แปล​ความหมาย​อัลกุรอาน​ - คำแปลโยรูบา * - สารบัญ​คำแปล

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

แปลความหมาย​ สูเราะฮ์: Al-Hajj   อายะฮ์:

Suuratul-Hajj

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمۡۚ إِنَّ زَلۡزَلَةَ ٱلسَّاعَةِ شَيۡءٌ عَظِيمٞ
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Dájúdájú ìmì tìtì Àkókò náà, n̄ǹkan ńlá ni.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
يَوۡمَ تَرَوۡنَهَا تَذۡهَلُ كُلُّ مُرۡضِعَةٍ عَمَّآ أَرۡضَعَتۡ وَتَضَعُ كُلُّ ذَاتِ حَمۡلٍ حَمۡلَهَا وَتَرَى ٱلنَّاسَ سُكَٰرَىٰ وَمَا هُم بِسُكَٰرَىٰ وَلَٰكِنَّ عَذَابَ ٱللَّهِ شَدِيدٞ
(Àkókò náà ni) ọjọ́ tí ẹ máa rí i tí gbogbo obìnrin tó ń fún ọmọ lọ́mú mu yóò gbàgbé ọmọ tí ó ń fún lọ́mú àti pé gbogbo aboyún yó sì máa bí oyún wọn. Ìwọ yó sì rí àwọn ènìyàn tí ọtí yóò máa pa wọ́n. Ọtí kò sì pa wọ́n, ṣùgbọ́n ìyà Allāhu (tó) le (ló fà á).
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُجَٰدِلُ فِي ٱللَّهِ بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَيَتَّبِعُ كُلَّ شَيۡطَٰنٖ مَّرِيدٖ
Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀. Ó sì ń tẹ̀lé gbogbo aṣ-Ṣaetọ̄n olórí kunkun.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
كُتِبَ عَلَيۡهِ أَنَّهُۥ مَن تَوَلَّاهُ فَأَنَّهُۥ يُضِلُّهُۥ وَيَهۡدِيهِ إِلَىٰ عَذَابِ ٱلسَّعِيرِ
Wọ́n kọ ọ́ lé (aṣ-ṣaetọ̄n) lórí pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé e, ó máa ṣì í lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ọ sí ọ̀nà ìyà Iná tó ń jo.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِن كُنتُمۡ فِي رَيۡبٖ مِّنَ ٱلۡبَعۡثِ فَإِنَّا خَلَقۡنَٰكُم مِّن تُرَابٖ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٖ ثُمَّ مِنۡ عَلَقَةٖ ثُمَّ مِن مُّضۡغَةٖ مُّخَلَّقَةٖ وَغَيۡرِ مُخَلَّقَةٖ لِّنُبَيِّنَ لَكُمۡۚ وَنُقِرُّ فِي ٱلۡأَرۡحَامِ مَا نَشَآءُ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى ثُمَّ نُخۡرِجُكُمۡ طِفۡلٗا ثُمَّ لِتَبۡلُغُوٓاْ أَشُدَّكُمۡۖ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰٓ أَرۡذَلِ ٱلۡعُمُرِ لِكَيۡلَا يَعۡلَمَ مِنۢ بَعۡدِ عِلۡمٖ شَيۡـٔٗاۚ وَتَرَى ٱلۡأَرۡضَ هَامِدَةٗ فَإِذَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡهَا ٱلۡمَآءَ ٱهۡتَزَّتۡ وَرَبَتۡ وَأَنۢبَتَتۡ مِن كُلِّ زَوۡجِۭ بَهِيجٖ
Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa àjíǹde, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà láti inú bááṣí ẹran tí ó pé ní ẹ̀dá àti èyí tí kò pé ní ẹ̀dá nítorí kí A lè ṣàlàyé (agbára Wa) fún yín. A sì ń mú ohun tí A bá fẹ́ dúró sínú àpò ìbímọ títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, A óò mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (ẹ óò máa ṣẹ̀mí lọ) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Ẹni tí wọ́n máa pa (ní kékeré) wà nínú yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí wọ́n máa dá (ìṣẹ̀mí) rẹ̀ sí di àsìkò ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ́ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Àti pé o máa rí ilẹ̀ ní gbígbẹ. Nígbà tí A bá sì sọ òjò kalẹ̀ lé e lórí, ó máa yíra padà. Ó máa gbèrú. Ó sì máa mú gbogbo oríṣiríṣi irúgbìn tó dára jáde.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّهُۥ يُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَأَنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَأَنَّ ٱلسَّاعَةَ ءَاتِيَةٞ لَّا رَيۡبَ فِيهَا وَأَنَّ ٱللَّهَ يَبۡعَثُ مَن فِي ٱلۡقُبُورِ
Àti pé dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu yóò gbé àwọn tó ń bẹ nínú sàréè dìde.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُجَٰدِلُ فِي ٱللَّهِ بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَلَا هُدٗى وَلَا كِتَٰبٖ مُّنِيرٖ
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān) àti ìmọ̀nà (sunnah Ànábì) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) tó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn).
