クルアーンの対訳 - ヨルバ語対訳 * - 対訳の目次

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

対訳 節: (6) 章: 雌牛章
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ سَوَآءٌ عَلَيۡهِمۡ ءَأَنذَرۡتَهُمۡ أَمۡ لَمۡ تُنذِرۡهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn, wọn kò níí gbàgbọ́.¹
1. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kádàrá wọn lórí jíjẹ́ kèfèrí wọn kò níí yí padà. Àmọ́ ní ti àwọn tí kádàrá ìrònúpìwàdà máa borí wọn, ìkìlọ̀ máa sọ wọ́n di mùsùlùmí. Āyah yìí sọ̀kalẹ̀ nítorí àwọn tí wọ́n ń kú sínú kèfèrí lẹ́yìn tí ìkìlọ̀ ti dé etí ìgbọ́ wọn pé, ọmọ Iná ni gbogbo ẹni tí kò bá kú sínú ’Islām. Nítorí náà, āyah yìí kò sọ̀kalẹ̀ nítorí gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí pé, a kúkú ń fojú rí àwọn kan nínú wọn tí wọ́n ń gba ’Islām. Àti pé ọ̀wọ́ àwọn tí àdánwò èdídí ọkàn, èdídí ìgbọ́rọ̀ àti èbìbò ojú bá wà lára wọn ló máa takú sínú kèfèrí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.
アラビア語 クルアーン注釈:
 
対訳 節: (6) 章: 雌牛章
章名の目次 ページ番号
 
クルアーンの対訳 - ヨルバ語対訳 - 対訳の目次

クルアーン・ヨルバ語対訳 - Abu Rahima Mikhail Aikweiny ヒジュラ暦1432年印刷

閉じる