Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀. Àti pé dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbèéraga.
(Àwọn ni) àwọn tí mọlāika ń pa nígbà tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn lọ́wọ́. Ní àsìkò yìí ni wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (wọ́n sì wí pé): “Àwa kò ṣe iṣẹ́ aburú kan kan.” Bẹ́ẹ̀ ni (irọ́ lẹ́pa)! Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ṣé wọ́n ń retí ohun kan yàtọ̀ sí pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí àṣẹ Olúwa rẹ dé? Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ti ṣe. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Wọ́n ń fi ìpín kan nínú ohun tí A pèsè fún wọn lélẹ̀ fún ohun tí wọn kò nímọ̀ nípa rẹ̀.[1] Mo fi Allāhu búra, dájúdájú wọn yóò bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń dá ní àdápa irọ́.
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n ń pe àwọn n̄ǹkan kan ní n̄ǹkan òrìṣà bí àpẹ̀ẹrẹ, wọ́n ń pe àwọn ẹran kan ní ẹran òrìṣà, wọ́n sì ń fi àwọn kan rúbọ fún àwọn òrìṣà wọn.
Wọ́n tún ń fi (bíbí) àwọn ọmọbìnrin lélẹ̀ fún Allāhu - Mímọ́ ni fún Un (kò bímọ). - Wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń fẹ́ lélẹ̀ fún tiwọn!
Wọ́n ń fi (ọmọbìnrin) - n̄ǹkan tí wọn kórira - lélẹ̀ fún Allāhu. Ahọ́n wọn sì ń ròyìn irọ́ pé dájúdájú rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni tàwọn. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Iná ni tiwọn. Àti pé dájúdájú wọ́n máa pa wọ́n tì sínú rẹ̀ ni.
Allāhu fi ara Rẹ̀ búra,[1] dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. Nígbà náà, aṣ-Ṣaetọ̄n ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn; òun sì ni ọ̀rẹ́ wọn ní òní. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
1. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi Ara Rẹ̀ búra. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún Un láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Òun l’Ó ni Ara Rẹ̀.
A kò sọ Tírà náà kalẹ̀ fún ọ bí kò ṣe pé kí o lè ṣàlàyé fún wọn ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí;[1] ó sì jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
Allāhu l’Ó ṣoore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan nínú arísìkí. Bẹ́ẹ̀, àwọn tí A fún ní oore àjùlọ, wọn kì í fún àwọn ẹrú wọn ní arísìkí wọn, nítorí kí wọ́n má baà wà ní dọ́gban̄dọ́gba pẹ̀lú wọn níbi arísìkí![1] Nítorí náà, ṣe ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yóò máa takò?
1. Àkàwé kan nìyí tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi lélẹ̀ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti pe làákàyè wọn sí ohun tí wọn kò lè gbà, àmọ́ tí wọ́n ń fi lọ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -.
Dípò (kí wọ́n jọ́sìn fún) Allāhu, wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò ní ìkápá arísìkí kan kan fún wọn nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; wọn kò sì lágbára (láti ṣe n̄ǹkan kan).
Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ẹrú kan tí ó wà lábẹ́ ọ̀gá, tí kò sì lè dá n̄ǹkan kan ṣe àti ẹni tí A fún ní arísìkí tó dára láti ọ̀dọ̀ wa, tí ó sì ń ná nínú rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Ṣé wọ́n dọ́gba bí?[1] Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
(Rántí) ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí kan dìde nínú gbogbo ìjọ (àwọn Ànábì), lẹ́yìn náà, A ò níí yọ̀ǹda (àròyé ṣíṣe) fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti padà ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A ó ṣe àlékún ìyà lórí ìyà fún wọn ni nítorí pé wọ́n ń ṣèbàjẹ́.
Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ yín máa tán. Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì máa wà títí láéláé. Dájúdájú A sì máa san àwọn tó ṣe sùúrù ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé tó dára. Dájúdájú A sì máa san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Àti pé A ṣe ohun tí A sọ fún ọ ṣíwájú ní èèwọ̀ fún àwọn tó di yẹhudi.[1] A kò sì ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.
Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jẹ́ aṣíwájú-àwòkọ́ṣe-rere, olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì jẹ́ ara àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Àwọn tí wọ́n ṣe (àgbéga) ọjọ́ Sabt fún ni àwọn tó yapa-ẹnu lórí rẹ̀.[1] Dájúdájú Olúwa rẹ yóò kúkú ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
1. Yíyapa-ẹnu tí àwọn yẹhudi yapa-ẹnu lórí ṣíṣe àgbéga fún ọjọ́ Jímọ̀, tí wọ́n sì fi ọjọ́ Sabt dípò rẹ̀, l’ó ṣokùnfà bí ọjọ́ náà ṣe di dandan fún ọ̀wọ́ wọn nìkan láti ṣe àgbéga rẹ̀.
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
Kết quả tìm kiếm:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".