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ثَانِيَ عِطۡفِهِۦ لِيُضِلَّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۖ لَهُۥ فِي ٱلدُّنۡيَا خِزۡيٞۖ وَنُذِيقُهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ عَذَابَ ٱلۡحَرِيقِ
Ó ń ṣègbéraga (sí òdodo, ó ń gbúnrí kúrò níbi òdodo) nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá àwọn ènìyàn lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àbùkù ń bẹ fún un nílé ayé. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, A sì máa fún un ní ìyà Iná jónijóni tọ́ wò.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتۡ يَدَاكَ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَيۡسَ بِظَلَّٰمٖ لِّلۡعَبِيدِ
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí ohun tí ọwọ́ rẹ̀ tì síwájú. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí sí àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَعۡبُدُ ٱللَّهَ عَلَىٰ حَرۡفٖۖ فَإِنۡ أَصَابَهُۥ خَيۡرٌ ٱطۡمَأَنَّ بِهِۦۖ وَإِنۡ أَصَابَتۡهُ فِتۡنَةٌ ٱنقَلَبَ عَلَىٰ وَجۡهِهِۦ خَسِرَ ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةَۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡخُسۡرَانُ ٱلۡمُبِينُ
Ó tún wà nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jọ́sìn fún Allāhu lórí ahọ́n. Tí rere bá ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa fi ọkàn balẹ̀ (sínú ẹ̀sìn). Tí ìfòòró bá sì ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa yíjú rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Ó ṣòfò láyé àti lọ́run. Ìyẹn sì ni òfò pọ́nńbélé.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
يَدۡعُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُۥ وَمَا لَا يَنفَعُهُۥۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلضَّلَٰلُ ٱلۡبَعِيدُ
Ó ń pè lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè kó ìnira bá a, tí kò sì lè ṣe é ní oore; ìyẹn ni ìṣìnà tó jìnnà (sí ìmọ̀nà).
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
يَدۡعُواْ لَمَن ضَرُّهُۥٓ أَقۡرَبُ مِن نَّفۡعِهِۦۚ لَبِئۡسَ ٱلۡمَوۡلَىٰ وَلَبِئۡسَ ٱلۡعَشِيرُ
Ó ń pe ohun tí ìnira rẹ̀ súnmọ́ ju àǹfààní rẹ̀ lọ. Dájúdájú (òrìṣà) burú ní aláfẹ̀yìntì, ó sì burú ní alásùn-únmọ́.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
إِنَّ ٱللَّهَ يُدۡخِلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يُرِيدُ
Dájúdájú Allāhu yóò mú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
مَن كَانَ يَظُنُّ أَن لَّن يَنصُرَهُ ٱللَّهُ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ فَلۡيَمۡدُدۡ بِسَبَبٍ إِلَى ٱلسَّمَآءِ ثُمَّ لۡيَقۡطَعۡ فَلۡيَنظُرۡ هَلۡ يُذۡهِبَنَّ كَيۡدُهُۥ مَا يَغِيظُ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá lérò pé Allāhu kò níí ran (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lọ́wọ́ láyé àti lọ́run, kí ó na okùn sí sánmọ̀ (àjà ilé rẹ̀) lẹ́yìn náà kí ó gé e (ìyẹn ni pé, kí ó pokùn so). Kí ó wò ó nígbà náà bóyá ète rẹ̀ lè mú (àrànṣe) tó ń bínú sí kúrò (lọ́dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -).[1]
1. Ìyẹn ni pé, abínú-ẹni kò lè pa kádàrá-ẹni dà. Ó kàn fẹ́ han ara rẹ̀ léémọ̀ ni.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلۡنَٰهُ ءَايَٰتِۭ بَيِّنَٰتٖ وَأَنَّ ٱللَّهَ يَهۡدِي مَن يُرِيدُ
Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní àwọn āyah tó yanjú. Dájúdájú Allāhu ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلصَّٰبِـِٔينَ وَٱلنَّصَٰرَىٰ وَٱلۡمَجُوسَ وَٱلَّذِينَ أَشۡرَكُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ يَفۡصِلُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tó di yẹhudi àti àwọn sọ̄bi’ūn àti àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn mọjūs àti àwọn tó ṣẹbọ, dájúdájú Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:62 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:90.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يَسۡجُدُۤ لَهُۥۤ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ وَٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُ وَٱلنُّجُومُ وَٱلۡجِبَالُ وَٱلشَّجَرُ وَٱلدَّوَآبُّ وَكَثِيرٞ مِّنَ ٱلنَّاسِۖ وَكَثِيرٌ حَقَّ عَلَيۡهِ ٱلۡعَذَابُۗ وَمَن يُهِنِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن مُّكۡرِمٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يَشَآءُ۩
