(Rántí) nígbà tí wọ́n sọ pé: “Dájúdájú Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀ ni bàbá wa nífẹ̀ẹ́ sí ju àwa. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni àwa. Dájúdájú bàbá wa mà ti wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.
Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ẹ má ṣe pa Yūsuf. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ ṣá fẹ́ wá n̄ǹkan ṣe (sí ọ̀rọ̀ rẹ̀), ẹ gbé e jù sínú ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga nítorí kí apá kan nínú àwọn onírìn-àjò lè he é lọ.”
Àwọn onírìn-àjò kan sì dé. Wọ́n rán apọnmi wọn (ní omi). Ó sì ju doro rẹ̀ sínú kànǹga. (Yūsuf sì dìrọ̀ mọ́ okùn doro bọ́ síta. Apọnmi sì) sọ pé: “Ire ìdùnnú rè é! Èyí ni ọmọdékùnrin.” Wọ́n sì fi pamọ́ fún títà (bí ọjà). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ fi owó-ọjà wọn sínú ẹrù (oúnjẹ) wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ nígbà tí wọ́n bá padà dé ọ̀dọ̀ ará ilé wọ́n (pé a ti dá a padà fún wọn), wọn yó sì lè padà wá.”
Nígbà tí wọ́n tú ẹrù oúnjẹ wọn, wọ́n rí i pé wọ́n ti dá owó-ọjà wọn padà fún wọn. Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni a tún ń fẹ́? Owó-ọjà wa nìyí tí wọ́n ti dá padà fún wa. A ó si tún fi wá oúnjẹ rà fún àwọn ẹbí wa. A ó sì dáàbò bo ọbàkan wa. A sì máa rí àlékún ẹrù oúnjẹ (tí) ràkúnmí kan lè rù sí i. Ìwọ̀n oúnjẹ kékeré sì nìyẹn (lọ́dọ̀ ọba).”
Ó sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́ kí ó ba yín lọ títí ẹ máa fi ṣe àdéhùn fún mi ní (orúkọ) Allāhu pé dájúdájú ẹ máa mú un padà wá bá mi àfi tí (àwọn ọ̀tá) bá ka yín mọ́.” Nígbà tí wọ́n fún un ní àdéhùn wọn tán, ó sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”
Nígbà tí wọ́n wọ (inú ìlú) ní àwọn àyè tí bàbá wọn pa láṣẹ fún wọn, kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe bùkátà kan nínú ẹ̀mí (Ànábì) Ya‘ƙūb tí ó múṣẹ. Dájúdájú onímọ̀ ni nípa ohun tí A fi mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
Nígbà tí wọ́n wọlé ti (Ànábì) Yūsuf, ó mú ọmọ-ìyá rẹ̀ mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Dájúdájú èmi ni ọmọ-ìyá rẹ. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.”
Wọ́n sọ pé: “Ẹ̀san rẹ̀; ẹni tí wọ́n bá bá a nínú ẹrù rẹ̀, òun náà ni ẹ̀san rẹ̀. Báyẹn ni àwa ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san (ní ọ̀dọ̀ tiwa).”[1]
1. Nínú òfin tí Allāhu gbékalẹ̀ lórí olè ní àsìkò Ànábì Ya'ƙūb - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni pé, tí ọwọ́ bá tẹ olè, wọ́n máa fà á lé olóhun lọ́wọ́, ó sì máa sọ ọ́ di ẹrú rẹ̀. Àmọ́ ní àsìkò Ànábì tiwa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ọrùn ọwọ́ olè ni wọ́n máa gé pẹ̀lú àwọn májẹ̀mu rẹ̀.
(Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: “Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fún yín. Nítorí náà, sùúrù tó rẹwà (lọ̀rọ̀ mi kàn báyìí). Ó ṣeé ṣe kí Allāhu bá mi mú gbogbo wọn wá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”
Nìgbà tí wọ́n wọlé tọ Yūsuf, wọ́n sọ pé: “Ìwọ ọba, ìnira (ebi) ti mú àwa àti ará ilé wa. A sì mú owó kan tí ẹ máa ta dànù lọ́wọ́.[1] Nítorí náà, wọn kóńgò (oúnjẹ) náà kún fún wa, kí ó sì ta wá lọ́rẹ. Dájúdájú Allāhu yóò san àwọn olùtọrẹ ní ẹ̀san rere.”
1. Ìyẹn ni pé, owó tí wọ́n mú dání kì í ṣe owó tí wọ́n lè gbà lọ́wọ́ wọn torí pé ó kéré púpọ̀, tàbí owó náà ti fẹ́ di kọ̀ǹdẹ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́.
Ó gbé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì sórí ìtẹ́. Wọ́n sì wó lulẹ̀ fún un, tí wọ́n forí kanlẹ̀ kí i.[1] Ó sọ pé: “Bàbá mi, èyí ni ìtúmọ̀ àlá mi (tí mo lá) ṣíwájú. Dájúdájú Olúwa mi ti sọ ọ́ di òdodo. Ó sì ṣe dáadáa fún mi nígbà tí Ó mú mi jáde kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó tún mu yín wá (bá mi) láti inú oko lẹ́yìn tí aṣ-Ṣaetọ̄n ti saburú sáààrin èmi àti àwọn ọbà-kan mi. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú fún ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ní àsìkò náà, kò lòdì sí òfin tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - fún Ànábì Ya'ƙūb àti àwọn ọmọ rẹ̀ - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - láti fi ìdọ̀bálẹ̀ àti ìkúnlẹ̀ kí ẹnikẹ́ni. Àmọ́ nínú òfin tí Allāhu fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó ti di èèwọ̀ láti fi ìdọ̀bálẹ̀ àti ìkúnlẹ̀ kí ẹnikẹ́ni. Ẹ wọ ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:34.
Olúwa mi, dájúdájú O ti fún mi nínú ìjọba. O tún fún mi nínú ìmọ̀ ìtúmọ̀ àlá. Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Ìwọ ni Alátìlẹ́yìn mi ní ayé àti ní ọ̀run, pa mí sípò mùsùlùmí. Kí O sì fi mí pẹ̀lú àwọn ẹni rere.”
(A kì í jẹ àwọn ènìyàn níyà) títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ bá tó sọ̀rètí nù (nípa ìgbàgbọ́ wọn), tí wọ́n sì mọ̀ pé wọ́n ti pe àwọn ní òpùrọ́. Àrànṣe Wa yó sì dé bá wọn. A sì máa gba ẹni tí A bá fẹ́ là. Wọn kò lè dá ìyà Wa padà lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
نتائج البحث:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".