क़ुरआन के अर्थों का अनुवाद - योरुबा अनुवाद * - अनुवादों की सूची

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

अर्थों का अनुवाद आयत: (48) सूरा: सूरा अल्-अम्बिया
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ ٱلۡفُرۡقَانَ وَضِيَآءٗ وَذِكۡرٗا لِّلۡمُتَّقِينَ
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) Hārūn ní ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun tó ń ṣòpínyà láààrin òdodo àti irọ́), ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).¹
1. Ọ̀rọ̀-ìpínyà, ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí nínú āyah yìí dúró fún àwọn ìròyìn tó wà lára tírà kan ṣoṣo tí Allāhu - tó ga jùlọ - fún Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Tírà náà ni at-Taorāt. Lẹ́yìn náà, ìwọ̀nyẹn ni àwọn ìròyìn tó máa ń wà lára ìkọ̀ọ̀kan tírà tí Allāhu máa ń sọ̀kalẹ̀ fún àwọn Ànábì Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -.
Kíyè sí i, gbogbo tírà tó ṣíwájú ti parí iṣẹ́ wọn. Ní àsìkò yìí, tírà ìkẹ́yìn nìkan ló ku gbogbo ayé kù. Ìyẹn sì ni al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Kódà bí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - bá padà sọ̀kalẹ̀ lópin ayé, kò níí tẹ̀lé tírà kan yàtọ̀ sí al-Ƙur’ān gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ ṣíwájú nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 8.
अरबी तफ़सीरें:
 
अर्थों का अनुवाद आयत: (48) सूरा: सूरा अल्-अम्बिया
सूरों की सूची पृष्ठ संख्या
 
क़ुरआन के अर्थों का अनुवाद - योरुबा अनुवाद - अनुवादों की सूची

पवित्र क़ुरआन के अर्थों का योरुबा अनुवाद। अनुवाद अबू रहीमा मीकाईल ऐकवीनी ने किया है। प्रकाशन वर्ष 1432 हीजरी।

बंद करें