Ṣé o ò wòye pé dájúdájú Allāhu ni àwọn tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí ilẹ̀, àti òòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, àwọn àpáta, àwọn igi, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn ń forí kanlẹ̀ fún? Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sì ni ìyà ti kò lé lórí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi àbùkù kàn, kò sí ẹnì kan tí ó máa ṣe àpọ́nlé rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah ar-Ra‘d; 13:15.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
۞ هَٰذَانِ خَصۡمَانِ ٱخۡتَصَمُواْ فِي رَبِّهِمۡۖ فَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قُطِّعَتۡ لَهُمۡ ثِيَابٞ مِّن نَّارٖ يُصَبُّ مِن فَوۡقِ رُءُوسِهِمُ ٱلۡحَمِيمُ
Àwọn oníjà méjì (kan) nìyí, wọ́n ń takò ara wọn nípa Olúwa wọn. Nítorí náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa gé aṣọ Iná fún wọn, wọ́n yó sì máa da omi tó gbóná gan-an lé wọn lórí láti òkè orí wọn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
يُصۡهَرُ بِهِۦ مَا فِي بُطُونِهِمۡ وَٱلۡجُلُودُ
Wọ́n máa fi yọ́ ohun tí ń bẹ nínú ikùn wọn àti awọ ara wọn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَلَهُم مَّقَٰمِعُ مِنۡ حَدِيدٖ
Àwọn òdùrọ irin (ìyà) sì wà fún wọn pẹ̀lú.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
كُلَّمَآ أَرَادُوٓاْ أَن يَخۡرُجُواْ مِنۡهَا مِنۡ غَمٍّ أُعِيدُواْ فِيهَا وَذُوقُواْ عَذَابَ ٱلۡحَرِيقِ
Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀ látara ìbànújẹ́, wọ́n á dá wọn padà sínú rẹ̀. (A óò sọ pé): “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
إِنَّ ٱللَّهَ يُدۡخِلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ يُحَلَّوۡنَ فِيهَا مِنۡ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٖ وَلُؤۡلُؤٗاۖ وَلِبَاسُهُمۡ فِيهَا حَرِيرٞ
Dájúdájú Allāhu yóò fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. A óò ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà àti àlúùlúù. Aṣọ àlàárì sì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَهُدُوٓاْ إِلَى ٱلطَّيِّبِ مِنَ ٱلۡقَوۡلِ وَهُدُوٓاْ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡحَمِيدِ
A fún wọn ní ìmọ̀nà síbi ohun tó dára nínú ọ̀rọ̀.[1] A sì tọ́ wọn sí ọ̀nà Ẹlẹ́yìn.
1. “Ohun tó dára nínú ọ̀rọ̀” dúró fún kalmọtuṣ-ṣahādah àti al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. “Ojú ọ̀nà Ẹlẹ́yìn” dúró fún ẹ̀sìn ’Islām àti Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí Allāhu Ọba Ẹlẹ́yìn gbékalẹ̀.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ ٱلَّذِي جَعَلۡنَٰهُ لِلنَّاسِ سَوَآءً ٱلۡعَٰكِفُ فِيهِ وَٱلۡبَادِۚ وَمَن يُرِدۡ فِيهِ بِإِلۡحَادِۭ بِظُلۡمٖ نُّذِقۡهُ مِنۡ عَذَابٍ أَلِيمٖ
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu àti Mọ́sálásí Haram, èyí tí A ṣe ní dọ́gbadọ́gba fún àwọn ènìyàn, olùgbé-inú rẹ̀ àti àlejò (fún ìjọ́sìn ṣíṣe), ẹnikẹ́ni tí ó bá ní èrò láti ṣe ìyípadà kan níbẹ̀ pẹ̀lú àbòsí, A máa mú un tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَإِذۡ بَوَّأۡنَا لِإِبۡرَٰهِيمَ مَكَانَ ٱلۡبَيۡتِ أَن لَّا تُشۡرِكۡ بِي شَيۡـٔٗا وَطَهِّرۡ بَيۡتِيَ لِلطَّآئِفِينَ وَٱلۡقَآئِمِينَ وَٱلرُّكَّعِ ٱلسُّجُودِ
(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣàfi hàn àyè ilé náà fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (A sì pa á láṣẹ) pé o ò gbọdọ̀ sọ kiní kan di akẹgbẹ́ fún Mi. Àti pé kí o ṣe ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, olùkírun, olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَأَذِّن فِي ٱلنَّاسِ بِٱلۡحَجِّ يَأۡتُوكَ رِجَالٗا وَعَلَىٰ كُلِّ ضَامِرٖ يَأۡتِينَ مِن كُلِّ فَجٍّ عَمِيقٖ
Kí o sì pe ìpè fún àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ Hajj. Wọn yóò wá bá ọ pẹ̀lú ìrìn ẹsẹ̀ àti lórí gbogbo n̄ǹkan ìgùn, wọn yóò máa wá láti àwọn ọ̀nà jíjìn
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
لِّيَشۡهَدُواْ مَنَٰفِعَ لَهُمۡ وَيَذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ فِيٓ أَيَّامٖ مَّعۡلُومَٰتٍ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُم مِّنۢ بَهِيمَةِ ٱلۡأَنۡعَٰمِۖ فَكُلُواْ مِنۡهَا وَأَطۡعِمُواْ ٱلۡبَآئِسَ ٱلۡفَقِيرَ
nítorí kí wọ́n lè rí àwọn àǹfààní tó ń bẹ fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè ṣèrántí orúkọ Allāhu fún àwọn ọjọ́ tí wọ́n ti mọ̀[1] lórí n̄ǹkan tí Allāhu pa lésè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi bọ́ aláìlera, tálíkà.
1. Ìyẹn àwọn ọjọ́ mẹ́wàá àkọ́kọ́ nínú oṣù Thul-hijjah.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ثُمَّ لۡيَقۡضُواْ تَفَثَهُمۡ وَلۡيُوفُواْ نُذُورَهُمۡ وَلۡيَطَّوَّفُواْ بِٱلۡبَيۡتِ ٱلۡعَتِيقِ
Lẹ́yìn náà, kí wọ́n yanjú ìdọ̀tí ara wọn fún ìparí iṣẹ́ Hajj wọn, kí wọ́n mú àwọn ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, kí wọ́n sì yípo Ilé Láéláé náà.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ذَٰلِكَۖ وَمَن يُعَظِّمۡ حُرُمَٰتِ ٱللَّهِ فَهُوَ خَيۡرٞ لَّهُۥ عِندَ رَبِّهِۦۗ وَأُحِلَّتۡ لَكُمُ ٱلۡأَنۡعَٰمُ إِلَّا مَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡۖ فَٱجۡتَنِبُواْ ٱلرِّجۡسَ مِنَ ٱلۡأَوۡثَٰنِ وَٱجۡتَنِبُواْ قَوۡلَ ٱلزُّورِ
Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu bu ọ̀wọ̀ fún, òhun ló lóore jùlọ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n sì ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn ní ẹ̀tọ́ fún yín àyàfi àwọn tí wọ́n ń kà (ní èèwọ̀) fún yín. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí ẹ̀gbin òrìṣà. Kí ẹ sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ irọ́.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
حُنَفَآءَ لِلَّهِ غَيۡرَ مُشۡرِكِينَ بِهِۦۚ وَمَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَكَأَنَّمَا خَرَّ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَتَخۡطَفُهُ ٱلطَّيۡرُ أَوۡ تَهۡوِي بِهِ ٱلرِّيحُ فِي مَكَانٖ سَحِيقٖ
(Ẹ jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe jẹ́ ẹni tí yóò máa ṣẹbọ sí I. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹbọ sí Allāhu, ó dà bí ẹni tó jábọ́ láti ojú sánmọ̀, tí ẹyẹ sì gbé e lọ tàbí (tí) atẹ́gùn jù ú sínú àyè tó jìnnà.[1]
1. Ìyẹn ni pé, rádaràda réderède ni ìkángun ẹni tó bá ṣẹbọ kú.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ذَٰلِكَۖ وَمَن يُعَظِّمۡ شَعَٰٓئِرَ ٱللَّهِ فَإِنَّهَا مِن تَقۡوَى ٱلۡقُلُوبِ
Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu fi ṣe àríṣàmì fún ẹ̀sìn ’Islām, dájúdájú ó wà lára níní ìbẹ̀rù Allāhu nínú ọkàn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
لَكُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى ثُمَّ مَحِلُّهَآ إِلَى ٱلۡبَيۡتِ ٱلۡعَتِيقِ
Àwọn àǹfààní wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, Ilé Láéláé náà ni ibùpa àwọn ẹran náà.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَلِكُلِّ أُمَّةٖ جَعَلۡنَا مَنسَكٗا لِّيَذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُم مِّنۢ بَهِيمَةِ ٱلۡأَنۡعَٰمِۗ فَإِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ فَلَهُۥٓ أَسۡلِمُواْۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُخۡبِتِينَ
Ìkọ̀ọ̀kan ìjọ (mùsùlùmí tó ṣíwájú) ni A yan ẹran pípa fún nítorí kí wọ́n lè dárúkọ Allāhu lórí ohun tí Ó pèsè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Òun ni kí ẹ jẹ́ mùsùlùmí fún. Kí o sì fún àwọn ọlọ́kàn ìrẹ̀lẹ̀, àwọn olùfọkànbalẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ní ìró ìdùnnú.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِرَ ٱللَّهُ وَجِلَتۡ قُلُوبُهُمۡ وَٱلصَّٰبِرِينَ عَلَىٰ مَآ أَصَابَهُمۡ وَٱلۡمُقِيمِي ٱلصَّلَوٰةِ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ
(Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá dárúkọ Allāhu (fún wọn), ọkàn wọn máa gbọ̀n rìrì. (Wọ́n jẹ́) onísùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí wọn. (Wọ́n jẹ́) olùkírun. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pa lésè fùn wọn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَٱلۡبُدۡنَ جَعَلۡنَٰهَا لَكُم مِّن شَعَٰٓئِرِ ٱللَّهِ لَكُمۡ فِيهَا خَيۡرٞۖ فَٱذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَيۡهَا صَوَآفَّۖ فَإِذَا وَجَبَتۡ جُنُوبُهَا فَكُلُواْ مِنۡهَا وَأَطۡعِمُواْ ٱلۡقَانِعَ وَٱلۡمُعۡتَرَّۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرۡنَٰهَا لَكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Àwọn ràkúnmí, A ṣe wọ́n nínú àwọn n̄ǹkan àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu fún yín. Oore wà lára wọn fún yín. Nítorí náà, ẹ dárúkọ Allāhu lé wọn lórí (kí ẹ sì gún wọn) ní ìdúró. Nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, ẹ jẹ nínú rẹ̀. Ẹ fi bọ́ ẹni tó ní ìtẹ́lọ́rùn àti atọrọjẹ. Báyẹn ni A ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
