Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (3) Sourate: AN-NISÂ’
وَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا تُقۡسِطُواْ فِي ٱلۡيَتَٰمَىٰ فَٱنكِحُواْ مَا طَابَ لَكُم مِّنَ ٱلنِّسَآءِ مَثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَۖ فَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا تَعۡدِلُواْ فَوَٰحِدَةً أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۚ ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَلَّا تَعُولُواْ
Tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé nípa (fífẹ́) ọmọ òrukàn,¹ ẹ fẹ́ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ si yín nínú àwọn obìnrin; méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin.² Ṣùgbọ́n tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé, (ẹ fẹ́) ẹyọ kan tàbí ẹrúbìnrin yín. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ pé ẹ ò níí ṣàbòsí.
1. Bí àpẹ̀ẹrẹ, kí ẹni tí ó ń mójútó ọmọ òrukàn obìnrin nífẹ̀ẹ́ láti fẹ́ ọmọbìnrin náà lẹ́yìn tí ó bàlágà tán, àmọ́ ọkùnrin náà kọ̀ láti fún un ní sọ̀daàkí rẹ̀ nítorí pé, ó mọ bí ogún ọmọbìnrin náà ṣe tó ní iye.
2. Kíyè sí i, àgbọ́yé “méjì” ni pé “fẹ́ méjì”, àgbọ́yé “mẹ́ta” ni pé “fẹ́ mẹ́ta”, àgbọ́yé “mẹ́rin” sì ni pé, “fẹ́ mẹ́rin”. Àgbọ́yé ọ̀rọ̀ àsọpọ̀ “wa” tó sì jẹyọ láààrin “mọthnā wa thulātha wa rubā‘” ni “tàbí”. Ìyẹn ni pé, “fẹ́ méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin”. Níwọ̀n ìgbà tí o ò bá gbọ́ “méjì” yé sí “fẹ́ méjì papọ̀ ní ọjọ́ kan náà”, tí o ò gbọ́ “mẹ́ta” yé sí “fẹ́ mẹ́ta papọ̀ ní ọjọ́ kan náà”, tí o ò sí gbọ́ “mẹ́rin” yé sí “fẹ́ mẹ́rin papọ̀ ní ọjọ́ kan náà”, o ò gbọ́dọ̀ gbọ́ “mọthnā wa thulātha wa rubā‘” yé sí “fẹ́ mẹ́sàn-án” ìyẹn, nípasẹ̀ lílo ọ̀rọ̀-àsopọ̀ “àti” fún ṣíṣírò méjì, mẹ́ta àti mẹ́rin papọ̀ mọ́ra wọn. Má sì ṣe sọ̀rọ̀ ní ìsọ̀rọ̀ àwọn aláìmọ̀kan nípa sísọ pé, “mẹ́ ni Ọlọ́hun wí”. Wọ́n ń parọ́ mọ́ Allāhu ni. Allāhu kò sọ “mẹ́”. Àwọn ni ìyà “mẹ́” ń wù ú jẹ.
Bákan náà, má ṣe korò ojú sí fífẹ́ ìyàwó dé orí méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin fún ẹni tí ó fẹ́ máa gbé bùkátà púpọ̀.
Ọkọ lè jẹ̀bi ẹ̀sùn àìṣe déédé, kódà kó jẹ́ oníyàwó kan péré, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ ahun, aláìbìkátà tàbí alápámáṣiṣẹ́ ọkùnrin.
Wòóore! Pẹ̀lú āyah yìí, mẹ́rin lòpin òǹkà àpapọ̀ ìyàwó tó lè wà nípò ìyàwó fún mùsùlùmí ẹyọ kan. Òfin t’ó rọ̀ mọ́ òǹkà àpapọ̀ ìyàwó Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni sūrah al-’Ahazāb; 33: 50 - 52. Òfin náà ló fún Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ẹ̀tọ́ láti fẹ́ kọjá mẹ́rin. Kò dojú rú rárá. Al-hamdu lillāh. Láti ọ̀dọ̀ ọmọ Ṣihāb, dájúdájú ó gbọ́ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ fún ọkùnrin kan láti ìdìlé Thaƙīf tí ó gba ’Islām, tí ìyàwó rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́wàá ní àsìkò tí ó gba ’Islām pé, “Mú mẹ́rin nínú wọn, kí o sì kọ àwọn yòókù sílẹ̀.” (Muwattọ’u Imām Mọ̄lik, Musnad Ṣāfi‘iy, Sunan Baehaƙiy àti Sọhīhu bn Hibbān)
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (3) Sourate: AN-NISÂ’
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture