti òdodo. Ta sì ni ó sọ òdodo ju Allāhu?
Les exégèses en arabe:
لَّيۡسَ بِأَمَانِيِّكُمۡ وَلَآ أَمَانِيِّ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِۗ مَن يَعۡمَلۡ سُوٓءٗا يُجۡزَ بِهِۦ وَلَا يَجِدۡ لَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا
Kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn yín, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn àwọn onítírà (ni òṣùwọ̀n ìdájọ́ ọ̀run. Àmọ́,) ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan, A óò san án ní ẹ̀san rẹ̀; kò sì níí rí aláfẹ̀yìntì tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:62.
Les exégèses en arabe:
وَمَن يَعۡمَلۡ مِنَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ مِن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَدۡخُلُونَ ٱلۡجَنَّةَ وَلَا يُظۡلَمُونَ نَقِيرٗا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ rere, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, onígbàgbọ́ òdodo sì ni, àwọn wọ̀nyẹn máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí fi àmì ẹ̀yìn kóró èso dàbínú ṣàbòsí sí wọn.
Les exégèses en arabe:
وَمَنۡ أَحۡسَنُ دِينٗا مِّمَّنۡ أَسۡلَمَ وَجۡهَهُۥ لِلَّهِ وَهُوَ مُحۡسِنٞ وَٱتَّبَعَ مِلَّةَ إِبۡرَٰهِيمَ حَنِيفٗاۗ وَٱتَّخَذَ ٱللَّهُ إِبۡرَٰهِيمَ خَلِيلٗا
Ta l’ó dára ní ẹ̀sìn ju ẹni tí ó jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, olùṣe-rere sì tún ni, ó tún tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām? Allāhu sì mú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní àyànfẹ́.
Les exégèses en arabe:
وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٖ مُّحِيطٗا
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa gbogbo n̄ǹkan.
Les exégèses en arabe:
وَيَسۡتَفۡتُونَكَ فِي ٱلنِّسَآءِۖ قُلِ ٱللَّهُ يُفۡتِيكُمۡ فِيهِنَّ وَمَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ فِي يَتَٰمَى ٱلنِّسَآءِ ٱلَّٰتِي لَا تُؤۡتُونَهُنَّ مَا كُتِبَ لَهُنَّ وَتَرۡغَبُونَ أَن تَنكِحُوهُنَّ وَٱلۡمُسۡتَضۡعَفِينَ مِنَ ٱلۡوِلۡدَٰنِ وَأَن تَقُومُواْ لِلۡيَتَٰمَىٰ بِٱلۡقِسۡطِۚ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِهِۦ عَلِيمٗا
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè ìdájọ́ nípa àwọn obìnrin. Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń sọ ìdájọ́ wọn fún yín. Ohun tí wọ́n ń ké fún yín nínú Tírà (al-Ƙur’ān náà ń sọ ìdájọ́ fún yín) nípa àwọn ọmọ-òrukàn lóbìnrin tí ẹ kì í fún ní ohun tí wọ́n kọ fún wọn (nínú ogún), tí ẹ tún ń ṣojú-kòkòrò pé ẹ fẹ́ fẹ́ wọn àti nípa àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọmọdé (tí ẹ̀ ń jẹ ogún wọn mọ́lẹ̀.) àti nípa pé kí ẹ dúró ti àwọn ọmọ òrukàn pẹ̀lú déédé. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ṣe ní rere, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀.
Les exégèses en arabe:
وَإِنِ ٱمۡرَأَةٌ خَافَتۡ مِنۢ بَعۡلِهَا نُشُوزًا أَوۡ إِعۡرَاضٗا فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَآ أَن يُصۡلِحَا بَيۡنَهُمَا صُلۡحٗاۚ وَٱلصُّلۡحُ خَيۡرٞۗ وَأُحۡضِرَتِ ٱلۡأَنفُسُ ٱلشُّحَّۚ وَإِن تُحۡسِنُواْ وَتَتَّقُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا
Tí obìnrin kan bá páyà oríkunkun tàbí ìkẹ̀yìnsí láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì pé kí wọ́n ṣe àtúnṣe láààrin ara wọn. Àtúnṣe sì dára júlọ. Wọ́n sì ti fi ahun àti ọ̀kánjúà ṣíṣe sínú ẹ̀mí ènìyàn. Tí ẹ bá ṣe rere, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.¹
1. Èyí ni ti olóríkunkun ọkùnrin. Ní ti olóríkunkun obìnrin, ẹ wo āyah 34.
Les exégèses en arabe:
وَلَن تَسۡتَطِيعُوٓاْ أَن تَعۡدِلُواْ بَيۡنَ ٱلنِّسَآءِ وَلَوۡ حَرَصۡتُمۡۖ فَلَا تَمِيلُواْ كُلَّ ٱلۡمَيۡلِ فَتَذَرُوهَا كَٱلۡمُعَلَّقَةِۚ وَإِن تُصۡلِحُواْ وَتَتَّقُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا
Ẹ kò lè ṣe déédé (nínú ìfẹ́) láààrin àwọn obìnrin, ẹ ò báà jẹ̀rankàn rẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe fì síbì kan tán pátápátá, kí ẹ wá pa (ẹnì kan) tì bí ohun tí wọ́n gbékọ́ ara ilé. Tí ẹ bá ṣàtúnṣe, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Les exégèses en arabe:
وَإِن يَتَفَرَّقَا يُغۡنِ ٱللَّهُ كُلّٗا مِّن سَعَتِهِۦۚ وَكَانَ ٱللَّهُ وَٰسِعًا حَكِيمٗا
Tí àwọn méjèèjì bá sì pínyà, Allāhu yóò rọ ìkíní kejì lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀ tó gbòòrò. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbòòrò (nínú ọrọ̀), Ọlọ́gbọ́n.
Les exégèses en arabe:
وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَلَقَدۡ وَصَّيۡنَا ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكُمۡ وَإِيَّاكُمۡ أَنِ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ وَإِن تَكۡفُرُواْ فَإِنَّ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَنِيًّا حَمِيدٗا
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú A ti pa á láṣẹ fún àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti ẹ̀yin náa pé kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn (tí ẹyìn tọ́ sí).
Les exégèses en arabe:
وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلًا
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́.
Les exégèses en arabe:
إِن يَشَأۡ يُذۡهِبۡكُمۡ أَيُّهَا ٱلنَّاسُ وَيَأۡتِ بِـَٔاخَرِينَۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ ذَٰلِكَ قَدِيرٗا
Tí (Allāhu) bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò lórí ilẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn. Ó sì máa mú àwọn mìíràn wá. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí ìyẹn.
Les exégèses en arabe:
مَّن كَانَ يُرِيدُ ثَوَابَ ٱلدُّنۡيَا فَعِندَ ٱللَّهِ ثَوَابُ ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ سَمِيعَۢا بَصِيرٗا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ẹ̀san nílé ayé, ṣebí lọ́dọ̀ Allāhu ní ẹ̀san ti ayé àti ti ọ̀run wà. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran.
