クルアーンの対訳 - ヨルバ語対訳 * - 対訳の目次

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

対訳 章: 引き抜く者章   節:

Suuratun-Naazihaat

وَٱلنَّٰزِعَٰتِ غَرۡقٗا
Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́ búra.
アラビア語 クルアーン注釈:
وَٱلنَّٰشِطَٰتِ نَشۡطٗا
Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo búra.
アラビア語 クルアーン注釈:
وَٱلسَّٰبِحَٰتِ سَبۡحٗا
Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀ búra.
アラビア語 クルアーン注釈:
فَٱلسَّٰبِقَٰتِ سَبۡقٗا
Ó tún fi àwọn mọlāika tó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà búra.
アラビア語 クルアーン注釈:
فَٱلۡمُدَبِّرَٰتِ أَمۡرٗا
Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń ṣètò nínú sánmọ̀ àti ilé ayé pẹ̀lú àṣẹ Allāhu búra.
アラビア語 クルアーン注釈:
يَوۡمَ تَرۡجُفُ ٱلرَّاجِفَةُ
Ní ọjọ́ tí ìmìtìtì máa mi gbogbo ayé tìtì.¹
1. Ìyẹn ní ọjọ́ tí ìfọn àkọ́kọ́ fún òpin ayé máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ohùn igbe tó máa le pin.
アラビア語 クルアーン注釈:
تَتۡبَعُهَا ٱلرَّادِفَةُ
Ohun tí ó máa tẹ̀lé e máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e.¹
1. Ìyẹn ní ọjọ́ tí ìfọn ìkejì fún àjíǹde máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ohùn igbe tó máa le pin.
アラビア語 クルアーン注釈:
قُلُوبٞ يَوۡمَئِذٖ وَاجِفَةٌ
Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.
アラビア語 クルアーン注釈:
أَبۡصَٰرُهَا خَٰشِعَةٞ
Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ.
アラビア語 クルアーン注釈:
يَقُولُونَ أَءِنَّا لَمَرۡدُودُونَ فِي ٱلۡحَافِرَةِ
Wọn yóò wí pé: “Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)?
アラビア語 クルアーン注釈:
أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمٗا نَّخِرَةٗ
Ṣé nígbà tí a ti di eegun tó kẹfun tán?”
アラビア語 クルアーン注釈:
قَالُواْ تِلۡكَ إِذٗا كَرَّةٌ خَاسِرَةٞ
Wọ́n wí pé: “Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni tó pè é ní irọ́.)”
アラビア語 クルアーン注釈:
فَإِنَّمَا هِيَ زَجۡرَةٞ وَٰحِدَةٞ
Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni.
アラビア語 クルアーン注釈:
فَإِذَا هُم بِٱلسَّاهِرَةِ
Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa.
アラビア語 クルアーン注釈:
هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
アラビア語 クルアーン注釈:
إِذۡ نَادَىٰهُ رَبُّهُۥ بِٱلۡوَادِ ٱلۡمُقَدَّسِ طُوًى
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonúfojì mímọ́, Tuwā.
アラビア語 クルアーン注釈:
ٱذۡهَبۡ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ
Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.
アラビア語 クルアーン注釈:
فَقُلۡ هَل لَّكَ إِلَىٰٓ أَن تَزَكَّىٰ
Kí o sì sọ pé: “Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí?
アラビア語 クルアーン注釈:
وَأَهۡدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخۡشَىٰ
Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, kí o sì páyà (Rẹ̀).”
アラビア語 クルアーン注釈:
فَأَرَىٰهُ ٱلۡأٓيَةَ ٱلۡكُبۡرَىٰ
Ó sì fi àmì tó tóbi hàn án.
アラビア語 クルアーン注釈:
فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ
(Àmọ́) ó pè é ní òpùrọ́. Ó sì yapa (rẹ̀).
アラビア語 クルアーン注釈:
ثُمَّ أَدۡبَرَ يَسۡعَىٰ
Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó).
アラビア語 クルアーン注釈:
فَحَشَرَ فَنَادَىٰ
Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì.
アラビア語 クルアーン注釈:
فَقَالَ أَنَا۠ رَبُّكُمُ ٱلۡأَعۡلَىٰ
Ó sì wí pé: “Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ.”
アラビア語 クルアーン注釈:
فَأَخَذَهُ ٱللَّهُ نَكَالَ ٱلۡأٓخِرَةِ وَٱلۡأُولَىٰٓ
Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́).¹
1. Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ náà nìyí, Fir‘aon wí pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èmi kò mọ̀ pé ọlọ́hun kan tún wà lẹ́yìn mi!” Sūrah al-Ƙọsọs; 28:38
