Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (48) Sourate: AN-NISÂ’
إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَغۡفِرُ أَن يُشۡرَكَ بِهِۦ وَيَغۡفِرُ مَا دُونَ ذَٰلِكَ لِمَن يَشَآءُۚ وَمَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَقَدِ ٱفۡتَرَىٰٓ إِثۡمًا عَظِيمًا
Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I.1 Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́.¹ Ẹni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti dá àdápa irọ́ (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
Ìyẹn ni ìdájọ́ ẹni tí ó kú sórí “aṣ-ṣirk” ẹbọ. Àmọ́ ẹni tí ó bá túúbá kúrò níbi ẹbọ ṣíṣe ṣíwájú ìpọ́kàkà ikú, tí ó sì ṣe ’Islām rẹ̀ dáradára, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - yóò ṣe àforíjìn fún un.
“Aṣ-ṣirk” ẹbọ ṣíṣe pín sí oríṣi méjì. Ìkíní: “aṣ-ṣirk al-’akbar” ẹbọ ńlá. Ẹbọ ńlá ni jíjọ́sìn fún ẹ̀dá kan tàbí pípe ẹ̀dá kan nínú àdúà lẹ́yìn Allāhu. Nítorí náà, ẹlẹ́bọ ńlá ni ẹni tí ó ń jọ́sìn fún ẹ̀dá. Ẹlẹ́bọ ńlá sì ni ẹni tí ó ń pe ẹ̀dá kan nínú àdúà rẹ̀ lẹ́yìn Allāhu. Bí àpẹ̀ẹrẹ, ẹbọ ńlá ni sísọ pé, “ní orúkọ Jésù”. Ìdájọ́ tó wà fún ẹni tí ó sọ bẹ́ẹ̀ ló wà fún ẹni tí ó ṣe “ààmín” sí irúfẹ́ àdúà ẹbọ náà. Ẹbọ ńlá ni ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà àti ẹ̀sìn nasrọ̄niyyah dúró lé (báyìí) nítorí pé, ẹni tí kì í ṣe Allāhu ni gbogbo wọn ń jọ́sìn fún, tí wọ́n tún ń képè nínú àdúà wọn. Irú ẹbọ ńlá yìí náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ nínú sūfī Tijāniyyah àti Ƙọ̄diriyyah àti ìjọ Ṣī‘ah. Àwọn ṣeeu ìjọ kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ń sọ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu.
Ìkejì: “aṣ-ṣirk al-’asgar” ẹbọ kékeré. Ẹbọ kékeré ni ṣekárími àti ohunkóhun tí ẹ̀dá bá fi ń sọ ẹ̀dá kan di akẹgbẹ́ Allāhu níbi àwọn iṣẹ́ àti ìròyìn Allāhu. Àpẹ̀ẹrẹ ẹbọ kékeré pọ̀ gan-an nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe ọmọnìyàn. Bí àpẹ̀ẹrẹ, fífi n̄ǹkan búra lẹ́yìn Allāhu bíi sí sọ pé, “Mo fi al-Ƙur’ān búra.” dípò sí sọ pé, “Mo fi Allāhu búra.” Tàbí “Mo fi Allāhu Ẹni tí Ó sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ búra.” Àpẹ̀ẹrẹ ẹbọ kékeré ni gbólóhùn “Bí Allāhu bá fẹ́, bí ìwọ náà bá fẹ́.” Dípò, “bí Allāhu bá fẹ́”. Àpẹ̀ẹrẹ mìíràn, “ọpẹ́lọpẹ́ lágbájá” dípò “Ọpẹ́lọpẹ́ Allāhu”. Àpẹ̀ẹrẹ mìíràn ni gbólóhùn “Ajé á tà á” tàbí “Ajé á wá.” Dípò “Allāhu á tà á.” Ìyàtọ̀ tó wà láààrin ẹbọ ńlá àti ẹbọ kékeré ni ìwọ̀nyí:
(1) Ẹbọ ńlá máa ba odidi ẹ̀sìn jẹ́ mọ́ mùsùlùmí lọ́wọ́, àmọ́ abala ibi tí ẹbọ kékeré bá ti ṣẹlẹ̀ nìkan ni ìbàjẹ́ máa kàn.
(2) Ẹbọ ńlá kò ní àforíjìn tí ènìyàn kò bá ronú pìwàdà títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, àmọ́ ẹlẹ́bọ kékeré lè rí àforíjìn bí kò bá ronú pìwàdà, ó sì lè jẹ̀yà rẹ̀ nínú Iná ní ọ̀run bí kò bá ronú pìwàdà lórí rẹ̀ ṣíwájú ikú rẹ̀.
(3) Iná gbére ni ẹ̀san ẹbọ ńlá fún ẹni tí ó bá kú sórí rẹ̀, àmọ́ ẹlẹ́bọ kékeré máa padà jáde kúrò nínú Iná bí ó bá jẹ́ pé, ó ti ipasẹ̀ ẹbọ kékeré wọnú Iná. Ẹ jẹ́ kí á ronú pìwàdà lórí gbogbo ẹbọ pátápátá.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (48) Sourate: AN-NISÂ’
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture