Check out the new design

Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail * - Indise ng mga Salin

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Salin ng mga Kahulugan Surah: Al-Mā’idah   Ayah:
وَقَالَتِ ٱلۡيَهُودُ وَٱلنَّصَٰرَىٰ نَحۡنُ أَبۡنَٰٓؤُاْ ٱللَّهِ وَأَحِبَّٰٓؤُهُۥۚ قُلۡ فَلِمَ يُعَذِّبُكُم بِذُنُوبِكُمۖ بَلۡ أَنتُم بَشَرٞ مِّمَّنۡ خَلَقَۚ يَغۡفِرُ لِمَن يَشَآءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَآءُۚ وَلِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَاۖ وَإِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ
Àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ wí pé: “Àwa ni ọmọ Allāhu àti olólùfẹ́ Rẹ̀.” Sọ pé: “Kí ni ìdí tí Ó ṣe ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín nígbà náà?” Rárá (kò rí bí ẹ ṣe wí, àmọ́) abara ni yín nínú àwọn tí Ó ṣẹ̀dá. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Ang mga Tafsir na Arabe:
يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ قَدۡ جَآءَكُمۡ رَسُولُنَا يُبَيِّنُ لَكُمۡ عَلَىٰ فَتۡرَةٖ مِّنَ ٱلرُّسُلِ أَن تَقُولُواْ مَا جَآءَنَا مِنۢ بَشِيرٖ وَلَا نَذِيرٖۖ فَقَدۡ جَآءَكُم بَشِيرٞ وَنَذِيرٞۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Ẹ̀yin onítírà, dájúdájú Òjíṣẹ́ Wa ti dé ba yín, tí ó ń ṣe àlàyé (ọ̀rọ̀) fún yín lẹ́yìn àsìkò tí A ti dá àwọn Òjísẹ́ dúró, nítorí kí ẹ má ṣe wí pé: “Kò sí oníròó ìdùnnú tàbí olùkìlọ̀ kan tí ó wá bá wa.” Nítorí náà, dájúdájú oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ kan ti wá ba yín. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ang mga Tafsir na Arabe:
وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦ يَٰقَوۡمِ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ جَعَلَ فِيكُمۡ أَنۢبِيَآءَ وَجَعَلَكُم مُّلُوكٗا وَءَاتَىٰكُم مَّا لَمۡ يُؤۡتِ أَحَدٗا مِّنَ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fún yín, nígbà tí Ó fi àwọn Ànábì sáààrin yín, tí Ó ṣe yín ní ọba, tí Ó tún fún yín ní n̄ǹkan tí kò fún ẹnì kan rí ní àgbáyé (lásìkò tiyín).
Ang mga Tafsir na Arabe:
يَٰقَوۡمِ ٱدۡخُلُواْ ٱلۡأَرۡضَ ٱلۡمُقَدَّسَةَ ٱلَّتِي كَتَبَ ٱللَّهُ لَكُمۡ وَلَا تَرۡتَدُّواْ عَلَىٰٓ أَدۡبَارِكُمۡ فَتَنقَلِبُواْ خَٰسِرِينَ
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ wọ orí ilẹ̀ mímọ́ tí Allāhu pa láṣẹ fún yín. Ẹ má se padà sẹ́yìn[1], nítorí kí ẹ má baà padà di ẹni òfò.
[1] Ẹ má ṣe sá fún jíja àwọn òmìrán lógun.
Ang mga Tafsir na Arabe:
قَالُواْ يَٰمُوسَىٰٓ إِنَّ فِيهَا قَوۡمٗا جَبَّارِينَ وَإِنَّا لَن نَّدۡخُلَهَا حَتَّىٰ يَخۡرُجُواْ مِنۡهَا فَإِن يَخۡرُجُواْ مِنۡهَا فَإِنَّا دَٰخِلُونَ
Wọ́n wí pé: “Mūsā, dájúdájú ìjọ ajẹni-nípá wà nínú ìlú náà. Dájúdájú àwa kò sì níí wọ inú rẹ̀ títí wọn yóò fi jáde kúrò nínú rẹ̀. Tí wọ́n bá jáde kúrò nínú rẹ̀, àwa máa wọ inú rẹ̀ nígbà náà.”
Ang mga Tafsir na Arabe:
قَالَ رَجُلَانِ مِنَ ٱلَّذِينَ يَخَافُونَ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمَا ٱدۡخُلُواْ عَلَيۡهِمُ ٱلۡبَابَ فَإِذَا دَخَلۡتُمُوهُ فَإِنَّكُمۡ غَٰلِبُونَۚ وَعَلَى ٱللَّهِ فَتَوَكَّلُوٓاْ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ
Àwọn ọkùnrin méjì kan nínú àwọn tí ń páyà (Allāhu) - Allāhu sì kẹ́ àwọn méjèèjì[1] - wọ́n sọ pé: “Ẹ gba ẹnu bodè wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n. Tí ẹ bá wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n, dájúdájú ẹ máa borí wọn. Allāhu sì ni kí ẹ gbáralé, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
[1] Allāhu ṣe ìtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀ ní ìrọ̀rùn fún àwọn méjèèjì. Èyí ni ìkẹ́ Allāhu lórí àwọn méjèèjì.
Ang mga Tafsir na Arabe:
 
Salin ng mga Kahulugan Surah: Al-Mā’idah
Indise ng mga Surah Numero ng Pahina
 
Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail - Indise ng mga Salin

Salin ni Abu Rahima Mikhail Aikweiny.

Isara