لَن يَنَالَ ٱللَّهَ لُحُومُهَا وَلَا دِمَآؤُهَا وَلَٰكِن يَنَالُهُ ٱلتَّقۡوَىٰ مِنكُمۡۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرَهَا لَكُمۡ لِتُكَبِّرُواْ ٱللَّهَ عَلَىٰ مَا هَدَىٰكُمۡۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Ẹran (tí ẹ pa) àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kò níí dé ọ̀dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù Allāhu láti ọ̀dọ̀ yín ló máa dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Báyẹn ni (Allāhu) ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe ìgbétóbi fún Allāhu nípa bí Ó ṣe fi ọ̀nà mọ̀ yín. Kí o sì fún àwọn olùṣe-rere ní ìró ìdùnnú.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
۞ إِنَّ ٱللَّهَ يُدَٰفِعُ عَنِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ خَوَّانٖ كَفُورٍ
Dájúdájú Allāhu ń ti aburú kúrò fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn oníjàǹbá, aláìgbàgbọ́.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
أُذِنَ لِلَّذِينَ يُقَٰتَلُونَ بِأَنَّهُمۡ ظُلِمُواْۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ نَصۡرِهِمۡ لَقَدِيرٌ
A yọ̀ǹda (ogun ẹ̀sìn jíjà) fún àwọn (mùsùlùmí) tí (àwọn kèfèrí) ń gbógun tì nítorí pé (àwọn kèfèrí) ti ṣe àbòsí sí wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí àrànṣe wọn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ٱلَّذِينَ أُخۡرِجُواْ مِن دِيَٰرِهِم بِغَيۡرِ حَقٍّ إِلَّآ أَن يَقُولُواْ رَبُّنَا ٱللَّهُۗ وَلَوۡلَا دَفۡعُ ٱللَّهِ ٱلنَّاسَ بَعۡضَهُم بِبَعۡضٖ لَّهُدِّمَتۡ صَوَٰمِعُ وَبِيَعٞ وَصَلَوَٰتٞ وَمَسَٰجِدُ يُذۡكَرُ فِيهَا ٱسۡمُ ٱللَّهِ كَثِيرٗاۗ وَلَيَنصُرَنَّ ٱللَّهُ مَن يَنصُرُهُۥٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ
(Àwọn ni) àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn ní ọ̀nà àìtọ́ àfi (nítorí pé) wọ́n ń sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa.” Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, wọn ìbá ti wó ilé ìsìn àwọn fadá, ṣọ́ọ̀ṣì, sínágọ́gù àti àwọn mọ́sálásí tí wọ́n ti ń dárúkọ Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.[1] Dájúdájú Allāhu yóò ṣe àrànṣe fún ẹnikẹ́ni tó ń ran (ẹ̀sìn ’Islām) Rẹ̀ lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.
1. Ó ti rinlẹ̀ nínú sunnah Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé àwa mùsùlùmí kò gbọdọ̀ da ilé ìsìn àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ wó lulẹ̀ ní àsìkò ogun ẹ̀sìn nítorí pé, àwọn ilé ìsìn náà rọrùn láti sọ di mọ́sálásí.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ٱلَّذِينَ إِن مَّكَّنَّٰهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ أَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُاْ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَمَرُواْ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَنَهَوۡاْ عَنِ ٱلۡمُنكَرِۗ وَلِلَّهِ عَٰقِبَةُ ٱلۡأُمُورِ
(Àwọn náà ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá fún wọn ní ipò lórí ilẹ̀, wọn yóò kírun, wọn yóò yọ Zakāh, wọn yóò pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì kọ ohun burúkú. Ti Allāhu sì ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدۡ كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ وَعَادٞ وَثَمُودُ
Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti ìjọ Thamūd kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ wọn ní òpùrọ́ ṣíwájú wọn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَقَوۡمُ إِبۡرَٰهِيمَ وَقَوۡمُ لُوطٖ
Àti pé ìjọ ’Ibrọhīm àti ìjọ (Ànábì) Lūt,
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَأَصۡحَٰبُ مَدۡيَنَۖ وَكُذِّبَ مُوسَىٰۖ فَأَمۡلَيۡتُ لِلۡكَٰفِرِينَ ثُمَّ أَخَذۡتُهُمۡۖ فَكَيۡفَ كَانَ نَكِيرِ
àti àwọn ará ìlú Mọdyan (àwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀). Wọ́n tún pe (Ànábì) Mūsā ní òpùrọ́. Mo sì lọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
فَكَأَيِّن مِّن قَرۡيَةٍ أَهۡلَكۡنَٰهَا وَهِيَ ظَالِمَةٞ فَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَبِئۡرٖ مُّعَطَّلَةٖ وَقَصۡرٖ مَّشِيدٍ
Nítorí náà, mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí; àwọn ilé wọn dàwó lulẹ̀ pẹ̀lú òrùlé rẹ̀. (Mélòó mélòó nínú) kànǹga tí wọ́n ti patì (nípasẹ̀ ìparun) àti ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì oníbíríkì (tó ti dahoro)!