Les exégèses en arabe:
۞ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُونُواْ قَوَّٰمِينَ بِٱلۡقِسۡطِ شُهَدَآءَ لِلَّهِ وَلَوۡ عَلَىٰٓ أَنفُسِكُمۡ أَوِ ٱلۡوَٰلِدَيۡنِ وَٱلۡأَقۡرَبِينَۚ إِن يَكُنۡ غَنِيًّا أَوۡ فَقِيرٗا فَٱللَّهُ أَوۡلَىٰ بِهِمَاۖ فَلَا تَتَّبِعُواْ ٱلۡهَوَىٰٓ أَن تَعۡدِلُواْۚ وَإِن تَلۡوُۥٓاْ أَوۡ تُعۡرِضُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí déédé nítorí ti Allāhu nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí, kódà kí (ẹ̀rí jíjẹ́ náà) tako ẹ̀yin fúnra yín tàbí àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí; yálà ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí aláìní, Allāhu súnmọ́ (yín) ju àwọn méjèèjì. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú láti má ṣe déédé. Tí ẹ bá yí ojú-ọ̀rọ̀ sódì tàbí tí ẹ bá gbúnrí kúrò (níbi déédé), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.¹
1. Ẹ tún wo sūrah al-Mọ̄'idah; 5:8.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ ءَامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلَّذِي نَزَّلَ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ مِن قَبۡلُۚ وَمَن يَكۡفُرۡ بِٱللَّهِ وَمَلَٰٓئِكَتِهِۦ وَكُتُبِهِۦ وَرُسُلِهِۦ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ فَقَدۡ ضَلَّ ضَلَٰلَۢا بَعِيدًا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbàgbọ́ dáadáa nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí (Allāhu) sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí Ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà tó jìnnà tefétefé.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ثُمَّ كَفَرُواْ ثُمَّ ءَامَنُواْ ثُمَّ كَفَرُواْ ثُمَّ ٱزۡدَادُواْ كُفۡرٗا لَّمۡ يَكُنِ ٱللَّهُ لِيَغۡفِرَ لَهُمۡ وَلَا لِيَهۡدِيَهُمۡ سَبِيلَۢا
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n sì lékún sí i nínú àìgbàgbọ́, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fí ọ̀nà mọ̀ wọ́n.¹
1. Āyah yìí àti āyah 48 àti 116 fi rinlẹ̀ fún wa pé, kò sí àforíjìn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá kú sínú àìgbàgbọ́ ńlá àti ìṣẹbọ ńlá sí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -
Les exégèses en arabe:
بَشِّرِ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ بِأَنَّ لَهُمۡ عَذَابًا أَلِيمًا
Fún àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ní ìró pé dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn.
Les exégèses en arabe:
ٱلَّذِينَ يَتَّخِذُونَ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۚ أَيَبۡتَغُونَ عِندَهُمُ ٱلۡعِزَّةَ فَإِنَّ ٱلۡعِزَّةَ لِلَّهِ جَمِيعٗا
(Àwọn ni) àwọn tó ń mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ṣé ẹ̀ ń wá agbára lọ́dọ̀ wọn ni? Dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo agbára pátápátá.
Les exégèses en arabe:
وَقَدۡ نَزَّلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ أَنۡ إِذَا سَمِعۡتُمۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ يُكۡفَرُ بِهَا وَيُسۡتَهۡزَأُ بِهَا فَلَا تَقۡعُدُواْ مَعَهُمۡ حَتَّىٰ يَخُوضُواْ فِي حَدِيثٍ غَيۡرِهِۦٓ إِنَّكُمۡ إِذٗا مِّثۡلُهُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ جَامِعُ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱلۡكَٰفِرِينَ فِي جَهَنَّمَ جَمِيعًا
(Allāhu) kúkú ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún yín nínú Tírà pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn āyah Allāhu pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọ́n sì ń fi ṣe ẹ̀fẹ̀, ẹ má ṣe jókòó tì wọ́n nígbà náà títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ dájúdájú bí irú wọn ni ẹ̀yin náà. Dájúdájú Allāhu yóò pa àwọn ṣòbẹ-ṣèlu mùsùlùmí pọ̀ mọ́ gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ nínú iná Jahanamọ.
Les exégèses en arabe:
ٱلَّذِينَ يَتَرَبَّصُونَ بِكُمۡ فَإِن كَانَ لَكُمۡ فَتۡحٞ مِّنَ ٱللَّهِ قَالُوٓاْ أَلَمۡ نَكُن مَّعَكُمۡ وَإِن كَانَ لِلۡكَٰفِرِينَ نَصِيبٞ قَالُوٓاْ أَلَمۡ نَسۡتَحۡوِذۡ عَلَيۡكُمۡ وَنَمۡنَعۡكُم مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۚ فَٱللَّهُ يَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ وَلَن يَجۡعَلَ ٱللَّهُ لِلۡكَٰفِرِينَ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ سَبِيلًا
(Àwọn ni) àwọn tó fẹ́ yọ̀ yín; tí ìṣẹ́gun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu bá jẹ́ tiyín, wọ́n á wí pé: “Ṣé àwa kò wà pẹ̀lú yín bí?” Tí ìpín kan bá sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́, (àwọn mùnááfìkí) á wí pé: “Ṣé àwa kò ti ní ìkápá láti jẹ gàba le yín lórí (àmọ́ tí àwa kò ṣe bẹ́ẹ̀), ṣé àwa kò sì dáàbò bò yín tó lọ́wọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (títí ọwọ́ yín fi ba ọrọ̀-ogun, nítorí náà kí ni ìpín tiwa tí ẹ fẹ́ fún wa?)”¹ Nítorí náà, Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde. Allāhu kò sì níí fún àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀nà (ìṣẹ́gun) kan lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
1. Ìyẹn ni pé, àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí yóò máa wá àǹfàní sọ́dọ̀ àwa mùsùlùmí àti àwọn aláìgbàgbọ́.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ يُخَٰدِعُونَ ٱللَّهَ وَهُوَ خَٰدِعُهُمۡ وَإِذَا قَامُوٓاْ إِلَى ٱلصَّلَوٰةِ قَامُواْ كُسَالَىٰ يُرَآءُونَ ٱلنَّاسَ وَلَا يَذۡكُرُونَ ٱللَّهَ إِلَّا قَلِيلٗا
Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń tan Allāhu, Òun náà sì máa tàn wọ́n. Nígbà tí wọ́n bá dúró láti kírun, wọ́n á dúró (ní ìdúró) òròjú, wọn yó sì máa ṣe ṣekárími (lórí ìrun). Wọn kò sì níí ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu (lórí ìrun) àfi díẹ̀.
Les exégèses en arabe:
مُّذَبۡذَبِينَ بَيۡنَ ذَٰلِكَ لَآ إِلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِ وَلَآ إِلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِۚ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ سَبِيلٗا
Wọ́n ń ṣe bàlàbàlà síhìn-ín sọ́hùn-ún, wọn kò jẹ́ ti àwọn wọ̀nyí, wọn kò sì jẹ́ ti àwọn wọ̀nyí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí ọ̀nà kan fún un.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُواْ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۚ أَتُرِيدُونَ أَن تَجۡعَلُواْ لِلَّهِ عَلَيۡكُمۡ سُلۡطَٰنٗا مُّبِينًا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ yín). Ṣé ẹ fẹ́ ṣe n̄ǹkan tí Allāhu yóò fi ní ẹ̀rí pọ́nńbélé lọ́wọ́ láti jẹ yín níyà ni?
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ فِي ٱلدَّرۡكِ ٱلۡأَسۡفَلِ مِنَ ٱلنَّارِ وَلَن تَجِدَ لَهُمۡ نَصِيرًا
Dájúdájú àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí yóò wà nínú àjà ìsàlẹ̀ pátápátá nínú Iná. O ò sì níí rí alárànṣe kan fún wọn.
Les exégèses en arabe:
إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُواْ وَأَصۡلَحُواْ وَٱعۡتَصَمُواْ بِٱللَّهِ وَأَخۡلَصُواْ دِينَهُمۡ لِلَّهِ فَأُوْلَٰٓئِكَ مَعَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَسَوۡفَ يُؤۡتِ ٱللَّهُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ أَجۡرًا عَظِيمٗا
Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n dúró ṣinṣin ti Allāhu, tí wọ́n sì ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn wọn fún Allāhu. Nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Láìpẹ́ Allāhu máa fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ẹ̀san ńlá.
Les exégèses en arabe:
مَّا يَفۡعَلُ ٱللَّهُ بِعَذَابِكُمۡ إِن شَكَرۡتُمۡ وَءَامَنتُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ شَاكِرًا عَلِيمٗا
Kí ni Allāhu máa fi ìyà yín ṣe, tí ẹ bá dúpẹ́, tí ẹ sì gbàgbọ́ ní òdodo? Allāhu sì ń jẹ́ Ọlọ́pẹ́,¹ Onímọ̀.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:158.
Les exégèses en arabe:
۞ لَّا يُحِبُّ ٱللَّهُ ٱلۡجَهۡرَ بِٱلسُّوٓءِ مِنَ ٱلۡقَوۡلِ إِلَّا مَن ظُلِمَۚ وَكَانَ ٱللَّهُ سَمِيعًا عَلِيمًا
Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ sí ariwo ọ̀rọ̀ burúkú (láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni)¹ àyàfi ẹni tí wọ́n bá ṣe àbòsí sí. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbọ́, Onímọ̀.
1. Bíi sísọ àbòsí náà síta, sísọ̀rọ̀ sí alábòsí náà àti ṣíṣẹ́ èpè fún un ní ìbámu sí irú àbòsí náà. Ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ti gbẹ̀san nìyẹn ní ìbámu sí sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:41.
Les exégèses en arabe:
إِن تُبۡدُواْ خَيۡرًا أَوۡ تُخۡفُوهُ أَوۡ تَعۡفُواْ عَن سُوٓءٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَفُوّٗا قَدِيرًا
Tí ẹ bá ṣàfi hàn rere tàbí ẹ fi pamọ́ tàbí ẹ ṣàmójú kúrò níbi aburú, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòjúúkúrò, Alágbára.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَكۡفُرُونَ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦ وَيُرِيدُونَ أَن يُفَرِّقُواْ بَيۡنَ ٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦ وَيَقُولُونَ نُؤۡمِنُ بِبَعۡضٖ وَنَكۡفُرُ بِبَعۡضٖ وَيُرِيدُونَ أَن يَتَّخِذُواْ بَيۡنَ ذَٰلِكَ سَبِيلًا
Dájúdájú àwọn tó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, wọ́n sì fẹ́ máa ṣòpínyà láààrin Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú apá kan, a sì ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan,” wọ́n sì fẹ́ mú ọ̀nà kan tọ̀ (lẹ́sìn) láààrin ìyẹn.
Les exégèses en arabe:
أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَٰفِرُونَ حَقّٗاۚ وَأَعۡتَدۡنَا لِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٗا مُّهِينٗا
Ní òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́. A sì ti pèsè Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Les exégèses en arabe:
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦ وَلَمۡ يُفَرِّقُواْ بَيۡنَ أَحَدٖ مِّنۡهُمۡ أُوْلَٰٓئِكَ سَوۡفَ يُؤۡتِيهِمۡ أُجُورَهُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمٗا
Àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọn kò sì ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn, láìpẹ́ àwọn wọ̀nyẹn, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Les exégèses en arabe:
يَسۡـَٔلُكَ أَهۡلُ ٱلۡكِتَٰبِ أَن تُنَزِّلَ عَلَيۡهِمۡ كِتَٰبٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِۚ فَقَدۡ سَأَلُواْ مُوسَىٰٓ أَكۡبَرَ مِن ذَٰلِكَ فَقَالُوٓاْ أَرِنَا ٱللَّهَ جَهۡرَةٗ فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّٰعِقَةُ بِظُلۡمِهِمۡۚ ثُمَّ ٱتَّخَذُواْ ٱلۡعِجۡلَ مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُ فَعَفَوۡنَا عَن ذَٰلِكَۚ وَءَاتَيۡنَا مُوسَىٰ سُلۡطَٰنٗا مُّبِينٗا
Àwọn onítírà ń bi ọ́ léèrè pé kí o sọ tírà kan kalẹ̀ láti inú sánmọ̀. Wọ́n kúkú bi (Ànábì) Mūsā ní ohun tí ó tóbi ju ìyẹn lọ. Wọ́n wí pé: “Fi Allāhu hàn wá ní ojúkojú.” Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gbá wọn mú nítorí àbòsí ọwọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di n̄ǹkan tí wọ́n jọ́sìn fún lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá wọn. A tún ṣàmójú kúrò níbi ìyẹn. A sì fún (Ànábì) Mūsā ní ẹ̀rí pọ́nńbélé.
Les exégèses en arabe:
وَرَفَعۡنَا فَوۡقَهُمُ ٱلطُّورَ بِمِيثَٰقِهِمۡ وَقُلۡنَا لَهُمُ ٱدۡخُلُواْ ٱلۡبَابَ سُجَّدٗا وَقُلۡنَا لَهُمۡ لَا تَعۡدُواْ فِي ٱلسَّبۡتِ وَأَخَذۡنَا مِنۡهُم مِّيثَٰقًا غَلِيظٗا
A gbé àpáta sókè orí wọn nítorí májẹ̀mu wọn. A sì sọ fún wọn pé: “Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà ìlú wọlé ní olùdáwọ́tẹ-orúnkún.” A tún sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà ní ọjọ́ Sabt.” A sì gba àdéhùn tó nípọn lọ́wọ́ wọn.
Les exégèses en arabe:
فَبِمَا نَقۡضِهِم مِّيثَٰقَهُمۡ وَكُفۡرِهِم بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَقَتۡلِهِمُ ٱلۡأَنۢبِيَآءَ بِغَيۡرِ حَقّٖ وَقَوۡلِهِمۡ قُلُوبُنَا غُلۡفُۢۚ بَلۡ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَيۡهَا بِكُفۡرِهِمۡ فَلَا يُؤۡمِنُونَ إِلَّا قَلِيلٗا
Nítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn, àti ṣíṣàìgbàgbọ́ wọn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu, àti pípa tí wọ́n ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́ àti wíwí tí wọ́n ń wí pé: “Ọkàn wa ti di.” - rárá, Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn ni nítorí àìgbàgbọ́ wọn. - Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn).
Les exégèses en arabe:
وَبِكُفۡرِهِمۡ وَقَوۡلِهِمۡ عَلَىٰ مَرۡيَمَ بُهۡتَٰنًا عَظِيمٗا
Àti nítorí àìgbàgbọ́ wọn àti ọ̀rọ̀ wọn lórí Mọryam ní ti ìbànilórúkọjẹ́ ńlá (Allāhu tún fi èdídí dí ọkàn wọn).
Les exégèses en arabe:
وَقَوۡلِهِمۡ إِنَّا قَتَلۡنَا ٱلۡمَسِيحَ عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ رَسُولَ ٱللَّهِ وَمَا قَتَلُوهُ وَمَا صَلَبُوهُ وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمۡۚ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُۚ مَا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٍ إِلَّا ٱتِّبَاعَ ٱلظَّنِّۚ وَمَا قَتَلُوهُ يَقِينَۢا
Àti nítorí ọ̀rọ̀ wọn (yìí): “Dájúdájú àwa pa Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam Òjíṣẹ́ Allāhu.” Wọn kò pa á, wọn kò sì kàn án mọ́ igi àgbélébùú, ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.¹ Dájúdájú àwọn tó yapa-ẹnu lórí rẹ̀, kúkú wà nínú iyèméjì lórí rẹ̀; kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀ àfi títẹ̀lé àbá dídá. Wọn kò pa á ní ti àmọ̀dájú.