アラビア語 クルアーン注釈:
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةٗ لِّمَن يَخۡشَىٰٓ
Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).
アラビア語 クルアーン注釈:
ءَأَنتُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَمِ ٱلسَّمَآءُۚ بَنَىٰهَا
Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ?
アラビア語 クルアーン注釈:
رَفَعَ سَمۡكَهَا فَسَوَّىٰهَا
Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé tó gún régé.
アラビア語 クルアーン注釈:
وَأَغۡطَشَ لَيۡلَهَا وَأَخۡرَجَ ضُحَىٰهَا
Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde.
アラビア語 クルアーン注釈:
وَٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ ذَٰلِكَ دَحَىٰهَآ
Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:29.
アラビア語 クルアーン注釈:
أَخۡرَجَ مِنۡهَا مَآءَهَا وَمَرۡعَىٰهَا
Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀.
アラビア語 クルアーン注釈:
وَٱلۡجِبَالَ أَرۡسَىٰهَا
Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin.
アラビア語 クルアーン注釈:
مَتَٰعٗا لَّكُمۡ وَلِأَنۡعَٰمِكُمۡ
Ìgbádùn ni fún yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
アラビア語 クルアーン注釈:
فَإِذَا جَآءَتِ ٱلطَّآمَّةُ ٱلۡكُبۡرَىٰ
Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé,
アラビア語 クルアーン注釈:
يَوۡمَ يَتَذَكَّرُ ٱلۡإِنسَٰنُ مَا سَعَىٰ
ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun tó ṣe níṣẹ́.
アラビア語 クルアーン注釈:
وَبُرِّزَتِ ٱلۡجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ
Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni tó ríran.
アラビア語 クルアーン注釈:
فَأَمَّا مَن طَغَىٰ
Nítorí náà, ní ti ẹni tó tayọ ẹnu-ààlà,
アラビア語 クルアーン注釈:
وَءَاثَرَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا
tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé,
アラビア語 クルアーン注釈:
فَإِنَّ ٱلۡجَحِيمَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ
dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
アラビア語 クルアーン注釈:
وَأَمَّا مَنۡ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ وَنَهَى ٱلنَّفۡسَ عَنِ ٱلۡهَوَىٰ
Ní ti ẹni tí ó páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀),
アラビア語 クルアーン注釈:
فَإِنَّ ٱلۡجَنَّةَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ
dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
アラビア語 クルアーン注釈:
يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرۡسَىٰهَا
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: “Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀?”
アラビア語 クルアーン注釈:
فِيمَ أَنتَ مِن ذِكۡرَىٰهَآ
Níbo ni ìwọ wà sí ìmọ̀ rẹ̀ ná?¹
1. Ìyẹn ni pé, ìwọ kò lè ní ìmọ̀ ọjọ́ rẹ̀. Ìmọ̀ nípa ọjọ́ wo gan-an ni òpin ayé máa ṣẹlẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti gbogbo ẹ̀dá pátápátá. Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ṣoṣo ni ìmọ̀ rẹ̀ wà. Àmọ́ Allāhu fi àwọn àmì ìṣáájú ọjọ́ náà mọ Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ìyẹn ni àwọn àmì òpin ayé.
アラビア語 クルアーン注釈:
إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَىٰهَآ
Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà.
アラビア語 クルアーン注釈:
إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخۡشَىٰهَا
Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni tó ń páyà rẹ̀.
アラビア語 クルアーン注釈:
كَأَنَّهُمۡ يَوۡمَ يَرَوۡنَهَا لَمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا عَشِيَّةً أَوۡ ضُحَىٰهَا
Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan.
アラビア語 クルアーン注釈:
 
対訳 章: 引き抜く者章
章名の目次 ページ番号
 
クルアーンの対訳 - ヨルバ語対訳 - 対訳の目次

クルアーン・ヨルバ語対訳 - Abu Rahima Mikhail Aikweiny ヒジュラ暦1432年印刷

閉じる