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَتَكُونَ لَهُمۡ قُلُوبٞ يَعۡقِلُونَ بِهَآ أَوۡ ءَاذَانٞ يَسۡمَعُونَ بِهَاۖ فَإِنَّهَا لَا تَعۡمَى ٱلۡأَبۡصَٰرُ وَلَٰكِن تَعۡمَى ٱلۡقُلُوبُ ٱلَّتِي فِي ٱلصُّدُورِ
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n sì ní àwọn ọkàn tí wọ́n máa fi ṣe làákàyè tàbí àwọn etí tí wọn máa fi gbọ́rọ̀? Dájúdájú àwọn ojú kò fọ́, ṣùgbọ́n àwọn ọkàn tó wà nínú igbá-àyà ló ń fọ́.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَيَسۡتَعۡجِلُونَكَ بِٱلۡعَذَابِ وَلَن يُخۡلِفَ ٱللَّهُ وَعۡدَهُۥۚ وَإِنَّ يَوۡمًا عِندَ رَبِّكَ كَأَلۡفِ سَنَةٖ مِّمَّا تَعُدُّونَ
Wọ́n sì ń kán ọ lójú fún ìyà náà. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Dájúdájú ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún nínú ohun tí ẹ̀ ń kà (ní òǹkà).[1]
1. Fífa ọjọ́ kan gùn kò ní òpin, bí Allāhu bá ṣe fẹ́ ni. Nítorí náà, ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Allāhu lè jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún tiwa, ó sì lè jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta) tiwa (50,000) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَكَأَيِّن مِّن قَرۡيَةٍ أَمۡلَيۡتُ لَهَا وَهِيَ ظَالِمَةٞ ثُمَّ أَخَذۡتُهَا وَإِلَيَّ ٱلۡمَصِيرُ
Mélòó mélòó nínú ìlú tí Mo lọ́ lára, tí wọ́n jẹ́ alábòsí. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّمَآ أَنَا۠ لَكُمۡ نَذِيرٞ مُّبِينٞ
Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, èmi mà ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín.”
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
فَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَرِزۡقٞ كَرِيمٞ
Nítorí náà, àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَٱلَّذِينَ سَعَوۡاْ فِيٓ ءَايَٰتِنَا مُعَٰجِزِينَ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَحِيمِ
Àwọn tó ṣe iṣẹ́ (burúkú) nípa àwọn āyah Wa, tí wọ́n ń dá àwọn ènìyàn ní agara (láti tẹ̀lé àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì lérò pé àwọn máa mórí bọ́ lọ́dọ̀ Allāhu); àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رَّسُولٖ وَلَا نَبِيٍّ إِلَّآ إِذَا تَمَنَّىٰٓ أَلۡقَى ٱلشَّيۡطَٰنُ فِيٓ أُمۡنِيَّتِهِۦ فَيَنسَخُ ٱللَّهُ مَا يُلۡقِي ٱلشَّيۡطَٰنُ ثُمَّ يُحۡكِمُ ٱللَّهُ ءَايَٰتِهِۦۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ
A kò rán Òjíṣẹ́ kan tàbí Ànábì kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, aṣ-Ṣaetọ̄n máa ju (n̄ǹkan) sínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu yóò pa ohun tí aṣ-Ṣaetọ̄n ń jù sínú rẹ̀ rẹ́. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo àwọn āyah Rẹ̀ rinlẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. [1]
1. Āyah yìí ń fi rinlẹ̀ pé, kò sí ṣaetọ̄n kan tí ó lè gba āyah mọ́ Òjíṣẹ́ Allāhu lẹ́nu.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
لِّيَجۡعَلَ مَا يُلۡقِي ٱلشَّيۡطَٰنُ فِتۡنَةٗ لِّلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ وَٱلۡقَاسِيَةِ قُلُوبُهُمۡۗ وَإِنَّ ٱلظَّٰلِمِينَ لَفِي شِقَاقِۭ بَعِيدٖ
(Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè fi ohun tí aṣ-Ṣaetọ̄n ń jù (sínú rẹ̀) ṣe àdánwò fún àwọn tí àìsàn ń bẹ nínú ọkàn wọn àti àwọn tí ọkàn wọn le. Dájúdájú àwọn alábòsí sì wà nínú ìyapa tó jìnnà (sí òdodo).
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَلِيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَيُؤۡمِنُواْ بِهِۦ فَتُخۡبِتَ لَهُۥ قُلُوبُهُمۡۗ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهَادِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
(Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní ìmọ̀ lè mọ̀ pé dájúdájú al-Ƙur’ān jẹ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, wọn yó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, ọkàn wọn yó sì balẹ̀ sí i. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fi ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām).
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَلَا يَزَالُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي مِرۡيَةٖ مِّنۡهُ حَتَّىٰ تَأۡتِيَهُمُ ٱلسَّاعَةُ بَغۡتَةً أَوۡ يَأۡتِيَهُمۡ عَذَابُ يَوۡمٍ عَقِيمٍ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kò sì níí yé wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ títí Àkókò náà yóò fi dé bá wọn ní òjijì tàbí (títí) ìyà ọjọ́ ìparun yóò fi dé bá wọn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ٱلۡمُلۡكُ يَوۡمَئِذٖ لِّلَّهِ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡۚ فَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ
Gbogbo ìjọba ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Allāhu tí Ó máa ṣèdájọ́ láààrin wọn. Nítorí náà, àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا فَأُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ
Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́; àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ثُمَّ قُتِلُوٓاْ أَوۡ مَاتُواْ لَيَرۡزُقَنَّهُمُ ٱللَّهُ رِزۡقًا حَسَنٗاۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهُوَ خَيۡرُ ٱلرَّٰزِقِينَ
Àwọn tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, lẹ́yìn náà, tí wọ́n pa wọ́n tàbí tí wọ́n kú; dájúdájú Allāhu yóò pèsè fún wọn ní ìpèsè tó dára. Dájúdájú Allāhu, Ó mà l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
لَيُدۡخِلَنَّهُم مُّدۡخَلٗا يَرۡضَوۡنَهُۥۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَعَلِيمٌ حَلِيمٞ
Dájúdájú (Allāhu) yóò fi wọ́n sínú àyè kan tí wọn yóò yọ́nú sí. Dájúdájú Allāhu mà ni Onímọ̀, Aláfaradà.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
۞ ذَٰلِكَۖ وَمَنۡ عَاقَبَ بِمِثۡلِ مَا عُوقِبَ بِهِۦ ثُمَّ بُغِيَ عَلَيۡهِ لَيَنصُرَنَّهُ ٱللَّهُۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٞ
Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́, lẹ́yìn náà tí wọ́n bá tún ṣàbòsí sí i, dájúdájú Allāhu yóò ṣàrànṣe fún un. Dájúdájú Allāhu mà ni Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ يُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِ وَأَنَّ ٱللَّهَ سَمِيعُۢ بَصِيرٞ
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ń fi òru bọ inú ọ̀sán, Ó sì ń fi ọ̀sán bọ inú òru. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ هُوَ ٱلۡبَٰطِلُ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ó ga, Ó tóbi.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَتُصۡبِحُ ٱلۡأَرۡضُ مُخۡضَرَّةًۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَطِيفٌ خَبِيرٞ
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, ilẹ̀ sì máa lọ́ràá wá? Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ
TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun mà ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ سَخَّرَ لَكُم مَّا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَٱلۡفُلۡكَ تَجۡرِي فِي ٱلۡبَحۡرِ بِأَمۡرِهِۦ وَيُمۡسِكُ ٱلسَّمَآءَ أَن تَقَعَ عَلَى ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا بِإِذۡنِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِٱلنَّاسِ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٞ
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ fún yín, àti ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn nínú agbami odò pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀, Ó ń mú sánmọ̀ dání tí kò fi jábọ́ sórí ilẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Dájúdájú Allāhu mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَحۡيَاكُمۡ ثُمَّ يُمِيتُكُمۡ ثُمَّ يُحۡيِيكُمۡۗ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَكَفُورٞ
Òun sì ni Ẹni tó ṣe yín ni alààyè, lẹ́yìn náà Ó ń sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà Ó máa sọ yín di alààyè. Dájúdájú ènìyàn mà ni aláìmoore.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
لِّكُلِّ أُمَّةٖ جَعَلۡنَا مَنسَكًا هُمۡ نَاسِكُوهُۖ فَلَا يُنَٰزِعُنَّكَ فِي ٱلۡأَمۡرِۚ وَٱدۡعُ إِلَىٰ رَبِّكَۖ إِنَّكَ لَعَلَىٰ هُدٗى مُّسۡتَقِيمٖ
Ìjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe jà ọ́ níyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Kí o sì pèpè sọ́dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú o kúkú wà lójú ọ̀nà tààrà. [1]
1. Gbólóhùn yìí “Ìjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò.” Ìyẹn nínú ’Islām tí Allāhu fi rán Òjíṣẹ́ wọn sí wọn nítorí pé, ’Islām ni ẹ̀sìn gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjísẹ́ Olọ́hun, àmọ́ ìlànà ìjọ́sìn kan láààrin ìjọ Òjíṣẹ́ kan sí òmíràn lè yàtọ̀.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَإِن جَٰدَلُوكَ فَقُلِ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا تَعۡمَلُونَ
Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ nígbà náà pé: “Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ٱللَّهُ يَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ
Allāhu máa ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.”
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
أَلَمۡ تَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّ ذَٰلِكَ فِي كِتَٰبٍۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ
Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Dájúdájú (àkọsílẹ̀) ìyẹn wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَمۡ يُنَزِّلۡ بِهِۦ سُلۡطَٰنٗا وَمَا لَيۡسَ لَهُم بِهِۦ عِلۡمٞۗ وَمَا لِلظَّٰلِمِينَ مِن نَّصِيرٖ
Wọ́n sì ń jọ́sìn fún ohun míiràn lẹ́yìn Allāhu tí (Allāhu) kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún àti ohun tí kò sí ìmọ̀ kan fún wọn lórí rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ تَعۡرِفُ فِي وُجُوهِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلۡمُنكَرَۖ يَكَادُونَ يَسۡطُونَ بِٱلَّذِينَ يَتۡلُونَ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِنَاۗ قُلۡ أَفَأُنَبِّئُكُم بِشَرّٖ مِّن ذَٰلِكُمُۚ ٱلنَّارُ وَعَدَهَا ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ
Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, o máa rí ohun tí ẹ̀mí kọ̀ (ìkorò-ojú) nínú ojú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́; wọn sì fẹ́ẹ̀ fọwọ́ ìnira kan àwọn tí ń ké àwọn āyah Wa fún wọn. Sọ pé: “Ṣé kí n̄g fún yín ní ìró ohun tó burú ju ìyẹn? Iná tí Allāhu ṣèlérí rẹ̀ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ni. Ìkángun náà sì burú.”