1. Kíyè sí ìyàtọ̀ pàtàkì tó wà láààrin awẹ́ gbólóhùn méjì yìí:
Ìkíní “ وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمْۚ” ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “وَلَكِنْ أُلْقِيَ شَبَهُهُ عَلَى غَيْرِهِ لهم” “ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.” Ìyẹn ni pé, àwọn ọ̀tá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, wọ́n kan ẹnì kan mọ́ igi àgbélébùú, wọ́n sì pa onítọ̀ún sórí igi àgbélébùú nítorí pé, Allāhu ti gbé àwòrán àti ìrísí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - wọ ẹni tí ó gba ikú Ànábì ‘Īsā kú. Onítọ̀ún gan-an ni wọ́n kàn mọ́ igi àgbélébùú, kì í ṣe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Èyí sì ni ète ti Allāhu tí Ó fi gba Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ìdí sì nìyí tí àwọn ọ̀tá rẹ̀ fi wà nínú iyèméjì nípa ta gan-an ni wọ́n kàn mọ́ igi àgbélébùú nítorí pé, ìrísí àwọn méjèèjì ló jọra wọn, ohùn àwọn méjèèjì kò jọra wọn rárá.
Síwájú sí i, ẹ̀kọ́ nípa mọfọ́lọ́jì èdè Lárúbáwá (ìyẹn ‘ilmu-ssọrf) fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọ̀rọ̀-orúkọ fún “شُبِّهَ” tó jẹyọ pẹ̀lú háràfí “lām” nínú awẹ́ gbólóhùn “ وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمْۚ” jẹ́ “شَبَهٌ” (ṣabahun / ṣabah) tàbí “شِبْهٌ” (ṣibhun / ṣibh) - ìtúmọ̀ “ìjọra / àfijọ. Àti pé àkòónú “شَبَهٌ”/ “شِبْهٌ” (ṣabahun / ṣibhun) nígbà náà ni pé, wọ́n ń lò ó fún n̄ǹkan méjì tó jẹ́ oríṣìí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àmọ́ tí wọ́n jọra wọn ní àwòrán. Ìtúmọ̀ yìí sì ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó pilẹ̀ lórí àwọn háràfí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí “ش ب ه” ní nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ẹ wo àwọn àyè náà; sūrah al-Baƙọrah; 2:25, sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:7, sūrah al-’Ani‘ām; 6: 99 àti 141, àti sūrah as-Zumọr; 39:23.
Ìkejì, “وَلَكِنْ شُبِّهَ عَلَيْهِمْ” ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “وَلَكِنِ اشْتُبِهَ عَلَيْهِمْ ” “ṣùgbọ́n a fi rú wọn lójú / ṣùgbọ́n a dà á rú mọ́ wọn lójú”. Ìyẹn sì kọ́ ni al-Ƙur’ān sọ. Wòóore, ẹ̀kọ́ nípa mọfọ́lọ́jì èdè Lárúbáwá (‘ilmu-ssọrf) tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọ̀rọ̀-orúkọ fún “شُبِّهَ” tó jẹyọ pẹ̀lú háràfí “ ‘alā” nínú gbólóhùn yìí jẹ́ “شُبْهَةٌ” (ṣubhatun / ṣubhah) – ìtúmọ̀: “ìrújú / rújúrújú”. Àmọ́ sá, “ìjọra” máa ń yọrí sí “ìrújú” nígbà tí kò bá sí “àmọ̀dájú”.
Àkíyèsí kejì: Gbogbo tírà tafsīr tó sọ̀rọ̀ lórí “وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمْ” “ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.” l’ó mú ọ̀rọ̀ wá lórí bí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ṣe gbé àwòrán ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - wọ ẹnì kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Kódà wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà wá ni láti ọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -, gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè rí i kà nínú tafsīr Zādu-l-Mọsīr. Ẹni tí kò bá ní ìmọ̀ nípa ipò Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì - nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ al-Ƙur’ān tàbí ẹni tí kò bá ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ hadīth l’ó lè pe ìtàn náà ní ìtàn ’Isrọ̄’īliyāt
Les exégèses en arabe:
بَل رَّفَعَهُ ٱللَّهُ إِلَيۡهِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمٗا
bí kò ṣe pé Allāhu gbé e wá sókè lọ́dọ̀ Rẹ̀ ni. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.¹
1. Āyah 157 àti 158 yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah tí ó sọ ìjọ Ahmadiyyah Ƙọ̄diyaniyyah tàbí Lahọ̄riyyah) di ìjọ kèfèrí. Ìdí ni pé, ìgbàgbọ́ ìjọ Ahmadiyyah ni pé, wọn kan ‘Īsā ọmọ Mọryam mọ́ igi àgbélébùú - kí ọlà Allāhu máa bá a -, àmọ́ kò kú sí orí rẹ̀. Ìjọ Ahmadiyyah sì tún gbà pé ‘Īsā ọmọ Mọryam sá àsálà wá sí ilẹ̀ India. Ó fẹ́ ìyàwó níbẹ̀. Ó kú síbẹ̀. Wọ́n sì sin ín síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìjọ Ahmadiyyah gbà pé ẹni tí ó padà wá sáyé lábẹ́ ìpadàbọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam kò jẹ́ ẹnì kan bí kò ṣe mirza Ghulam Ahmad, olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah.
Ọ̀nà tí èyí sì gbà ṣẹlẹ̀ nìyí nínú ìtọ́kasí wọn: “The word of God which I set out at some places in my book, the Baraheen Ahmadiyya explains how God Almighty made me Isa Son of Mary. In that book God first named me Mary and then disclosed that God had breathed His spirit into this Mary and said that after the breathing of this spirit my status as Mary was converted into my status as Isa, and thus Isa having been born of Mary was called Son of Mary.” Ìtúmọ̀: Mirza Ghulam Ahmad wí pé “Ọ̀rọ̀ Allāhu tí mo mú jáde láti inú ìwé mi, Baraheen Ahmadiyya, ó ń ṣe àlàyé ọ̀nà tí Allāhu gbà sọ mí di ‘Īsā ọmọ Mọryam. Nínú ìwé yẹn, Allāhu kọ́ sọ mí ní Mọryam. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi hàn mí pé Allāhu ti fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ sí Mọryam yìí lára. Ó sì sọ pé lẹ́yìn tí Òun ti fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ sí mi lára, ipò mi gẹ́gẹ́ bí Mọryam ti paradà báyìí, mo sì ti di ‘Īsā. Èyí rí bẹ́ẹ̀ fún wí pé bíbí tí Mọryam bí ‘Īsā ni wọ́n fi ń pè é ní ‘Īsā ọmọ Mọryam. [Ìwé Tadhkirah, òǹkọ̀wé: = = (Ahmadi) Muhammad Zafrullah Khan; ojú ewé: 369.] Ibi dandan Allāhu kí ó máa bá òpùrọ́ yìí.
Les exégèses en arabe:
وَإِن مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ إِلَّا لَيُؤۡمِنَنَّ بِهِۦ قَبۡلَ مَوۡتِهِۦۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يَكُونُ عَلَيۡهِمۡ شَهِيدٗا
Kò sì níí sí ẹnì kan nínú àwọn onítírà (láyé nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam bá sọ̀kalẹ̀ padà láti ojú sánmọ̀) àfi kí ó gbà á gbọ́ ní òdodo ṣíwájú ikú rẹ̀.¹Ní Ọjọ́ Àjíǹde, ó sì máa jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn.
1. Àgbọ́yé méjì ni àwọn tafsīr mú wá lórí arọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ tó jẹyọ nínú àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ yìí “قَبْلَ مَوْتِهِۦۖ”.
Àgbọ́yé kìíní ni pé, arọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Nípa bẹ́ẹ̀ ìtúmọ̀ āyah náà máa lọ báyìí pé: “Kò sì níí sí ẹnì kan nínú àwọn onítírà (láyé nígbà tí ‘Īsā bá sọ̀kalẹ̀ padà láti ojú sánmọ̀) àfi kí ó gba ‘Īsā ọmọ Mọryam gbọ́ ní òdodo ṣíwájú ikú ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -.” Èyí sì máa jẹ́ oore ìronúpìwàdà àti ìpadà sínú ẹ̀sìn ’Islām fún ọ̀wọ́ àwọn tí ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - bá padà bá láyé nínú àwọn tó ti sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - di olúwa àti olùgbàlà wọn.
