Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (34) Sourate: AN-NISÂ’
ٱلرِّجَالُ قَوَّٰمُونَ عَلَى ٱلنِّسَآءِ بِمَا فَضَّلَ ٱللَّهُ بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ وَبِمَآ أَنفَقُواْ مِنۡ أَمۡوَٰلِهِمۡۚ فَٱلصَّٰلِحَٰتُ قَٰنِتَٰتٌ حَٰفِظَٰتٞ لِّلۡغَيۡبِ بِمَا حَفِظَ ٱللَّهُۚ وَٱلَّٰتِي تَخَافُونَ نُشُوزَهُنَّ فَعِظُوهُنَّ وَٱهۡجُرُوهُنَّ فِي ٱلۡمَضَاجِعِ وَٱضۡرِبُوهُنَّۖ فَإِنۡ أَطَعۡنَكُمۡ فَلَا تَبۡغُواْ عَلَيۡهِنَّ سَبِيلًاۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيّٗا كَبِيرٗا
Àwọn ọkùnrin ni òpómúléró¹ fún àwọn obìnrin nítorí pé, Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan² àti nítorí ohun tí wọ́n ń ná nínú dúkìá wọn.³ Àwọn obìnrin rere ni àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ (Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà àṣẹ ọkọ), àwọn olùṣọ́-ẹ̀tọ́ ọkọ ní kọ̀rọ̀ fún wí pé Allāhu ṣọ́ (ẹ̀tọ́ tiwọn náà fún wọn lọ́dọ̀ ọkọ wọn). Àwọn tí ẹ sì ń páyà oríkunkun wọn4, ẹ ṣe wáàsí fún wọn, ẹ takété sí ibùsùn wọn, ẹ lù wọ́n. Tí wọ́n bá sì tẹ̀lé àṣẹ yín, ẹ má ṣe fí ọ̀nà kan kan wá wọn níjà5. Dájúdájú Allāhu ga, Ó tóbi.6
1. aláṣẹ, olùdarí, alámòójútó àti onímọ̀ràn rere.
2. Ìyẹn ni pé, Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún àwọn ọkùnrin lórí àwọn obìnrin wọn.
3. Ìyẹn ni pé, àwọn ọkùnrin ni wọn yóò máa gbé bùkátà àwọn obìnrin wọn. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọkùnrin ti yẹrí kúrò níbẹ̀. Ìdí nìyí tí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ obìnrin fi kún ìgboro fọ́fọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣì tí ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dẹ sí àwọn ará ìlú jẹ́ okùnfà kan pàtàkì, àwọn ọlọ́mọge fúnra wọn ń fi títako ṣíṣe ìyàwó kejì tàbí ìkẹta tàbí ìkẹrin bọ́ sí ọwọ́ alápámáṣiṣẹ́ ọ̀dọ́ ọkùnrin.
4. Èyí ni ti olóríkunkun obìnrin. Ní ti olóríkunkun ọkùnrin, ẹ wo āyah 128.
5. Ẹ má ṣe fi ọ̀nà kan kan ṣàbòsí sí wọn, Ẹ má ṣe fi ọ̀nà kan kan tayọ ẹnu-ààlà sí wọn.
6. Kíyè sí i, ọkọ kò gbọ́dọ̀ lu ìyàwó rẹ̀ àfi pẹ̀lú àwọn májẹ̀mu mẹ́fà kan. Ìkíní: lílù náà gbọ́dọ̀ jẹ́ lẹ́yìn tí wáàsí àti títakété sí ibùsùn rẹ̀ kò bá so èso rere lára ìyàwó. Ìkejì: lílù náà kò gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lásìkò ìbínú. Ìkẹta: ohun tí ọkọ yóò fi lu ìyàwó rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ nípọn ju etí aṣọ lọ. Ìkẹrin: kò gbọ́dọ̀ tayọ òǹkà mẹ́wàá. Ìkarùn-ún: kò gbọ́dọ̀ fi àpá sí ìyàwó rẹ̀ lára. Ìkẹfà: kò gbọ́dọ̀ lu ìyàwó rẹ̀ ní àyè ọ̀wọ̀ tàbí àyè ẹlẹgẹ́ bí ojú, orí àti ikùn. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Sọ̄d; 38:44.
Bákan náà, tí lílù bá ń wáyé lemọ́lemọ́, ìfisùn fún àtúnṣe tàbí ìkọ̀sílẹ̀ lọpọ́n súnkàn ní ìbámu sí āyah 35.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (34) Sourate: AN-NISÂ’
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture