पवित्र कुरअानको अर्थको अनुवाद - योरुबा अनुवाद * - अनुवादहरूको सूची

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

अर्थको अनुवाद सूरः: सूरतुल् मअारिज   श्लोक:

Suuratul-Mahaarij

سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابٖ وَاقِعٖ
Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀
अरबी व्याख्याहरू:
لِّلۡكَٰفِرِينَ لَيۡسَ لَهُۥ دَافِعٞ
sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́
अरबी व्याख्याहरू:
مِّنَ ٱللَّهِ ذِي ٱلۡمَعَارِجِ
lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga.
अरबी व्याख्याहरू:
تَعۡرُجُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٖ كَانَ مِقۡدَارُهُۥ خَمۡسِينَ أَلۡفَ سَنَةٖ
Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).¹
1. Ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta ọdún (50,000). Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hajj; 22:47.
अरबी व्याख्याहरू:
فَٱصۡبِرۡ صَبۡرٗا جَمِيلًا
Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù tó rẹwà.
अरबी व्याख्याहरू:
إِنَّهُمۡ يَرَوۡنَهُۥ بَعِيدٗا
Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun tó jìnnà.
अरबी व्याख्याहरू:
وَنَرَىٰهُ قَرِيبٗا
A sì ń wò ó ní ohun tó súnmọ́.
अरबी व्याख्याहरू:
يَوۡمَ تَكُونُ ٱلسَّمَآءُ كَٱلۡمُهۡلِ
(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí ògéré epo gbígbóná,
अरबी व्याख्याहरू:
وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ
àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun,
अरबी व्याख्याहरू:
وَلَا يَسۡـَٔلُ حَمِيمٌ حَمِيمٗا
ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀).
अरबी व्याख्याहरू:
يُبَصَّرُونَهُمۡۚ يَوَدُّ ٱلۡمُجۡرِمُ لَوۡ يَفۡتَدِي مِنۡ عَذَابِ يَوۡمِئِذِۭ بِبَنِيهِ
Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.
अरबी व्याख्याहरू:
وَصَٰحِبَتِهِۦ وَأَخِيهِ
Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀,
अरबी व्याख्याहरू:
وَفَصِيلَتِهِ ٱلَّتِي تُـٔۡوِيهِ
àti àwọn ẹbí rẹ̀ tó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé,
अरबी व्याख्याहरू:
وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا ثُمَّ يُنجِيهِ
àti gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).
अरबी व्याख्याहरू:
كَلَّآۖ إِنَّهَا لَظَىٰ
Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná tó ń jò fòfò).
अरबी व्याख्याहरू:
نَزَّاعَةٗ لِّلشَّوَىٰ
Ó máa bó awọ orí tòró.
अरबी व्याख्याहरू:
تَدۡعُواْ مَنۡ أَدۡبَرَ وَتَوَلَّىٰ
(Iná) yó máa ké sí ẹni tó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i,
अरबी व्याख्याहरू:
وَجَمَعَ فَأَوۡعَىٰٓ
ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn).
अरबी व्याख्याहरू:
۞ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ خُلِقَ هَلُوعًا
Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà.
अरबी व्याख्याहरू:
إِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ جَزُوعٗا
Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó.
अरबी व्याख्याहरू:
وَإِذَا مَسَّهُ ٱلۡخَيۡرُ مَنُوعًا
Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì ba oore, ó máa yahun.
अरबी व्याख्याहरू:
إِلَّا ٱلۡمُصَلِّينَ
Àyàfi àwọn olùkírun,
अरबी व्याख्याहरू:
ٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ دَآئِمُونَ
àwọn tí wọ́n dúnnímọ́ ìrun wọn;
अरबी व्याख्याहरू:
وَٱلَّذِينَ فِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقّٞ مَّعۡلُومٞ
àwọn tó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn
अरबी व्याख्याहरू:
لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ
sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún;
अरबी व्याख्याहरू:
وَٱلَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ
àwọn tó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo;
अरबी व्याख्याहरू:
وَٱلَّذِينَ هُم مِّنۡ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشۡفِقُونَ
àwọn tó ń páyà ìyà Olúwa wọn,
अरबी व्याख्याहरू:
إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمۡ غَيۡرُ مَأۡمُونٖ
dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí;
अरबी व्याख्याहरू:
وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِفُرُوجِهِمۡ حَٰفِظُونَ
àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
अरबी व्याख्याहरू:
إِلَّا عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَإِنَّهُمۡ غَيۡرُ مَلُومِينَ
àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú,
अरबी व्याख्याहरू:
فَمَنِ ٱبۡتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡعَادُونَ
nítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùtayọ-ẹnu ààlà;
अरबी व्याख्याहरू:
وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِأَمَٰنَٰتِهِمۡ وَعَهۡدِهِمۡ رَٰعُونَ
àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn;
अरबी व्याख्याहरू:
وَٱلَّذِينَ هُم بِشَهَٰدَٰتِهِمۡ قَآئِمُونَ
àwọn tó ń dúró ti ìjẹ́rìí (òdodo) wọn;
अरबी व्याख्याहरू:
وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ يُحَافِظُونَ
àti àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn.
अरबी व्याख्याहरू:
أُوْلَٰٓئِكَ فِي جَنَّٰتٖ مُّكۡرَمُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
अरबी व्याख्याहरू:
فَمَالِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قِبَلَكَ مُهۡطِعِينَ
Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ,
अरबी व्याख्याहरू:
عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ عِزِينَ
tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)?
अरबी व्याख्याहरू:
أَيَطۡمَعُ كُلُّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُمۡ أَن يُدۡخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٖ
Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni?
अरबी व्याख्याहरू:
كَلَّآۖ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّمَّا يَعۡلَمُونَ
Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀.
अरबी व्याख्याहरू:
فَلَآ أُقۡسِمُ بِرَبِّ ٱلۡمَشَٰرِقِ وَٱلۡمَغَٰرِبِ إِنَّا لَقَٰدِرُونَ
Nítorí náà, Èmi ń fi Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn¹ búra, dájúdájú Àwa ni Alágbára
1. Ìyẹn ni pé, Èmi, Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn ń fi ara Mi búra. Wòóore: Èròǹgbà Allāhu pẹ̀lú “mọṣriƙ” àti “mọgrib” nínú sūrah al-Muzzammil; 73:9 ni agbègbè ibùyọ òòrùn àti agbègbè ibùwọ̀ òòrùn. Èròǹgbà Allāhu pẹ̀lú “mọṣriƙọen” nínú sūrah ar-Rahmọ̄n; 55:17 ni ibùyọ òòrùn lásìkò ẹ̀rùn àti ibùyọ òòrùn lásìkò òjò. Bákan náà, “mọgribaen” ibùwọ̀ òòrùn lásìkò ẹ̀rùn àti ibùwọ̀ òòrùn lásìkò òjò. Bákan náà, èròǹgbà Allāhu pẹ̀lú “mọṣāriƙ àti mọgārib” ni àwọn ọgọ́sàn-án ibùyọ òòrùn àti ọgọ́sàn-án ibùwọ̀ òòrùn. (Tafsīr Bagawiy)
अरबी व्याख्याहरू:
عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ خَيۡرٗا مِّنۡهُمۡ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ
láti yí (ìrísí wọn) padà (ní ọjọ́ Àjíǹde) sí (ìrísí kan) tó máa dára ju (ìrísí) wọn (tayé). Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara.¹
1. Ẹ tún wo sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:60-61 àti sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:3-4.
अरबी व्याख्याहरू:
فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
अरबी व्याख्याहरू:
يَوۡمَ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ سِرَاعٗا كَأَنَّهُمۡ إِلَىٰ نُصُبٖ يُوفِضُونَ
Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.
अरबी व्याख्याहरू:
خَٰشِعَةً أَبۡصَٰرُهُمۡ تَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٞۚ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمُ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ
Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
अरबी व्याख्याहरू:
 
अर्थको अनुवाद सूरः: सूरतुल् मअारिज
अध्यायहरूको (सूरःहरूको) सूची رقم الصفحة
 
पवित्र कुरअानको अर्थको अनुवाद - योरुबा अनुवाद - अनुवादहरूको सूची

पवित्र कुर्आनको अर्थको योरुबा भाषामा अनुवाद, अनुवादक शैख अबू रहीमा मिकाईल एकविनी, प्रकाशन : १४३२ हिज्री ।

बन्द गर्नुस्