Àgbọ́yé kejì ni pé, arọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún ikú àwọn onítírà tó ń pọ́kàkà ikú. Nípa bẹ́ẹ̀ ìtúmọ̀ āyah náà máa lọ báyìí pé: “Kò sì níí sí ẹnì kan nínú àwọn onítírà àfi kí ó gba ‘Īsā ọmọ Mọryam gbọ́ ní òdodo ṣíwájú ikú àwọn onítírà náà lásìkò ìpọ́kàkà ikú.”
Àlàyé tí àwọn onímọ̀ Tafsīr mú wá fún àgbọ́yé kejì yìí ni pé, àwọn mọlāika máa fi àwòrán ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - han ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ kú láti fojú rí àṣìṣe rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ó máa ronú pìwàdà lásìkò náà, àmọ́ kò sí ìronúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ òdodo tó wúlò lásìkò ìpọ́kàkà ikú.
Àgbọ́yé méjèèjì wọ̀nyí kúkú dára, àmọ́ nígbà tí pọ́n-na (ṣubhah) bá jẹyọ nínú āyah al-Ƙur’ān, ọ̀nà kan pàtàkì nínú ìyọnípọ́n-na ni lílo hadīth Ànábì. Àmọ́, ṣíwájú kí á tó lè lo hadīth kan kan fún ìyọnípọ́n-na, al-Ƙur’ān fúnra rẹ̀ ni ohun àkọ́kọ́ tí a máa lò. Èyí máa ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ wíwo sàkánì tí ọ̀rọ̀ onípọ́n-na náa ti jẹyọ. A máa wòye sí ọ̀rọ̀ tí ń bá á bọ̀ níwájú (tàbí) àti ọ̀rọ̀ tí ó tún mú wá lẹ́yìn rẹ̀ (bí ó bá wà). Kódà ìwòye yìí lè ṣẹlẹ̀ nígbà mìíràn nínú āyah kan náà. Nítorí náà, lórí āyah yìí, àgbọ́yé tó gbéwọ̀n jùlọ ni àgbọ́yé kìíní. Èyí tí ó ń fi rinlẹ̀ pé ikú ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - lópin ayé ni arọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, ọ̀rọ̀ tó jẹyọ nínú āyah 157 ń sọ nípa pé àwọn kan ń sọ pé àwọn pa ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, àwọn kàn án mọ́ igi àgbélébùú. Ó sì ti kú. Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - sì sọ pé ọ̀rọ̀ náà kò rí bẹ́ẹ̀ rárá bí kò ṣe pé Òun gbé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - wá sókè lọ́dọ̀ Òun ni. Òkodoro ọ̀rọ̀ náà sì máa hàn sí gbogbo ayé ní àsìkò ìpadà-sọ̀kalẹ̀ rẹ̀ láti ojú sánmọ̀. Ìyẹn sì ni àlàyé tó jẹyọ nínú àwọn āyah 158 àti 159.
Síwájú sí i, kalmọh “رفع” (rọfa‘a) lè túmọ̀ sí àgbéga tẹ̀mí (ìyẹn, àgbéga ipò gẹ́gẹ́ bí èyí tó jẹyọ nínú sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:176 àti sūrah Mọryam; 19:57) tàbí kí ó túmọ̀ sí àgbéga tara (ìyẹn gbígbé ara kúrò láti àyè ìsàlẹ̀ sí àyè òkè gẹ́gẹ́ bí èyí tó jẹyọ nínú sūrah Fātir; 35:10). Àmọ́ kò ní tàbí-ṣùgbọ́n nínú mọ́ pé, ìgbàkígbà tí harafi “إلى” bá ti tẹ̀lé “رفع”, àgbéga tara l’ó máa jẹ́ ìtúmọ̀ rẹ̀. Wàyí, níwọ̀n ìgbà tí ó sì ti jẹ́ pé òkè sánmọ̀ ni pàápàá bíbẹ Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - wà, ìdí nìyí tí “بَل رَّفَعَهُ ٱللَّهُ إِلَيْهِۚ” fi túmọ̀ sí “kò rí bẹ́ẹ̀, Allāhu gbé ‘Īsā ọmọ Mọryam wá sókè sínú sánmọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ ni.”
Bí ẹnì kan bá wá ń retí kalmọh “السماء” (sánmọ̀) nínú āyah náà ṣíwájú kí ó tó lè gbàgbọ́ pé nínú sánmọ̀ ni Allāhu gbé ‘Īsā ọmọ Mọryam wá ní ẹ̀mí àti ara, bóyá ni onítọ̀ún gbàgbọ́ pé sánmọ̀ ni pàápàá bíbẹ Allāhu gan-an wà. Lórí èyí, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:18.
Nítorí náà, gbogbo Mùsùlùmí onisunnah l’ó mọ̀ ní àmọ̀dájú pé, òkè sánmọ̀ keje ni Allahu wà nítorí pé, sánmọ̀ yìí náà ni Ànábì wa Muhammad - kí ọlà Allāhu máa bá a - gùn lọ láti lọ gba ìrun wákàtí márààrùn wá lọ́dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - lásìkò ìrìn òru àti ìgun-sánmọ̀ gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi rinlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ sūrah al-’Isrọ̄’.
Kíyè sí i! Tòhun ti bí àìgbàgbọ́ Fir‘aon ṣe gbópọn tó, ó kúkú gbà pé sánmọ̀ ni Allāhu wà. Ó sì bẹ Hāmọ̄n ní ilé gíga fíofío kọ́. Ó fẹ́ yọjú wo Allāhu! (sūrah al-Ƙọsọs; 28:38). Nítorí náà, inú sánmọ̀ ni Allāhu gbé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - wá. Ó sì wà níbẹ̀, kì í ṣe ní ti ìgbésí ayé ti ayé, àmọ́ ní ti ìgbésí ayé tó bá inú sánmọ̀ mu, ìyẹn irú ìgbésí ayé tàwọn mọlāika, tí wọn kì í jẹun, tí wọn kì í mu, tí wọn kì í ṣẹ̀gbin, tí wọn kì í dàgbà sí i, tí wọn kì í gbó lára àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àti pé nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ tí ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - máa ṣe nígbà tí ó bá padà dé láti ojú sánmọ̀ níbi rírún àgbélébùú, pípa ẹlẹ́dẹ̀, kíkọ gbogbo ẹ̀sìn àfi ẹ̀sìn ’Islām nìkan ṣoṣo, pípa Mọsīh Dajjāl àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ l’ó máa mú kí àwọn onítírà àsìkò náà ronú pìwàdà sínú ẹ̀sìn ’Islām.
Kíyè sí i, ìpadàbọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - lópin ayé kì í ṣe ní àwòrán ipò Ànábì, bí kò ṣe ní àwòrán ọmọlẹ́yìn Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti adájọ́ onídéédé nítorí pé, kò níí sí Ànábì titun kan kan mọ́ lẹ́yìn Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àti pé, ìjọ Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nìkan l’ó wà láyé báyìí, nítorí náà Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ẹni tí kádàrá rẹ̀ jẹmọ́ ìpadàbọ̀ sáyé kò níí wà nípò Ànábì lásìkò náà bí kò ṣe pé, ó máa wà nípò ọ̀kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn Ànábì àsìkò yìí. Ìdí sì nìyí tí kò fi níí fi tírà kan dájọ́ lẹ́yìn al-Ƙur’ān. Pẹ̀lú àlàyé yìí, àgbọ́yé kejì kò lè rọ́nà lọ.
