Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan tó wà lórí ilẹ̀ àfi kí arísìkí rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì mọ ibùgbé rẹ̀ (nílé ayé) àti ilẹ̀ tí ó máa kú sí. Gbogbo rẹ̀ ti wà nínú àkọsílẹ̀ tó yanjú.
Bóyá o fẹ́ gbé apá kan ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ sílẹ̀, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá ọkàn rẹ nípa rẹ̀ (ní ti ìpáyà pé) wọ́n ń wí pé: “Kí ó sì jẹ́ pé àpótí-ọrọ̀ kan sọ̀kalẹ̀ fún un, tàbí kí mọlāika kan bá a wá?” Olùkìlọ̀ ni ìwọ. Allāhu sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn nílé ayé. A ò sì níí dín kiní kan kù fún wọn nílé ayé.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kò níí sí kiní kan fún wọn mọ́ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àfi Iná. N̄ǹkan tí wọ́n gbélé ayé ṣe sì máa bàjẹ́. Òfò sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n wí pé: “Nūh, o mà kúkú ti jà wá níyàn. O sì ṣe àríyànjiyàn púpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa wá tí o bá wà lára àwọn olódodo.”
Ìmọ̀ràn mi kò sì lè ṣe yín ní àǹfààní tí mo bá fẹ́ gbà yín nìmọ̀ràn, tí Allāhu bá fẹ́ pa yín run. Òun ni Olúwa yín. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.”
A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh pé, dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa gbàgbọ́ mọ́ nínú ìjọ rẹ àfi ẹni tó ti gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Kí o sì kan ọkọ̀ ojú-omi náà lójú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Má sì ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣàbòsí. Dájúdájú wọ́n máa tẹ̀ wọ́n rì ni.
Ó sì ń kan ọkọ̀ ojú-omi náà lọ. Ìgbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. (Ànábì Nūh) sì sọ pé: “Tí ẹ bá fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, dájúdájú àwa náà yóò fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́.¹
A kò níí sọ n̄ǹkan kan (sí ọ) bí kò ṣe pé, àwọn kan nínú àwọn òrìṣà wa ti fi ìnira kàn ọ́ (ló fi ń sọ ìsọkúsọ nípa wọn).” Ó sọ pé: “Dájúdájú èmi ń fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí àti pé kí ẹ̀yin náà jẹ́rìí pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ
Nítorí náà, tí ẹ bá pẹ̀yìn dà (níbi òdodo), mo kúkú ti fi ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ jíṣẹ́ fún yín, Olúwa mi yó sì fi ìjọ kan tó máa yàtọ̀ sí ẹ̀yin rọ́pò yín. Ẹ kò sì lè kó ìnira kan kan bá A. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.”
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Hūd àti àwọn tó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa; A gbà wọ́n là nínú ìyà tó nípọn.
Nígbà tí ó rí ọwọ́ wọn pé kò kan oúnjẹ náà, ó pajú dà sí wọn (ó f’ojú òdì wo àìjẹun wọn). Ìbẹ̀rù wọn sì mú un.¹ Wọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwọn ènìyàn (Ànábì) Lūt ni Wọ́n rán àwa sí.”
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n sì dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ sísun lé wọn lórí ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.
A kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Nítorí náà, àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nígbà tí àṣẹ Olúwa rẹ dé. Wọn kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìparun.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́¹. Dájúdájú Olúwa ni Aṣèyí-ó-wùú.
1. Ẹ wo àlàyé lórí àgbọ́yé “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’An‘ām; 6:128.
Ní ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ¹, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́.² (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin.
1. Bíbẹ nínú Iná àti bíbẹ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ kò túmọ̀ sí pé òpin yóò dé bá Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra gẹ́gẹ́ bí òpin yóò ṣe dé bá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀nà ìbátan níbi àfiwé tí ń bẹ láààrin àwọn méjéèjì ni pé, ó jẹ́ ara ẹwà èdè láti ṣe àfihàn ìgbà pípẹ́ fún n̄ǹkan. Lára irúfẹ èyí náà ni, bí àpẹ̀ẹrẹ, kí ọkùnrin kan sọ pé, “Èmi yóò máa jẹ́ ọkúnrin ní òdiwọ̀n ìgbà tí ilẹ̀ bá ń ṣú, tí ilẹ̀ bá ń mọ́.”
Ṣíwájú sí i, ìgbàgbọ́ àwa mùsùlùmí ahlu-sunnah wal-janmọ̄n‘ah ni pé, kò sí òpin ìgbà fún Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra ní ọ̀run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn kan lè kọ́kọ́ wọ inú Iná ṣíwájú kí Allāhu - tó ga jùlọ - tó padà mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀ pẹ̀lú àánú Rẹ̀ tàbí pẹ̀lú ìṣìpẹ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Lẹ́yìn náà, ó máa ṣẹ́ ku kìkìdá àwọn ọmọ Iná Gbére, wọn yó sì ṣe gbére nínú Iná.
Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ni. Kò sì níí sí ẹnì kan tí ó máa ti inú Ọgbà Ìdẹ̀ra bọ́ sínú Iná Gbére.
Ẹ̀rí nínú sunnah Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, tí á tún lè fi ní àgbọ́yé àwọn āyah wọ̀nyí dáradára ni hadīth Abu-Sa‘īd al-Kudri - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: “Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò mú Ikú wá ní ìrísí àgbò funfun, tí ó ní dúdú lára. Olùpèpè kan yó sì pèpè báyìí pé, “Ẹ̀yin ará Ọgbà Ìdẹ̀ra”. Àwọn ará Ọgbà Ìdẹ̀ra yó sì narùn jáde síta, wọn yóò wo (ìta). Olùpèpè yó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ èyí?” Wọn yóò sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni Ikú.” Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì máa rí i. Lẹ́yìn náà, olùpèpè máa pèpè báyìí pé, “Ẹ̀yin ará Iná”. Àwọn ará Iná yó sì narùn jáde síta, wọn yóò wo (ìta). Olùpèpè yó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ èyí?” Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni Ikú.” Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì máa rí i. Nígbà náà, A óò pa Ikú. Lẹ́yìn náà, olùpèpè kan yóò sọ pé: “Ẹ̀yin ará Ọgbà Ìdẹ̀ra, gbére (ni tiyín báyìí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), kò sì sí Ikú mọ́. Olùpèpè yóò tún sọ pé: “Ẹ̀yin ará Iná, gbére (ni tiyín báyìí nínú Iná), kò sì sí Ikú mọ́.” Al-Bukāriy; Kitāb at-Tafsīr.
2. Awẹ́ gbólóhùn yìí “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́”, àgbọ́yé rẹ̀ ni pípẹ́ tí àwọn kan yóò pẹ́ kí wọ́n tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó kúkú ti hàn kedere pé àwọn kan yóò ṣíwájú àwọn mìíràn wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra látára bí ìrìn-àjò ẹ̀dá bá ṣe rí lórí afárá Iná.
Bákàn náà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kan yóò kọ́kọ́ wọ inú Iná ṣíwájú kí wọ́n tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àti pé àwọn kan wulẹ̀ ti wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ṣíwájú Ọjọ́ Àjíǹde ẹ̀dá. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n kú sí ipò ṣẹhīd, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mú hadīth wá lórí èyí nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:154.
Nítorí náà, nípa ti èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra, “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” túmọ̀ sí “àfi pípẹ́ tí Olúwa rẹ bá fẹ́ fún àwọn kan láti pẹ́ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Nígbà tí gbogbo wọn bá sì péjú pésẹ̀ tán sínú rẹ̀, wọn yó sì máa wà nínú rẹ̀ títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá pa Ikú. Kí Allāhu jẹ́ kí á tètè wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Ní ìsọníṣókí, ìyàtọ̀ wà nínú àgbọ́yé “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” nípa ti èrò Iná àti “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” nípa ti èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àmọ́ àgbọ́yé àwọn méjèèjì kò jẹmọ́ pé òpin máa dé bá Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ọgbà gbére ni méjèèjì. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sajdah; 32:20.
Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún. Wọn kò jọ́sìn fún kiní kan bí kò ṣe bí àwọn bàbá wọn náà ṣe ń jọ́sìn (fún àwọn òrìṣà) ní ìṣáájú. Dájúdájú Àwa yóò san wọ́n ní ẹ̀san ìpín (ìyà) wọn láì níí dín in kù.
Dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí A ṣe pa ìwọ àti ẹnikẹ́ni tí ó bá rónú pìwàdà pẹ̀lú rẹ láṣẹ. Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà. Dájúdájú Òun ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Olúwa rẹ kì í pa àwọn ìlú run lọ́nà àbòsí, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ bá jẹ́ olùṣàtùn-únṣe.¹
1. Àwọn kan sọ pé, a tún lè túmọ̀ āyah yìí kan náà báyìí pé, “Allāhu kì í pa àwọn ìlú run fún wí pé wọ́n ń ṣẹbọ sí I, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ará ìlú náà bá ń ṣe déédé láààrin ara wọn.” (Tọbariy)
Gbogbo (n̄ǹkan tí) À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ nínú àwọn ìró àwọn Òjísẹ́ ni èyí tí A fi ń fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀. Òdodo tún dé bá ọ nínú (sūrah) yìí. Wáàsí àti ìrántí tún ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí pátápátá. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí o sì gbáralé E. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbéra nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
نتائج البحث:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".