Check out the new design

Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail * - Indise ng mga Salin

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Salin ng mga Kahulugan Surah: Al-Mā’idah   Ayah:
سَمَّٰعُونَ لِلۡكَذِبِ أَكَّٰلُونَ لِلسُّحۡتِۚ فَإِن جَآءُوكَ فَٱحۡكُم بَيۡنَهُمۡ أَوۡ أَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡۖ وَإِن تُعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ فَلَن يَضُرُّوكَ شَيۡـٔٗاۖ وَإِنۡ حَكَمۡتَ فَٱحۡكُم بَيۡنَهُم بِٱلۡقِسۡطِۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُقۡسِطِينَ
Wọ́n ń tẹ́tí gbọ́ irọ́, wọ́n sì ń jẹ n̄ǹkan èèwọ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá wá bá ọ, ṣèdájọ́ láààrin wọn tàbí kí o ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn kò lè kó ìnira kan kan bá ọ. Tí o bá sì fẹ́ dájọ́, ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn onídéédé.
Ang mga Tafsir na Arabe:
وَكَيۡفَ يُحَكِّمُونَكَ وَعِندَهُمُ ٱلتَّوۡرَىٰةُ فِيهَا حُكۡمُ ٱللَّهِ ثُمَّ يَتَوَلَّوۡنَ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَۚ وَمَآ أُوْلَٰٓئِكَ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Báwo ni wọ́n á ṣe fi ọ́ ṣe adájọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé at-Taorāh wà lọ́dọ̀ wọn. Ìdájọ́ Allāhu sì wà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n ń pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
Ang mga Tafsir na Arabe:
إِنَّآ أَنزَلۡنَا ٱلتَّوۡرَىٰةَ فِيهَا هُدٗى وَنُورٞۚ يَحۡكُمُ بِهَا ٱلنَّبِيُّونَ ٱلَّذِينَ أَسۡلَمُواْ لِلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلرَّبَّٰنِيُّونَ وَٱلۡأَحۡبَارُ بِمَا ٱسۡتُحۡفِظُواْ مِن كِتَٰبِ ٱللَّهِ وَكَانُواْ عَلَيۡهِ شُهَدَآءَۚ فَلَا تَخۡشَوُاْ ٱلنَّاسَ وَٱخۡشَوۡنِ وَلَا تَشۡتَرُواْ بِـَٔايَٰتِي ثَمَنٗا قَلِيلٗاۚ وَمَن لَّمۡ يَحۡكُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Dájúdájú Àwa sọ at-Taorāh kalẹ̀. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ ń bẹ nínú rẹ̀. Àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí ń fi ṣe ìdájọ́ fún àwọn tó di yẹhudi. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin ẹ̀sìn (ń fi ṣe ìdájọ́) nítorí ohun tí A fún wọn ṣọ́ nínú tírà Allāhu. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe páyà ènìyàn. Ẹ páyà Mi. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó kékeré. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni aláìgbàgbọ́.
Ang mga Tafsir na Arabe:
وَكَتَبۡنَا عَلَيۡهِمۡ فِيهَآ أَنَّ ٱلنَّفۡسَ بِٱلنَّفۡسِ وَٱلۡعَيۡنَ بِٱلۡعَيۡنِ وَٱلۡأَنفَ بِٱلۡأَنفِ وَٱلۡأُذُنَ بِٱلۡأُذُنِ وَٱلسِّنَّ بِٱلسِّنِّ وَٱلۡجُرُوحَ قِصَاصٞۚ فَمَن تَصَدَّقَ بِهِۦ فَهُوَ كَفَّارَةٞ لَّهُۥۚ وَمَن لَّمۡ يَحۡكُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ
A sì ṣe é ní òfin sínú rẹ̀ fún wọn pé dájúdájú ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, imú fún imú, etí fún etí àti eyín fún eyín. Òfin ẹ̀san gbígbà sì wà fún ojú-ọgbẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sí yọ̀ǹda ìgbẹ̀san, ó sì máa jẹ́ pípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ fún un. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí.
Ang mga Tafsir na Arabe:
 
Salin ng mga Kahulugan Surah: Al-Mā’idah
Indise ng mga Surah Numero ng Pahina
 
Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail - Indise ng mga Salin

Salin ni Abu Rahima Mikhail Aikweiny.

Isara