Àmọ́ sá, tí ẹnì kan bá bá àgbọ́yé kejì yìí lọ, kò la àtakò lọ níwọ̀n ìgbà tí onítọ̀ún kò bá ti tako ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - láti ojú sánmọ̀ l’ópin ayé nítorí pé, níwọ̀n ìgbà tí hadīth tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ti fi rinlẹ̀, aláìgbàgbọ́ tí ó máa jẹ̀bi ikú lábẹ́ òfin ’Islām ni ẹnikẹ́ni nínú àwọn mùsùlùmí tó bá tako ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - láti ojú sánmọ̀ l’ópin ayé. Wòóore! Gbogbo òǹkà arọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ “ẹyọ ẹnì kẹta” ìyẹn “هـُ” tó jẹyọ láti inú āyah 157 títí dé 159 nínú sūrah yìí jẹ́ méjìlá. Àyè kan péré l’ó ti ń tọ́ka sí Allāhu, ìyẹn sì ni kalmọh “إِلَيْهِ”, ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni mọ́kànlá yòókù ń tọ́ka sí nítorí pé, ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìkan ni kókó nínú àwọn āyah náà. Ìwòyesí yìí tún jẹ́ àtìlẹ́yìn fún àgbọ́yé kìíní láti fi rinlẹ̀ pé “قَبْلَ مَوْتِهِۦۖ” ń túmọ̀ sí “ṣíwájú ikú ‘Isā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - lópin ayé.
Les exégèses en arabe:
فَبِظُلۡمٖ مِّنَ ٱلَّذِينَ هَادُواْ حَرَّمۡنَا عَلَيۡهِمۡ طَيِّبَٰتٍ أُحِلَّتۡ لَهُمۡ وَبِصَدِّهِمۡ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ كَثِيرٗا
Nítorí àbòsí láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n di yẹhudi, A ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa kan ní èèwọ̀ fún wọn, èyí tí wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn (tẹ́lẹ̀. A ṣe é ní èèwọ̀ fún wọn sẹ́) nípa bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu.
Les exégèses en arabe:
وَأَخۡذِهِمُ ٱلرِّبَوٰاْ وَقَدۡ نُهُواْ عَنۡهُ وَأَكۡلِهِمۡ أَمۡوَٰلَ ٱلنَّاسِ بِٱلۡبَٰطِلِۚ وَأَعۡتَدۡنَا لِلۡكَٰفِرِينَ مِنۡهُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا
Àti gbígbà tí wọ́n ń gba owó èlé, tí A sì ti kọ̀ ọ́ fún wọn, àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ dúkìá àwọn ènìyàn lọ́nà èrú. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Les exégèses en arabe:
لَّٰكِنِ ٱلرَّٰسِخُونَ فِي ٱلۡعِلۡمِ مِنۡهُمۡ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَ يُؤۡمِنُونَ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ وَمَآ أُنزِلَ مِن قَبۡلِكَۚ وَٱلۡمُقِيمِينَ ٱلصَّلَوٰةَۚ وَٱلۡمُؤۡتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ أُوْلَٰٓئِكَ سَنُؤۡتِيهِمۡ أَجۡرًا عَظِيمًا
Ṣùgbọ́n àwọn tó jindò nínú ìmọ̀ nínú wọn àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, wọ́n gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, (wọ́n tún gbàgbọ́ nínú àwọn mọlāika) tó ń kírun, àtí àwọn tó ń yọ Zakāh àti àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní ẹ̀san ńlá.
Les exégèses en arabe:
۞ إِنَّآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ كَمَآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ نُوحٖ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ مِنۢ بَعۡدِهِۦۚ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَٱلۡأَسۡبَاطِ وَعِيسَىٰ وَأَيُّوبَ وَيُونُسَ وَهَٰرُونَ وَسُلَيۡمَٰنَۚ وَءَاتَيۡنَا دَاوُۥدَ زَبُورٗا
Dájúdájú Àwa (fi ìmísí) ránṣẹ́ sí ọ gẹ́gẹ́ bí A ṣe fi ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh àti àwọn Ànábì (mìíràn) lẹ́yìn rẹ̀. A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀), àti (Ànábì) ‘Īsā, ’Ayyūb, Yūnus, Hārūn àti Sulaemọ̄n. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr.
Les exégèses en arabe:
وَرُسُلٗا قَدۡ قَصَصۡنَٰهُمۡ عَلَيۡكَ مِن قَبۡلُ وَرُسُلٗا لَّمۡ نَقۡصُصۡهُمۡ عَلَيۡكَۚ وَكَلَّمَ ٱللَّهُ مُوسَىٰ تَكۡلِيمٗا
Àti àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A ti sọ ìtàn wọn fún ọ ṣíwájú pẹ̀lú àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ. Allāhu sì bá (Ànábì) Mūsā sọ̀rọ̀ tààrà.
Les exégèses en arabe:
رُّسُلٗا مُّبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى ٱللَّهِ حُجَّةُۢ بَعۡدَ ٱلرُّسُلِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمٗا
(A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí) àwọn Òjíṣẹ́ (ti jíṣẹ́). Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Les exégèses en arabe:
لَّٰكِنِ ٱللَّهُ يَشۡهَدُ بِمَآ أَنزَلَ إِلَيۡكَۖ أَنزَلَهُۥ بِعِلۡمِهِۦۖ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَشۡهَدُونَۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدًا
Ṣùgbọ́n Allāhu ń jẹ́rìí sí ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àwọn mọlāika náà ń jẹ́rìí (sí i). Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ قَدۡ ضَلُّواْ ضَلَٰلَۢا بَعِيدًا
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n kúkú ti ṣìnà ní ìṣìnà tó jìnnà.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَظَلَمُواْ لَمۡ يَكُنِ ٱللَّهُ لِيَغۡفِرَ لَهُمۡ وَلَا لِيَهۡدِيَهُمۡ طَرِيقًا
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣàbòsí, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fi ojú-ọ̀nà kan mọ̀ wọ́n.
Les exégèses en arabe:
إِلَّا طَرِيقَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٗا
Àyàfi ojú-ọ̀nà iná Jahanamọ. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.¹
1. Èyí wà fún ẹni tí ó bá kú sínú àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ìkéde ẹ̀sìn ’Islām ti dé etí ìgbọ́ rẹ̀. Bákan náà, ẹ wo āyah 48 àti āyah 116.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدۡ جَآءَكُمُ ٱلرَّسُولُ بِٱلۡحَقِّ مِن رَّبِّكُمۡ فَـَٔامِنُواْ خَيۡرٗا لَّكُمۡۚ وَإِن تَكۡفُرُواْ فَإِنَّ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Òjíṣẹ́ náà ti dé ba yín pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, kí ẹ gbà á gbọ́ l’ó dára jùlọ fún yín. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَا تَغۡلُواْ فِي دِينِكُمۡ وَلَا تَقُولُواْ عَلَى ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡحَقَّۚ إِنَّمَا ٱلۡمَسِيحُ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ رَسُولُ ٱللَّهِ وَكَلِمَتُهُۥٓ أَلۡقَىٰهَآ إِلَىٰ مَرۡيَمَ وَرُوحٞ مِّنۡهُۖ فَـَٔامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦۖ وَلَا تَقُولُواْ ثَلَٰثَةٌۚ ٱنتَهُواْ خَيۡرٗا لَّكُمۡۚ إِنَّمَا ٱللَّهُ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ سُبۡحَٰنَهُۥٓ أَن يَكُونَ لَهُۥ وَلَدٞۘ لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا
Ẹ̀yin onítírà, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà nínú ẹ̀sìn yín, kí ẹ sì má sọ ohun kan nípa Allāhu àfi òdodo. Òjíṣẹ́ Allāhu ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni (Ó fi dá Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam). Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ yé sọ mẹ́ta (lọ́kan) mọ́. Kí ẹ jáwọ́ níbẹ̀ ló jẹ́ oore fún yín. Allāhu nìkan ni Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Ó mọ́ tayọ kí Ó ní ọmọ. TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Alámòjúútó.¹
1. Kíyè sí i, Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - fún ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní orúkọ mẹ́rin wọ̀nyí nínú āyah yìí: “mọsīh”, “rọsūlullāh”, “kalmọtu-llāh” àti “rūhu-llāh”. Àwọn nasọ̄rọ̄ sì ń tìràn mọ́ “mọsīh”, “kalmọtu-llāh” àti “rūhu-llah” bí ẹni pé orúkọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí túmọ̀ sí pé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni olùgbàlà, ọlọ́run, ẹlẹ́dàá àti olúwa. Èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá.
Ní àkọ́kọ́ náà, nínú èdè Lárúbáwá kò sí èyí tí ó túmọ̀ sí olùgbàlà tàbí ọlọ́run tàbí ẹlẹ́dàá tàbí olúwa nínú àwọn orúkọ àti ìròyìn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà tí al-Ƙur’ān fún ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -.
Ìtúmọ̀ “mọsīh” nínú èdè Lárúbáwá nìwọ̀nyí: ẹni tí kò ní kòjẹ̀gbin, alárìnká tí kò ní ibùgbé kan ní pàtó, ẹni tí wọ́n fi òróró pa lára, ẹni tí ó máa ń fọwọ́ àdúà pa aláìlera láti tọrọ ìwòsàn fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́hun, olódodo, ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ rẹ́.
Ní ti “kalmọtu-llāh”, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “ọ̀rọ̀ Allāhu / ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun”. Ọ̀rọ̀ Allāhu ni ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - nítorí pé, Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - ṣẹ̀dá rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn “kun fayakūn”. Ìtúmọ̀ yìí sì ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi rinlẹ̀ fúnra Rẹ̀ nínú sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:45, 47 àti 59 pẹ̀lú sūrah Mọryam; 19:35. Kódà pípè tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - pe ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní “kalmọtu-llāh” jẹ́ àpọ́nlé fún un ni nítorí pé, kò wúlẹ̀ sí ẹ̀dá kan, yálà n̄ǹkan ẹlẹ́mìí tàbí aláìlẹ́mìí, àfi kí ó jẹ́ “kalmọtu-llāh”. Ìyẹn ni pé, gbogbo ẹ̀dá tí Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀ l’Ó sọ “Jẹ́ bẹ́ẹ̀” fún ṣíwájú kí irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ tó máa bẹ. Allāhu nìkan ṣoṣo l’Ó sì ni “Jẹ́ bẹ́ẹ̀”, kì í ṣe ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - tàbí ẹlòmíìràn.
Bákan náà, ní ti “rūhu-llāh”, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “ẹ̀mí Allāhu / ẹ̀mí Ọlọ́hun ”. Ẹ̀mí Allāhu ni ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -nítorí pé, Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀ sínú ikùn ìyá rẹ̀, Ó sì ní kí mọlāika Jibrīl - kí ọlà Allāhu máa bá a - wá fẹ́ atẹ́gùn ẹ̀mí mímọ́ sára ìyá rẹ̀ nítorí kí ‘Īsā lè di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí. Àti ẹ̀mí mímọ́ àti ẹ̀mí àìmọ́ tàbí ẹ̀mí òkùnkùn, Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá ìkíní kejì wọn. Kì í ṣe Èṣù. Èṣù kò dá ohun kan kan. Èṣù gan-an fúnra rẹ̀, ẹ̀dá kan nínú àwọn ẹ̀dá tí Allāhu ṣẹ̀dá l’ó wà. Wòóore, fúnra Allāhu l’Ó kúkú fẹ́ atẹ́gùn ẹ̀mí mímọ́ kan sára Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a - nígbà tí Ó mọ ọ́n kalẹ̀ tán ní ọ̀bọrọgidi gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah Sọ̄d; 38:72 àti sūrah al-Hijr; 15:29. Ìyẹn kò sì sọ Ànábì Ādam di olúwa lẹ́yìn Allāhu. Báwo ni ‘Īsā ọmọ Mọryam tí wọ́n fi atẹ́gùn ẹ̀mí rẹ̀ rán mọlāika Jibril ṣe máa wá di olúwa? Rárá, kò lè di olúwa. Tí Allāhu bá wá pe ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní “rūhu-llāh” àpọ́nlé ni fún un nítorí pé, kò sí ẹ̀dá ẹlẹ́mìí kan níbikíbi àfi kí ó jẹ́ pé “rūhu-llāh” ni òun náà.
Síwájú sí i, lílo “Ọlọ́hun” gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán fún ẹ̀dá kan nínú àwọn ẹ̀dá Ọlọ́hun kò sọ n̄ǹkan náà di ọlọ́hun tàbí olúwa tàbí ẹlẹ́dàá tàbí olùgbàlà, àmọ́ àpọ́nlé ni fún ẹ̀dá náà.
Wòye sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí kí ó tún lè yé ọ yékéyéké: Ẹ̀mí wo ni Ọlọ́hun fi sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí? Ẹ̀mí wo ni Ọlọ́hun fi sọ Mọryam di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí? Ẹ̀mí wo ni Ọlọ́hun fi sọ Èṣù di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí? Èsì kan náà ni gbogbo wọn ní. Èsì náà sì ni pé, “Ẹ̀mí Ọlọ́hun “rūhu-llāh” ni.” Èyí tí ó túmọ̀ sí pé Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá ẹ̀mí tó wà lára ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.
Síwájú sí i, nínú al-Ƙur’ān, Allāhu pe ràkúnmí kan ní “nọ̄ƙọtu-llāh”, ìtúmọ̀ “ràkúnmí Ọlọ́hun”. Èyí kò sì túmọ̀ sí pé, “ràkúnmí ni Ọlọ́hun” bí kò ṣe pé ràkúnmí ìyanu tí ó jáde tòhun ti ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti inú àpáta. Àti pé Allāhu fi ṣe àpọ́nlé fún orúkọ ràkúnmí náà ni.
Bákan náà, nínú al-Ƙur’ān, Allāhu pe ilé kan ní “Baetu-llāh”, ìtúmọ̀ “ilé Ọlọ́hun”. Èyí kò sì túmọ̀ sí pé “ilé ni Ọlọ́hun” bí kò ṣe pé ilé tí àwọn ẹ̀dá ti ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun, ìyẹn sì ni mọ́sálásí. Àti pé Allāhu fi ṣe àpọ́nlé fún orúkọ ilé náà ni.