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ضُرِبَ مَثَلٞ فَٱسۡتَمِعُواْ لَهُۥٓۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَن يَخۡلُقُواْ ذُبَابٗا وَلَوِ ٱجۡتَمَعُواْ لَهُۥۖ وَإِن يَسۡلُبۡهُمُ ٱلذُّبَابُ شَيۡـٔٗا لَّا يَسۡتَنقِذُوهُ مِنۡهُۚ ضَعُفَ ٱلطَّالِبُ وَٱلۡمَطۡلُوبُ
Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi àkàwé kan lélẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ́tí sí i. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, wọn kò lè dá eṣinṣin kan, wọn ìbàá para pọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tí eṣinṣin náà bá sì gba kiní kan mọ́ wọn lọ́wọ́, wọn kò lè gbà á padà lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀lẹ ni ẹni tí ń wá n̄ǹkan (lọ́dọ̀ òrìṣà) àti (òrìṣà) tí wọ́n ń wá n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
مَا قَدَرُواْ ٱللَّهَ حَقَّ قَدۡرِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ
Wọn kò bu ọ̀wọ̀ fún Allāhu ní ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí I. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
ٱللَّهُ يَصۡطَفِي مِنَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ رُسُلٗا وَمِنَ ٱلنَّاسِۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعُۢ بَصِيرٞ
Allāhu l’Ó ń ṣa àwọn kan lẹ́ṣà (láti jẹ́) Òjíṣẹ́ nínú àwọn mọlāika àti nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.[1]
1. Kíyè sí i! Jíjẹ́ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Allāhu ti wá sí òpin torí pé Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni òpin gbogbo wọn ní ìbámu sí sūrah al-’Ahzāb; 33:40.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ
Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱرۡكَعُواْ وَٱسۡجُدُواْۤ وَٱعۡبُدُواْ رَبَّكُمۡ وَٱفۡعَلُواْ ٱلۡخَيۡرَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ۩
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ dáwọ́tẹ orúnkún (lórí ìrun), ẹ forí kanlẹ̀, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, kí ẹ sì ṣe rere nítorí kí ẹ lè jèrè.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
وَجَٰهِدُواْ فِي ٱللَّهِ حَقَّ جِهَادِهِۦۚ هُوَ ٱجۡتَبَىٰكُمۡ وَمَا جَعَلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلدِّينِ مِنۡ حَرَجٖۚ مِّلَّةَ أَبِيكُمۡ إِبۡرَٰهِيمَۚ هُوَ سَمَّىٰكُمُ ٱلۡمُسۡلِمِينَ مِن قَبۡلُ وَفِي هَٰذَا لِيَكُونَ ٱلرَّسُولُ شَهِيدًا عَلَيۡكُمۡ وَتَكُونُواْ شُهَدَآءَ عَلَى ٱلنَّاسِۚ فَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱعۡتَصِمُواْ بِٱللَّهِ هُوَ مَوۡلَىٰكُمۡۖ فَنِعۡمَ ٱلۡمَوۡلَىٰ وَنِعۡمَ ٱلنَّصِيرُ
Ẹ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ẹ lè gbà jagun fún Un. Òun l’Ó ṣà yín lẹ́ṣà, kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn. (Ẹ tẹ̀lé) ẹ̀sìn bàbá yín (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. (Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí nítorí kí Òjíṣẹ́ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún yín àti nítorí kí ẹ̀yin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn.[1] Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh, kí ẹ sì bá Allāhu dúró. Òun ni Aláàbò yín. Ó dára ni Aláàbò. Ó sì dára ní Alárànṣe.
1. Ọ̀kan pàtàkì nínú ẹ̀rí tó ń fi rinlẹ̀ pé, Allāhu kò fi ẹ̀sìn nasrọ̄niyyah tàbí ẹ̀sìn yahudiyyah rán Òjíṣẹ́ kan kan rí ni gbólóhùn “(Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí”.
ตัฟสีรต่างๆ​ ภาษาอาหรับ:
 
แปลความหมาย​ สูเราะฮ์: Al-Hajj
สารบัญสูเราะฮ์ หมายเลข​หน้า​
 
แปล​ความหมาย​อัลกุรอาน​ - คำแปลโยรูบา - สารบัญ​คำแปล

การแปลความหมายอัลกุรอานเป็นภาษาโยรูบาโดย เชค อบูเราะหีมะฮ์ มิคาเอล ไอควีนีย์ จัดพิมพ์ในปี ฮ.ศ. 1432

ปิด