Bákan náà, nínú al-Ƙur’ān, Allāhu pe ẹ̀dá kan ní “’abdullāh”, ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun”. Èyí kò sì túmọ̀ sí pé “ẹrú ni Ọlọ́hun” bí kò ṣe pé ẹ̀dá tí ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun, tí ó sì wà lábẹ́ òfin Ọlọ́hun pẹ̀lú ìjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀ pátápátá fún Ọlọ́hun. Àti pé Allāhu fi ṣe àpọ́nlé fún ẹ̀dá náà ni nítorí pé, gbogbo wa ni ẹrú Ọlọ́hun, a fẹ́ tàbí a kọ̀. Báwo wá ni “kalmọtu-llāh” ṣe máa túmọ̀ sí “kalmọh ni Ọlọ́hun / ọ̀rọ̀ ni Ọlọ́hun”? Àní sẹ́ báwo ni “rūhu-llāh” ṣe máa túmọ̀ sí “rūhu ni Ọlọ́hun / ẹ̀mí ni Ọlọ́hun”? Ìròrí àwọn nasọ̄rọ̄ lásán ni ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ náà, tí wọ́n ti mú wọ inú ìwé wọn pé “Láti ìṣẹ̀ṣẹ̀kọ́ṣe ni ọ̀rọ̀ ti wà. Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọlọ́run sì ni ọ̀rọ̀ náà.” Láéláé, Ọlọ́hun àwa mùsùlùmí kì í ṣe ọ̀rọ̀. Ọlọ́hun wa kì í ṣe ẹ̀mí. Nítorí náà, kò sí ẹ̀dá kan àfi kí ó di bíbẹ nígbà tí Allāhu bá sọ pé “Jẹ́ bẹ́ẹ̀” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Bákan náà, mọ̀ dájú pé àpọ́nlé ni Mọ́là, Haúsá l’a Haúsá ń jẹ́. Nínú àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ (noun phrase), ìgbàkígbà tí Allāhu bá fi orúkọ ara Rẹ̀ ṣe ẹ̀yán-ajórúkọ (nominal modifier) fún ọ̀rọ̀-orúkọ kan ìyẹn ni pé, ìgbàkígbà tí Allāhu bá ṣe àfitì ẹ̀dá kan nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ tì sọ́dọ̀ ara Rẹ̀, bí irú èyí “kalmọtu-llāh, rūhu-llāh, nāƙọtu-llāh, baetu-llāh, kitābu-llāh, ‘abdu-llāh, nabiyyu-llāh, rọsūlu-llāh” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, yàtọ̀ sí pé Allāhu fi ṣe àpọ́nlé fún ọ̀rọ̀-orúkọ agbẹ̀yán náà, kò tún ní ìtúmọ̀ mìíràn bí kò ṣe láti fi “ìbátan ìní” hàn (possessive genitive).
Nínú àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn, ẹ̀hun oníbàátan ìní (possessive genitive construction) ni ìtúmọ̀ tó máa ń wà níbikíbi tí Allāhu bá ti lo orúkọ ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán-ajórúkọ nínú àpólà orúkọ, kì í sì ní ìtúmọ̀ alálàjẹ́ (appositive).
Pẹ̀lú àlàyé yìí, ìtúmọ̀ “kalmọtu-llāh” ni “kalmọh ti Allāhu / kalmọh tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ kalmọh nítorí pé, kalmọh kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu”.
Rūhu-llāh, “rūhu ti Allāhu / rūhu tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ rūhu nítorí pé, rūhu kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu”. Nāƙọtu-llāh “nāƙọh ti Allāhu / nāƙọh tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ nāƙọh nítorí pé, nāƙọh kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu”. Baetu-llāh, “baeutu ti Allāhu / baetu tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ baetu nítorí pé, baetu kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Gẹ́gẹ́ bí a sì ti sọ síwájú pé àpọ́nlé láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó jẹ́ fún ẹ̀dá kan nígbàkígbà tí Allāhu bá fi orúkọ ara Rẹ̀ ṣe ẹ̀yán ajórúkọ fún un. Nítorí náà, kò wúlẹ̀ sí kiní kan láyé àti lọ́run, yálà ipò ọlá tàbí ipò ìjọba, àfi kí ó jẹ́ ohun ìní fún Allāhu nítorí pé, ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ gbogbo wọn.
Báwo wá ni Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá ṣe lè jẹ́ ohun ìní, tí ohun ìní sì máa tún jẹ́ Allāhu, Ọlọ́hun Olúwa? Kò lè ṣẹlẹ̀ láéláé. Nítorí náà, èyíkéyìí orúkọ ipò tí Allāhu bá lò fún ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, kò fi ibì kan kan túmọ̀ sí pé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni olúwa tàbí olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu. Ṣebí àràkárà tí alágbẹ̀dẹ bá fi irin dá, kò lè sọ irin di alágbẹ̀dẹ.
Les exégèses en arabe:
لَّن يَسۡتَنكِفَ ٱلۡمَسِيحُ أَن يَكُونَ عَبۡدٗا لِّلَّهِ وَلَا ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ ٱلۡمُقَرَّبُونَۚ وَمَن يَسۡتَنكِفۡ عَنۡ عِبَادَتِهِۦ وَيَسۡتَكۡبِرۡ فَسَيَحۡشُرُهُمۡ إِلَيۡهِ جَمِيعٗا
Mọsīh kò kọ̀ láti jẹ́ ẹrú fún Allāhu. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn mọlāika tí wọ́n súnmọ́ Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti jọ́sìn fún Un, tí ó tún ṣègbéraga, (Allāhu) yóò kó wọn jọ papọ̀ pátápátá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Les exégèses en arabe:
فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَيُوَفِّيهِمۡ أُجُورَهُمۡ وَيَزِيدُهُم مِّن فَضۡلِهِۦۖ وَأَمَّا ٱلَّذِينَ ٱسۡتَنكَفُواْ وَٱسۡتَكۡبَرُواْ فَيُعَذِّبُهُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا وَلَا يَجِدُونَ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا
Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ó sì máa ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Ní ti àwọn tó bá sì kọ̀ (láti jọ́sìn fún Allāhu), tí wọ́n sì ṣègbéraga, (Allāhu) yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro. Wọn kò sì níí rí alátìlẹ́yìn tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدۡ جَآءَكُم بُرۡهَٰنٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكُمۡ نُورٗا مُّبِينٗا
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. A sì tún sọ ìmọ́lẹ̀ tó yanjú kalẹ̀ fún yín.
Les exégèses en arabe:
فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَٱعۡتَصَمُواْ بِهِۦ فَسَيُدۡخِلُهُمۡ فِي رَحۡمَةٖ مِّنۡهُ وَفَضۡلٖ وَيَهۡدِيهِمۡ إِلَيۡهِ صِرَٰطٗا مُّسۡتَقِيمٗا
Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu, tí wọ́n sì dúró ṣinṣin tì Í, Ó máa fi wọ́n sínú ìkẹ́ àti ọlá kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó sì máa fi wọ́n mọ ọ̀nà tààrà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Les exégèses en arabe:
يَسۡتَفۡتُونَكَ قُلِ ٱللَّهُ يُفۡتِيكُمۡ فِي ٱلۡكَلَٰلَةِۚ إِنِ ٱمۡرُؤٌاْ هَلَكَ لَيۡسَ لَهُۥ وَلَدٞ وَلَهُۥٓ أُخۡتٞ فَلَهَا نِصۡفُ مَا تَرَكَۚ وَهُوَ يَرِثُهَآ إِن لَّمۡ يَكُن لَّهَا وَلَدٞۚ فَإِن كَانَتَا ٱثۡنَتَيۡنِ فَلَهُمَا ٱلثُّلُثَانِ مِمَّا تَرَكَۚ وَإِن كَانُوٓاْ إِخۡوَةٗ رِّجَالٗا وَنِسَآءٗ فَلِلذَّكَرِ مِثۡلُ حَظِّ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۗ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ أَن تَضِلُّواْۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمُۢ
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè ìbéèrè, sọ pé: “Allāhu ń fún yín ní ìdájọ́ nípa ẹni tí kò ní òbí, kò sì ní ọmọ. Tí ènìyàn kan bá kú, tí kò ní ọmọ láyé, tí ó sì ní arábìnrin kan, ìdajì ni tirẹ̀ nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. (Arákùnrin) l’ó máa jẹ gbogbo ogún arábìnrin rẹ̀, tí kò bá ní ọmọ láyé. Tí arábìnrin bá sì jẹ́ méjì, ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ni tiwọn nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. Tí wọ́n bá sì jẹ́ arákùnrin (púpọ̀) lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ti ọkùnrin kan ni ìpín obìnrin méjì. Allāhu ń ṣe àlàyé fún yín kí ẹ má baà ṣìnà. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Sourate: AN-NISÂ’
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture